Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Bíbélì Kíkà Gbádùn Mọ́ Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Bíbélì Kíkà Gbádùn Mọ́ Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . 

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Bíbélì Kíkà Gbádùn Mọ́ Mi?

Báwo lo ṣe máa ń ka Bíbélì lemọ́lemọ́ tó? (Sàmì sí ọ̀kan)

□ Ojoojúmọ́

□Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀

□Ìgbà míì ․․․․․

Parí gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Bí mi ò bá gbádùn Bíbélì kíkà, ó sábà máa ń jẹ́ nítorí pé . . . (Sàmì sí èyí tó jẹ́)

□ Ó sú mi

□ Kò yé mi

□ Ọkàn mi ò pa pọ̀

□ Ìdí míì ․․․․․

ṢÉ KÌ Í wù ẹ́ láti máa ka Bíbélì? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o gbà pẹ̀lú ohun tí Will ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ, ó ní, “Ó dà bíi pé kíka Bíbélì máa ń súni.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Ìyẹn bó ò bá mọ bó ṣe yẹ kó o kà á.”

Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ bó ṣe yẹ ká ka Bíbélì? Ó dáa, ṣé wà á fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè

ṣe àwọn ìpinnu tó dáa?

ní ojúlówó ọ̀rẹ́?

kojú ìṣòro?

Bíbélì láwọn àbá tó gbéṣẹ́ lórí àwọn ohun iyebíye yìí àtàwọn míì. Lóòótọ́, ó lè gba ìsapá láti wá àwọn ohun iyebíye yìí. Àmọ́, ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn ń wá ohun ìṣúra: Bó bá nira láti rí ohun ìṣúra yìí, ayọ̀ téèyàn máa ní á pọ̀ nígbà tó bá rí i!—Òwe 2:1-6.

Báwo lo ṣe lè rí àwọn ìṣúra iyebíye nínú Bíbélì? Àpótí kékeré tó wà lápá ọ̀tún, èyí tó o lè gé jáde látinú ìwé ìròyìn yìí, á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ka Bíbélì, wàá sì rí ọ̀nà tó o lè gbà kà á ní òdì kejì rẹ̀. Tún gbé àwọn àbá tó bá wù ẹ́ láwọn ojú ìwé tó kàn yẹ̀ wò.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

Wọ́n máa ń sọ pé béèyàn bá ṣe sapá tó lèèyàn ṣe máa jèrè tó.

◼ Báwo nìyẹn ṣe jẹ́ òtítọ́ tó bá dọ̀rọ̀ Bíbélì kíkà?

◼ Ìgbà wo lo lè wáyè láti máa ka Bíbélì?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 19]

BÓ ṢE YẸ KÓ O MÁA KA BÍBÉLÌ

Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí kà Bíbélì . . .

◼ Rí i pé kò sáriwo kó o bàa lè pọkàn pọ̀.

◼ Gbàdúrà pé kóhun tó ò ń kà yé ẹ.

Bó o ṣe ń kà á lọ́wọ́ . . .

◼ Lo àwòrán ilẹ̀ àtàwọn àwòrán nípa Bíbélì láti fojú inú wo ohun tí Bíbélì sọ.

◼ Ronú lórí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, kó o sì ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀.

◼ Ka àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé àtàwọn atọ́ka etí ìwé.

◼ Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi:

ÀWỌN NǸKAN TÓ ṢE KÓKÓ: Ìgbà wo làwọn nǹkan náà ṣẹlẹ̀? Ta ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ò ń kà? Àwọn wo la sọ ọ́ sí?

ÌTUMỌ̀: Báwo ni mo ṣe lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí fún ẹlòmíì?

BÓ TI ṢE PÀTÀKÌ TÓ: Kí nìdí tí Jèhófà Ọlọ́run fi jẹ́ kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú Bíbélì? Kí ni ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa ànímọ́ Jèhófà tàbí ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan? Ẹ̀kọ́ wo ni mo lè rí fi sílò látinú ohun tí mo kà?

Lẹ́yìn tó o bá ti ka Bíbélì . . .

◼ Túbọ̀ ṣe ìwádìí. Lo ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, irú bí ìwé Insight on the Scriptures àti ìwé “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” tó bá wà ní èdè rẹ.

◼ Tún gbàdúrà. Sọ àwọn ohun tó o kọ́ àti bó o ṣe pinnu láti lò ó fún Jèhófà. Dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún Bíbélì ọ̀rọ̀ rẹ̀.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 20]

Ọ̀NÀ WO LO MÁA GBÀ KA BÍBÉLÌ?

Àwọn nǹkan tó o lè ṣe . . .

 ❑ Kà á látìbẹ̀rẹ̀ dópin.

❑ Kà á bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra, bóyá bí wọ́n ṣe kọ àwọn ìwé náà tàbí báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé.

❑ Máa ka apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́.

