Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

5 Ṣé Ìyà Máa Dópin?

5 Ṣé Ìyà Máa Dópin?

Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì

Tá a bá gbà pé ìyà máa dópin, ìrètí tá a ní yìí á mú kí ìgbésí ayé wa dáa sí i, á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

Ronú Lórí Èyí

Ó wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti fòpin sí ìyà, àmọ́ agbára wọn ò gbé e. Kíyè sí àwọn nǹkan yìí:

Ìmọ̀ ìṣègùn ti tẹ̀ síwájú gan-an lóòótọ́, àmọ́ . . .

  • Àrùn ọkàn ló ṣì ń pa èèyàn tó pọ̀ jù lọ.

  • Àrùn jẹjẹrẹ ń pa àìmọye èèyàn lọ́dọọdún.

  • Bákan náà, nínú ìwé ìròyìn Frontiers in Immunology, ọ̀jọ̀gbọ́n David Bloom sọ́ pé: “Àwọn àrùn tó ń ranni tó ti wà tipẹ́, tó sì dà bíi pé wọ́n ti lọ tẹ́lẹ̀ tún ti wá ń yọjú léraléra, wọ́n sì ń han aráyé léèmọ̀.”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ọrọ̀ púpọ̀ . . .

  • Àìmọye ọmọdé ló ń kú lọ́dọọdún, àwọn tó wà ní agbègbè àwọn tálákà ló sì ń jìyà náà jù lọ.

  • Àìmọye èèyàn ló ń gbé níbi tí kò sí ètò ìmọ́tótó tó dáa.

  • Àìmọye èèyàn ni kò ní omi tó mọ́.

Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń tẹnu mọ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó . . .

  • Títí di báyìí, wọ́n ṣì ń ta èèyàn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. Àwọn ijọba kan kò fìyà jẹ àwọn olubi náà. Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé ohun tó fà á ni pé àwọn orílẹ̀-èdè náà “kò mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ tàbí wọn ò lágbára láti mú àwọn ọ̀daràn náà.”

    TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I

    Wo fídíò Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? Ó wà lórí ìkànnì jw.org.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ọlọ́run ń bójú tó wa.

Ó máa ń dùn ún tá a bá ń jẹ̀rora, tínú wa sì bà jẹ́.

“[Ọlọ́run] kò gbójú fo ìyà tó ń jẹ ẹni tí ara ń ni, kò sì ṣàì ka ìpọ́njú rẹ̀ sí; kò gbé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún un.”​SÁÀMÙ 22:24.

“Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”​1 PÉTÉRÙ 5:7.

Ìyà ṣì máa dópin.

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe gbogbo ohun tó ṣèlérí fún wa.

“Ọlọ́run . . . máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​ÌFIHÀN 21:3, 4.

Ọlọ́run máa mú ohun tó ń fa ìyà tó ń jẹ wá kúrò.

Ó máa ṣe é nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, èyí tó gbé kalẹ̀ lọ́run.

“Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé. A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì. . . . Òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.”​DÁNÍẸ́LÌ 2:44.