Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Kò Lè Jóòótọ́!”

“Kò Lè Jóòótọ́!”

ỌKÙNRIN kan ará New York ròyìn pé: “Jonathan ọmọkùnrin mi ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní kìlómítà díẹ̀ sí wa. Aya mi Valentina, kìí fẹ́ kí ó lọ síbẹ̀. Ojora ọkọ̀ tí-ń-lọ-tí-ń-bọ̀ sábà máa ń mú un nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin náà fẹ́ràn àwọn ohun-èèlò tí ń lo agbára iná mànàmáná, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì ní ìsọ̀-iṣẹ́ kan níbi tí òun ti lè nírìírí bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Ilé ni mo wà ní ìwọ̀-oòrùn Manhattan, New York. Aya mi sì ti lọ kí ìdílé rẹ̀ ní Puerto Rico. ‘Jonathan yóò dé láìpẹ́,’ ni mo rò. Bẹ́ẹ̀ ni agogo ẹnu ilẹ̀kùn dún. ‘Dájúdájú òun nìyẹn.’ Kò rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́pàá àti àwọn ọ̀jáfáfá oníṣègùn pàjáwìrì ni. ‘Ìwọ ha dá ìwé-àṣẹ ìwakọ̀ yìí mọ̀ bí?’ ní ọ̀gá ọlọ́pàá náà béèrè. ‘Bẹ́ẹ̀ni, ti ọmọkùnrin mi ni, Jonathan ni ó ni ín.’ ‘A ní ìròyìn búburú kan fún ọ. Jàm̀bá kan ti ṣẹlẹ̀, àti pé . . . ọmọkùnrin rẹ, . . . ọmọkùnrin rẹ sì ti kú.’ Ìhùwàpadà mí àkọ́kọ́ ni, ‘Kò lè jóòótọ́!’ Ìròyìn gbankọgbì yẹn dá ọgbẹ́ kan sínú ọkàn-àyà wa tí ó ṣì ń san síbẹ̀, àní ní àwọn ọdún lẹ́yìn náà.”

‘A ní ìròyìn búburú kan fún ọ. Jàm̀bá kan ti ṣẹlẹ̀, àti pé . . . ọmọkùnrin rẹ, . . . ọmọkùnrin rẹ ti kú.’

Baba kan ní Barcelona (Spain) kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn lọ́hùn-⁠ún ní Spain ní àwọn ọdún 1960, a jẹ́ ìdílé aláyọ̀. María aya mi wà níbẹ̀, àti àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, David, Paquito, àti Isabel, tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ 13, 11, àti 9 ní ìtòtẹ̀léra bí a ti dárúkọ wọn.

“Ní ọjọ́ kan ní March 1963, Paquito dé sílé láti ilé-ẹ̀kọ́ ó sì ráhùn nípa níní ẹ̀fọ́rí lílekoko. Ohun tí ó lè jẹ́ okùnfà rẹ̀ tojúsú wa​—⁠ṣùgbọ́n èyíinì kìí ṣe fún ìgbà pípẹ́. Wákàtí mẹ́ta lẹ́yìn náà ó ti kú. Ẹ̀jẹ̀ ṣíṣàn sínú ọpọlọ rẹ̀ tí mú kí ó gbẹ́mìí mì.

“Ikú Paquito wáyé ní èyí tí ó jú 30 ọdún sẹ́yìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìroragógó àdánù náà ṣì wà lára wa títí di òní. Kò sí bí àwọn òbí ṣe lè pàdánù ọmọ kan kí wọn má sì nímọ̀lára pé wọ́n ti pàdánù ohun kan tí ó wá láti inú àwọn fúnraawọn​—láìka iye ìgbà tí ó ti kọjá tàbí iye àwọn ọmọ mìíràn tí wọ́n ní sí.”

Àwọn ìrírí méjì wọ̀nyí, nínú èyí tí àwọn òbí ti pàdánù àwọn ọmọ, jẹ́ àpẹẹrẹ ṣíṣe kedere nípa bí ọgbẹ́ náà ti lè jinlẹ̀ tó tí ó sì lè pẹ́ tó nígbà tí ọmọ kan bá kú. Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ dókítà kan tí ó kọ̀wé ti jẹ́ òtítọ́ tó pé: “Ikú ọmọ kan sábà máa ń jẹ́ abaninínújẹ́ àti adaniláàmú ju ikú àgbàlagbà nítorí pé ọmọ ní a retí pé kí ó jẹ́ ẹni tí yóò kú kẹ́yìn nínú ìdílé. . . . Ikú ọmọdé èyíkéyìí dúró fún ìpàdánù àwọn àlá ọjọ́-ọ̀la, àwọn ìbátan [ọmọkùnrin, aya ọmọ ẹni, ọmọ-ọmọ], àwọn ìrírí . . . tí a kò tíì gbádùn tẹ́lẹ̀.” Ìmọ̀lára àdánù ńláǹlà yìí sì lè kan obìnrin èyíkéyìí tí ó ti pàdánù ọmọ kan nípasẹ̀ ìṣẹ́nú.

