Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọmọ Tó Rẹ̀ Tẹnutẹnu

Àwọn Ọmọ Tó Rẹ̀ Tẹnutẹnu

Àwọn Ọmọ Tó Rẹ̀ Tẹnutẹnu

◼ Nígbà tí olùkọ́ bi ọmọ ọdún mẹ́jọ kan tó ń jẹ́ Pablo nípa iṣẹ́ tó ní kó ṣe wá láti ilé, ó sọ pé: “Mi ò ní àkókò tó pọ̀ tó. Ó ti rẹ̀ mí.” Oorun wà lójú ọmọdékùnrin tó ti ilẹ̀ Sípéènì wá yìí. Ọ̀pọ̀ ọmọdé bíi tiẹ̀ ló sì máa ń rẹ̀ tẹnutẹnu lẹ́yìn tí wọ́n bá ti lo àkókò tó gùn tó wákàtí méjìlá fún gbígba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá. Kí ló fà á tí wọ́n fi ń da iṣẹ́ bò wọ́n tó bẹ́ẹ̀ níléèwé?

Àwọn òbí kan máa ń fàwọn ọmọ wọn sẹ́nu àwọn ìgbòkègbodò míì tó ń wáyé lẹ́yìn iléèwé kíyẹn lè mọ́wọ́ wọn dí títí dìgbà tí Mọ́mì tàbí Dádì fi máa dé. Àwọn míì sì ń rọ́ iṣẹ́ tó pọ̀ lé àwọn ọmọ wọn lórí torí pé wọ́n fẹ́ kí wọ́n ta yọ níléèwé kí wọ́n bàa lè rọ́wọ́ mú nídìí iṣẹ́ tí wọ́n bá fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Ìyẹn lọ̀pọ̀ òbí lórílẹ̀-èdè South Korea fi máa ń rán àwọn ọmọ wọn lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n á ti kàwé ní àkàjáṣan, níbi tí wọ́n á ti máa ti orí iṣẹ́ kan bọ́ sí òmíràn, léyìí tó lè bẹ̀rẹ̀ láti agogo méje ààbọ̀ òwúrọ̀ nígbà míì, títí di ọ̀gànjọ́ tàbí ààjìn òru, fún ọjọ́ méje lọ́sẹ̀. Ìwé ìròyìn New York Times sọ pé: “Gbogbo ohun tó bá gbà ni wọ́n máa ń fún un káwọn ọmọ wọn bàa lè lọ sí yunifásítì tó dára jù lọ.”

Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ lédè Sípáníìṣì, ìyẹn Mujer hoy, sọ pé: “Àwọn òbí ‘tí ò kọ ohun tó máa gbà’ ń fẹ́ láti ṣe ohun tó dára jù lọ fáwọn ọmọ wọn, àmọ́ èyí ń béèrè pé káwọn ọmọ ṣiṣẹ́ kára gan-an níléèwé.” Káwọn ọmọ bàa lè tẹ́ àwọn òbí wọn lọ́rùn, wọ́n lè máa ṣe ju ohun tí agbára wọ́n gbé lọ, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Antonio Cano, tó jẹ́ ààrẹ àjọ kan tó ń ṣèwádìí ìdààmú ọkàn, ìyẹn Spanish Society for the Study of Anxiety and Stress, sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a kíyè sí, wọ́n ń fi iṣẹ́ pá àwọn ọmọdé lórí.” Àti pé gẹ́gẹ́ bí àwọn àjọ míì ṣe sọ, bá a bá kó ọmọ mẹ́wàá tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún jọ lórílẹ̀-èdè Sípéènì, mẹ́rin lára wọn ló máa ń ní ìdààmú ọkàn. Irú ìdààmú ọkàn bẹ́ẹ̀ ní ọṣẹ́ tó ń ṣe, ó tiẹ̀ lè mú kí ọmọ kan para ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè South Korea, “láàárín àwọn ọ̀dọ́mọdé tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́wàá sí mọ́kàndínlógún, bá a bá yọwọ́ jàǹbá mọ́tò, pípara-ẹni lohun kejì tó wọ́pọ̀ jù lọ tó máa ń fa ikú,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The New York Times ṣe sọ.

Àmọ́ ṣá o, àwọn èwe gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ kára níléèwé, àwọn òbí sì gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tó bá wà ní agbára wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́, torí pé èèyàn kì í ṣe èwe lẹ́ẹ̀mejì. Síbẹ̀, “àwọn ọmọdé kì í ṣe àgbàlagbà. Wọn ò sì lè kojú iṣẹ́ àṣedòru tí wọ́n ń gbé kà wọ́n láyà,” gẹ́gẹ́ bí Irene Arrimadas, tó jẹ́ olùkọ́ ṣe sọ. Àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ tó mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ nìyí máa ń rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ní àkókò tó pọ̀ tó láti sinmi, àti pé wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìdílé tó gbámúṣé. Sólómọ́nì Ọba sọ ìdí táwọn òbí fi gbọ́dọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:6.