Monday: Ìtàn tó dùn (Jẹ́nẹ́sísìẸ́sítérì)

Tuesday: Ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ (MátíùJòhánù)

Wednesday: Ìtàn àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní (Ìṣe)

Thursday: Àsọtẹ́lẹ̀ àti ìwà rere (AísáyàMálákì àti Ìṣípayá)

Friday: Ewì àti orin tó gbádùn mọ́ni (Jóòbù, Sáàmù, Orin Sólómọ́nì)

Saturday: Ọgbọ́n téèyàn fi ń gbélé ayé (Òwe, Oníwàásù)

Sunday: Lẹ́tà sáwọn ìjọ (RóòmùJúdà)

Ọ̀nà yòówù kó o yàn, rí i dájú pé ò ń sàmì síbi tó o kà! Bó o bá ti ka orí kan tán, fi àmì yìí sí i, tàbí kó o ṣe àkọsílẹ̀ ibi tó o ti kà lọ́nà míì.

Gé àpótí yìí, kó o sì fi sínú Bíbélì rẹ!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 20]

JẸ́ KÓ DÀ BÍI PÉ Ó Ń ṢẸLẸ̀ LỌ́WỌ́!

Jẹ́ kóhun tó ò ń kà gbádùn mọ́ ẹ. Bí àpẹẹrẹ:

□ To àwọn orúkọ pọ̀ sí ìdílé-ìdílé.

□ Ya àwòrán. Bí àpẹẹrẹ, bó o ṣe ń kà nípa àwọn olóòótọ́ ayé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, kíyè sí bí ànímọ́ ẹni yẹn àti ìṣe ẹ̀ ṣe yọrí sí ìbùkún fún un.—Òwe 28:20.

[Àwòrán]

Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run

Onígbọràn

Olóòótọ́

Ábúráhámù

□ Ya àwọn àwòrán tó ṣàkàwé ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

□ Ya àwọn àwòrán kéékèèké láti ṣàkàwé báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú abala ìtàn kọ̀ọ̀kan.

□ Fọwọ́ ara ẹ ṣe nǹkan tó o kà, irú bí ọkọ̀ áàkì tí Nóà kàn.—Wo Jí! [Gẹ̀ẹ́sì] January 2007, ojú ìwé 22 fún àlàyé síwájú sí i.

□ Kí ìwọ, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ, tàbí àwọn aráalé ẹ jọ kà á sókè. Àbá: Ní kí ẹnì kan ka apá tó jẹ́ tí asọ̀tàn. Àwọn tó kù sì lè máa ka ọ̀rọ̀ àwọn tí ìtàn náà dá lé lórí.

□ Mú ìtàn kan, kó o sì sọ ọ́ di ìròyìn. Kó o wá ka ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà lóríṣiríṣi ọ̀nà tó gbà ṣẹlẹ̀, tó fi mọ́ “ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò” látọ̀dọ̀ àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn àtàwọn tó ṣojú wọn.

□ Mú ìtàn nípa ẹni tó ṣe ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání, kó o sì fojú inú wo bọ́ràn náà ṣe lè parí sí ibòmíì! Bí àpẹẹrẹ, gbé bí Pétérù ṣe sẹ́ Jésù yẹ̀ wò. (Máàkù 14:66-72) Ọ̀nà tó sàn jù wo ni Pétérù ì bá ti gbà bójú tó ọ̀ràn náà?

□ Máa wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a ṣe sórí àwo CD tàbí kásẹ́ẹ̀tì tàbí kó o máa fetí sí i.

Kọ àwòkẹ́kọ̀ọ́ tìẹ. Fi àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìtàn náà sínú ẹ̀.—Róòmù 15:4.

ÀBÁ: Kí ìwọ àti díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 21]

BÓ ṢE LÈ GBÁDÙN MỌ́ Ẹ

◼ Ní àfojúsùn! Kọ ọjọ́ tó o máa fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì sórí ìlà yìí.

․․․․․

◼ Yan apá tó o nífẹ̀ẹ́ sí nínú Bíbélì. (Wo àpótí náà,  “Ọ̀nà Wo Lo Máa Gbà Ka Bíbélì?”) Kó o wá kọ apá tó o máa kọ́kọ́ kà sórí ìlà.

․․․․․

◼ Kọ́kọ́ lo àkókò díẹ̀. Kódà, ó sàn kó o máa ka Bíbélì láàárín ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] péré ju kó o má kà á rárá. Kọ iye àkókò tó o lè yà sọ́tọ̀ láti máa fi kà á sísàlẹ̀.

․․․․․

Àbá: Ní Bíbélì tí wà á máa lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nìkan. Máa kọ ọ̀rọ̀ sí i. Máa sàmì sáwọn ẹsẹ Bíbélì tó gbàfiyèsí ẹ jù lọ.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Mo máa ń gbìyànjú láti ka ẹsẹ bíi mélòó kan nínú Bíbélì kí n tó lọ sùn. Èyí máa ń jẹ́ kí n rí nǹkan tó dáa ronú lé lórí kí oorun tó gbé mi lọ.”—Megan.