Aya kan tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ṣàlàyé pé: “Russell, ọkọ mi, ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ oníṣègùn ní ojúkò ogun Pacific nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Òun ti rí ó sì ti la àwọn ogun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ já. Ó padà wá sí United States sínú ìgbésí-ayé tí ó túbọ̀ tòrò. Nígbà tí ó yá, ó ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nígbà tí ó fi díẹ̀ lé ní ẹni 60 ọdún, ó bẹ̀rẹ̀síí nímọ̀lára àwọn àmì-àrùn ìṣòro ọkàn-àyà. Ó gbìyànjú láti gbé ìgbésí-ayé alákitiyan. Nígbà náà, ní ọjọ́ kan ní July 1988, ó jìyà lọ́wọ́ àìsàn àìṣiṣẹ́ déédéé ọkàn-àyà lọ́nà lílekoko ó sì kú. Àdánù ńláǹlà ni ikú rẹ̀ jẹ́. Kò tilẹ̀ fún mi láyè láti sọ pé ó dìgbóṣe. Kìí kàn ṣe pé ó jẹ́ ọkọ fún mi nìkan ni. Ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ jùlọ ni. A ti jọ ṣàjọpín ìgbésí-ayé papọ̀ fún 40 ọdún. Nísinsìnyí ó dàbí ẹni pé mó níláti dojúkọ ìdánìkanwà yíyàtọ̀ kan.”

Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀ràn ìbànújẹ́ tí ń ṣubú tẹ àwọn ìdílé jákèjádò ayé lójoojúmọ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ń kẹ́dùn yóò ti sọ fún ọ, nígbà tí ikú bá mú ọmọ rẹ, ọkọ rẹ, aya rẹ, òbí rẹ, ọ̀rẹ́ rẹ lọ, ohun tí Paulu òǹkọ̀wé Kristian pè é nítòótọ́ ni ó jẹ́, “ọ̀tá ìkẹyìn.” Gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń jẹ́, ìhùwàpadà àkọ́kọ́ tí ó bá ìwà ẹ̀dá mú sí ìròyìn afoniláyà náà lè jẹ́ sísẹ́ ẹ, “Kò lè jóòótọ́! N kò gbà á gbọ́.” Àwọn ìhùwàpadà mìíràn sábà máa ń tẹ̀lé e, gẹ́gẹ́ bí a óò ti ríi.​—⁠1 Korinti 15:25, 26.

Bí ó ti wù kí ó rí, kí a tó gbé ìmọ̀lára ẹ̀dùn-ọkàn yẹ̀wò, ẹ jẹ́ kí a dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì kan. Ikú ha túmọ̀sí òpin ẹni yẹn bí? Ìrètí èyíkéyìí ha wà láti tún rí àwọn olólùfẹ́ wa bí?

Ìrètí kan Tí Ó Dájú Wà

Òǹkọ̀wé Bibeli náà Paulu fúnni ní ìrètí ìtura kúrò lọ́wọ́ “ọ̀tá ìkẹyìn,” náà ikú. Ó kọ̀wé pé: “Ikú ni ọ̀tá ìkẹyìn tí a óò parun.” “Ọ̀tá ìkẹyìn tí a óò fòpin sí ni ikú.” (1 Korinti 15:26, The New English Bible) Èéṣe tí ìyẹn fi dá Paulu lójú tóbẹ́ẹ̀? Nítorí pé a ti kọ́ ọ láti ọwọ́ ẹnìkan tí a jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu Kristi. (Iṣe 9:3-19) Ìdí nìyẹn tí Paulu tún fi lè kọ̀wé pé: “Nítorí ìgbà tí ó ti ṣe pé nípa ènìyàn [kan Adamu] ni ikú ti wá, nípa ènìyàn [kan Jesu Kristi] ni àjíǹde nínú òkú sì ti wá pẹ̀lú. Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ni a óò sì sọ gbogbo ènìyàn di alààyè nínú Kristi.”​—⁠1 Korinti 15:21, 22.

Jesu kẹ́dùn gidigidi nígbà tí ó pàdé opó Naini tí ó sì rí ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó ti kú. Àkọsílẹ̀ Bibeli sọ fún wa pé: “Bí [Jesu] sí ti súnmọ́ ẹnu bodè ìlú [Naini], sì kíyèsí i, wọ́n ń gbé òkú kan jáde, ọmọ kanṣoṣo náà ti ìyá rẹ̀, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí Oluwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, Má sọkún mọ́. Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ àga pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́ ẹ́. Ó sì wí pé, Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, Dìde. Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀síí ohùn ífọ̀. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọrun lógo, wí pé, Wòlíì ńlá dìde nínú wa; àti pé, Ọlọrun sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò.” Ṣàkíyèsí bí àánú ti sún Jesu, tí ó fi jí ọmọkùnrin opó náà dìde! Wo ohun tí ìyẹn ń sọ fún wa nípa ọjọ́-ọ̀la!​—⁠Luku 7:12-16.

Níbẹ̀, lójú àwọn tí ọ̀ràn ṣojú wọn, Jesu ṣe àjíǹde mánigbàgbé kan. Ó jẹ́ ẹ̀rí àjíǹde tí òun ti sọ tẹ́lẹ̀ ní àkókò kan ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìmúpadàbọ̀ sí ìyè lórí ilẹ̀-ayé lábẹ́ “ọ̀run titun” kan. Jesu ti sọ ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn pé: “Kí èyí kí ó máṣe yà yín ní ẹnu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀ nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní isà òkú yóò gbọ́ ohùn rẹ̀. Wọn óò sì jáde wá.”​—Ìfihàn 21:1, 3, 4; Johannu 5:28, 29; 2 Peteru 3:13.

Àwọn mìíràn tí ọ̀ràn àjíǹde ṣojú wọn ni Peteru, papọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn lára àwọn 12 tí wọ́n bá Jesu rìn nínú ìrìn-àjò rẹ̀. Wọ́n fetí araawọn gbọ́ nígbà tí Jesu tí a jí dìde sọ̀rọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ Òkun Galili. Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Jesu wí fún wọn pé, Ẹ wá jẹun òwúrọ̀. Kò sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ bi í pé, Ta ni ìwọ íṣe? nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Oluwa ni. Jesu wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fifún wọ́n, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja. Èyí ni ìgbà kẹta nísinsìnyí tí Jesu farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú.”​—Johannu 21:12-14.

Nítorí náà ni Peteru fi lè kọ̀wé pẹ̀lú ìdánilójú hán-ún hán-ún pé: “Olùbùkún ni Ọlọrun àti Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹni tí ó tún wa bí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ̀, sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú.”​—1 Peteru 1:3.

Aposteli Paulu sọ ìdálójú ìrètí rẹ̀ jáde nígbà tí ó sọ pé: “Èmi ń gba nǹkan gbogbo gbọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì. Mo sì ní ìrètí sípa ti Ọlọrun, èyí tí àwọn tìkáraawọn jẹ́wọ́, pé àjíǹde òkú ń bọ̀ àti ti olóòótọ́ àti ti aláìṣòótọ́.”​—⁠Iṣe 24:14, 15.

Nítorí náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lè ní ìrètí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ náà ti rírí àwọn olólùfẹ́ wọn láàyè lẹ́ẹ̀kan síi lórí ilẹ̀-ayé ṣùgbọ́n lábẹ́ àwọn ipò tí ó yàtọ̀ pátápátá. Kí ni àwọn ipò wọ̀nyẹn yóò jẹ́? Àwọn àlàyé lẹ́kùn-⁠ún-rẹ́rẹ́ síwájú síi nípa ìrètí tí a gbékarí Bibeli fún àwọn olólùfẹ́ wa tí a ti pàdánù ni a óò jíròrò ní ẹ̀ka tí ó parí ìwé pẹlẹbẹ yìí, tí a fún ní àkòrí náà “Ìrètí Tí Ó Dájú fún Àwọn Òkú.”

Ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́ ná jẹ́ kí a gbé àwọn ìbéèrè tí ìwọ lè ní yẹ̀wò bí o bá ń kẹ́dùn òfò olólùfẹ́ kan: Ó ha bójúmu láti kẹ́dùn ní ọ̀nà yìí bí? Báwo ni mo ṣe lè gbé pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn mi? Kí ni ohun tí àwọn ẹlòmíràn lè ṣe láti ràn mi lọ́wọ́ láti lè kojú rẹ̀? Báwo ni mo ṣe lè ran àwọn mìíràn tí ń kẹ́dùn lọ́wọ́? Àti ní pàtàkì, Kí ni ohun tí Bibeli sọ nípa ìrètí tí ó dájú fún àwọn òkú? Èmi yóò ha tún rí àwọn olólùfẹ́ mi láé bí? Níbo sì ni?