Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táwọn Ọkùnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

Kí Nìdí Táwọn Ọkùnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Kí Nìdí Táwọn Ọkùnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

Bọ̀bọ́ yìí mọ̀ pé mo gbajúmọ̀ gan-an torí mo ti sọ fún un pé àwọn ọkùnrin gba tèmi. Ó rẹ́rìn-ín nígbà tí mo sọ fún un nípa ohun tí kò bọ́gbọ́n mu táwọn ọ̀rẹ́ mi kan ṣe. Ó mọ̀ pé mo gbọ́n gan-an, mo tiẹ̀ ti tọ́ ọ sọ́nà nígbà tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tí kò yẹ kó sọ. Mi ò wá mọ ìdí tí kò fi tíì sọ fún mi pé ká máa fẹ́ra wa.

Ọmọ yìí rẹwà lóòótọ́, àmọ́ ó jọ pé ẹwà ojú lásán ni! Kì í tiẹ̀ fún mi láyè láti sọ̀rọ̀! Bí mo bá wá jàjà sọ̀rọ̀, àṣìṣe mi ló máa ń rí! Bí mo bá ti rí i báyìí, ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi kí n wábi gbà.

ṢÉ Ó máa ń dùn ẹ́ pé àwọn ọkùnrin ò rí tìẹ rò? Ọ̀pọ̀ obìnrin ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń dùn, títí kan àwọn tó o rò pé àwọn ọkùnrin gba tiwọn gan-an! Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Joanne yẹ̀ wò. Ó jẹ́ obìnrin tó jojú ní gbèsè, tó ní làákàyè, tó sì mọ ọ̀rọ̀ sọ. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn ọkùnrin ò gba tèmi. Àwọn kan tí mo fẹ́ràn tiẹ̀ kọ́kọ́ fìfẹ́ hàn sí mi, àmọ́ nígbà tó yá wọn ò bá mi sọ̀rọ̀ mọ́ rárá!”

Kí ló máa ń fa àwọn ọkùnrin mọ́ra lára obìnrin? Kí ló sì máa ń lé wọn sá? Kí lo lè ṣe tí ọkùnrin tó níwà ọmọlúwàbí á fi kọnu sí ẹ, tó ò sì ní fi ara rẹ wọ́lẹ̀?

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe

Mọ ara rẹ dunjú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí bàlágà lọkàn rẹ túbọ̀ ń fà sí ọkùnrin. Ọkàn rẹ tiẹ̀ lè ti fà sí àwọn ọkùnrin bíi mélòó kan. Ìyẹn kì í ṣohun tuntun. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọkùnrin tí ọkàn rẹ kọ́kọ́ fà sí lo bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, ó ṣeé ṣé kí ìyẹn ṣàkóbá fún ìmọ̀lára rẹ àti àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó máa gba àkókò kó o tó lè ní àwọn ànímọ́ rere kan, kó o tó lè ‘yí èrò rẹ pa dà’ lórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì, kí ọwọ́ rẹ sì tó lè tẹ àwọn kan lára àwọn àfojúsùn rẹ.Róòmù 12:2; 1 Kọ́ríńtì 7:36; Kólósè 3:9, 10.

Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló máa ń fẹ́ láti fa ojú àwọn obìnrin tí kò lè dá ìpinnu ṣe tàbí tí kò tíì ní ìrírí mọ́ra. Àmọ́, kì í ṣe ànímọ́ tí obìnrin náà ní ló wu irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń fẹ́ ò ju pé kí wọ́n bá a sùn lọ. Ohun tó dájú ni pé obìnrin tó láwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ kí àjọṣe wọn nítumọ̀ ni ọkùnrin tó mọ ohun tó tọ́ máa fẹ́ fi ṣe aya.—Mátíù 19:6.

Ohun táwọn ọkùnrin kan sọ: “Ó máa ń wù mí kí obìnrin lè ṣèpinnu, kó sì mọ ohun tó ń ṣe.”—James.

“Mo nífẹ̀ẹ́ sí obìnrin tí kì í kàn gbà pé gbogbo ohun tí mo bá ṣáà ti sọ náà ló tọ̀nà, àmọ́ tó máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ì báà jẹ́ ọmọ tó rẹwà, mi ò fẹ́ obìnrin tó jẹ́ pé ohun tó bá ṣáà ti wù mí gbọ́ ló máa ń sọ. Mo máa ń bẹ̀rù irú obìnrin bẹ́ẹ̀!”—Darren.

“Òótọ́ ni pé ọmọbìnrin tó bá rẹwà máa ń kọ́kọ́ wù mí. Àmọ́, ẹwà yẹn kì í pẹ́ ṣá lójú mi bí mo bá ti rí i pé ọmọbìnrin náà kò ní àfojúsùn kan pàtó. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ó mọ ohun tó fẹ́ fi ayé rẹ̀ ṣe, pàápàá bí mo bá rí i pé ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ díẹ̀ lára àwọn àfojúsùn rẹ̀, ìyẹn á mú kí n gba tiẹ̀ gan-an ni.”—Damien.

Máa bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì. Bó ṣe máa ń wù ẹ́ pé kí ọkùnrin fẹ́ràn ẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló máa ń wu àwọn ọkùnrin gan-an pé kéèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí Bíbélì fi sọ pé kí ọkọ fẹ́ràn aya rẹ̀, àmọ́ kí aya ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún ọkọ rẹ̀. (Éfésù 5:33) Ìwádìí táwọn kan ṣe fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, torí pé ọ̀dọ́kùnrin mẹ́fà nínú mẹ́wàá ló sọ pé àwọn ka ọ̀wọ̀ sí pàtàkì ju ìfẹ́ lọ. Nínú ìwádìí yẹn, èyí tó ju méje lọ nínú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó jẹ́ àgbàlagbà ló fara mọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyẹn sọ.

Bíbọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì kò túmọ̀ sí pé èrò rẹ ò ní yàtọ̀ sí tiwọn tàbí pé o ò ní máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 21:10-12) Bó o bá ṣe sọ èrò rẹ ló máa pinnu bóyá ọkùnrin máa sún mọ́ ẹ tàbí ó máa sá fún ẹ. Bó o bá ń ta ko gbogbo ohun tó bá sọ tàbí tó ò ń tún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe, ó lè máa rò pé o ò bọ̀wọ̀ fóun bó ṣe yẹ. Àmọ́ tó o bá jẹ́ kó mọ̀ pé o gba ohun tó sọ, tó o sì mẹ́nu ba àwọn nǹkan tó dáa nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó fara mọ́ èrò rẹ, kó sì ka ọ̀rọ̀ rẹ sí. Tún rántí pé ọkùnrin tó bá lákìíyèsí á mọ̀ tó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé rẹ̀ àtàwọn ẹlòmíì. a

Ohun táwọn ọkùnrin kan sọ: “Inú àwọn ọkùnrin máa ń dùn tí wọ́n bá mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn tà létí ẹnì kan, pàápàá létí ọmọbìnrin tí wọ́n bá fẹ́ràn.”—Anthony

“Lójú tèmi, ọ̀wọ̀ ló ṣe pàtàkì jù nígbà táwọn méjì bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra wọn. Bó pẹ́ bó yá wọ́n á wá nífẹ̀ẹ́ ara wọn.”—Adrian.

“Bí ọmọbìnrin kan bá lè bọ̀wọ̀ fún mi, á jẹ́ pé kò ní ṣòro fún un láti nífẹ̀ẹ́ mi nìyẹn.”—Mark.

