ÀWỌN Ọ̀DỌ́
10: Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbọ́kàn Lé
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ
Tí ọ̀dọ́ kan bá fẹ́ jẹ́ ẹni tó ṣeé gbọ́kàn lé, ó gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé òfin àwọn òbí rẹ̀, kó máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, kó sì máa sọ òtítọ́. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn òbí rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti ẹni tó bá gbà á sí iṣẹ́ máa gbẹ́kẹ̀ lé e.
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ
Lọ́pọ̀ ìgbà, bí àwọn òbí ẹ bá ṣe gbọ́kàn lé ẹ tó ni wọ́n á ṣe fún ẹ lómìnira tó.
“Tó o bá fẹ́ káwọn òbí rẹ gbọ́kàn lé ẹ, o gbọ́dọ̀ máa fi hàn nínú ìwà ẹ pé o mọ ohun tó tọ́ láti ṣe àti pé o mọ nǹkan tó ò ń ṣe, ó sì yẹ kó o máa fi hàn bẹ́ẹ̀ tó o bá wà pẹ̀lú wọn àtìgbà tó ò bá sí pẹ̀lú wọn.”—Sarahi.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kí ó fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—Jákọ́bù 3:13.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Tó o bá fẹ́ káwọn òbi rẹ máa gbọ́kàn lé ẹ, tàbí tó bá wù ẹ́ kí wọ́n túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ, àwọn nǹkan tó o lè ṣe rèé:
Jẹ́ olóòótọ́. Tó o bá ń purọ́, kò sẹ́ni tó máa fọkàn tán ẹ. Àmó tó o bá ń sọ òótọ́ ní gbogbo ìgbà, kódà nígbà tó o bá ṣe àṣìṣe, àwọn èèyàn máa fọkàn tán ẹ.
“Ó rọrùn láti jẹ́ olóòótọ́ tó o bá ń ṣe nǹkan dáadáa. Àmọ́ kì í rọrùn tó o bá ṣe nǹkan tó lè mú káwọn èèyàn máa fojú burúkú wò ẹ́. Síbẹ̀, tó o bá gbìyànjú láti jẹ́ olóòótọ́, àwọn èèyàn máa túbọ̀ fọkàn tán ẹ.”—Caiman.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “A dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
Jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn agbanisíṣẹ́ ló sọ pé “ẹni táwọn bá fẹ́ gbà sí iṣẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán.” Tó o bá jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán nísìnyí, á ṣe ẹ́ láàǹfààní tó o bá dàgbà.
“Àwọn òbí mi máa ń mọ̀ tí mo bá ṣe ohun tó yẹ kí n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tí mo bá ṣe àwọn iṣẹ́ ilé láì jẹ́ pé wọ́n sọ fún mi, inú wọn máa ń dùn. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán mi.”—Sarah.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìfohùnṣọ̀kan rẹ, mo sì mọ̀ pé ìwọ yóò tilẹ̀ ṣe ju àwọn ohun tí mo wí.’—Fílémónì 21.
Jẹ́ onísùúrù. Ó lè rọrùn fún àwọn èèyàn láti tètè kíyè sí bó o ṣe ń dàgbà, àmọ́ ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò kí wọ́n tó lè mọ̀ bóyá o ní ìwà àgbà, o sì mọ ohun tó ò ń ṣe.
“Kì í ṣe ohun tó o bá ṣe lẹ́ẹ̀kàn ṣoṣo ló máa jẹ́ kí àwọn òbí rẹ àti àwọn míì fọkàn tán ẹ. Àmọ́ tó o bá ń hùwà dáadáa nìgbà gbogbo, tó o sì fi hàn pé o mọ ohun tí ò ń ṣe, wọ́n á fọkàn tán ẹ.”—Brandon.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Ẹ fi ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.’ —Kólósè 3:12.