Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ-ọla Agbayanu Kan

Ọjọ-ọla Agbayanu Kan

Laipẹ Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ ni a o mu kuro lẹnu iṣẹ

Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ ki yoo tan awọn eniyan jẹ fun ìgbà pipẹ mọ́. Ni bayii na Jehofa ti le wọn jade kuro ni ọrun. (Iṣipaya 12:9) Ni ọjọ iwaju ti kò jinna mọ́, Ọlọrun yoo tun gbe igbesẹ lodisi Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀. Ninu iran lati ọdọ Ọlọrun, apọsiteli Johanu sọ pe: “Mo sì ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wa, ti oun ti ìṣikà ọ̀gbun ni, ati ẹ̀wọ̀n nla kan ni ọwọ rẹ̀, o sì di dragoni naa mu, ejo atijọ ni, tii ṣe Eṣu, ati Satani, o sì dè é ni ẹgbẹrun ọdun. O sì gbé e sọ sinu ọ̀gbun naa, o sì tì í, o sì fi èdídí dí i lori rẹ̀, ki o ma baa tan awọn orilẹ-ede jẹ mọ titi ẹgbẹrun ọdun naa yoo fi pe.” (Iṣipaya 20:1-3) Lẹhin ọ rẹhin, Eṣu ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ ni a o parun titilae.—Iṣipaya 20:10.

Awọn eniyan buburu lori ilẹ-aye ni a o tun mu kuro pẹlu.—Saamu 37:9, 10; Luuku 13:5.

Awọn Oku Yoo Walaaye Lẹẹkan Sii!

Awọn oku yoo pada wa si iye lori ilẹ-aye

Lẹhin ti o ba ti mu Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ kuro lọna, Jehofa yoo mu ọpọlọpọ ibukun wa fun araye. Iwọ yoo ranti pe awọn oku jẹ alailẹmii, aláìsí. Jesu fi iku wé oorun—oorun asunwọra ti kò ni àlá ninu. (Johanu 11:11-14) O ṣe eyi nitori o mọ̀ pe akoko nbọ nigba ti awọn ti o sùn ninu iku yoo ji dide si iye. O sọ pe: “Wakati nbọ, ninu eyi ti gbogbo awọn ti o wà ni isa oku yoo . . . jade wa.”—Johanu 5:28, 29; fiwe Iṣe 24:15.

A o mu wọn wa si iye nihin-in lori ilẹ-aye. Dipo ifilọ pe awọn eniyan ti ku, irohin alayọ ni a o maa gbọ́ nipa awọn eniyan ti a ti mu pada wá si iye! Ẹ wo iru ayọ ti yoo jẹ lati ki awọn ololufẹ wa kaabọ pada lati inu isa-oku!