Múra lọ́nà tó tọ́, kó o sì máa mọ́ tónítóní nígbà gbogbo. A lè fi aṣọ àti ìmúra rẹ wé ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn tó ń sọ ohun tó ò ń rò àti irú ẹni tó o jẹ́ fáwọn èèyàn. Kó tiẹ̀ tó di pé o bẹ̀rẹ̀ sí bá ọkùnrin kan sọ̀rọ̀, ìmúra rẹ á ti jẹ́ kó mọ irú ẹni tó o jẹ́. Ojú tó dáa ló máa fi wò ẹ́ bí ìmúra rẹ bá jẹ́ ti ọmọlúwàbí. (1 Tímótì 2:9) Tí aṣọ bá fún mọ́ ẹ lára pinpin, tó ṣí ara sílẹ̀ tàbí tó rí wúruwùru, kíá ló ti máa mọ̀ pé o kì í ṣe ọmọlúwàbí!

Ohun táwọn ọkùnrin kan sọ: “Bí obìnrin kan bá ṣe múra máa ń sọ irú ẹni tó jẹ́. Tó bá jẹ́ pé aṣọ tó ṣí ara sílẹ̀ tàbí tó rí wúruwùru ló wọ̀, ìyẹn á jẹ́ kí n mọ̀ pé ńṣe ló ń pe àfiyèsí sí ara rẹ̀.”—Adrian.

“Mo fẹ́ràn obìnrin tó bá ń tọ́jú irun rẹ̀, tí ara rẹ̀ kì í rùn, tí ohùn rẹ̀ sì tuni lára. Ìgbà kan wà tí mo rí ọmọbìnrin kan tí ẹwà rẹ̀ kọ́kọ́ fà mí mọ́ra, àmọ́, nígbà tí mo wá rí i pé ọ̀bùn ṣìọ̀ṣìọ̀ ni, ńṣe ni ìfẹ́ yẹn pòórá.”—Ryan.

“Mo máa ń gba ti obìnrin tó mọ̀ pé kò dìgbà tóun bá tọ́jú tọ́tè, tóun wọ aṣọ tó fún mọ́ra pinpin tàbí èyí tó ṣí ara sílẹ̀ káwọn ọkùnrin tó lè gba tòun.”—Ethan.

“Ká sòótọ́, ọkàn mi máa ń kọ́kọ́ fà sí ọmọbìnrin tó bá wọ aṣọ tó fún mọ́ra pinpin tàbí tó ṣí ara sílẹ̀, àmọ́, mi ò lè fẹ́ irú obìnrin bẹ́ẹ̀.”—Nicholas.

Ohun Tí Kò Yẹ Kó O Ṣe

Má ṣe sọ ara rẹ di oníṣekúṣe. Àwọn obìnrin lè fa ojú àwọn ọkùnrin mọ́ra lọ́nà tó lágbára. Wọ́n sì lè lo agbára tí wọ́n ní yìí lọ́nà tó tọ́ tàbí lọ́nà tí kò tọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 29:17, 18; Òwe 7:6-23) Bó bá jẹ́ pé gbogbo ọkùnrin tó o bá ṣáà ti rí lo máa ń fẹ́ fa ojú wọn mọ́ra, oníṣekúṣe làwọn èèyàn á máa pè ẹ́.

Ohun táwọn ọkùnrin kan sọ: “Tí ọkùnrin bá kàn jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin kan tó wà pa tí wọ́n sì ń fara kanra, ó máa ń dùn mọ́ ọkùnrin. Torí náà, ojú oníṣekúṣe ni mo máa fi ń wo obìnrin tó bá ń fọwọ́ jẹ ọkùnrin lára ṣáá nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀.”—Nicholas.

“Bó bá jẹ́ pé gbogbo ọkùnrin tí obìnrin kan bá ṣáà ti pàdé ló máa ń fọwọ́ jẹ lára tàbí tójú ẹ̀ ò kúrò lára gbogbo ọkùnrin tó bá ń kọjá, oníṣekúṣe lèmi ka irú wọn sí, mo sì máa ń jìnnà sí wọn.”—José.

