Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìbálòpọ̀ Máa Jẹ́ Ká Túbọ̀ Fẹ́ràn Ara Wa?

Ṣé Ìbálòpọ̀ Máa Jẹ́ Ká Túbọ̀ Fẹ́ràn Ara Wa?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Ṣé Ìbálòpọ̀ Máa Jẹ́ Ká Túbọ̀ Fẹ́ràn Ara Wa?

Kò tíì ju oṣù méjì péré lọ tí Heather àti Mike bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra, àmọ́ lójú Heather, ṣe ló dà bíi pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọra. Léraléra ni wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wọn lórí fóònù, ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n tún máa fi ń bára wọn sọ̀rọ̀ lórí fóònù, ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì wọ̀ gan-an ni! Àmọ́ ní báyìí tí wọ́n jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ́wọ́ alẹ́ tí òṣùpá lé téńté, ohun tí Mike fẹ́ látọ̀dọ̀ Heather ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ.

Láàárín oṣù méjì tó kọjá, Mike àti Heather ò ṣe ju kí wọ́n kàn di ara wọn lọ́wọ́ mú, kí wọ́n sì fẹnu konu fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lọ. Heather kò fẹ́ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀, kò fẹ́ kí Mike fi òun sílẹ̀. Kò sẹ́ni tó gba tiẹ̀ tó Mike ńṣe ni Mike máa ń kẹ́ ẹ lójú méjèèjì. Ó tún rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘ . . . èmi àti Mike kúkú fẹ́ràn ara wa gan-an ni.’

Ó ṢEÉ ṣe kó o ti máa ro ibi tí ọ̀rọ̀ Heather àti Mike máa já sí. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o má ronú kan bí ìbálòpọ̀ ṣe máa mú kí nǹkan yí pa dà bìrí láàárín wọn, ó sì dájú pé kì í ṣe àyípadà sí rere. Ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí ná:

Tó o bá rú òfin àdánidá kan, irú bí òfin òòfà tó máa ń mú kí gbogbo ohun tó bá ti lọ sókè pa dà wálẹ̀, ìwọ lo máa jìyà rẹ̀. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ tó o bá rú òfin nípa irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, bí èyí tó sọ pé: “Ẹ ta kété sí àgbèrè.” a (1 Tẹsalóníkà 4:3) Kí làwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó o bá rú òfin yìí? Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ṣé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? Gbìyànjú láti ṣàkọsílẹ̀ ohun búburú mẹ́ta tó lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tò ṣègbéyàwó. Kọ ọ́ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.

1. ․․․․․

2. ․․․․․

3. ․․․․․

Ní báyìí, wo àwọn ohun tó o kọ. Ṣé o kọ àrùn tó máa ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, oyún ẹ̀sín àti pípàdánù ojú rere Ọlọ́run? Ó dájú pé àwọn ohun búburú yìí lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni tó bá rú òfin Ọlọ́run nípa àgbèrè.

Síbẹ̀, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o ṣèṣekúṣe. O lè máa ronú pé, ‘kò sóhun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi.’ Ṣebí gbogbo èèyàn ló ń ní ìbálòpọ̀? Kódà, àwọn ojúgbà rẹ níléèwé kì í fọ̀rọ̀ bò rárá nígbà tí wọ́n bá ń ṣàlàyé báwọn ṣe ń gbádùn ìbálòpọ̀, ó sì dà bíi pé nǹkan kan ò ṣe wọ́n. Ìwọ náà sì lè máa ronú bíi ti Heather tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, pé ìbálòpọ̀ á jẹ́ kíwọ àti ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín dáadáa. Kò kúkú sẹ́ni tó máa fẹ́ kí wọ́n máa fòun ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé òun ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí. Ṣé kò wá ní sàn kéèyàn kúkú ṣe kinní ọ̀hún?

Àmọ́, rò ó dáadáa o! Ó yẹ kó o kọ́kọ́ mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń ṣe é. Òótọ́ ni pé, o lè ti ka àwọn àkọsílẹ̀ kan tó fi hàn pé àìmọye àwọn ọ̀dọ́ ló ń gbéra wọn sùn. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, ọ̀dọ́ méjì nínú mẹ́ta lórílẹ̀-èdè yẹn ló ti ń ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó jáde iléèwé girama. Àmọ́, èyí fi hàn pé ọ̀dọ́ kan nínú mẹ́ta ni kò tíì ní ìbálòpọ̀, iye yìí náà sì pọ̀ díẹ̀. Àwọn tó wá ń ní ìbálòpọ̀ ńkọ́? Àwọn olùwádìí kan ti rí i pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ẹ̀dùn ọkàn yìí máa ń dà láàmú.

