Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táyà Mi Fi Máa Ń Já Láti Sọ Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Fáwọn Ẹlòmíì?

Kí Nìdí Táyà Mi Fi Máa Ń Já Láti Sọ Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Fáwọn Ẹlòmíì?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Táyà Mi Fi Máa Ń Já Láti Sọ Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Fáwọn Ẹlòmíì?

“Àwọn ìgbà kan wà tí mo ti láǹfààní láti sọ ohun ti mo gbà gbọ́ fáwọn ojúgbà mi nílé ẹ̀kọ́. Àmọ́ ṣe ni mo dákẹ́.”—Kaleb. a

“Olùkọ́ wa béèrè lọ́wọ́ gbogbo kíláàsì pé kí lèrò wa nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sọ pé ara ẹranko lèèyàn ti wá. Mo mọ̀ pé àǹfààní ńlá nìyí fún mi láti sọ ohun tí mo gbà gbọ́. Àmọ́ ṣe ni mo dákẹ́ lọ gbári láìfọhùn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bà mí nínú jẹ́ gan-an ni.”—Jasmine.

BÓ BÁ jẹ́ pé Kristẹni ni ẹ́, ìwọ náà ti lè wà nírú ipò ti Kaleb àti Jasmine bára wọn yìí rí. Bíi tiwọn, àwọn òtítọ́ tó o ti kọ́ láti inú Bíbélì lè wú ẹ lórí kó o sì fẹ́ sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì. Síbẹ̀, bó o bá ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tó o bá sọ ọ́, ńṣe làyà ẹ á là gààrà. Àmọ́ o lè dẹni tó ń fìgboyà sọ̀rọ̀. Lọ́nà wo? Bó o bá ṣe ń múra sílẹ̀ fún sáà ilé ẹ̀kọ́ lọ́dọọdún, lo àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí:

1. Kọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù sílẹ̀. Bó o bá ń ronú nípa bó o ṣe máa ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́, ẹ̀rù ohun tó lè tìdí ẹ̀ yọ lè máa bà ẹ́! Àmọ́ nígbà míì, o lè dín ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ kù, bó o bá kọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù sílẹ̀.

Parí àwọn gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí.

◼ Bí mo bá ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ níléèwé, nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ nìyí:

․․․․․

Ó lè tù ẹ́ lára tó o bá mọ̀ pé àwọn nǹkan tó ń bà ẹ́ lẹ́rù náà ló ń ba àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni bíi tìẹ náà lẹ́rù. Bí àpẹẹrẹ, Christopher tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sọ pé: “Mo máa ń bẹ̀rù pé àwọn ẹlẹgbẹ́ mi á fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì tún lè máa sọ fáwọn ẹlòmíì pé mi ò dákan mọ̀.” Kaleb, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, tún sọ pé: “Mo máa ń bẹ̀rù pé ẹnì kan lè bi mí ní ìbéèrè tí mi ò ní lè dáhùn.”

2. Gbà pé o gbọ́dọ̀ ṣe é. Ṣé ohun tí ò lè ṣẹlẹ̀ ló ń bà ẹ́ lẹ́rù ni? Ó lè má rí bẹ́ẹ̀. Ashley sọ pé: “Àwọn ọmọ kan wà tí wọ́n máa ń ṣe bíi pé wọ́n fẹ́ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, àmọ́ tó bá yá wọ́n máa fàwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ dá àpárá lójú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi.” Irú ohun tá a ń sọ yìí ṣẹlẹ̀ sí Nicole ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó sọ pé: “Ọmọ kan fi ẹsẹ Bíbélì kan nínú Bíbélì tiẹ̀ wé tèmi, ó rí i pé ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ yàtọ̀ síra. Ló bá ní wọ́n ti yí Bíbélì mi pa dà. Ó yà mí lẹ́nu! Mi ò mohun tí mo lè sọ.” b

Irú ipò báyìí máa ń kóni láyà jẹ gan-an ni! Àmọ́, dípò kó o torí ẹ̀ gbẹ́nu dákẹ́, ńṣe ni kó o gbà pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣàì ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni. (2 Tímótì 3:12) Matthew tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá sọ pé: “Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn òun, tórí náà a ò lè retí pé kí gbogbo èèyàn fẹ́ràn wa tàbí ohun tá a gbà gbọ́.”—Jòhánù 15:20.

3. Ronú nípa àǹfààní tó wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ àǹfààní kankan tiẹ̀ wà nínú kéèyàn máa sọ ohun tó gbà gbọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fi í dá àpárá? Amber ẹni ọdún mọ́kànlélógún [21] rò pé àǹfààní wà níbẹ̀. Ó sọ pé: “Kò rọrùn rárá láti ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn tí ò ka Bíbélì sí, àmọ́ wàá lè túbọ̀ lóye ohun tó o gbà gbọ́.”—Róòmù 12:2.

Tún pa dà lọ ka àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀ pó ṣeé ṣe kó máa bà ẹ́ lẹ́rù. Wá ronú nípa àǹfààní méjì, ó kéré tán, tíyẹn lè mú wá, kó o sì kọ ọ́ sórí ìlà yìí.

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Báwo ni sísọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́ ṣe lè dín yẹ̀yẹ́ táwọn ojúgbà ẹ ń fi ẹ́ ṣe kù? Báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kíwọ fúnra ẹ̀ dára ẹ lójú? Báwo ló ṣe máa nípa lórí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà Ọlọ́run àti ìfẹ́ tó ní sí ẹ?—Òwe 23:15.

4. Múra sílẹ̀. Òwe 15:28 sọ pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” Lẹ́yìn tó o bá ti ṣàṣàrò lórí ohun tó o máa sọ, tún gbìyànjú láti ronú kan àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè bi ẹ́. Ṣe ìwádìí lórí àwọn ìbéèrè yẹn, kó o sì múra ìdáhùn tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.—Wo àtẹ tá a pè ní  “Wéwèé Ohun Tó O Máa Sọ,” lójú ìwé 23.

5. Gbé ìgbésẹ̀. Bó o bá ti ṣe tán láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì, báwo ló ṣe yẹ kó o bẹ̀rẹ̀? Ọ̀nà tó bá wù ẹ́ lo lè gbà bẹ̀rẹ̀. Lọ́nà kan, a lè fi sísọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́ wé, wíwẹ̀ lódò: Àwọn kan máa ń rọra rìn wọnú omi; àwọn míì máa ń bẹ́ sódò. Lọ́nà kan náà, o lè rọra bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ láì mú ti ẹ̀sìn wọ̀ ọ́, kó o fi mọ̀ bí wọ́n bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ. Àmọ́, tó o bá rí i pé ìrònú ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ máa ń bò ẹ́ mọ́lẹ̀, o lè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lọ́kàn ẹ ní tààràtà bí ìgbà téèyàn bẹ́ sódò. (Lúùkù 12:11, 12) Andrew tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Ó rọ̀ mí lọ́rùn láti sọ ohun tí mo gbà gbọ́ ju kí n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú nípa bí mo ṣe máa sọ ọ́. Tí mo bá ṣáà ti bẹ̀rẹ̀ màá rí i pé, ó rọ̀ mí lọ́rùn ju bí mo ṣe rò lọ!” c

6. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Bó ò ṣe ní fò sínú odò tí kò jìn, ṣọ́ra kó o má tọrùn bọ àríyànjiyàn tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Rántí pé ìgbà míì wà tó yẹ kó o sọ̀rọ̀, àwọn ìgbà kan sì wà tó yẹ kó o dákẹ́. (Oníwàásù 3:1, 7) Ìgbà míì tiẹ̀ wà tí Jésù kì í fèsì ìbéèrè tí wọ́n bá bi í. (Mátíù 26:62, 63) Tún rántí ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ọlọgbọn eniyan ti ri ibi tẹlẹ̀, o si pa ara rẹ̀ mọ: ṣugbọn awọn òpè tẹ̀ siwaju, a si jẹ wọn níyà.”—Òwe 22:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Nítorí náà tó o bá ti fura pé àríyànjiyàn ti fẹ́ wáyé, má ṣe “tẹ̀ siwaju” nínú ìjíròrò náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o fọgbọ́n dáhùn ní ṣókí. Bí àpẹẹrẹ, tọ́mọ iléèwé ẹ bá ń fúngun mọ́ ẹ pé, ‘Kí ló fà á tó o kì í mu sìgá?’ o lè dá a lóhùn pé, ‘Mi ò fẹ́ fa ìdọ̀tí ságbárí ni!’ Ohun tó bá wá sọ tẹ̀ lé e ló máa pinnu bóyá wàá ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fún un.

Bó o bá tẹ̀ lé àwọn àbá wọ̀nyí á jẹ́ kó o lè “wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà” ìgbàgbọ́ ẹ. (1 Pétérù 3:15) Ó yẹ kó o mọ̀ pé, mímúra tán láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ ẹ nígbàkigbà ò ní kí àyà ẹ máà já mọ́ o. Ohun ti Alana tó ti pé ọdún méjìdínlógún sọ ni pé: “Bó o bá lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì, láìka ìbẹ̀rù tó mú ẹ sí, ṣe ló máa dà bíi pé ó ṣe àṣeyọrí ńlá kan, ìyẹn ni pé o ti pa ìbẹ̀rù tì, ó sì ti borí èrò pé nǹkan lè yíwọ́. Tí wọ́n bá wá gba ohun tó o sọ, ayọ̀ ẹ á tún légbá kan! Inú ẹ máa dùn pé o fìgboyà sọ tinú ẹ jáde.”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Ọ̀rọ̀ táwọn atúmọ̀ Bíbélì lò yàtọ̀ síra. Àmọ́, àwọn kan rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ju àwọn míì lọ.

c Wo àpótí tá a pè ní  “Àwọn Ìbéèrè Tó O Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò,” lójú ìwé 24.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

Àbí ẹnì kan níléèwé  lè máa ronú báyìí?

‘Mo mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. O lè máa rò pé màá fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́, àmọ́ ẹni iyì ni ẹ́ lójú mi. Kí nìdí tó fi dà bíi pé mìmì kan ò mì ẹ́, láìka gbogbo ìṣòro tó pọ̀ láyé sí? Èmi ti kú sára ní tèmi o. Ṣé ogun míì máa tó jà ni? Ṣé àwọn òbí mi máa kọra wọn sílẹ̀? Ṣé màá lè fi ara rere pa dà sílé lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ láìjẹ́ pé wọ́n yìnbọn pa mí tàbí kí wọ́n gún mi pa? Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ń jà ràn-ìn lọ́kàn mi, àmọ́ ṣe ló dà bíi pé ọkàn tìẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Ṣé ẹ̀sìn tó ò ń ṣe ló ràn ẹ́ lọ́wọ́? Mo fẹ́ ká jọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó wọ̀nyí, àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí láti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀. Jọ̀ọ́ ṣó o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò náà?’

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ójú ìwé 24]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Àwọn ojúgbà mi kan ti fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ rí torí mo sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fún wọn. Àmọ́ tí wọ́n bá ti rí i pé mi ò ka ọ̀rọ̀ wọn sí, ṣe ni wọ́n máa ń fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́.”—Francesca, láti orílẹ̀-èdè Belgium.

“Bó ò bá jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó o gbà gbọ́, o lè gbàgbé pé Kristẹni ni ẹ́, kó o wá máa tẹ̀ síbi tí gbogbo èèyàn ń tẹ̀ sí. O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà; o gbọ́dọ̀ mọ ohun tó ò ń ṣe.”—Samantha, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

“Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọdé, mi ò fẹ́ yàtọ̀ sáwọn ẹlẹgbẹ́ mi. Àmọ́ bí mo ṣe ń dàgbà sí i ni mo wá ń mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ti ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé tó dára. Èyí túbọ̀ fún mi nígboyà, ó sì jẹ́ kí n mọyì ohun tí mo gbà gbọ́.”—Jason, láti orílẹ̀-èdè New Zealand.

 [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ O LÈ FI BẸ̀RẸ̀ ÌJÍRÒRÒ

“Kí lo máa fi àkókò ìsinmi tó o máa gbà nílé ẹ̀kọ́ ṣe?” [Tó bá ti dáhùn, sọ àwọn nǹkan tẹ̀mí tó o fẹ́ ṣé fún un, bíi lílọ sí àpéjọ àgbègbè tàbí bó o ṣe máa fi kún àkókò tí wàá lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.]

◼ Sọ̀rọ̀ lórí kókó ìròyìn kan, kó o wá béèrè pé: “Ṣó o gbọ́ ìròyìn yẹn? Kí lo rò nípa ẹ̀?”

“Ṣó o rò pé ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ lágbàáyé báyìí [tàbí ìṣòro míì] á pa dà níyanjú? [Jẹ́ kó dáhùn.] Kí nìdí tó o fi rò bẹ́ẹ̀?”

“Ẹ̀sìn wo lò ń ṣe?”

“Ibo lo rò pó o máa wà lọ́dún márùn-ún sákòókò tá a wà yìí?” [Bó bá ti dáhùn, sọ àwọn nǹkan tẹ̀mí tó o fẹ́ lépa fún un.]

