Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rẹ́ Èké

Ọ̀rẹ́ Èké

Ọ̀rẹ́ Èké

O ní “ọ̀rẹ́” kan tẹ́ ẹ ti mọra láti ìgbà tó o wà lọ́dọ̀ọ́. Ó máa ń jẹ́ kó o túbọ̀ rí ara rẹ bí ẹni tó ti gòkè àgbà, ó sì máa ń jẹ́ kó o lè bá ẹgbẹ́ pé. Kò sígbà tí nǹkan bá tojú sú ẹ, tí kì í wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti “tù ẹ́ lára.” Lọ́rọ̀ kan ṣá, ọ̀pọ̀ ìgbà lo máa ń gbára lé e fún ìrànlọ́wọ́.

Àmọ́ nígbà tó yá, o wá kíyè sí àwọn nǹkan kan tí kò dáa nípa ọ̀rẹ́ rẹ yìí. Ó fẹ́ máa wà pẹ̀lú rẹ ṣáá nígbà gbogbo, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé èyí ò ní jẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dáa wò ẹ́ láwọn ibì kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mú kó o túbọ̀ rí ara rẹ bíi pé o ti gòkè àgbà, àkóbá tó ń ṣe fún ìlera rẹ kò kéré rárá. Paríparí rẹ̀, ó ti jí lára owó rẹ.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, o ti gbìyànjú láti fòpin sí àjọṣe yín, àmọ́ kò fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀. Ká kúkú sọ pé òun ló ń darí rẹ. O kábàámọ̀ pé o ní irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀.

IRÚ nǹkan tí ojú ọ̀pọ̀ àwọn tó ń mu sìgá ń rí nìyí. Lẹ́yìn àádọ́ta [50] ọdún tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Earline ti ń mu sìgá, ó sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ tí sìgá máa ń ṣe fún mi ju èyí tí èèyàn èyíkéyìí lè ṣe fún mi lọ. Yàtọ̀ sí pé ó ti pẹ́ tá a ti ń bára wa bọ̀, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé òun nìkan ló máa ń kù mí kù.” Nígbà tó yá, obìnrin yìí wá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ èké àti apanilára ni sìgá. Kódà, ohun kan péré ni ọ̀rọ̀ obìnrin yìí fi yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Nígbà tó wá mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa kórìíra sìgá mímu, torí pé ó máa ń ṣàkóbá fún ara, ó jáwọ́ nínú àṣà yìí.—2 Kọ́ríńtì 7:1.

Bákan náà, ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Frank pinnu láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, torí pé ó fẹ́ ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí. Àmọ́, lẹ́yìn ọjọ́ tó pinnu pé òun kò ní mu sìgá mọ́, ńṣe ló tún bẹ̀rẹ̀ sí í rá pálá nínú yàrá rẹ̀ tó ń wá àwọn àmukù sìgá tó há sáwọn ibì kan ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Ọkùnrin náà sọ pé: “Èyí ló pe orí mi wálé tí mo sì ṣe ìpinnu. Bí mo ṣe ń rá pálá nínú ìdọ̀tí torí pé mò ń wá àmukù sìgá rí mi lára gan-an ni. Bó ṣe di pé mi ò fẹnu kan sìgá mọ́ nìyẹn o.”

Kí nìdí tó fi ṣòro tó bẹ́ẹ̀ láti jáwọ́ nínú sìgá mímu? Àwọn olùṣèwádìí sọ àwọn ohun mélòó kan tó fà á. (1) Bíi ti oògùn olóró, àwọn ohun tí wọ́n ń mú jáde láti ara tábà lè di bára kú. (2) Béèyàn bá fa èròjà olóró inú sìgá sí agbárí, ó máa dé inú ọpọlọ láàárín ìṣẹ́jú àáyá méje. (3) Sìgá mímu máa ń di bára kú torí wọ́n sábà máa ń mu ún láwọn ibi tí wọ́n bá ti ń jẹun, tí wọ́n ti ń mutí, tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀, tí wọ́n ti ń wá ìtura kúrò lọ́wọ́ ìdààmú ọkàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Síbẹ̀, bá a ṣe rí i nínú ọ̀rọ̀ Earline àti Frank, èèyàn lè jáwọ́ nínú àṣà tó ń di bárakú tó sì ń pani lára yìí. Bó bá jẹ́ pé o máa ń mu sìgá, tó o sì fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀, tó o bá ka àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, ó lè jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun fún ẹ.