Ẹ̀dùn Ọkàn Àkọ́kọ́: ÌDÁLẸ́BI. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó ló sọ pé àwọn kábàámọ̀ rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Ẹ̀dùn Ọkàn Kejì: ÀÌFỌKÀN TÁN ARA ẸNI. Lẹ́yìn tí ọkùnrin àti obìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó bá ti ní ìbálòpọ̀, wọ́n á máa ronú pé, ‘Ta ló mọ ẹlòmíì tó ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀?’

Ẹ̀dùn Ọkàn Kẹta: ÌWÀ Ọ̀DÀLẸ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ní ìbálòpọ̀, ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin fi ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ sílẹ̀, kó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹlòmíì.

Ẹ̀dùn Ọkàn Kẹrin: ÌJÁKULẸ̀. Nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún, àwọn ọmọbìnrin sábà máa ń fẹ́ ẹni tó máa tọ́jú wọn, kì í ṣe ẹni tó kàn máa bá wọn sùn tán, tí á sì já wọn jù sílẹ̀.

Yàtọ̀ sáwọn ohun tá a ti sọ yìí, tún gbé èyí yẹ̀ wò: Àìmọye àwọn ọmọkùnrin ló máa ń sọ pé àwọn ò lè fẹ́ ọmọbìnrin tí àwọn bá ti bá sùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé, wọn ò fẹ́ oníṣekúṣe obìnrin!

Ṣé ọ̀rọ̀ yìí yà ẹ́ lẹ́nu? Bóyá ó tiẹ̀ múnú bí ẹ pàápàá. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, yálà obìnrin ni ẹ́ tàbí ọkùnrin, máa rántí pé: Àwọn ohun tí wọ́n máa ń fi hàn nínú fíìmù àti lórí tẹlifíṣọ̀n nípa ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó yàtọ̀ sí bọ́rọ̀ náà ṣe rí gan-an lójú ayé. Àwọn tó ń ṣe fíìmù àtàwọn olórin máa ń gbé ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún lárugẹ, wọ́n sì ń mú kó dà bíi pé ìfẹ́ tòótọ́ ni. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́ jẹ o! Ńṣe làwọn tó fẹ́ dọ́gbọ́n tàn ẹ́ sínú ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó kàn fẹ́ tẹ́ ìfẹ́ ọkàn ara wọn lọ́rùn. (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ṣó o rò pé ẹni tó bá fẹ́ràn rẹ lóòótọ́ á ṣe ohun tó máa ṣàkóbá fún ara àti ìmọ̀lára rẹ? (Òwe 5:3, 4) Ṣé ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ dénú á tàn ẹ́ láti ṣe ohun tó máa mú kí àjọṣe ìwọ àti Ọlọ́run bà jẹ́?—Hébérù 13:4.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tó o bá lọ ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó, ṣe lo ta ara rẹ lọ́pọ̀, tó o sì sọ nǹkan tó níye lórí gan-an nù. (Róòmù 1:24) Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kó sí pàkúté yìí fi máa ń wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, bíi pé àwọn ti jẹ́ kí ẹnì kan jí ohun pàtàkì kan nínú ara àwọn! Má ṣe jẹ́ kírú èyí ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Bí ẹnì kan bá fẹ́ dọ́gbọ́n tàn ẹ́ kẹ́ ẹ lè bá ara yín lòpọ̀, tó ń sọ pé, “Tó o bá fẹ́ràn mi, wàá gbà fún mi,” ìwọ náà fún un lésì láìyẹhùn pé, “Tó o bá fẹ́ràn mi, o ò ní fi lọ̀ mí!”

