Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí 1

“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí”

“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí”

1, 2. (a) Àwọn ìbéèrè wo lo máa fẹ́ bi Ọlọ́run? (b) Kí ni Mósè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run?

KÁ NÍ o ṣàdédé gbóhùn Olódùmarè látọ̀run, tó ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí lo máa ṣe ná? Pé o kàn tiẹ̀ gbóhùn Ọ̀gá Ògo lásán àyà rẹ á já! Wàá kọ́kọ́ súnra kì ná. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o wá ṣọkàn gírí, kó o dá a lóhùn. Kí òun náà sì fèsì, kó sì fọkàn rẹ balẹ̀ pé o tiẹ̀ lè bi òun ní ìbéèrè èyíkéyìí tó o bá fẹ́. Irú ìbéèrè wo lo máa wá bi í?

2 Nígbà àtijọ́, ọkùnrin kan wà tó bára rẹ̀ nínú irú ipò yẹn gẹ́lẹ́. Mósè lorúkọ rẹ̀. Yóó yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ irú ìbéèrè tó yàn láti bi Ọlọ́run ní tiẹ̀. Kò béèrè nǹkan kan nípa ara rẹ̀, kò béèrè nípa bí ayé òun ṣe máa rí lọ́jọ́ ọ̀la, tàbí nípa àwọn ìṣòro tó ń pọ́n aráyé lójú. Kàkà bẹ́ẹ̀, orúkọ Ọlọ́run ló béèrè. Èyí lè ṣe ọ́ ní kàyéfì, torí pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Mósè ti mọ orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́. A jẹ́ pé nǹkan kan ń bẹ lẹ́yìn ìbéèrè tó béèrè yìí. Ká sòótọ́, òun ni ìbéèrè pàtàkì jù lọ tó yẹ kí Mósè béèrè. Ìdáhùn rẹ̀ kan gbogbo wa pátá. Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì tí wàá fi lè sún mọ́ Ọlọ́run. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pàtàkì yẹn.

3, 4. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ tí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ fi wáyé láàárín Mósè àti Ọlọ́run, ní kúkúrú kí ni ohun tí wọ́n sọ?

3 Ẹni ọgọ́rin ọdún ni Mósè jẹ́ lákòókò yẹn. Ó tó odindi ogójì ọdún tó ti sá kúrò nílùú àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lóko ẹrú ní Íjíbítì. Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń da agbo ẹran àna rẹ̀ nínú pápá, ó rí ohun abàmì kan. Iná ń sọ làù lára igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé, igi kékeré náà kò jóná. Iná yìí sì ń jó láìdáwọ́dúró, ó ń ràn yòò lẹ́bàá òkè náà. Ni Mósè bá sún mọ́ ibẹ̀ láti wò ó. Bẹ́ẹ̀ ló dédé gbóhùn láti inú iná yẹn, tí ẹnì kan ń bá a sọ̀rọ̀! Áà, èèmọ̀ rèé! Àṣé Ọlọ́run ni ó lo áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀, tí òun àti Mósè sì jùmọ̀ sọ̀rọ̀ fúngbà díẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí o ti mọ ìtàn yẹn, pé ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti rán Mósè níṣẹ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀ láti lọ. Ọlọ́run ní kí Mósè fi ìgbé ayé ìdẹ̀ra tó ń gbé sílẹ̀ kí ó padà sí Íjíbítì láti lọ gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú.—Ẹ́kísódù 3:1-12.

4 Wàyí o, onírúurú ìbéèrè ni Mósè ì bá ti fi àkókò yẹn bi Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, kíyè sí ohun tó béèrè, ó ní: “Ká ní mo wá dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ni ó rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì sọ fún mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn?”—Ẹ́kísódù 3:13.

5, 6. (a) Kókó pàtàkì wo ni ìbéèrè tí Mósè béèrè kọ́ wa? (b) Kí ni ìwà àìdáa táwọn èèyàn ti hù sí orúkọ Ọlọ́run? (d) Kí nìdí tí sísọ tí Ọlọ́run sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ fáráyé fi ṣe pàtàkì gan-an?

