Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Rántí Dúpẹ́ Oore!

Máa Rántí Dúpẹ́ Oore!

Máa Rántí Dúpẹ́ Oore!

ÌGBÀ wo ni ẹnì kan dìídì kọ̀wé sí ẹ láti dúpẹ́ oore tó o ṣe fún un? Ìgbà wo ni ìwọ náà dìídì kọ̀wé sí ẹnì kan láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀?

Lóde oní tí ayé ti di ayé kọ̀ǹpútà, fífi ọwọ́ kọ lẹ́tà láti dúpẹ́ oore ti ń di ohun àtijọ́. Síbẹ̀, fífi ọwọ́ kọ lẹ́tà láti dúpẹ́ oore jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tá a fi ń sọ fún àwọn èèyàn pé a mọyì inú rere wọn. Àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí máa jẹ́ ká mọ báa ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

1. Fi ọwọ́ ara rẹ kọ ìwé náà dípò kó o fi ẹ̀rọ tẹ̀ ẹ́.

2. Dárúkọ ẹni tó o kọ lẹ́tà sí nínú ìwé náà.

3. Tó o bá rí ẹ̀bùn gbà, dárúkọ ẹ̀bùn náà, kó o sì sọ bó o ṣe máa lò ó.

4. Tún sọ ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ ní ìparí lẹ́tà rẹ.

Lẹ́tà tá a fi ọwọ́ kọ láti dúpẹ́ oore máa ń jẹ́ ìwúrí fún ẹni tá a bá kọ ọ́ sí.

Nítorí náà, fi hàn pé o kì í ṣe aláìmoore nígbà tí ẹnì kan bá ṣoore fún ẹ, tó gbà ẹ́ lálejò tàbí tó fún ẹ lẹ́bùn. Máa rántí dúpẹ́ oore!

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àǹtí Mojí Mi Ọ̀wọ́n, #2

Ẹ ṣeun gan-an fún aago tó ní àláàmù #3 tẹ́ ẹ fún mi! Aago náà wúlò fún mi gan-an, torí pé mo ti máa ń sùn púpọ̀ jù. Inú mi dùn pé mo rí yín lọ́sẹ̀ tó kọjá. Ṣé ayọ̀ àti àlàáfíà ni ẹ dé ilé? Láyọ̀ la tún máa ríra o.

Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀bùn tẹ́ ẹ fún mi! #4

Èmi ni tiyín ní tòótọ́,

Ṣọlá

[Àwòrán]

#1

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

ÀWỌN ÀBÁ TÓ O LÈ TẸ̀ LÉ

● Tó bá jẹ́ owó ni ẹnì kan fún ẹ, má ṣe mẹ́nu kan iye owó yẹn nígbà tó o bá ń dúpẹ́. Bí àpẹẹrẹ, dípò kó o sọ iye owó tí ẹni náà fún ẹ, o lè sọ pé: “Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀bùn tẹ́ ẹ fún mi. Màá fi ra . . .”

● Ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bùn náà àti bó o ṣe mọyì ẹ̀bùn náà nìkan ni kó o kọ sínú lẹ́tà rẹ. Kì í ṣe inú lẹ́tà ìdúpẹ́ lo ti máa ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bó o ṣe lo àkókò ìsinmi rẹ tàbí nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ìwòsàn tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ.

● Má ṣe ṣàròyé nípa ìṣòro èyíkéyìí tó o bá ní pẹ̀lú ẹ̀bùn náà. Bí àpẹẹrẹ, o kò ní fi hàn pé o moore tó o bá kọ ọ́ sínú lẹ́tà náà pé: “Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀wù tẹ́ ẹ rà fún mi, àmọ́ ó tóbi jù mí lọ!”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká ya aláìmoore. (Lúùkù 17:11-19) Ó gbà wá níyànjú pé ká “máa gbàdúrà láìdabọ̀” sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́.”​—1 Tẹsalóníkà 5:17, 18.