Máa fi sọ́kàn pé ara rẹ ṣe iyebíye gan-an, kò sì ní dáa kó o ta ara ẹ lọ́pọ̀. Fi hàn pé o lè pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ pé ká sá fún àgbèrè. Tó o bá sì wá ṣègbéyàwó nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wàá lómìnira láti ní ìbálòpọ̀. Wàá sì lè gbádùn rẹ̀ dáadá, láìsí ìdààmú tàbí àbámọ̀, o ò sì ní kó sínú àìbalẹ̀ ọkàn tí àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó máa ń ní.—Òwe 7:22, 23; 1 Kọ́ríńtì 7:3.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú Bíbélì, kì í ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ni ọ̀rọ̀ náà “àgbèrè” ń tọ́ka sí, àmọ́ ó tún kan àwọn nǹkan míì tí àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya máa ń ṣe, irú bíi fífọwọ́ pa èyà ìbímọ ẹlòmíì, fifi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì tàbí bíbá ẹlòmíì lò pọ̀ ní ihò ìdí. Tó o bá fẹ́ àlàyé púpọ̀ sí i, wo ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá 2, ojú ìwé 42 sí 47.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

● Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó lè máa wu àwa ẹ̀dá aláìpé, kí nìdí tí kò fi yẹ kó o lọ́wọ́ sí i?

● Kí lo máa ṣe bí ẹnì kan bá sọ pé kẹ́ ẹ jọ ní ìbálòpọ̀?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Tó o bá kàn sọ pé o ò ṣe, ìyẹn ò ní kí ẹni yẹn fi ẹ́ sílẹ̀. Bó o bá ṣe sọ̀rọ̀ ló ṣe pàtàkì. Tó o bá kàn rọra sọ̀rọ̀, tó sì dà bíi pé ohun tó o sọ kò dénú ẹ, onítọ̀hún náà á ti mọ̀. Torí náà, o gbọ́dọ̀ dúró lórí ohun tó o sọ!”

“Ọ̀rọ̀ kì í yanjú tó o bá kàn sọ pé ‘mi ò ṣe.’ Kódà, tó o bá ṣàlàyé àwọn ohun tó o gbà gbọ́, ìyẹn ò ní kí onítọ̀hún fi ẹ́ sílẹ̀. Mo mọ àwọn kan tí wọ́n máa ń ṣakọ pé àwọn ti mú Kristẹni kan ‘balẹ̀.’ Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé, àfi kéèyàn kúrò lọ́dọ̀ wọn. Èyí kì í rọrùn láti ṣe o, àmọ́ ohun tó ran àwọn kan lọ́wọ́ nìyẹn.”

“Torí pé o jẹ́ Kristẹni, o ní àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ káwọn ẹlòmíì fẹ́ràn rẹ. Torí náà, o gbọ́dọ̀ wà lójúfò, kó o sì kọ̀ jálẹ̀ táwọn kan bá fẹ́ kó o ṣohun tí kò tọ́. Fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ànímọ́ tó o ní. Má ṣe ta ara rẹ lọ́pọ̀!”

[Àwọn àwòrán]

Diana

James

Joshua

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

FI HÀN PÉ ỌKÙNRIN NI Ẹ́!

Tó o bá ní ọmọbìnrin tó ò ń fẹ́, ṣé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú lóòótọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó mọ̀ pé,

o lè pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́

o ní ọgbọ́n tó o lè fi yẹra fún àwọn ipò tó lè mú kẹ́ ẹ ṣèṣekúṣe

o ní ìfẹ́ rẹ̀ débi pé o ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa ṣàkóbá fún un

Tó o bá ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí, inú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ máa dùn bíi ti ọmọbìnrin Ṣúnémù tó sọ pé: “Tèmi ni olólùfẹ́ mi, tirẹ̀ sì ni èmi.” (Orin Sólómọ́nì 2:16) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ni wàá fi hàn pé ọkùnrin ni ẹ́!

Wo Òwe 22:3; 1 Kọ́ríńtì 6:18; 13:4-8.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

ÀBÁ

Tó bá dọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ kí ọkùnrin àti obìnrin máa ṣe pẹ̀lú ara wọn, ìlànà tó dára tó yẹ kó o máa tẹ̀ lé rèé: Tí kì í bá ṣe ohun tó o fẹ́ kí àwọn òbí rẹ ká mọ́ ẹ lọ́wọ́, a jẹ́ pé kò yẹ kó o ṣe é nìyẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Tó o bá ń ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó, ṣe lò ń ṣe ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ẹ ṣúkaṣùka. Ńṣe ló dà bí ìgbà tó o fi àwòrán tó rẹwà tí ẹnì kan fún ẹ ṣe ìnusẹ̀