“Mo máa ń ronú lórí ẹsẹ kan fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Mo máa ń ka gbogbo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, mo máa ń wo atọ́ka etí ìwé, mo sì tún máa ń ṣe àfikún ìwádìí. Nígbà míì, mo lè má parí ìwádìí lórí ẹsẹ kan ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan, àmọ́ mo ti rí ọ̀pọ̀ nǹkan nínú bí mo ṣe ń kà á yìí!”—Corey.

“Nígbà kan rí, mo ti ka Bíbélì tán láàárín oṣù mẹ́wàá. Bí mo ṣe yára kà á yìí mú kí n rí àwọn apá tí mi ò kíyè sí rí tí Bíbélì ti bára mu.”—John.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

O LÁǸFÀÀNÍ LÁTI YÀN!

Mú ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Ọ̀pọ̀ ìtàn tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi ló wà nínú Bíbélì. Mú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó o nífẹ̀ẹ́ sí, kó o sì kà á láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí.

Àbá: Wo ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ Apá 2, lójú ìwé 292, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, wà á rí àbá nípa bó o ṣe lè kọ́ ohun tó pọ̀ látinú àkọsílẹ̀ náà.

Ka ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ka Mátíù (ìwé Ìhìn Rere àkọ́kọ́), Máàkù (tí wọ́n kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbádùn mọ́ni sì kún inú rẹ̀ fọ́fọ́), Lúùkù (tó sọ̀rọ̀ ní pàtàkì lórí àdúrà àtàwọn obìnrin), tàbí ìwé Jòhánù (tí ọ̀pọ̀ lára ohun tó sọ ò sí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere yòókù).

Àbá: Kó o tó ka ìwé Ìhìn Rere tó o bá yàn, gbé àwọn ìsọfúnni nípa ìwé náà àti ẹni tó kọ ọ́ yẹ̀ wò ní ṣókí, kó o bàa lè mọ ìdí tó fi yàtọ̀ sáwọn ìwé Ìhìn Rere tó kù.

Yan sáàmù kan. Bí àpẹẹrẹ:

Bó bá ṣe ẹ́ bíi pé o dá níkàn wà tó ò sì lọ́rẹ̀ẹ́, ka Sáàmù 142.

Bínú ẹ bá bà jẹ́ nítorí àwọn àṣìṣe tó o ṣe, ka Sáàmù 51.

Bó o bá ń ṣiyè méjì nípa bí ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe wúlò tó, ka Sáàmù 73.

Àbá: Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn sáàmù tó o ti kà tó sì fún  níṣìírí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

WÁDÌÍ JINLẸ̀

◼ Ronú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ronú lórí ìgbà tí ohun tó ò ń kà wáyé, ibi tó ti wáyé, àtàwọn ipò tó yí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ká.

Àpẹẹrẹ: Ka Ìsíkíẹ́lì 14:14. Ọmọ ọdún mélòó ló ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì jẹ́ nígbà tí Jèhófà sọ pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ rere bíi Nóà àti Jóòbù?

Amọ̀nà: Ọdún karùn-ún lẹ́yìn tí wọ́n mú Dáníẹ́lì nígbèkùn lọ sí Bábílónì ni wọ́n kọ ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 14, ó ṣeé ṣe kó má tíì pé ogún ọdún nígbà yẹn.

Ohun iyebíye tó o lè rí látinú ìwádìí rẹ: Ǹjẹ́ Dáníẹ́lì kéré jù fún Jèhófà láti rí ìṣòtítọ́ rẹ̀? Ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání wo ló ṣe tó yọrí sí ìbùkún fún un? (Dáníẹ́lì 1:8-17) Báwo ni àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

◼ Ṣàyẹ̀wò àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀. Nígbà míì, ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì ló gbàfiyèsí ẹ jù lọ.

Àpẹẹrẹ: Fi ohun tó wà nínú Mátíù 28:7 wéra pẹ̀lú Máàkù 16:7. Kí nìdí tí Máàkù fi sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ náà pé Jésù máa tó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn “àti Pétérù”?

Amọ̀nà: Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ò ṣojú Máàkù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹnu Pétérù ló ti gbọ́ ọ.

Ohun iyebíye tó o lè rí látinú ìwádìí rẹ: Kí nìdí tí ọkàn Pétérù fi balẹ̀ nígbà tó gbọ́ pé Jésù tún fẹ́ rí òun? (Máàkù 14:66-72) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ lòun jẹ́ fún Pétérù? Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kó o sì jẹ́ ọ̀rẹ́ rere?

◼ Túbọ̀ ṣe ìwádìí. Wo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún àlàyé.

Àpẹẹrẹ: Ka Mátíù 2:7-15. Ìgbà wo làwọn awòràwọ̀ wá kí Jésù?

Amọ̀nà: Wo Ilé Ìṣọ́ January 1, 2008, ojú ìwé 31, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé ìròyìn yìí.

Ohun iyebíye tó o lè rí látinú ìwádìí rẹ: Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè fún Jésù àtàwọn òbí ẹ̀ nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì? Báwo ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lábẹ́ ipò tó nira?—Mátíù 6:33, 34.