 [Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Wéwèé Ohun Tó o Máa Sọ

Gé àtẹ yìí fún lílò!

Àbá: Jíròrò ìsọfúnni tó wà nínú àtẹ yìí pẹ̀lú àwọn òbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Kọ ìdáhùn rẹ sínú àtẹ náà. Kó o wá gbìyànjú láti ronú kan àwọn ìbéèrè míì táwọn ọmọléèwé ẹ lè bi ẹ́.

Ìwà híhù

Ìbéèrè

Kí lèrò ẹ nípa bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀?

ìdáhùn

Mi ò kórìíra àwọn tó ń ṣe é, àmọ́ ìwà wọ́n ni mi ò fara mọ́.

Ìbéèrè míì

Ṣé kì í ṣe pó o ní ẹ̀tanú sí wọn?

Ìwádìí

1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Àwọn Ìdáhùn Tí  Ó Gbéṣẹ́ Apá Kejì,  orí 28. d

ìdáhùn

Rárá, torí gbogbo ohun tó bá ti jẹ mọ́ ìṣekúṣe ni mo kórìíra.

Ìfẹ́sọ́nà

Ìbéèrè

Kí ló dé tó ò lẹ́ni tó ò ń fẹ́?

ìdáhùn

Mo fẹ́ dàgbà tó kí n tó lẹ́ni tí màá fẹ́.

Ìbéèrè míì

Àbí ẹ̀sìn ẹ ò fàyè gbà á ni?

Ìwádìí

Sólómọ́nì 8:4; Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, orí 1.

ìdáhùn

Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹni tó bá wù wá láti bá ṣègbéyàwó la máa ń fẹ́ sọ́nà, èmi ò sì tíì ṣe tán láti gbéyàwó báyìí!

Àìdásí-tọ̀túntòsì

Ìbéèrè

Kí ló fà á tó o kì í kí àsíá?

ìdáhùn

Mo bọ̀wọ̀ fún orílẹ̀-èdè yìí, àmọ́ mi ò lè sìn ín.

Ìbéèrè míì

Ṣé pé o ò lèjà fún orílẹ̀-èdè rẹ?

Ìwádìí

Aísáyà 2:4; Jòhánù 13:35; Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?,ojú ìwé 148 sí 151. e

ìdáhùn

Rárá, ó sì dá mi lójú pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè míì náà ò ní orílẹ̀-èdè tiwa .

Ẹ̀jẹ̀

Ìbéèrè

Kí nìdí tí ẹ kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀ sára?

ìdáhùn

Oríṣiríṣi ìtọ́jú tó péye ni mo lè gbà, pàápàá irú èyí tí ò lè fúnni lárùn Éèdì. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀, ìdí nìyẹn témi fi kọ ìtọ́jú tó bá ti ní í ṣe pẹ̀lú gbígba ẹ̀jẹ̀.

Ìbéèrè míì

Tó bá jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe ẹ́ yẹn lè gbẹ̀mí ẹ ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run ò lè torí ìyẹn dárí jì ẹ́ ni?

Ìwádìí

Ìṣe 5:28, 29; Hébérù 11:6; Bíbélì Fi Kọ́ni, ojú ìwé 129 sí 131.

ìdáhùn

Yíyàn

Ìbéèrè

Lágbájá tó wà níjọ yín ṣohun báyìí báyìí. Kí nìdí tíwọ ò fi lè ṣe é?

ìdáhùn

Ìlànà Ọlọ́run ni wọ́n n kọ́ wa kì í ṣe pé wọ́n máa ń fipá mú wa ṣe nǹkan! Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ohun tó máa ṣe.

Ìbéèrè míì

Ṣéyẹn ò fi hàn pé ṣe lẹ̀ ń fá rí apá kan dá apá kan sí?

Ìwádìí

ìdáhùn

Ìṣẹ̀dá

Ìbéèrè

Kí nìdí tó ò fi gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́?

ìdáhùn

WKí nìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sọ pé ara ẹranko lati wa gbọ́? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó yẹ kí wọ́n jẹ́ ògbógi gan-an ò fẹnu kò lórí ẹ̀, ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni kí n wá gbà gbọ́!

Ìbéèrè míì

Ìwádìí

ìdáhùn

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

d Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

e Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ńṣe ni sísọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́ dà bíi wíwẹ̀ lódò. O lè rọra rìn wọnú omi, àbí kẹ̀ kó o bẹ́ ludò!