Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọ̀gá Ẹ Ni Owó àbí Ẹrú Ẹ?

Ṣé Ọ̀gá Ẹ Ni Owó àbí Ẹrú Ẹ?

Ṣé Ọ̀gá Ẹ Ni Owó àbí Ẹrú Ẹ?

ṢÉ ÀRÙN àìlówólọ́wọ́ máa ń ṣe ẹ́? Ìròyìn fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé làrùn àìlówólọ́wọ́ ń ṣe. Kí ni àrùn àìlówólọ́wọ́?

Dókítà Roger Henderson, tó jẹ́ olùṣèwádìí nípa ọpọlọ lórílẹ̀-èdè United Kingdom, ló ṣẹ̀dá gbólóhùn èdè Gẹ̀ẹ́sì tó túmọ̀ sí “àrùn àìlówólọ́wọ́” lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó fi ṣàpèjúwe àmì téèyàn fi máa ń mọ̀ bí ẹnì kan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro owó. Lára irú àmì bẹ́ẹ̀ ni kéèyàn má lè mí délẹ̀ dáadáa, ẹ̀fọ́rí, èébì, èèyi ara, kóúnjẹ má wuni jẹ, kéèyàn máa bínú láìnídìí, ìjayà àti èròkerò. Dókítà Henderson ròyìn pé, “kò sóhun tó ń jáni láyà bí àìlówólọ́wọ́.”

Kò yani lẹ́nu pé láwọn oṣù ẹnu àìpẹ́ yìí àwọn èèyàn tó ń ní ìdààmú ọkàn nítorí owó túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìṣòro àìlówólọ́wọ́ tó ń jà ràn-ìn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ti mú káwọn èèyàn kárí ayé pàdánù iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ibùgbé àti owó tí wọ́n tọ́jú pa mọ́. Àwọn ilé ìfowópamọ́ ńláńlá ti kógbá sílé, kódà àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù lọ pàápàá ti yára wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá, kí ọrọ̀ wọn máa bàa run pátápátá. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, owó oúnjẹ àti tàwọn ohun kòṣeémánìí tó ń ga sí i ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣàníyàn.

Ìṣòro owó ò mọ́ sígbà táwọn èèyàn ò bá lówó lọ́wọ́ ṣá o. Láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, nígbà tí nǹkan ṣẹnuure, ọ̀pọ̀ èèyàn ni àníyàn ṣíṣe nípa ọ̀ràn owó ti hàn léèmọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè South Africa, The Witness, sọ pé ní báyìí o, “ńṣe làwọn èèyàn” jákèjádò ilẹ̀ Áfíríkà “túbọ̀ ń di ẹlẹ́nu mà-rí-mà-jẹ, wọ́n ń jẹ èrè àjẹpajúdé nídìí ọjà, wọ́n sì ń kó ọrọ̀ àlùmọ́nì jọ.” Ìwé ìròyìn náà to díẹ̀ lára àwọn àníyàn tó ń hàn wọ́n léèmọ̀, lára wọn ni “másùnmáwo, gbèsè, ìfi-nǹkan ṣòfò, iṣẹ́ àṣekúdórógbó, ìrẹ́jẹ, ìlara àti ìsoríkọ́.” Wọ́n sọ pé owó ló fà á táwọn èèyàn ò fi lè gbé ìgbé ayé rere mọ́ nílẹ̀ Áfíríkà.

Kí orílẹ̀-èdè Íńdíà tó kó sínú ìṣòro owó tí wọ́n wà báyìí, ọ̀rọ̀ ajé wọn ti búrẹ́kẹ́ gan-an. Ìwé ìròyìn India Today International sọ pé ọdún 2007 ni orílẹ̀-èdè Íńdíà “ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í náwó lọ́nà tí a kò rírú rẹ̀ rí.” Àmọ́, nígbà yẹn, ẹ̀rù ń ba àwọn aláṣẹ tó wà níbẹ̀ pé ọrọ̀ ajé tó búrẹ́kẹ́ lórílẹ̀-èdè náà lè yọrí sí àìbalẹ̀-ọkàn àti ìwà ipá.

Àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí kan ti wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n ń náwó ní ìná àpá sórí àwọn nǹkan afẹ́. Àmọ́, ti pé wọ́n ń náwó bó ṣe wù wọ́n, ò mú kí wọ́n láyọ̀. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé àpọ̀jù owó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó ń fa sísọ ọtí mímu di bárakú, ìsoríkọ́ àti pípara ẹni lórílẹ̀-èdè náà. Ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé bí owó ọ̀hún ṣe pọ̀ tó, “agbára káká la máa fi rí ẹnì kan nínú ará Amẹ́ríkà mẹ́tà,” tó lè sọ pé òun ní “ojúlówó ayọ̀.”

Àwọn Tí Ò Níṣòro Owó

Síbẹ̀, nígbà ọ̀pọ̀ tàbí nígbà ọ̀wọ́n, a ṣì rí ọ̀pọ̀ olówó tàbí òtòṣì, tí wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàníyàn nípa owó àti àwọn nǹkan ìní tara. Kí ló fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Nínú ìròyìn kan tó dá lórí ohun tówó wà fún, ìyẹn The Meaning of Money, àwọn olùṣèwádìí kan kíyè sí i pé àwọn èèyàn kan wá tó jẹ́ pé “owó ni ọlọ́run wọn, ibi tó bá darí wọn sí ni wọ́n sì máa ń gbà. Èyí lè yọrí sí másùnmáwo àti ìdààmú ọkàn.” Wọ́n wá fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé: “Ó dà bíi pé àwọn tó máa ń fètò sí bí wọ́n ṣe ń náwó kì í ṣe kọjá agbára wọn, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Ọ̀gá ni wọ́n jẹ́ fún owó, wọn kì í ṣe ẹrú ẹ̀ . . . A tiẹ̀ lè fọwọ́ sọ̀yà pé àwọn tó bá ń fètò sí bí wọ́n ṣe ń náwó ò ní máa ní ìṣòro àìbalẹ̀ ọkàn, torí náà kò sí ohun táá máa gbé wọn lọ́kàn sókè.”

Ojú wo lo fi ń wo owó? Báwo ni ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé tó lè yí pa dà nígbàkigbà ṣe ń nípa lórí ẹ? Ṣé ọ̀gá ẹ ni owó, àbí ẹrú ẹ? Bóyá àrùn àìlówólọ́wọ́ kì í tiẹ̀ ṣe ẹ́. Síbẹ̀, yálà a jẹ́ olówó tàbí òtòṣì, gbogbo wa la ṣì lè fojú winá ìṣòro owó. Ṣe àgbéyẹ̀wò bó o ṣe lè ṣe àwọn ìyípadà nínú ọ̀nà tó ò ń gbà náwó àti bó ṣe lè mú kó o túbọ̀ ní ìbàlẹ̀ ọkàn kí ayọ̀ ẹ̀ sì pọ̀ sí i.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 4]

Ọ̀gá ẹ ni owó bó bá jẹ́ pé . . .

O kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa owó torí pé kì í fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀

Owó máa ń fa àríyànjiyàn nínú ìdílé yín

O máa ń náwó ní ìná àpà

Ìgbà gbogbo lẹ̀rù máa ń bà ẹ́ pé gbèsè wà lọ́rùn ẹ

O ò mọye tó ń wọlé fún ẹ

O ò mọye tó ò ń ná

O ò mọye gbèsè tó wà lọ́rùn ẹ

Gbèsè tó ò ń jẹ ti pọ̀ ju iye tó o rò pó yẹ kó jẹ́ lọ

O kì í tètè san gbèsè tó ṣẹ́ jọ sí ẹ lọ́rùn

Díẹ̀ lo máa ń rí san pa dà lára owó ọjà tó o rà láwìn

Owó tó o fẹ́ fi ṣe nǹkan míì lo fi ń sanwó ọjà tó o rà láwìn

O ní láti wáṣẹ́ kún iṣẹ́ kó o tó lè san gbèsè tó wà lọ́rùn ẹ

O lọ yá owó láti fi san gbèsè tó wà lọ́rùn ẹ

Owó tó ò ń tọ́jú lo fi ń sanwó iná, omi, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Agbára káká lowó fi ń ṣẹ́ kù sí ẹ lọ́wọ́ bóṣù bá fi máa parí

Ó máa ń ṣòro fún ẹ láti tọ́jú owó tó pọ̀ pa mọ́

Àìlówó lọ́wọ́ máa ń di àìsàn sí ẹ lára, ó sì máa ń mú kó o dààmú

[Credit Line]

Ibi tá a ti rí ìsọfúnni: Ìwé Money Sickness Syndrome, látọwọ́ Dókítà Roger Henderson