Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Bọ́jọ́ Ọ̀la Rẹ Ṣe Máa Rí?

Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Bọ́jọ́ Ọ̀la Rẹ Ṣe Máa Rí?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Bọ́jọ́ Ọ̀la Rẹ Ṣe Máa Rí?

Ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ti kádàrá bí ìgbésí ayé àti ọjọ́ ọ̀la àwọn ṣe máa rí. Èrò wọn ni pé, gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá látìgbà tó ti wà nínú oyún títí dọjọ́ ikú ló ti wà lákọọ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n máa ń sọ pé, ‘Ó ṣe tán alágbára ni Ọlọ́run, ó mohun gbogbo, torí arínúróde ni, torí náà ó gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, èyí tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ àtèyí tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.’

ÌWỌ ńkọ́, kí lèrò ẹ? Ṣé Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá? Àbí kẹ̀, ṣé lóòótọ́ lèèyàn lómìnira láti yan ohun tó fẹ́ àbí àsọdùn lásán ni? Kí ni Bíbélì sọ?

Ṣóhun Gbogbo Ni Ọlọ́run Ń Mọ̀ àbí Èyí Tó Bá Yàn Láti Mọ̀?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run lágbára láti mọ ohun tó bá ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Ìwé Aísáyà 46:10 sọ pé ó ń “ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin.” Ó tiẹ̀ lo àwọn èèyàn láti kọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀. (2 Pétérù 1:21) Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló sì ń nímùúṣẹ torí pé Ọlọ́run ní ọgbọ́n àti agbára láti mú wọn ṣẹ ní kíkún. Torí náà, kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run máa ń mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ nìkan ni, ó tún máa ń kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà tó bá wù ú. Àmọ́, ṣé Ọlọ́run ló ń kádàrá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan tàbí iye ẹ̀dá tó máa rí ìgbàlà pàápàá? Bíbélì ò sọ bẹ́ẹ̀.

Ohun tí Bíbélì fi kọ́ wa ni pé kìkì ohun tí Ọlọ́run bá yàn láti mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú nìkan ló máa ń mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn olóòótọ́ máa la ìparun àwọn ẹni burúkú já ní òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (Ìṣípayá 7:9, 14) Kíyè sí i pé, Ọlọ́run ò sọ pé iye báyìí làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá máa jẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ńṣe ni Ọlọ́run dà bí baba onífẹ̀ẹ́ tó ní ìdílé ńlá kan. Ó mọ̀ pé ó kéré tán, àwọn kan lára àwọn ọmọ Òun máa nífẹ̀ẹ́ Òun, àmọ́ kò pinnu iye àwọn tó máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣàgbéyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe ń lo agbára tó ní láti pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Torí pé òun ni Ọlọ́run Olódùmarè, agbára rẹ̀ ò láàlà. (Sáàmù 91:1; Aísáyà 40:26, 28) Àmọ́, ṣó kàn máa ń lo agbára rẹ̀ bó ṣe wù ú ni? Rárá. Bí àpẹẹrẹ, ó yàn láti má ṣe pa ìlú Bábílónì tó jẹ́ ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ run títí dìgbà tí àkókò fi tó láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Mo ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Aísáyà 42:14) Bó ṣe máa ń ṣe náà nìyẹn bó bá kan mímọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kó sì pinnu ohun tó máa ṣe. Jèhófà ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu kó lè yọ̀ǹda fún wa láti lo òmìnira tó fún wa láti yan ohun tá a fẹ́.

Bí Ọlọ́run ṣe ń pààlà sí ọ̀nà tó ń gbà lo agbára rẹ̀ ò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, kò sì sọ ọ́ di aláìpé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fi títóbi rẹ̀ hàn, tó sì ń mú ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìdí sì ni pé kò lo ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arínúróde àti alágbára nìkan, àmọ́ ó tún ń lò ó gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó ń yọ̀ǹda fáwọn ẹ̀dá rẹ̀ onílàákàyè láti yan ohun tí wọ́n bá fẹ́.

