Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 26

Jóòbù Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ọlọ́run

Jóòbù Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ọlọ́run

ǸJẸ́ àánú ọkùnrin aláìsàn yìí ò ṣe ọ́? Jóòbù ni orúkọ ẹ̀, obìnrin tó o sì ń wò yẹn ni ìyàwó ẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ń sọ fún Jóòbù? Ó ń sọ pé, ‘Bú Ọlọ́run, kí o sì kú.’ Jẹ́ ká wo ohun tó mú un sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀, àti ìdí tí Jóòbù fi jìyà tó bẹ́ẹ̀.

Olóòótọ́ èèyàn tó ń ṣègbọràn sí Jèhófà ni Jóòbù. Ó ń gbé ní ilẹ̀ Úsì tí kò jìnnà púpọ̀ sí Kénáánì. Jèhófà fẹ́ràn Jóòbù gidigidi, ṣùgbọ́n ẹnì kan wà tó kórìíra rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni náà?

Sátánì Èṣù ni. Ṣé o rántí, Sátánì ni áńgẹ́lì búburú tó kórìíra Jèhófà. Ó mú kí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó sì rò pé òun á lè mú kí gbogbo àwọn èèyàn tó kù ṣàìgbọràn sí Jèhófà pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ èyí ṣeé ṣe fún un bí? Ó tì o. Ìwọ ṣáà ronú nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn. Mélòó nínú wọn lo lè dárúkọ?

Lẹ́yìn tí Jékọ́bù àti Jósẹ́fù ti kú ní Íjíbítì, Jóòbù tún ni ẹni tó ṣe olóòótọ́ jù lọ sí Jèhófà ní gbogbo ayé. Jèhófà fẹ́ kí Sátánì mọ̀ pé kò lè sọ gbogbo èèyàn di ẹni búburú, nítorí náà ó wí pé: ‘Wo Jóòbù. Wo bó ti jẹ́ olóòótọ́ sí mi tó.’

Sátánì jiyàn pé: ‘Torí pé o bù kún fún un tó sì ní ọ̀pọ̀ nǹkan rere ló mú un jẹ́ olóòótọ́. Ṣùgbọ́n tó o bá gba àwọn nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ ẹ̀, ó máa bú ọ.’

Jèhófà bá sọ pé: ‘Lọ ṣe ohun tó o sọ yẹn. Gba àwọn nǹkan tó ní. Gbogbo nǹkan burúkú tó bá wù ọ́ ni kó o ṣe sí Jóòbù. Ká wá máa wò ó bóyá ó máa bú mi. Ṣùgbọ́n rí i dájú pé o ò pa á o.’

Lákọ̀ọ́kọ́, Sátánì mú kí àwọn olè jí àwọn màlúù àti ràkúnmí Jóòbù, wọ́n sì pa àwọn àgùntàn rẹ̀. Ẹ̀yìn náà ló tún mú kí ìjì líle pa àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin mẹ́wàá. Lẹ́yìn èyí, Sátánì fi àrùn burúkú kọ lu Jóòbù bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí. Jóòbù jìyà gan-an ni. Ìdí nìyí tí ìyàwó rẹ̀ fi sọ fún un pé kó ‘Bú Ọlọ́run kó o sì kú.’ Ṣùgbọ́n Jóòbù kò ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, àwọn ọ̀rẹ́ èké mẹ́ta kan wá, wọ́n sì sọ fún un pé torí pé ó ti ṣe ohun tí kò dára tẹ́lẹ̀ ló ṣe ń jìyà. Ṣùgbọ́n Jóòbù kò dáwọ́ ìṣòtítọ́ rẹ̀ dúró.

Èyí mú inú Jèhófà dùn gidigidi, ó sì bù kún Jóòbù gẹ́gẹ́ bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí. Ó wo àrùn rẹ̀ sàn. Jóòbù bí ọmọ mẹ́wàá mìíràn tí wọ́n rẹwà, ó sì ní ìlọ́po méjì màlúù ati àgùntàn àti ràkúnmí ju èyí tó kọ́kọ́ ní lọ.

Ṣé ìwọ náà á máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà gbogbo bíi ti Jóòbù? Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run á bù kún ìwọ náà. Yóò ṣeé ṣe fún ọ láti máa gbé ayé títí láé nígbà tó bá sọ gbogbo ayé di ẹlẹ́wà bí ọgbà Édẹ́nì.