“Ojú oníṣekúṣe ni mo máa fi ń wo obìnrin tó bá ń fọwọ́ jẹ gbogbo ọkùnrin lára, tó sì máa ń yára gba ti ọkùnrin èyíkéyìí tó bá fún un láfiyèsí jù lọ.”—Ethan.

Má toro mọ́ ọkùnrin. Bíbélì sọ pé tí ọkùnrin àti obìnrin bá ti ṣègbéyàwó, wọ́n á di “ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Lẹ́yìn ìgbéyàwó, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo òmìnira tí tọkọtaya ní nígbà tí wọ́n ṣì wà lápọ̀n ni wọn kì í ní mọ́, wọ́n á wá ṣe ara wọn lọ́kan. (1 Kọ́ríńtì 7:32-34) Àmọ́ ṣá o, tó bá jẹ́ pé ìwọ àti ọkùnrin kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọra yín ni, o ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa retí pé gbogbo nǹkan tí tọkọtaya máa ń sọ fún ara wọn náà lẹ gbọ́dọ̀ máa sọ fún ara yín. Bí o kò bá fara balẹ̀, tó ò ń retí pé tìẹ ni kó máa gbọ́ ní gbogbo ìgbà, èyí lè ba àjọṣe yín jẹ́. b

Ohun táwọn ọkùnrin kan sọ: “Mi ò gba ti obìnrin tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe ló máa ń fẹ́ mọ̀, tó sì dà bíi pé kì í fẹ́ bá àwọn míì da nǹkan pọ̀ àfi èmi nìkan ṣá, tí kò sì ní nǹkan míì tó ń rò.”—Darren.

“Bí ọmọbìnrin tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù mi ṣáá, tó sì ń fẹ́ mọ àwọn tá a jọ wà níbi tí mo wà, pàápàá tó bá fẹ́ mọ orúkọ àwọn obìnrin tó bá wà láàárín wa, á jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wa ò lè wọ̀ nìyẹn.”—Ryan.

“Èmi ò fẹ́ ọmọbìnrin tí kò bá ti ní jẹ́ kí n gbádùn ara mi pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi ọkùnrin, tó sì máa ń bínú pé mi kì í pe òun wá sọ́dọ̀ mi nígbà gbogbo.”—Adrian.

Má Ṣe Fi Ara Rẹ Wọ́lẹ̀

Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn obìnrin kan tó jẹ́ pé kò sóhun tí wọn ò lè ṣe kí ọkùnrin lè gba tiwọn. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń wọ́ ara wọn nílẹ̀ kí wọ́n ṣáà lè ní ọ̀rẹ́kùnrin tàbí ọkọ pàápàá. Àmọ́, ó yẹ kó o máa rántí ìlànà tó sọ pé ‘ohun tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn ló máa ká.’ (Gálátíà 6:7-9) Bó o bá tara ẹ lọ́pọ̀, tó o sì pa ìwà ọmọlúwàbí tì, àwọn ọkùnrin tí kò mọyì ẹ, tí wọn ò sì ka ìwà ọmọlúwàbí sí pàtàkì ló máa gba tìẹ.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe gbogbo ọkùnrin ló máa gba tìẹ, ohun tó dáa sì nìyẹn! Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹwà ara àti ẹwà inú rẹ lo fún láfiyèsí, wàá “níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run,” irú ọkùnrin tó tọ́ sí ẹ lo sì máa fi ṣe ọkọ.—1 Pétérù 3:4.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . “ nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Àmọ́ ṣá o, bí ẹni méjì bá ti bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra wọn, ó yẹ kí wọ́n máa finú han ara wọn.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

● Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún èrò àti ìmọ̀lára ọkùnrin kan?

● Kí lo lè ṣe tó ò fi ní wọ́ ara rẹ nílẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Bó ṣe jẹ́ pé táyà kẹ̀kẹ́ méjèèjì ló ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ṣe pàtàkì