Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Àdúrà Mi Sunwọ̀n Sí i?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Àdúrà Mi Sunwọ̀n Sí i?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Àdúrà Mi Sunwọ̀n Sí i?

“Téèyàn bá ń fẹ́ láti bójú tó ojúṣe rẹ níléèwé, níbi iṣẹ́, láàárín àwọn ọ̀rẹ́ àti nínú ìdílé lọ́nà tó tọ́, nígbà míì èèyàn sábà máa ń gbàgbé ẹni tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn Ọlọ́run.”—Faviola, ọmọ ọdún 15, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

“Ẹ MÁA gbàdúrà láìdabọ̀.” (1 Tẹsalóníkà 5:17) “Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (Fílípì 4:6) Bó bá jẹ́ Kristẹni ni ẹ́, ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn dáadáa. Ó tún ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé àdúrà ni ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó jẹ́ àgbàyanu jù lọ. Rò ó wò ná, kò sígbà tó ò lè bá Ọlọ́run Olódùmarè sọ̀rọ̀, ì báà jẹ́ lọ́sàn-án tàbí lóru! Bíbélì sì sọ pé: “Ó ń gbọ́ tiwa.” a1 Jòhánù 5:14.

Síbẹ̀ bíi ti ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, ó lè ṣòro fún ẹ láti máa gbàdúrà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe sí i? Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ kó o (1) mọ ohun tó fa ìṣòro náà, (2) gbé àwọn ohun àfojúsùn kalẹ̀ lórí ọ̀ràn àdúrà, kó o sì (3) wá ojútùú sí ìṣòro náà kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àfojúsùn rẹ.

Lákọ̀ọ́kọ́, mọ ohun tí ìṣòro náà jẹ́. Apá wo nínú àdúrà gan-an ló jẹ́ ìṣòro rẹ? Kọ ìdáhùn rẹ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ohun tó kàn ni pé kó o ní ohun tó ò ń fojú sùn. Nísàlẹ̀ yìí, mú èyí tó o fẹ́ fi ṣe àfojúsùn rẹ, tàbí kó o kọ ọ́ sórí ìlà tó wà níwájú “Òmíràn.”

□ Mo fẹ́ kí n túbọ̀ máa gbàdúrà.

□ Mi ò fẹ́ máa gbàdúrà kan náà nígbà gbogbo.

□ Mo fẹ́ túbọ̀ máa gbàdúrà látọkànwá.

□ Òmíràn ․․․․․

Bó O Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Náà

Àdúrà dà bí ilẹ̀kùn téèyàn lè ṣí nígbàkigbà. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń sọ pé àwọn kì í ṣí ìlẹ̀kùn náà déédéé, bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣí i. Bíwọ náà bá wà lára irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀, má ṣe juwọ́ sílẹ̀! Wàyí o, o ti mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro náà, o si tí gbé àwọn àfojúsùn kan kalẹ̀. Ohun tó kù ni pé kó o rí kọ́kọ́rọ́ tó o máa fi ṣí ilẹ̀kùn tá a fi àdúrà wé yìí. Gbé àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó wáyé yẹ̀ wò, kó o sì kíyè sí àwọn àbá tó máa jẹ́ kó o borí wọn.

Ìṣòro: ÀÌKA NǸKAN SÍ. “Nígbà míì, torí pé mo ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe, mo máa ń gbàgbé láti gbàdúrà.”—Preeti, ọmọ ogún ọdún láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ọ̀nà Àbáyọ: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.”—Éfésù 5:15, 16.

Ohun Tó O Lè Ṣe: Yan àkókò tí wàá fẹ́ máa gbàdúrà lójoojúmọ́. O tiẹ̀ lè máa kọ ọ́ sínú ìwé kan pàápàá, bó o ṣe máa ń kọ àdéhùn tó ò bá fẹ́ gbàgbé sílẹ̀. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Yoshiko, láti orílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Tí mi ò bá yan àkókò kan pàtó tí màá gbàdúrà, àwọn nǹkan míì á dí mi lọ́wọ́.”

Ìṣòro: ÌPÍNYÀ ỌKÀN. “Mi kì í pọkàn pọ̀ bí mo bá ń gbàdúrà, àwọn nǹkan míì ni mo máa ń rò dípò kí n fọkàn sí ohun tí mò ń sọ.”—Pamela, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.

Ọ̀nà Àbáyọ: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.”—Mátíù 12:34.

Ohun Tó O Lè Ṣe: Bó o bá ṣì tún ń ro nǹkan míì nígbà tó o bá ń gbàdúrà, o lè máa gbàdúrà kúkúrú títí dìgbà tí wàá fi lè máa pọkàn pọ bó o bá ń gbàdúrà. Nǹkan míì tó o tún lè ṣe ni pé kó o máa gbàdúrà lórí ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Marina tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ pé: “Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́tàlá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àdúrà pé ó jẹ́ ọ̀nà kan láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Ìyẹn sì mú kí n máa sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún un nínú àdúrà.”

Ìṣòro: ÀSỌTÚNSỌ. “Tí mo bá ń gbàdúrà, mo máa ń rí i pé ohun kan náà ni mò ń sọ ṣáá.”—Dupe, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] láti orílẹ̀-èdè Benin.

Ọ̀nà Àbáyọ: “Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.”—Sáàmù 77:12.

Ohun Tó O Lè Ṣe: Tó bá jẹ́ pé nǹkan kan náà lo kàn ń sọ ṣáá, o kú lè máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìbùkún tó ò ń rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà lójoojúmọ́. Kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìbùkún yẹn. Kó o ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan, wàá rí i pé tọ́sẹ̀ yẹn bá fi máa parí, wàá ti gbàdúrà lórí nǹkan méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láìjẹ́ pé o sọ ohun kan náà lásọtúnsọ. Kó o wá máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa àwọn nǹkan míì tó ò ń ṣe lójoojúmọ́. Bruno ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan láti orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Tí mo bá ń gbàdúrà, ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ni àdúrà mi máa ń dá lé.” Ohun tí Samantha ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà máa ń ṣe nìyẹn. Ó ní: “Mo máa ń gbìyànjú láti rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lónìí tó yàtọ̀ sí tàwọn ọjọ́ míì, lẹ́yìn náà màá wá gbàdúrà nípa àwọn nǹkan yẹn. Ìyẹn ni kì í jẹ́ kí n máa sọ ohun kan náà lásọtúnsọ.” b

Ìṣòro: IYÈMÉJÌ. “Lọ́jọ́ kan ti mo gbàdúrà nípa ìṣòro kan tí mo ní nílé ìwé, ìṣòro náà ò lọ. Ńṣe nìṣòro náà tiẹ̀ wá ń pọ̀ sí i. Mo wá ronú pé, ‘Ki ni mo tún ń gbàdúrà fún? Jèhófà ò kúkú ní gbọ́!’”—Minori, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] láti orílẹ̀-èdè Japan.

Ọ̀nà Àbáyọ: “Pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun [Jèhófà Ọlọ́run] yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13.

Ohun Tó O Lè Ṣe: Ohun kan tó dájú ni pé, Jèhófà ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Torí náà, lẹ́yìn tó o bá ti gbàdúrà lórí ọ̀ràn kan, gbìyànjú láti lóye ìṣòro náà dáadáa. Dípò tí wàá fi máa dúró de irú ìdáhùn tó o fẹ́ gan-an, wo ọ̀nà míì tí Ọlọ́run ti gbà dáhùn àdúrà rẹ. Ti pé o ṣì jẹ́ Kristẹni fi hàn pé Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà rẹ, kì í ṣe ní ti pé ó mú ìṣòro náà kúrò, àmọ́ ó fún ẹ lókun láti fara dà á.—Fílípì 4:13.

Ìṣòro: ÌTÌJÚ. “Ojú máa ń tì mí bí mo bá ronú nípa ohun táwọn ọmọ iléèwé mi máa sọ tí wọ́n bá rí mi tí mò ń gbàdúrà kí n tó jẹun ọ̀sán.”—Hikaru, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] láti orílẹ̀-èdè Japan.

Ọ̀nà Àbáyọ: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.”—Oníwàásù 3:1.

Ohun Tó O Lè Ṣe: Àwọn èèyàn á rí ẹ bó o bá ń gbàdúrà, àmọ́ kò pọn dandan pé kó o gbàdúrà lọ́nà táwọn èèyàn á fi máa pàfiyèsí sí ẹ. Bí àpẹẹrẹ, Nehemáyà tó jẹ́ adúróṣinṣin gbàdúrà ṣókí níwájú Atasásítà Ọba, kò sì sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé ọbà yẹn mọ̀ pé Nehemáyà gbàdúrà. (Nehemáyà 2:1-5) Ìwọ náà lè gbàdúrà sí Jèhófà láìpe àfiyèsí ẹnikẹ́ni.—Fílípì 4:5.