Yàtọ̀ síyẹn, bó bá jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni Ọlọ́run ti kádàrá, tó fi mọ́ gbogbo jàǹbá tó ń ṣẹlẹ̀ àti gbogbo ìwà búburú, ǹjẹ́ a ṣì sọ tá a bá sọ pé òun ló jẹ̀bi gbogbo láabi àti ìjìyà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé? Torí náà, tá a bá fara balẹ̀ wò ó, a máa rí i pé ẹ̀kọ́ nípa kádàrá ò pọ́n Ọlọ́run lé, ńṣe ló ń tàbùkù sí i. Ó ń fi Ọlọ́run hàn gẹ́gẹ́ bí òǹrorò, aláìdáa àti aláìnífẹ̀ẹ́, gbogbo èyí sì jẹ́ òdì kejì pátápátá sóhun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀.—Diutarónómì 32:4.

Ọwọ́  Ló Wà

Ọlọ́run bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, . . . kí o sì yan ìyè, . . . nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn; nítorí òun ni ìyè rẹ àti gígùn ọjọ́ rẹ.” (Diutarónómì 30:19, 20) Ká ní Ọlọ́run ti kádàrá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kọ̀ọ̀kan pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun kí wọ́n sì rí ìyè, tàbí kí wọ́n ṣàìka òun sí, kí wọ́n sì kú, òfo àti asán lọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún wọn ì bá jẹ́. Ǹjẹ́ o gbà pé Ọlọ́run tó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo” àti Ọlọ́run ìfẹ́ lè hùwà àìdáa bẹ́ẹ̀?—Sáàmù 37:28; 1 Jòhánù 4:8.

Àrọwà tí Ọlọ́run pa fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti yan ìyè túbọ̀ kàn wá lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ, torí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń fi hàn pé ńṣe la túbọ̀ ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (Mátíù 24:3-9; 2 Tímótì 3:1-5) Báwo la ṣe lè yan ìyè? A lè yan ìyè bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe yàn án.

Báwo Lo Ṣe Lè “Yan Ìyè”?

Bá a ṣe lè yan ìyè ni pé ká ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà,’ ká ‘fetí sí ohùn rẹ̀’ ká sì ‘fà mọ́ ọn.’ Ọ̀nà kan tá a lè gba ṣe àwọn nǹkan yìí ni pé, ká mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi kan, ká sì mọ àwọn nǹkan tó ń fẹ́ ká ṣe. Nínú àdúrà tí Jésù Kristi gbà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: ‘Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ̀ ọ́, ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jésù Kristi, ẹni tí ìwọ rán.’—Jòhánù 17:3, Bibeli Mimọ.

A lè rí òtítọ́ tó ṣeyebíye yìí nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16) Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa yìí jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé kò kádàrá ọjọ́ ọ̀la wa àmọ́ ó fẹ́ ká yan ohun tá a fẹ́ níbàámu pẹ̀lú àwọn ìsọfúnni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Aísáyà 48:17, 18.

Ọlọ́run wá ń tipasẹ̀ Bíbélì sọ fún wa pé: ‘Èyí lohun tí mo ní lọ́kàn nípa ayé àti ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń gbénú ẹ̀, ohun tẹ́ ẹ sì gbọ́dọ̀ ṣe nìyí kẹ́ ẹ bàa lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ọwọ́ yín ló kù sí láti yàn bóyá ẹ máa fetí sí mi tàbí ẹ máa ṣàìgbọràn.’ A ti wá rí i kedere báyìí pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run lágbára láti kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, kì í fi òmìnira tó fún wa láti yan ohun tá a fẹ́ dù wá! Ṣé wàá yan ìyè “nípa fífetí sí ohùn [Ọlọ́run] àti nípa fífà mọ́ ọn”?

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Dé ìwọ̀n àyè wo ni Ọlọ́run máa ń lo agbára tó ní láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la?—Diutarónómì 30:19, 20; Aísáyà 46:10.

◼ Kí nìdí tí Ọlọ́run kì í fi í kádàrá gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ tó fi mọ́ àwọn láabi tó ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn?—Diutarónómì 32:4.

◼ Kí ló máa pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí?—Jòhánù 17:3.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Bíbélì kọ́ wa pé, Ọlọ́run máa ń pààlà sí agbára rẹ̀ bó bá fẹ́ kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú