Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣọtẹ ni Ilẹ Akoso Ẹmi

Iṣọtẹ ni Ilẹ Akoso Ẹmi

Nigba ti Satani lo ejò lati ba Efa sọrọ, obinrin naa darapọ mọ́ ọn ninu iṣọtẹ rẹ̀ lodisi Ọlọrun

Gbogbo awọn ẹda ẹmi ti Jehofa da jẹ rere. Nigba ti o ya angẹli kan yipada di buburu. Oun ni Satani Eṣu. Satani fẹ ki awọn eniyan lori ilẹ-aye maa jọsin oun dipo ki wọn jọsin Jehofa. Eyi ni ohun ti o ṣẹlẹ:

Ọpọlọpọ awọn eso igi ti nso eso aladun wà ninu ọgba Edeni. Jehofa sọ fun Adamu ati aya rẹ̀, Efa, pe wọn lè jẹ ninu wọn fàlàlà. Ṣugbọn igi kan wa ti Ọlọrun sọ pe wọn kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀. O sọ pe bi wọn ba jẹ ninu rẹ̀, dajudaju wọn yoo ku.—Jẹnẹsisi 2:9, 16, 17.

Ni ọjọ kan Efa wà ni oun nikan nigba ti ejò kan ba a sọrọ. Dajudaju, kii ṣe ejo naa niti gidi ni o sọrọ; Satani Eṣu ni ẹni ti o mu ki o dabi ẹni pe ejo naa ni o sọrọ. Satani sọ fun Efa pe bi o ba jẹ eso ti a kà leewọ naa, oun yoo gbọ́n bi Ọlọrun. O tun sọ pe oun ki yoo kú. Ṣugbọn irọ ni awọn ọrọ wọnyi. Bi o ti wu ki o ri, Efa gba Satani gbọ́ o sì jẹ eso naa. Lẹhin naa, o mu ninu rẹ̀ fun Adamu, oun naa sì jẹ ẹ pẹlu.—Jẹnẹsisi 3:1-6.

Lati inu itan ohun ti o ṣẹlẹ gidi yii, awa kẹkọọ pe Satani jẹ ọlọtẹ ati opurọ kan. O sọ fun Efa pe bi oun ba ṣaigbọran si Ọlọrun, oun ki yoo kú. Iyẹn jẹ irọ. O ku bẹẹ naa sì ni Adamu. Satani kò ku nigba naa, bi o tilẹ jẹ pe oun yoo ṣe bẹẹ nigba ti o ba ya nitori pe oun ti dẹṣẹ. Laaarin akoko yii, bi o ti wu ki o ri, oun walaaye o sì nbaa lọ lati ṣi ọpọlọpọ eniyan lọna. Oun ṣì jẹ opurọ sibẹ, o sì ngbiyanju lati mu ki awọn eniyan ru awọn ofin Ọlọrun.—Johanu 8:44.

Awọn Angẹli Miiran Ṣọtẹ

Lẹhin naa, awọn angẹli miiran yipada di buburu. Awọn angẹli wọnyi ṣakiyesi awọn obinrin eniyan ẹlẹwa lori ilẹ-aye, wọn sì fẹ lati ni ibalopọ takọtabo pẹlu wọn. Nitori naa wọn wa sori ilẹ-aye wọn sì gbe awọ ara ọkunrin wọ̀. Lẹhin naa wọn mu awọn obinrin wọnyi fun araawọn. Eyi lodisi ète Ọlọrun.—Jẹnẹsisi 6:1, 2; Juuda 6.

Awọn angẹli buburu wa si aye lati hu iwa palapala pẹlu awọn obinrin

O tun da ọpọlọpọ iṣoro silẹ fun araye. Awọn iyawo awọn angẹli wọnyi bi awọn ọmọ, ṣugbọn wọn kii wulẹ ṣe ọmọ lasan. Wọn dagba lati di awọn òmìrán oniwa ipa ati oniwa ika. Nikẹhin ilẹ-aye wá kun fun iwa ipa ti Jehofa fi pinnu lati pa awọn eniyan buburu run nipasẹ ikun omi nla kan. Kiki awọn eniyan ti wọn la ikun omi naa ja ni Noa olododo ati idile rẹ̀.—Jẹnẹsisi 6:4, 11; 7:23.

Awọn angẹli buburu wọnyi, bi o ti wu ki o ri, pada si ilẹ akoso ẹmi; wọn kò kú. Ṣugbọn a jẹ wọn níyà. A kò yọnda fun wọn lati pada sinu idile Ọlọrun ti awọn angẹli olododo. Siwaju sii, Jehofa kò tun yọnda fun wọn lati gbe awọ ara eniyan wọ̀ mọ́. Nigba ti o ba sì yá, wọn yoo ku lakooko idajọ nla naa.—2 Peteru 2:4; Juuda 6.

A Le Satani Jade Kuro Ni Ọrun

Satani ati awọn angẹli buburu rẹ̀ ni a le jade kuro ni ọrun

Ogun kan ṣẹlẹ ni ọrun ni apa ibẹrẹ ọrundun wa yii. Iwe Bibeli naa Iṣipaya ṣapejuwe ohun ti o ṣẹlẹ: “Ogun sì nbẹ ni ọrun: Maikẹli [Jesu Kristi ti a ti ji dide] ati awọn angẹli [daradara] rẹ̀ ba dragoni [Satani], naa jagun; dragoni sì jagun ati awọn angẹli [buburu] rẹ̀. Wọn kò sì lè ṣẹgun; bẹẹ ni a kò sì ri ipo wọn mọ ni ọrun. A sì le dragoni nla naa jade, ejo laelae ni ti a npe ni Eṣu ati Satani, ti ntan gbogbo aye jẹ, a sì lé e ju si ilẹ aye, a sì le awọn angẹli [buburu] rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.”

Ki ni iyọrisi rẹ̀? Irohin naa nbaa lọ pe: “Nitori naa ẹ maa yọ, ẹyin ọrun, ati ẹyin ti ngbe inu wọn.” Awọn angẹli daradara lè yọ̀ nitori pe Satani ati awọn angẹli, tabi ẹmi buburu, kò tun si ni ọrun mọ́. Ṣugbọn ki ni nipa awọn eniyan lori ilẹ-aye? Bibeli sọ pe: “Ègbé ni fun aye ati fun òkun! Nitori Eṣu sọkalẹ tọ yin wa ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgbà kukuru ṣáá ni oun ní.”—Iṣipaya 2:7-9, 12.

Bẹẹni, Satani ati awọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ buburu nṣi awọn eniyan lọna wọn sì nfa ègbé nla fun awọn eniyan lori ilẹ-aye. Awọn angẹli buburu wọnyi ni a npe ni awọn ẹmi-eṣu. Wọn jẹ awọn ọta Ọlọrun. Gbogbo wọn jẹ olubi.