5 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìbéèrè tó béèrè yẹn kọ́ wa pé Ọlọ́run lórúkọ kan. Kò sì yẹ kí ẹnikẹ́ni fọwọ́ yẹpẹrẹ mú kókó tá a sọ wẹ́rẹ́ yìí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò kà á sí. Àwọn èèyàn ti yọ orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an kúrò nínú àìmọye ìtumọ̀ Bíbélì, wọ́n sì fi orúkọ oyè bí “Olúwa” àti “Ọlọ́run” rọ́pò rẹ̀. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìwà àfojúdi tó bani nínú jẹ́ jù lọ táwọn èèyàn tipasẹ̀ ìsìn hù. Ó dáa, kí lo kọ́kọ́ máa ń ṣe tó o bá bá ẹnì kan pàdé? Wàá fẹ́ mọ orúkọ rẹ̀, àbí? Bí ọ̀ràn mímọ Ọlọ́run ṣe rí náà nìyẹn. Ọlọ́run kì í ṣe ẹnì kan tí kò lórúkọ, tó kàn ta kété láìbìkítà, ẹni tá ò lè mọ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti tiwa ò sì lè yéra. Ẹni gidi kan ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fojú rí i. Ó lórúkọ, Jèhófà sì lorúkọ rẹ̀.

6 Pẹ̀lúpẹ̀lù, nígbà tí Ọlọ́run sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ fáráyé, ohun ńlá kan tó mórí yá gágá ló fẹ́ gbé ṣe. Ó wá ń ké sí wa pé ká máa bọ̀ wá mọ òun. Ó ń fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tó dára jù lọ la yàn nígbèésí ayé wa, èyíinì ni pé ká sún mọ́ òun. Kì í wá ṣe pé Jèhófà kàn sọ orúkọ rẹ̀ fún wa nìkan ni, ó tún kọ́ wa nípa ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn pàápàá.

Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run

7. (a) Ní ṣáńgílítí, kí ni orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí? (b) Kí ni Mósè fẹ́ mọ̀ ní ti gidi nígbà tó bi Ọlọ́run lórúkọ tó ń jẹ́?

7 Jèhófà ló fúnra rẹ̀ yan orúkọ tó ń jẹ́, orúkọ yẹn sì kún fún ìtumọ̀. Àwọn èèyàn gbà pé “Jèhófà” túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Kò sí ẹni tó dà bíi rẹ̀ láyé lọ́run, torí òun ló mú kí ohun gbogbo wà, ó sì ń mú kí gbogbo ète rẹ̀ ṣẹ. Ohun àgbàyanu sì nìyẹn lọ́tọ̀. Ṣùgbọ́n ṣé jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ Ẹlẹ́dàá nìkan ṣoṣo ni ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ mọ sí? Ó dájú pé ohun tí Mósè fẹ́ mọ̀ ju ìyẹn lọ. Ká sòótọ́, ó mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, ó sì mọ orúkọ Ọlọ́run. Àwọn èèyàn ti mọ orúkọ Ọlọ́run ṣáájú ìgbà ayé Mósè. Wọ́n ti ń lò ó láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Láìsí àní-àní, nígbà tí Mósè ń béèrè orúkọ Ọlọ́run, ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn gan-an ló fẹ́ mọ̀. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun tó ń sọ ni pé: ‘Kí ni màá sọ nípa rẹ fún Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ, tí wọ́n á fi gbà ọ́ gbọ́, tí wọ́n á sì fi ní ìdánilójú pé wàá gbà wọ́n là lóòótọ́?’

8, 9. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn ìbéèrè Mósè, kí sì nìdí tí ọ̀nà tí àwọn kan gbà túmọ̀ ohun tí Ọlọ́run sọ kò fi tọ̀nà? (b) Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà, “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́”?

8 Nígbà tí Jèhófà máa fèsì, ó jẹ́ kó mọ apá kan tó wúni lórí nínú àwọn ànímọ́ Rẹ̀, tó sì jẹ mọ́ ìtumọ̀ orúkọ Rẹ̀. Ó sọ fún Mósè pé: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan túmọ̀ ibí yìí sí: “Èmi ni ẹni tí ó wà.” Ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó jẹ́ pé a fara balẹ̀ túmọ̀ fi hàn pé kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ń mú un dá Mósè lójú pé òun wà ní ti gidi o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń kọ́ Mósè àti àwa èèyàn òde òní pẹ̀lú, ní ohun tó wé mọ́ orúkọ yẹn. Jèhófà “yóò jẹ́,” tàbí pé yóò sọ ara rẹ̀ di, ohunkóhun tó bá yẹ kó jẹ́ láti lè mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Bíbélì ti J. B. Rotherham kúkú túmọ̀ ẹsẹ yìí ní ṣàkó pé: “Èmi Yóò Di ohunkóhun yòówù tó bá wù mí.” Ìjìmì kan nínú ìmọ̀ èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì ṣàlàyé àpólà gbólóhùn yìí pé: “Ohunkóhun tí ipò nǹkan yẹn ì báà jẹ́ tàbí èyí tí ì báà gbà . . . , Ọlọ́run yóò ‘di’ ohun tí yóò jẹ́ ojútùú nǹkan yẹn.”

9 Kí ni ìyẹn wá túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ó túmọ̀ sí pé ohun yòówù kó dènà dè wọ́n, inú ìṣòro líle koko yòówù kí wọ́n wà, Jèhófà yóò di ohun tó bá yẹ́ kí ó jẹ́ láti lè dá wọn nídè kúrò lóko ẹrú kí ó sì kó wọ́n wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. Dájúdájú, orúkọ yẹn mú kí wọ́n gbọ́kàn lé Ọlọ́run. Orúkọ yẹn lè fún àwa náà ní irú ìgbọ́kànlé kan náà pẹ̀lú lóde òní. (Sáàmù 9:10) Èé ṣe?

10, 11. Báwo ni orúkọ Jèhófà ṣe mú ká máa wò ó pé ó jẹ́ Baba tó mọ ọwọ́ yí padà jù lọ àti Baba tó ju baba lọ láyé àtọ̀run? Ṣàpèjúwe rẹ̀.

10 Bí àpẹẹrẹ: Àwọn òbí mọ bó ṣe yẹ kí àwọn máa yíwọ́ padà àti bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ máa mú ara wọn bá ipòkípò mu láti lè tọ́jú ọmọ wọn. Lójúmọ́ kan, ó lè di dandan kí òbí di olùtọ́jú aláìsàn, kí ó di agbọ́únjẹ, olùkọ́, abániwí, adájọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Báwọn òbí mìíràn bá tiẹ̀ wo onírúurú nǹkan tí àwọn ọmọ wọn ń retí kí àwọn máa ṣe, ó máa ń kà wọ́n láyà. Wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ọmọ wọn ṣe gbà wọ́n gbọ́ tinútinú tó. Àti pé àwọn ọmọ máa ń gbà pé kò sí ohun tí bàbá tàbí màmá àwọn ò lè ṣe. Wọ́n gbà pé kì í nira fún àwọn òbí àwọn láti mú kí ibi tó ń dun àwọn fúyẹ́, pé gbogbo ìjà ni wọn yóò máa bá àwọn là, gbogbo ohun ìṣeré tó bá sì bà jẹ́ ni wọ́n máa tún ṣe, àti pé gbogbo ìbéèrè olófìn-íntótó tó bá sáà ti sọ sí àwọn lọ́kàn ni wọ́n máa dáhùn. Gbogbo èyí máa ń jẹ́ kí ẹ̀rù ba àwọn òbí mìíràn tí wọ́n bá ti rántí àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tiwọn, àní ó tiẹ̀ máa ń kó ìdààmú bá wọn pàápàá. Wọ́n máa ń gbà pé agbára àwọn ò lè gbé gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn rárá.

