Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí 3

“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”

“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”

1, 2. Ìran wo ni wòlíì Aísáyà rí, kí ló sì kọ́ wa nípa Jèhófà?

Ẹ̀RÙ Ọlọ́run ba Aísáyà ó sì wárìrì nígbà tó rí ìran kan, ìyẹn ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àfi bíi pé nǹkan yẹn ń ṣẹlẹ̀ lójú ayé gan-an ni! Àní ó ṣe Aísáyà débi tó fi kọ ọ́ síwèé lẹ́yìn náà pé òun “rí Jèhófà” sójú bí ó ṣe wà lórí ìtẹ́ Rẹ̀ gíga fíofío. Ó ní ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì ńlá tó wà ní Jerúsálẹ́mù.—Aísáyà 6:1, 2.

2 Ohun tí Aísáyà gbọ́ tún mú kí ẹ̀rù Ọlọ́run bà á. Ó wárìrì nígbà tó gbọ́ ìró orin kan tó mi ilẹ̀ tẹ́ńpìlì tìtì dé ìpìlẹ̀ rẹ̀ pàápàá. Àwọn séráfù tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà nípò gíga gan-an ló ń kọ orin yẹn. Ègbè orin ọlọ́lá ńlá, adùnyùngbà tí wọn ń kọ, lọ báyìí pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbogbo ilẹ̀ ayé ni ògo rẹ̀.” (Aísáyà 6:3, 4) Bí wọ́n ṣe ń pe ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” lẹ́ẹ̀mẹta nínú orin wọn ń fún ọ̀rọ̀ náà ní ìtẹnumọ́ pàtàkì, ó sì tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé Jèhófà ló jẹ́ ẹni mímọ́ jù lọ. (Ìṣípayá 4:8) Látòkèdélẹ̀ Bíbélì ni a ti tẹnu mọ́ ìjẹ́mímọ́ Jèhófà. Nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹsẹ Bíbélì ni a ti so orúkọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ “mímọ́” tàbí “ìjẹ́mímọ́.”

3. Báwo ni èrò òdì tí àwọn kan ní nípa jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ mímọ́ ṣe ń sún wọn láti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run dípò kí wọ́n sún mọ́ ọn?

3 Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ọ̀kan nínú ohun pàtàkì tí Jèhófà fẹ́ ká kọ́kọ́ mọ̀ nípa òun ni pé òun jẹ́ ẹni mímọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, torí ìjẹ́mímọ́ yìí gan-an làwọn kan lóde òní kò ṣe fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run. Àṣìṣe tí àwọn kan máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń ka ìjẹ́mímọ́ sí ọmọ ìyá kan náà pẹ̀lú ẹ̀mí jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni àti ẹ̀mí ìtara òdì nípa ìsìn. Ní ti àwọn èèyàn tí kò ka ara wọn sí ẹni iyì, jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ lè kà wọ́n láyà dípò tí ì bá fi máa wù wọ́n. Ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé àwọn ò tẹ́rú tó ń sún mọ́ Ọlọ́run mímọ́ yìí rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń kẹ̀yìn sí Ọlọ́run nítorí pé ó jẹ́ ẹni mímọ́. Ó ṣeni láàánú gan-an ni, torí pé jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ yìí gan-an nìdí pàtàkì tó fi yẹ ká sún mọ́ ọn. Èé ṣe? Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìjẹ́mímọ́ tòótọ́ jẹ́.

Kí Ni Ìjẹ́mímọ́?

4, 5. (a) Kí ni jíjẹ́ mímọ́ túmọ̀ sí, kí ni kò sì túmọ̀ sí? (b) Ọ̀nà méjì pàtàkì wo ni Jèhófà ti gbà jẹ́ ẹni tó “yà sọ́tọ̀”?

