Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Òǹkàwé Wa Ọ̀wọ́n:

Ǹjẹ́ o sún mọ́ Ọlọ́run? Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run rárá. Èrò àwọn kan ni pé Ọlọ́run ti jìnnà jù sí aráyé kò sì bìkítà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn; àwọn mìíràn sì gbà pé àwọn ò kàn tiẹ̀ tẹ́ni tó ń sún mọ́ Ọlọ́run rárá ni. Ṣùgbọ́n, Bíbélì rọ̀ wá tìfẹ́tìfẹ́ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ọlọ́run tiẹ̀ mú un dá àwọn tó ń sìn ín lójú pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Aísáyà 41:13.

Báwo la ó ṣe wá dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ lọ́nà yìí? Kí á tó lè dọ̀rẹ́ ẹnì kan, a ó ti kọ́kọ́ mọ onítọ̀hún, ìwà àti ìṣe rẹ̀ yóò sì wù wá gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣèwádìí nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi hàn. Tí a bá ń fara balẹ̀ ronú nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn lọ́kọ̀ọ̀kan, tí à ń rí i bí Jésù Kristi ṣe ń gbé àwọn ànímọ́ yìí yọ láìkù síbì kan, tí a sì ń mọ ọ̀nà tí àwa pẹ̀lú lè gbà máa fi àwọn ànímọ́ náà hàn, a óò dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run. A óò rí i pé Jèhófà lẹni tó ní ẹ̀tọ́ tó sì yẹ kí ó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Àti pé, òun tún ni Baba tó tó baba í ṣe fún gbogbo wa pátá. Bí ó ṣe jẹ́ alágbára, onídàájọ́ òdodo, ọlọ́gbọ́n àti onífẹ̀ẹ́ tó yìí, kì í kọ àwọn ọmọ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀ rárá.

Ǹjẹ́ kí ìwé yìí mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, kí o di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, kí o lè wà láàyè láti máa yìn ín lógo títí láé.

Àwa Òǹṣèwé