11 Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà náà jẹ́. Kò sóhun tí kò lè dà láti lè tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀-ayé lọ́nà tó dára jù lọ láìjẹ́ pé ó rú èyíkéyìí nínú àwọn ìlànà pípe tó ní. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe lorúkọ rẹ̀ yẹn, Jèhófà, ń gbìn ín sí wa lọ́kàn pé ká máa wò ó gẹ́gẹ́ bíi Baba tó ju baba lọ láyé àtọ̀run. (Jákọ́bù 1:17) Kò sì pẹ́ tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olóòótọ́ yòókù fi fúnra wọn rí i pé orúkọ ro Jèhófà lóòótọ́. Tìyanutìyanu ni wọ́n ń wò ó bí ó ṣe sọ ara rẹ̀ dẹni tó jẹ́ Ọ̀gágun Ajagunṣẹ́gun, Olùdarí gbogbo ipá àdáyébá bí afẹ́fẹ́, omi, iná àtàwọn nǹkan yòókù, Afúnnilófin tí kò lẹ́gbẹ́, Onídàájọ́ tó ta yọ, àgbà Oníṣẹ́ Ọnà, Olùpèsè oúnjẹ àti omi lọ́nà àrà, Ẹni tí kì í jẹ́ kí aṣọ àti bàtà gbó mọ́ni lára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

12. Báwo ni ìṣarasíhùwà Fáráò nípa Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí ti Mósè?

12 Nípa báyìí, Ọlọ́run ti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀, ó ti ṣí ọ̀pọ̀ ohun tó wúni lórí payá nípa òun ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn gan-an, àní ó tún ṣe ohun tó fi hàn pé orúkọ yẹn máa ń ro òun lóòótọ́. Dájúdájú, Ọlọ́run ń fẹ́ ká mọ òun. Ìhà wo ni àwa wá kọ sí i o? Mósè fẹ́ mọ Ọlọ́run. Ẹ̀mí tó ní yẹn ló yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà, tó fi dẹni tó sún mọ́ Bàbá rẹ̀ ọ̀run tímọ́tímọ́. (Númérì 12:6-8; Hébérù 11:27) Ó bani nínú jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn tó wà nígbà ayé Mósè ló ní irú ẹ̀mí tó ní yìí. Nígbà tí Mósè dárúkọ Jèhófà fún Fáráò, Ọba Íjíbítì, ńṣe ni agbéraga ọba yẹn fi ìkanra sọ pé: “Ta ni Jèhófà?” (Ẹ́kísódù 5:2) Fáráò kò fẹ́ láti mọ̀ síwájú sí i nípa Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹlẹ́yà ló fi ọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣe, ó ní kí Ọlọ́run yẹn bára ẹ̀ dà sọ́hùn-ún o jàre. Irú ìṣarasíhùwà kan náà làwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ní lóde òní. Ìṣarasíhùwà yìí kì í jẹ́ káwọn èèyàn lóye òótọ́ ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí, pé, Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ.

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ

13, 14. (a) Kí nìdí tí a fi fún Jèhófà ní orúkọ oyè púpọ̀ nínú Bíbélì, kí sì ni díẹ̀ lára wọn? (Wo àpótí “ Díẹ̀ Nínú Àwọn Orúkọ Oyè Jèhófà.”) (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló tọ́ kí á pè ní “Olúwa Ọba Aláṣẹ”?

13 Jèhófà mọ bí a ṣe máa ń yíwọ́ padà àti bí ó ṣe máa ń mú ara rẹ̀ bá ipòkípò mu gan-an débi pé a fún un ní oríṣiríṣi orúkọ oyè nínú Ìwé Mímọ́. Kì í ṣe pé orúkọ oyè wọ̀nyí wá fẹ́ rọ́pò orúkọ tó ń jẹ́ fúnra rẹ̀ o; kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n túbọ̀ kọ́ wa nípa ohun tí orúkọ rẹ̀ dúró fún gan-an. Bí àpẹẹrẹ, a pè é ní “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” (2 Sámúẹ́lì 7:22) Orúkọ oyè gíga lọ́lá yìí, tó fara hàn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà nínú Bíbélì, sọ ipò Jèhófà fún wa. Òun nìkan ló láṣẹ láti jẹ́ Ọba ayé òun ọ̀run. Wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

14 Jèhófà nìkan ni Ẹlẹ́dàá, kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ìṣípayá 4:11 sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Kò sí ẹlòmíràn tí àwọn ọ̀rọ̀ ńlá yìí tọ́ sí rárá àfi òun. Ọlá Jèhófà mà ni ohun gbogbo tó wà láyé àtọ̀run fi wà o! Láìsí àní-àní, Jèhófà ló ni ọlá, agbára àti ògo tó tọ́ sí Olúwa Ọba Aláṣẹ àti Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.

