Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ìwọ Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Ẹ?

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ìwọ Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Ẹ?

Ẹ̀rọ ìgbàlódé wúlò púpọ̀. Àwọn èèyàn máa ń fi tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ síra wọn, wọ́n fi ń kọ lẹ́tà, wọ́n lè lo ìkànnì àjọlò, wọ́n tiẹ̀ lè máa rí ara wọn bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà wọn jìn síra.

Àmọ́, àwọn kan ti sọ ọ̀rẹ́ wọn di ọ̀rẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé, ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí wọn ni pé . . .

  • wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gba tàwọn ọ̀rẹ́ wọn rò.

  • wọ́n sábà máa ń dá wà, wọn kì í sì í láyọ̀.

  • wọ́n máa ń ro tara wọn nìkan.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

ÌGBATẸNIRÒ

Tẹ́nì kan bá fẹ́ máa gba ti ọmọnìkejì ẹ̀ rò, àfi kó fara balẹ̀, kó sì fi sùúrù ronú nípa onítọ̀hún. Àmọ́ èèyàn ò lè ráyè ṣèyẹn níbi tó ti ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, tó ń gba èsì pa dà, tó sì tún ń wo ohun tó ń lọ lórí ìkànnì àjọlò.

Tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ẹ̀rọ ìgbàlódé, kó o tó mọ̀, gbogbo àkókò ẹ ni wàá máa fi fèsì àwọn ọrọ̀ tó ń wọlé látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Ohun táá wá jẹ ẹ́ lógún ni bó o ṣe máa ráyè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ náà dípò kó o wá bí wàá ṣe ran ọ̀rẹ́ ẹ kan tó níṣòro lọ́wọ́.

RÒ Ó WÒ NÁ: Báwo lo ṣe máa bá àwọn òrẹ́ ẹ “kẹ́dùn” tó bá jẹ́ pé àtẹ̀jíṣẹ́ lo fi ń bá wọn sọ̀rọ̀?​—1 PÉTÉRÙ 3:8.

ÌBÀNÚJẸ́

Ìwádìí kan fi hàn pé inú ọ̀pọ̀ èèyàn kì í dùn tí wọ́n bá ti pẹ́ jù lórí ìkànnì àjọlò; àti pé téèyàn bá kàn ṣáà ń wo fọ́tò àtàwọn nǹkan míì táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì, “á máa ṣèèyàn bíi pé ó kàn ń fàkókò ẹ̀ ṣòfò ni.”

Bákan náà, tẹ́nì kan bá ń wo àwọn fọ́tò tó jojú ní gbèsè táwọn kan gbé sórí ìkànnì àjọlò, inú ẹ̀ lè bà jẹ́ kó sì máa ronú pé ńṣe lòun ń jìyà níbi táwọn tó kù ti ń gbádùn ara wọn.

RÒ Ó WÒ NÁ: Tó o bá ń lo ìkànnì àjọlò, kí lo lè ṣe kó o má bàa fi ara ẹ wé àwọn èèyàn kan débi tí wàá fi ro ara ẹ pin?​—GÁLÁTÍÀ 6:4.

ÌMỌTARA-ẸNI-NÌKAN

Olùkọ́ kan kíyè sí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ kan máa ń ṣohun tó fi hàn pé “àwọn tí wọ́n bá lè rí jẹ lọ́dọ̀ wọn nìkan ni wọ́n máa ń bá ṣọ̀rẹ́.” * Ńṣe làwọn tó bá nírú ìwà yìí máa ń wo àwọn ọ̀rẹ́ wọn bíi fóònù téèyàn ń tẹ̀ nígbà tó bá nílò ẹ̀, táá sì pa á tì síbì kan nígbà tí kò bá nílò ẹ̀.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé ohun tó ò ń gbé sórí ìkànnì ò fi hàn pé kárími lò ń ṣe, tàbí pé ò ń fi ohun tó o ní ṣe fọ́rífọ́rí? ​—GÁLÁTÍÀ 5:26.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

MÁA FỌGBỌ́N LO Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ

Tó o bá ń fọgbọ́n lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, wàá máa ráyè fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ, ọ̀rẹ́ yín á sì túbọ̀ máa lágbára.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ìfẹ́ . . . kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.”​—1 KỌ́RÍŃTÌ 13:​4, 5.

Sàmì sí àwọn tí wàá fẹ́ tẹ̀ lé lára àwọn àbá yìí tàbí kó o kọ èyí tíwọ fúnra ẹ ronú kàn.

  • Túbọ̀ máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú (dípò kó o máa lo àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí lẹ́tà orí ẹ̀rọ nìkan)

  • Wá ibì kan fi fóònù ẹ sí (tàbí kó o yí i sílẹ̀) tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀

  • Dín àkókò tó o fi ń wo ohun táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì àjọlò kù

  • Túbọ̀ máa tẹ́tí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀

  • Lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ ẹ kan tó níṣòro kó o lè ràn án lọ́wọ́

^ ìpínrọ̀ 17 Ìwé Reclaiming Conversation ló sọ ọ́.