Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 92

Jésù Jí Òkú Dìde

Jésù Jí Òkú Dìde

ỌMỌ ọdún méjìlá [12] ni ọmọbìnrin tó ò ń wò yìí. Jésù ló dì í lọ́wọ́ mú yẹn, tí bàbá àti ìyá rẹ̀ sì dúró síwájú rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó mú kí ayọ̀ hàn ní ojú wọn? Jẹ́ ká wò ó ná.

Èèyàn pàtàkì kan báyìí tó ń jẹ́ Jáírù ni bàbá ọmọbìnrin yìí. Ní ọjọ́ kan, ọmọbìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn. Ṣùgbọ́n ara rẹ̀ kọ̀ kò yá. Ṣe ni àìsàn rẹ̀ túbọ̀ ń le sí i. Ọkàn Jáírù àti ìyàwó rẹ̀ ò balẹ̀ nítorí ó dà bíi pé ọmọbìnrin wọn kékeré yìí máa kú. Òun ni ọmọbìnrin kan ṣoṣo tí wọ́n bí. Ni Jáírù bá wá Jésù lọ. Ó ti gbọ́ nípa iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ń ṣe.

Ìgbà tí Jáírù rí Jésù, ogunlọ́gọ̀ èèyàn ló wà yí i ká. Ṣùgbọ́n Jáírù rá pálá wọ àárín wọn lọ, ó sì wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Jésù. Ó sọ pé: ‘ọmọbìnrin mi ń ṣàìsàn burúkú-burúkú.’ Ó bẹ Jésù pé: ‘Jọ̀wọ́ wá bá mi mú un lára dá.’ Jésù sọ fún un pé òun ń bọ̀.

Bí wọ́n ti ń rìn lọ, àwọn èrò ń ti ara wọn, oníkálukú fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jésù. Lójijì, Jésù dúró. Ó béèrè pé: ‘Ta ló fọwọ́ kàn mí?’ Jésù mọ̀ ọ́n lára pé agbára jáde kúrò lára òun, torí náà, ó mọ̀ pé ẹnì kan ti fọwọ́ kan òun. Ṣùgbọ́n ta ló lè jẹ́? Obìnrin kan tí àìsàn ti ń ṣe láti bí ọdún méjìlá [12] ni. Ó wá láti fi ọwọ́ kan aṣọ Jésù, ó sì gba ìwòsàn!

Èyí fi Jáírù lọ́kàn balẹ̀ torí ó ti rí i bó ṣe rọrùn tó fún Jésù láti wo ẹnì kan sàn. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá ni ìránṣẹ́ kan dé. Ó wí fún Jáírù pé: ‘Má ṣe yọ Jésù lẹ́nu mọ́. Ọmọbìnrin rẹ ti kú.’ Ohun tó sọ yìí ta sí Jésù létí, ó sì wí fún Jáírù pé: ‘Má fòyà, ara rẹ̀ á yá.’

Nígbà tí wọ́n wá dé ilé Jáírù, àwọn èèyàn ń fi ìbànújẹ́ ńláǹlà sunkún. Ṣùgbọ́n Jésù wí pé: ‘Ẹ má sunkún mọ́. Ọmọ yẹn ò kú. Sísùn ló ń sùn.’ Ṣùgbọ́n wọ́n rẹ́rìn-ín, wọ́n sì fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ torí tí wọ́n mọ̀ pé ọmọ yẹn ti kú.

Ìgbà yẹn ni Jésù mú bàbá àti ìyá ọmọ náà àti mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wọ inú iyàrá tí wọ́n tẹ́ ọmọ náà sí. Ó di ọwọ́ ọmọ yìí mú, ó sì wí pé: ‘Dìde!’ Ọmọbìnrin yìí sì jí sí ààyè, gẹ́gẹ́ bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí. Ó sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn káàkiri! Ìdí nìyí tí bàbá àti ìyá rẹ̀ fi láyọ̀ púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀.

Èyí kì í ṣe ẹni àkọ́kọ́ tí Jésù jí dìde kúrò nínú òkú o. Ẹni àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ọmọ opó kan tó ń gbé ní ìlú Náínì. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jésù tún jí Lásárù, àbúrò Màríà àti Màtá dìde kúrò nínú òkú. Nígbà tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba Ọlọ́run, ó máa mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó ti kú padà sí ìyè. Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí mú inú wa dùn?