15. Kí nìdí tí a fi ń pe Jèhófà ní “Ọba ayérayé”?

15 Orúkọ oyè mìíràn tó tún wà fún Jèhófà nìkan ṣoṣo ni “Ọba ayérayé.” (1 Tímótì 1:17; Ìṣípayá 15:3) Kí ni èyí túmọ̀ sí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára òye wa kò lè gbé e láti mọ ohun tó túmọ̀ sí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, síbẹ̀ òtítọ́ pọ́ńbélé ni pé Jèhófà jẹ́ ẹni ayérayé, láìní ìbẹ̀rẹ̀ láìlópin. Sáàmù 90:2 sọ pé: “Àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.” Nípa báyìí, Jèhófà kò ní ìbẹ̀rẹ̀ rárá; kò sígbà kankan rí tí kò wà. Ìyẹn ló ṣe tọ́ bí a ṣe pè é ní “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” torí pé ó ti ń bẹ láti ayérayé wá ṣáájú ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tó wà láyé àtọ̀run! (Dáníẹ́lì 7:9, 13, 22) Nítorí náà, ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa béèrè nípa ẹ̀tọ́ tó ní láti jẹ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ?

16, 17. (a) Kí nìdí tí a ò fi lè rí Jèhófà, èé ṣe tí kò sì fi yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu? (b) Kí nìdí tí wíwà tí Jèhófà wà kò fi dà bí wíwà ohunkóhun tí a lè fọwọ́ kàn tàbí tí a lè rí?

16 Síbẹ̀, ńṣe làwọn kan ṣì ń fapá jánú pé ẹ̀tọ́ wo ló ní, àní gẹ́gẹ́ bí Fáráò ti ṣe. Ara ohun tó fa ìṣòro yìí ni pé, kìkì ohun tí ọmọ aráyé aláìpé bá lè fojú rí ló máa ń fẹ́ gbà gbọ́. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, a ò lè fojú rí Olúwa Ọba Aláṣẹ. Ẹni ẹ̀mí, tí ojú ọmọ adáríhurun ò lè rí ni. (Jòhánù 4:24) Yàtọ̀ síyẹn, bí èèyàn ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀ bá dé sàkáání ibi tí Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ wà pẹ́nrẹ́n, onítọ̀hún pa rẹ́ nìyẹn. Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún Mósè pé: “Ìwọ kò lè rí ojú mi, nítorí pé kò sí ènìyàn tí ó lè rí mi kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.”—Ẹ́kísódù 33:20; Jòhánù 1:18.

17 Kò yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu. Díẹ̀ lásán lára ògo Jèhófà ni Mósè rí, ẹ̀rí tiẹ̀ sì fi hàn pé ó tipasẹ̀ áńgẹ́lì aṣojú Ọlọ́run rí i ni. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i? Fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn náà, ńṣe ni awọ ojú Mósè ń “mú ìtànṣán jáde.” Ẹ̀rù gan-an ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wo ojú Mósè. (Ẹ́kísódù 33:21-23; 34:5-7, 29, 30) Ó dájú, nígbà náà pé, kò sí ọmọ adáríhurun kankan tó tẹ́ni tó ń fojú rí Olódùmarè, Olúwa Ọba Aláṣẹ, nínú ògo rẹ̀ gan-gan! Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni Ọlọ́run kàn dà bí ànímọ́ kan tí kì í ṣe nǹkan gidi tó ṣeé rí tó sì ṣeé fọwọ́ kàn? Rárá o. Ṣebí àwọn nǹkan kan wà tí a kò lè fojú rí síbẹ̀ tá a gbà pé wọ́n wà, irú bí afẹ́fẹ́, ìgbì rédíò, àti èrò inú wa. Pẹ̀lúpẹ̀lù, òyígíyigì ni Jèhófà, ẹni tó ti ń bẹ tí yóò sì máa wà bẹ́ẹ̀, tí kò lè yí padà títí ayérayé! Nípa bẹ́ẹ̀, wíwà tí Ọlọ́run wà kò dà bí wíwà ohunkóhun tí a lè fọwọ́ kàn tàbí tí a lè rí, nítorí pé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ nǹkan tí a lè rí pátá ló máa ń gbó tó sì máa ń díbàjẹ́. (Mátíù 6:19) Ó dára, nígbà náà, ṣé ká kàn kà á sí ohun àfòyemọ̀ lásán tí kì í ṣe ẹni gidi kan ni, tàbí ká kàn gbà pé ó jẹ́ ohun kò-lórí-kò-nídìí kan, ohun tó dá wà, tó sì wá di Orísun Ẹ̀dá? Jẹ́ ká ronú lórí àlàyé tó tẹ̀ lé e yìí ná.

