Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣiṣẹsin Jehofa, Kii Ṣe Satani

Ṣiṣẹsin Jehofa, Kii Ṣe Satani

Gbogbo wa ní yíyàn kan. Yala ki a ṣiṣẹsin Jehofa tabi ki a ṣiṣẹsin Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀. Awa kò lè ṣe mejeeji. Ẹ wo bi o ti bọgbọnmu to lati ṣiṣẹsin Jehofa!

Jehofa Dara

Gẹgẹ bi a ti rí i, awọn ẹmi-eṣu gbadun ṣiṣe ipalara ati titan awọn eniyan jẹ. Jehofa kò ri bẹẹ rara. O nifẹẹ araye gẹgẹ bi baba ti nifẹẹ awọn ọmọ rẹ̀. Oun jẹ Olùfunni ni “ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pipe.” (Jakọbu 1:17) Oun kò fawọ ohunkohun ti o dara sẹhin kuro lọdọ araye, ani bi o tilẹ ná-an ni ohun pupọ gan-an paapaa.—Efesu 2:4-7.

Jesu, Ọmọkunrin Ọlọrun, fi ifẹ hàn fun awọn eniyan nipa mimu wọn larada

Ronu nipa awọn nnkan ti Jesu Ọmọkunrin Ọlọrun ṣe lori ilẹ-aye. Oun mu ki awọn ẹni ti o yadi sọrọ ó sì pese iriran fun awọn afọju. O wo awọn adẹ́tẹ̀ sàn ati awọn arọ eniyan. O le awọn ẹmi-eṣu jade o sì wo oniruuru awọn aisan sàn. Jesu, nipasẹ agbara Ọlọrun, tilẹ ji awọn oku dide si iye paapaa.—Matiu 9:32-35; 15:30, 31; Luuku 7:11-15.

Kaka ki o purọ lati ṣì wa lọna, Ọlọrun maa nsọ otitọ nigbagbogbo. Oun kò tan ẹnikẹni jẹ ri.—Numeri 23:19.

Yẹra Fun Awọn Iṣe Aimọ

Gan-an gẹgẹ bi okùn aláǹtakùn ti nmu kokoro, ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan wà labẹ ìdè igbagbọ ninu ohun asan ati eke. Wọn bẹru awọn oku. Wọn bẹru awọn ẹmi-eṣu. Wọn ndaamu nipa awọn ègún, awọn àmì, awọn oògùn, ati awọn agbara awo. Wọn wa labẹ ìdè awọn igbagbọ ati àṣà ti a gbe kari awọn irọ́ Satani Eṣu. Awọn iranṣẹ Ọlọrun ni a kò dẹkunmu nipasẹ eyikeyii ninu awọn nnkan wọnyi.

Jehofa lagbara pupọpupọ ju Satani lọ. Bi iwọ ba nṣiṣẹsin Jehofa, oun yoo daabobo ọ kuro lọwọ awọn ẹmi-eṣu. (Jakọbu 4:7) Awọn èèdì ki yoo le mu ọ. Fun apẹẹrẹ, ni Nigeria, awọn ògbóǹkangí adáhunṣe mẹta kan fi èèdì mú Ẹlẹ́rìí Jehofa kan lati pa á nitori pe o kọ̀ lati fi ilu silẹ. Nigba ti èèdì naa kuna, ẹ̀rù ba ọkan ninu awọn adáhunṣe naa, o lọ sọdọ Ẹlẹ́rìí naa, o sì bẹbẹ fun aanu.

Awọn ara Efesu sun awọn iwe idán wọn

Bi awọn ẹmi-eṣu ba gbejako ọ, iwọ lè ke pe orukọ Jehofa oun yoo sì daabobo ọ. (Owe 18:10) Ṣugbọn ki iwọ baa le ni aabo Ọlọrun, o nilati ja araàrẹ gbà patapata kuro lọwọ ibaṣepọ eyikeyii ti o niiṣe pẹlu ibẹmiilo ati ijọsin ẹmi-eṣu. Awọn olujọsin Ọlọrun ni Efesu igbaani ṣe bẹẹ. Wọn kó gbogbo iwe wọn lori idán jọ wọn sì sun wọn níná. (Iṣe 19:19, 20) Awọn iranṣẹ Ọlọrun lonii gbọdọ ṣe ohun kan naa. Gba ara rẹ lọwọ oògùn, ìgbàdí, awọn okùn “aabo,” agbara awo, awọn ìwé idán, ati ohunkohun ti o nii ṣe pẹlu àṣà ibẹmiilo.

Sọ Ijọsin Tootọ Dàṣà

Bi iwọ ba fẹ lati wu Ọlọrun, kò tó lati wulẹ fi ijọsin eke silẹ ki o sì dawọ ṣiṣe awọn ohun ti o buru duro. Iwọ gbọdọ fi taratara sọ ijọsin mimọgaara dàṣà. Bibeli fi ohun ti o nilo hàn:

Pésẹ̀ si awọn ipade Kristẹni.—Heberu 10:24, 25

Kẹkọọ Bibeli.—Johanu 17:3

Waasu fun awọn ẹlomiran.—Matiu 24:14

Gbadura si Jehofa.—Filipi 4:6, 7

Ṣe baptism.—Iṣe 2:41

Darapọ Pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa

Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ ní awọn eniyan lori ilẹ-aye ti nkọni ti wọn sì nṣe awọn ohun ti kò tọna. Ṣugbọn Jehofa ni awọn eniyan pẹlu. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. (Aisaya 43:10) Eyi ti o ju million mẹrin awọn Ẹlẹ́rìí ni o wa jakejado ilẹ-aye. Gbogbo wọn ngbiyanju lati ṣe ohun ti o dara ati lati kọ awọn eniyan ni otitọ. Ni ọpọlọpọ ilẹ, iwọ le pade wọn ni Gbọngan Ijọba, nibi ti wọn yoo ti fi tọyayatọyaya ki ọ kaabọ.

Iṣẹ wọn ni lati ran awọn eniyan lọwọ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun. Wọn yoo kẹkọọ Bibeli pẹlu rẹ ninu ile rẹ, ni riran ọ lọwọ lati kẹkọọ bi iwọ ṣe le ṣiṣẹsin Jehofa ni ọna ti o tọ. Iwọ kò nilati sanwo fun eyi. Awọn Ẹlẹ́rìí layọ lati kọni ni otitọ nitori pe wọn nifẹẹ awọn eniyan wọn sì nifẹẹ Jehofa Ọlọrun.

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo ran ọ lọwọ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun