Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹgbẹẹgbẹrun Awọn Ẹda Ẹmi

Ẹgbẹẹgbẹrun Awọn Ẹda Ẹmi

Bibeli sọ fun wa pe ọpọlọpọ awọn ẹda ẹmi ni nbẹ. Jehofa funraarẹ jẹ ẹmi kan.—Johanu 4:24; 2 Kọrinti 3:17, 18.

Ni akoko kan Jehofa nikanṣoṣo ni o wa ni agbaye. Nigba ti o yá oun bẹrẹsii ṣẹ̀dá awọn ẹda ẹmi ti a npe ni angẹli. Wọn lagbara wọn sì loye ju awọn eniyan lọ. Jehofa da ọpọlọpọ awọn angẹli; Daniẹli iranṣẹ Ọlọrun, ninu iran, ri ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn angẹli.—Daniẹli 7:10; Heberu 1:7.

Ọlọrun da awọn angẹli wọnyi ani ṣaaju ki o to da ilẹ-aye paapaa. (Joobu 38:4-7) Ko si ọkankan ninu wọn ti o jẹ eniyan tí ó ti gbe tí o sì ti ku lori ilẹ-aye ri.

Ẹmi titobi naa, Jehofa, ṣẹ̀dá ẹgbẹẹgbẹrun awọn ẹda ẹmi