Ọlọ́run Tó Ní Ànímọ́

18. Ìran wo ni Ìsíkíẹ́lì rí gbà, kí sì ni ojú mẹ́rin tí “àwọn ẹ̀dá alààyè” tó wà láyìíká Jèhófà ní dúró fún?

18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rí Ọlọ́run, àwọn àkọsílẹ̀ amóríyá kan wà nínú Bíbélì tó mú ká lè róye bí inú ọ̀run lọ́hùn-ún ṣe rí. Ìwé Ìsíkíẹ́lì orí kìíní jẹ́ ọ̀kan nínú irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀. Ìsíkíẹ́lì rí ìran kan nípa ètò Jèhófà lókè ọ̀run, tó dà bí àgbá kẹ́kẹ́ ọ̀run tó pabanbarì. Bí ó ṣe ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ńlá tó wà láyìíká Jèhófà wúni lórí gan-an ni. (Ìsíkíẹ́lì 1:4-10) “Àwọn ẹ̀dá alààyè” wọ̀nyí sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́, ìrísí wọn sì sọ àwọn nǹkan pàtàkì fún wa nípa Ọlọ́run tí wọ́n ń sìn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n ní ojú mẹ́rin, ìyẹn ojú akọ màlúù, ti kìnnìún, ti idì àti tèèyàn. Ẹ̀rí fi hàn pé, ìwọ̀nyí dúró fún àwọn ànímọ́ títayọ mẹ́rin tí Jèhófà ní.—Ìṣípayá 4:6-8, 10.

19. Ànímọ́ wo ni (a) ojú akọ màlúù dúró fún? (b) ojú kìnnìún dúró fún? (d) ojú idì dúró fún? (e) ojú ènìyàn dúró fún?

19 Nínú Bíbélì, akọ màlúù sábà máa ń dúró fún agbára, ó sì bá a mu bẹ́ẹ̀ nítorí pé ẹranko alágbára ńlá ni akọ màlúù jẹ́. Kìnnìún sábà máa ń dúró fún ìdájọ́ òdodo ní tirẹ̀, nítorí ìdájọ́ òdodo gba ìgboyà. Irú ìgboyà bẹ́ẹ̀ sì ni ànímọ́ táwọn èèyàn mọ̀ mọ́ kìnnìún látayébáyé. Idì jẹ́ ẹyẹ táráyé mọ̀ dáadáa pé ojú rẹ̀ ń ríran jìnnàjìnnà, débi pé ó lè rí àwọn nǹkan kéékèèké tó jìnnà réré sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, ojú idì ṣeé fi wé ọgbọ́n tó ríran jìnnà tí Ọlọ́run ní. Ojú ènìyàn wá ńkọ́ o? Ṣé a kúkú mọ̀ pé àwòrán Ọlọ́run ni a dá èèyàn, ìyẹn ló ṣe jẹ́ pé òun nìkan ló lè gbé ànímọ́ tó gba iwájú nínú gbogbo ànímọ́ Ọlọ́run yọ, ìyẹn ìfẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Apá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà nínú ìwà Jèhófà yìí, ìyẹn agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́, jẹ́ èyí tí Ìwé Mímọ́ sábà máa ń tẹnu mọ́ léraléra débi tá a kúkú fi lè pè wọ́n ní olú ànímọ́ mẹ́rin tí Ọlọ́run ní.

