Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ? BÁ A ṢE LÉ ṢÀṢEYỌRÍ TÓ MÁA TỌ́JỌ́

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ? BÁ A ṢE LÉ ṢÀṢEYỌRÍ TÓ MÁA TỌ́JỌ́

Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tá a lè kà sí àṣeyọrí. Ohun tó kọ́ni yàtọ̀ sí èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní pé, ìwọ̀nba làwọn tó máa ń rìnnà kore. Bíbélì ò fọwọ́ sí ohun táwọn èèyàn máa ń sọ pé ‘ibi tí èrò ọkàn rẹ bá darí rẹ sí,’ ni ọ̀nà àṣelà rẹ. Àti kékeré ni wọ́n ti máa ń gbìn èrò yìí sáwọn ọmọdé lọ́kàn, àmọ́ ìjákulẹ̀ ni irú èrò bẹ́ẹ̀ máa ń já sí nígbẹ̀yìn.

Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tí ò lè ṣàṣeyọrí, ó kàn gba ìsapá ni. Jẹ́ ká gbé àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ yẹ̀ wò.

  • OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

    “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.”​—Oníwàásù 5:​10.

    OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ. Ti pé ẹnì kan kó ọrọ̀ jọ kò sọ pé ó máa ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọrọ̀ kì í fúnni láyọ̀. Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Jean M. Twenge sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Generation Me, pé: “Àwọn tó ń lé bí wọ́n ṣe máa di ọlọ́rọ̀ máa ní ìdààmú ọkàn to pọ̀ ju àwọn tó ń lé bí wọ́n á ṣe máa gbé lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwádìí fi ń yé wa pé owó kò le ra ayọ̀, wàá rí i pé tó o bá ti lé owó kọjá ìwọ̀nba tó o nílò láti gbẹ́ ẹ̀mí ró, àìbalẹ̀ ọkàn lèyí tó kù.”

    OHUN TÓ O LÈ ṢE. Àwọn nǹkan mí ì wà tó ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ àti dúkìá lọ, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni kó o máa lé. Rántí ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.”​—Lúùkù 12:15.

  • OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

    “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”​—Òwe 16:​18.

    OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ. Ìgbéraga tàbí lílépa ipò ńlá kì í jẹ́ kéèyàn lè ṣàṣeyọrí gidi. Ìwé kan tó ń jẹ́ Good to Great sọ pé: “Bí ẹ bá rí iléeṣẹ́ tó ń gbèrú dáadáa, ẹ wádìí wò, àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ yẹn ni ò ṣe jura wọn lọ, wọn ò sì gbé ìgbésí ayé ṣekárími. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ mí ì ti máa ń gbéra ga jù. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ló máa fi tiwọn kó bá iléeṣẹ́, tí wọ́n á sì jẹ ẹ́ run kanlẹ̀.” Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ níbẹ̀ ni pé téèyàn bá ń ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ó ń bọ̀ wá tẹ́ nìyẹn, kò sì lè ṣàṣeyọrí.

    OHUN TÓ O LÈ ṢE. Dípò kó o máa le bí wàá ṣe dépò ńlá nínú ayé yìí, ì bá dáa kó o ṣe bó o ti mọ. Ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.” Èyí fi hàn pé agbéraga èèyàn ò lè ṣàṣeyọrí!​—Gálátíà 6:3.

  • OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

    “Kò sí ohun tí ó sàn ju pé . . . [kéèyàn] rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”​—Oníwàásù 2:​24.

    OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ. Tó o bá fara síṣẹ́, wàá gbádùn iṣẹ́ rẹ. Ìdí nìyí tí ọ̀mọ̀wé Madeline Levine fi sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Teach Your Chil­dren Well, pé: “Ìdí iṣẹ́ ẹni la ti ń mọni lọ́lẹ, ará ohun tó ń mú kéèyàn ṣàṣeyọrí nídìí iṣẹ́ ni pé kó mọ iṣẹ́ náà dunjú, kó sì jára mọ́ ọn tọkàntọkàn.” Bí ìjákulẹ̀ bá tiẹ̀ ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, téèyàn ò bá jọ̀gọ nù, á ṣàṣeyọrí.

    OHUN TÓ O LÈ ṢE. Ṣiṣẹ́ kára kó o lè já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ, tó o bá tiẹ̀ ko ìṣòro, fara dà á. Bó o bá ní àwọn ọmọ lọ́dọ̀, yanṣẹ́ fún wọn bí ọjọ́ orí wọn ṣe mọ. Bí wọ́n bá ko ìṣòro nídìí rẹ̀, má kàn sáré bá wọn yanjú ìṣòro náà, fún wọn láyè láti wá ọ̀nà àbáyọ, kí àwọn náà lè mọ béèyàn ṣe ń fàyà rán ìṣòro. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọdé ń fẹ́, ohun tó sì máa sọ wọ́n di ọ̀jáfáfá lẹ́yìnwá ọ̀la nìyẹn.

  • OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

    “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.”​—Oníwàásù 9:4.

    OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ. Ó dáa kéèyàn gbájú mọ́ṣẹ́ lóòótọ́, àmọ́ kò yẹ kó sọ ara rẹ̀ di ẹrú iṣẹ́. Èrè wò ló wà nínú kéèyàn ṣiṣẹ́-ṣiṣẹ́ kó di ẹni ńlá, kí wàhálà iṣẹ́ wá sọ ọ́ di aláìsàn tàbí kó má tiẹ̀ ráyè fáwọn ìdílé rẹ̀? Àwọn tá a lè sọ pé wọ́n ṣàṣeyọrí ní ti gidi sábà máa ń fi iṣẹ́ sí ààyè rẹ̀, wọ́n ń mójú tó ìlera wọn, wọ́n sì ń ráyè fún ìdílé wọn.

    OHUN TÓ O LÈ ṢE. Tọ́jú ara rẹ, kó o sì máa sinmi déédéé. Torí pé ẹ̀mí ò láàrọ̀, ká ṣiṣẹ́ bí ẹrú ò sì da nǹkan kan fúnni! Tó o bá tìtorí iṣẹ́ lọ ṣe ara rẹ léṣe tàbí já ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ jù sílẹ̀, ǹjẹ́ àṣeyọrí tó o bá ṣe nídìí iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè tọ́jọ́?

  • OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

    “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”​—Mátíù 5:3.

    OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ. Téèyàn bá fẹ́ ṣàṣeyọrí tó máa tọ́jọ́, ó pọndandan kó kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ ­Ọlọ́run, kó ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ń kọ́, kó sì máa fi ṣèwà hù. Ohun tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà karí ayé ń ṣe nìyẹn. Bá a tiẹ̀ nílò nǹkan tara díẹ̀, torí pé a fi ti Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa, àníyàn ọkàn wa ò kọjá àfaradà.​—Mátíù 6:​31-​33.

    OHUN TÓ O LÈ ṢE. Á dáa tí ìwọ náà bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o lè mọ bí wàá ṣe ṣàṣeyọrí tó máa tọ́jọ́. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí ­Jèhófà ládùúgbò rẹ tàbí kó o lọ sí orí ìkànnì wa ìyẹn,www.pr418.com/yo..