Ìṣòro: ÈRÒ PÉ A Ò YẸ LẸ́NI TÓ Ń GBÀDÚRÀ. “Gbogbo ìṣòro mi ni Jèhófà mọ̀. Ó ti sú èmi fúnra mi, mo sì rò pé ó ṣeé ṣe kó ti sú òun náà! Nígbà míì mo tiẹ̀ máa ń rò pé mi ò yẹ lẹ́ni tó ń bá a sọ̀rọ̀.”—Elizabeth, ọmọ ogún [20] ọdún láti orílẹ̀-èdè Ireland.

Ọ̀nà Àbáyọ: ‘Kó gbogbo àníyàn rẹ lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún ọ.’—1 Pétérù 5:7.

Ohun Tó O Lè Ṣe: Gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti dá kẹ́kọ̀ọ́, ṣèwádìí lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí kó o sì ṣàṣàrò lórí wọn: Lúùkù 12:6, 7; Jòhánù 6:44; Hébérù 4:16; 6:10; 2 Pétérù 3:9. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí á jẹ́ kó o rí i pé Jèhófà ń fẹ́ gbọ́ ohun tó ò ń sọ àti pé kò dìgbà tó o bá di ògbóǹkangí Kristẹni kó tó gbọ́ àdúrà rẹ. Onísáàmù náà Dáfídì, tóun náà ń ṣàníyàn tó sì ní ìdààmú ọkàn fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” cSáàmù 34:18.

Ti pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ń gbọ́ àdúrà rẹ fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ ẹ́ lógún. Nicole, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan láti orílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Jèhófà kò fa iṣẹ́ gbígbọ́ àdúrà wa lé àwọn áńgẹ́lì lọ́wọ́. Ó dájú pé, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ń gbọ́ àdúrà wa, ó ní láti ka àwọn àdúrà náà sí pàtàkì.”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Torí pé kò dìgbà tá a bá sọ̀rọ̀ jáde kí Ẹlẹ́dàá tó gbọ́ wa, ó lè “gbọ́” àwọn ohun tó wà lọ́kàn wa tá ò sọ jáde pàápàá.—Sáàmù 19:14.

c Tó o bá ronú pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan tó o ti dá ní kò jẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà rẹ, ńṣe ni kó o fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn òbí rẹ létí. Kó o tún lọ bá “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ [fún ìrànlọ́wọ́].” (Jákọ́bù 5:14) Àwọn alàgbà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tún pa dà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Kí làwọn ohun tó ṣe pàtàkì sí Jèhófà tó o lè gbàdúrà nípa rẹ̀?

◼ Àwọn ọ̀ràn tó kan àwọn ẹlòmíì wo lo lè bá Jèhófà sọ nínú àdúrà?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ójú ìwé 18]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ

“Ṣe ni àdúrà dà bí àkọsílẹ̀ kan tó jẹ́ pé ìwọ àti Jèhófà nìkan ló lè kà á.” —Olayinka, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

“Jẹ́ ká sọ pé o ní ọ̀rẹ́ kan tó o ti fún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn. Ṣàdédé ló bẹ̀rẹ̀ sí í yàn ẹ́ lódì. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà bá ò bá gbàdúrà sí i mọ́.”—Chinta, láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà.

“Mo máa ń ronú pé kò dáa kí n sọ àwọn ẹ̀dùn ọ̀kan mi jáde. Àmọ́, àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà ti jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn ìgbà kan wà tínú èèyàn á dùn tàbí tínú èèyàn á bà jẹ́, nǹkan sì lè tojú súni nígbà míì, àmọ́ mo ti mọ̀ pé èèyàn lè sọ gbogbo nǹkan yẹn fún Jèhófà. Ní báyìí mo ti wá mọ ohun tó yẹ kí n ṣe nígbà tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀.”—Amber, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Tó bá dà bíi pé ọ̀nà àtigbàdúrà ti dí pa, ṣe ni kó o lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi kọ́kọ́rọ́ láti fi ṣí i