20. Ǹjẹ́ ó yẹ kí á máa kọminú pé bóyá ànímọ́ Jèhófà lè ti yí padà, kí sì nìdí tí o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

20 Ǹjẹ́ ó yẹ kí ominú máa kọ wá pé bóyá Ọlọ́run á ti yí padà ní báyìí lẹ́yìn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn tí a ti ṣàpèjúwe irú ẹni tó jẹ́ sínú Bíbélì? Rárá o, ànímọ́ Ọlọ́run kì í yí padà rárá. Ó sọ fún wa pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Jèhófà kì í pa ìṣe rẹ̀ dà léraléra bí ọ̀gà ṣe ń pàwọ̀ dà, kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tó gbà ń bójú tó onírúurú ipò tó bá yọjú fi hàn pé ó jẹ́ Baba tí ó tó baba ì ṣe. Àwọn apá tó bá yẹ kí ó lò gẹ́lẹ́ lára ànímọ́ rẹ̀, ní àsìkò kan pàtó, ló máa ń jẹ́ kó lékè. Nínú gbogbo ànímọ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìfẹ́ ló gba iwájú. Ó máa ń hàn nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run bá ń ṣe pátá. Ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ ló gbà ń lo agbára, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n rẹ̀. Àní Bíbélì pàápàá sọ ohun àrà ọ̀tọ̀ kan nípa Ọlọ́run àti ànímọ́ rẹ̀ yìí. Ó ní: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ṣàkíyèsí pé kò sọ pé Ọlọ́run ìfẹ́ tàbí pé Ọlọ́run máa ń fẹ́ràn ẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Ìfẹ́ yẹn gan-an tí ó jẹ́, ló máa ń sún un ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe.

“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí”

21. Kí ni a óò máa mọ̀ lára bí a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà sí i?

21 Ǹjẹ́ o ti rí ibi tí ọmọ kékeré kan ti ń fi bàbá rẹ̀ han àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi orí yíyá gágá sọ fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe ọmọdé, pé, “Bàbá mi nìyẹn”? Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló yẹ kí Jèhófà ṣe rí sí àwọn tó ń sìn ín. Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan yóò wà tí àwọn olóòótọ́ èèyàn yóò kéde pé: “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí.” (Aísáyà 25:8, 9) Bí o bá ṣe túbọ̀ ń ní ìjìnlẹ̀ òye nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà ni wàá ṣe máa mọ̀ ọ́n lára pé Baba tó tó baba í ṣe gan-an lo ní.

22, 23. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Bàbá wa ọ̀run, báwo la sì ṣe mọ̀ pé ó ń fẹ́ ká sún mọ́ òun?

22 Láìka ohun yòówù kí àwọn agbawèrèmẹ́sìn àti onímọ̀ èrò orí ti fi kọ́ àwọn ènìyàn sí, ó dájú pé Jèhófà kì í ṣe Bàbá kan tó ta kété láìbìkítà, tó fọwọ́ lẹ́rán tó kàn ń wòran. Ó hàn gbangba pé ọkàn wa kò ní fà mọ́ Ọlọ́run tí kò dá síni, àti pé Bíbélì ò tiẹ̀ fi hàn pé irú bàbá bẹ́ẹ̀ ni Bàbá wa ọ̀run jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, “Ọlọ́run aláyọ̀” ló pè é. (1 Tímótì 1:11) Ó ní ìmí ẹ̀dùn, ó sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára. Ó máa ń “dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀” bí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ olóye bá ń rú àwọn ìlànà tó là sílẹ̀ fún ire wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:6; Sáàmù 78:41) Ṣùgbọ́n tí a bá hùwà ọlọgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe sọ, a máa ń “mú ọkàn-àyà” rẹ̀ yọ̀.—Òwe 27:11.

23 Bàbá wa yìí ń fẹ́ ká sún mọ́ òun. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà wá níyànjú pé kí á ‘táràrà fún un, kí á sì rí i ní ti gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.’ (Ìṣe 17:27) Ṣùgbọ́n, báwo ló tiẹ̀ ṣe lè ṣeé ṣe pé kí ẹ̀dá ènìyàn lásánlàsàn sún mọ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run?