Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Yí Ẹ̀rẹ̀kẹ́ Kejì?

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Yí Ẹ̀rẹ̀kẹ́ Kejì?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Yí Ẹ̀rẹ̀kẹ́ Kejì?

NÍNÚ ìwàásù tí Jésù Kristi ṣe lórí òkè, èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ bí ẹní mọ owó, ó sọ pé: “Má ṣe dúró tiiri lòdì sí ẹni burúkú; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí èkejì sí i pẹ̀lú.”—Mátíù 5:39.

Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ṣé ohun tó ń sọ ni pé kí àwọn Kristẹni sọ ara wọn di ẹni tó ń fara gba ìyà láìṣe ohunkóhun láti dáàbò bo ara wọn? Ṣé ó ń retí pé kí àwọn Kristẹni má ṣe gbèjà ara wọn tí wọ́n bá ń jìyà, kí wọ́n má sì gbé ọ̀rọ̀ lọ sí ilé ẹjọ́?

Ohun Tí Jésù Ní Lọ́kàn

Tá a bá fẹ́ lóye ohun tí Jésù ní lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ ronú nípa ọ̀rọ̀ tó ń sọ bọ̀, ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e àti àwọn tó ń sọ̀rọ̀ náà fún. Ohun tí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ni Jésù fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tá a fà yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ó sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’”—Mátíù 5:38.

Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí Jésù ti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ni Ẹ́kísódù 21:24 àti Léfítíkù 24:20. Ohun kan tó gba àfiyèsí ni pé, ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Ọlọ́run, lẹ́yìn tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ bá ti jẹ́jọ́ níwájú àwọn àlùfáà àtàwọn adájọ́, tí wọ́n sì ti wò ó bóyá ó mọ̀ọ́mọ̀ hùwà ọ̀hún ni tàbí ohun kan ló mú kó dẹ́ṣẹ̀ náà ni wọ́n tó lè fi ìyà “ojú fún ojú” tí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn mẹ́nu bà jẹ ẹni náà lọ́nà tó tọ́.—Diutarónómì 19:15-21.

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn Júù kò fi òfin yìí sílò bó ṣe yẹ mọ́. Ìwé kan tí Ọ̀gbẹ́ni Adam Clarke kọ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún láti fi ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Ó jọ pé àwọn Júù ti sọ òfin yìí [ìyẹn òfin ojú fún ojú, eyín fún eyín] di òfin tó ń gbà wọ́n láyè láti máa di kùnrùngbùn síra wọn, wọ́n sì fi ń dá ara wọn láre láti máa gbẹ̀san. Bí wọ́n ṣe ń gbẹ̀san ara wọn ti wá lékenkà, ohun tí wọ́n sì máa ń ṣe pa dà máa ń le ju aburú tí ẹni tó ṣẹ̀ wọ́n ṣe lọ.” Àmọ́ Ìwé Mímọ́ kò fún wa láṣẹ láti máa gbẹ̀san fúnra wa.

Ohun tí Jésù fi kọ́ni nínú ìwàásù tó ṣe lórí òkè nípa ‘yíyí ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì’ jẹ́ ká mọ ohun tí Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túmọ̀ sí ní ti gidi. Jésù kò ní in lọ́kàn pé bí wọ́n bá ti gbá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, kí wọ́n yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì sí onítọ̀hún kó lè gbá ìyẹn náà. Bó ṣe rí nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, títí dòní olónìí, bí ẹnì kan bá gbá ẹlòmíì létí, kì í ṣe pé ó fẹ́ dá àpá sí onítọ̀hún lára, àmọ́ ńṣe ló fẹ́ fi ìwọ̀sí lọ ẹni náà, kí wọ́n lè jọ wọ̀yá ìjà.

Torí náà, ohun tí Jésù ń sọ ni pé bí ẹnì kan bá gbá ẹlòmíì létí nítorí kó lè pè é níjà tàbí tó ń fi ẹni náà ṣe yẹ̀yẹ́ láti mú un bínú, kí ẹni tí wọ́n ń pè níjà náà má ṣe gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti yẹra fún ohun tó lè mú kí àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í fi oró ya oró.—Róòmù 12:17.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí bá ohun tí Sólómọ́nì Ọba sọ mu, ó ní: “Má sọ pé: ‘Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí mi gan-an, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe sí i. Èmi yóò san án padà fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ rẹ̀.’” (Òwe 24:29) Ẹni tó bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù máa yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì ní ti pé kò ní jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì fipá mú òun láti wọ̀yá ìjà pẹ̀lú wọn.—Gálátíà 5:26.

Ǹjẹ́ Ó Burú Kéèyàn Gbèjà Ara Rẹ̀?

Láti yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì kò túmọ̀ sí pé Kristẹni kan kò ní gbèjà ara rẹ̀ nígbà tí àwọn oníwà ipá bá gbéjà kò ó. Jésù kò sọ pé ká má gbèjà ara wa, àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé a kò gbọ́dọ̀ fi ìbínú lu ẹni tó bá gbéjà kò wá, ká má ṣe jẹ́ kí inú bí wa débi tá a máa fi gbẹ̀san. Bí ẹnì kan bá fẹ́ bá wa jà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí ìjà má bàa wáyé. Bákan náà, bí àwọn ọ̀daràn bá gbéjà kò wá, ó yẹ ká ṣe nǹkan kan láti dáàbò bo ara wa, ká sì wá ìrànlọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá.

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi ìlànà kan náà yìí sílò bó ṣe yẹ nígbà tí wọ́n ń gbèjà ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi òfin tó wà nígbà ayé rẹ̀ gbèjà ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti wàásù, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mátíù 28:19, 20) Nígbà kan tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì ń wàásù káàkiri ìlú Fílípì, àwọn aláṣẹ ìlú náà mú wọn, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń rú òfin.

Lẹ́yìn náà, wọ́n na àwọn méjèèjì lẹ́gba ní gbangba, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìgbọ́ ẹjọ́ wọn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù láǹfààní láti lo ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ ìlú Róòmù, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà táwọn aláṣẹ ìlú náà gbọ́ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni Pọ́ọ̀lù, ẹ̀rù bà wọ́n torí ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde rẹ̀, torí náà wọ́n pàrọwà fún Pọ́ọ̀lù àti Sílà pé kí wọ́n rọra máa lọ láìfa ìjọ̀ngbọ̀n kankan. Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.”—Ìṣe 16:19-24, 35-40; Fílípì 1:7.

Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó ti di dandan fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti fi òfin gbèjà ẹ̀tọ́ wọn léraléra ní ilé ẹjọ́, kí wọ́n lè máa bá a nìṣó láti jọ́sìn Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣe èyí, kódà láwọn ilẹ̀ táwọn aláṣẹ ti ń fi ẹnu lásán sọ pé àwọn èèyàn ní òmìnira ẹ̀sìn. Nígbà táwọn ọ̀daràn bá gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti láwọn ìgbà tí wọ́n bá wà nínú ewu, a ò retí pé kí wọ́n kàn máa yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì ni ti pé kí wọ́n kàn máa fara gba ìwọ̀sí, kí wọ́n má sì gbèjà ara wọn. Wọ́n máa ń fi òfin gbèjà ara wọn.

Torí náà, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ohun tó bá pọn dandan láti fìdí ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní múlẹ̀ lábẹ́ òfin, bí wọ́n tiẹ̀ mọ̀ pé àṣeyọrí tí èyí máa mú wá lè máà tó nǹkan. Torí náà, bíi ti Jésù, wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti yanjú, ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run máa ṣe ohun tó tọ́ torí pé òun ni arínúróde àti pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìdájọ́ pípé ti máa ń wá. (Mátíù 26:51-53; Júúdà 9) Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń rántí pé ti Jèhófà ni ẹ̀san.—Róòmù 12:17-19.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ni kò yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣe?—Róòmù 12:17.

● Ǹjẹ́ Bíbélì lòdì sí fífi òfin gbèjà ara ẹni? —Fílípì 1:7.

● Ìgbọ́kànlé wo ni Jésù ní nínú Bàbá rẹ̀?—Mátíù 26:51-53.