4 Pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ kò túmọ̀ sí pé ó dà bí ẹni tó jọra ẹ̀ lójú jù, tó jẹ́ onírera tàbí ẹni tó ń wo àwọn yòókù tìkà-tẹ̀gbin. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ kórìíra irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀. (Òwe 16:5; Jákọ́bù 4:6) Nítorí náà, kí ni ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” túmọ̀ sí ní ti gidi? Nínú èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ sí mímọ́ wá látinú ọ̀rọ̀ kan tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ “yà sọ́tọ̀.” Nínú ìjọsìn, tí a bá sọ pé ohun kan jẹ́ “mímọ́,” ó fi hàn pé nǹkan yẹn jẹ́ èyí tí a yà sọ́tọ̀ fún ìlò ọ̀tọ̀, tàbí ohun tí a kà sí nǹkan ọ̀wọ̀. Sísọ pé ohun kan jẹ́ mímọ́ sì tún máa fúnni ní ìtumọ̀ pé ohun náà mọ́ nigín-nigín tàbí pé ó mọ́ gaara. Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe wá kan Jèhófà? Ṣé èyí túmọ̀ sí pé ó “ya” ara rẹ̀ “sọ́tọ̀” kúrò lọ́dọ̀ àwa ọmọ aráyé aláìpé, tó sì jìnnà réré sí wa ni?

5 Rárá o. Jèhófà tó jẹ́ “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì” sọ pé òun ń gbé “láàárín” àwọn èèyàn òun, bẹ́ẹ̀ ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn tó ń wí yìí o. (Aísáyà 12:6; Hóséà 11:9) Nítorí náà, jíjẹ́ tó jẹ́ mímọ́ kò mú kí ó dẹni tó jìnnà réré sí wa. Báwo ló ṣe wá jẹ́ ẹni tó “yà sọ́tọ̀” nígbà náà? Ọ̀nà méjì pàtàkì ló gbà jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ó jẹ́ nítorí pé ó yàtọ̀ sí gbogbo ìṣẹ̀dá nítorí pé òun ni Ẹni Gíga Jù Lọ. Bí ó ṣe mọ́ gaara àti bí ó ṣe mọ́ nigín-nigín jẹ́ lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́. (Sáàmù 40:5; 83:18) Ìkejì, Jèhófà ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ gédégédé sí gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀, èyí sì jẹ́ kókó kan tó tù wá nínú. Kí nìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀?

6. Báwo ni jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ ẹni tó yà sọ́tọ̀ gédégédé kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lè jẹ́ ìtùnú fún wa?

6 Ojúlówó ìjẹ́mímọ́ ṣọ̀wọ́n nínú ayé tí à ń gbé yìí. Ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ti àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run ló ní àbùkù lọ́nà kan ṣáá nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti kó àbààwọ́n bá a. Gbogbo wa ló di dandan fún pé ká máa gbógun ti ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú wa. Gbogbo wa ni ẹ̀ṣẹ̀ lè gbé mì káló bí a kò bá wà lójúfò. (Róòmù 7:15-25; 1 Kọ́ríńtì 10:12) Ní ti Jèhófà, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí i láéláé. Níwọ̀n bí ó ti jìnnà réré sí ẹ̀ṣẹ̀, àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kankan ò lè ta sí i lára rárá bó ti wú kò kéré mọ́. Èyí túbọ̀ jẹ́ ká gbà pé Jèhófà jẹ́ Baba tó tó baba í ṣe lóòótọ́, nítorí ó fi hàn pé ó ṣeé gbọ́kàn lé pátápátá. Jèhófà kò dà bí àwọn bàbá ẹlẹ́ran ara bíi tiwa tó lè yíwà padà kó sì ya ìyàkuyà tàbí kí ó di ìkà ènìyàn. Jíjẹ́ tó jẹ́ mímọ́ kò lè jẹ́ kó ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láé. Àní ní àwọn ìgbà kan, Jèhófà tiẹ̀ fi ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ búra, nítorí kò sóhun tó tún lè mú kí ìbúra rẹ̀ dáni lójú ju ìyẹn lọ. (Ámósì 4:2) Ǹjẹ́ èyí kò fini lọ́kàn balẹ̀?

7. Kí nìdí tí a fi lè sọ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ tinú-tòde ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀?

7 Jèhófà jẹ́ mímọ́ tinú-tòde ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Àpẹẹrẹ kan rèé: Wo ọ̀rọ̀ méjì yìí, “ènìyàn” àti “àìpé.” A ò lè ṣàpèjúwe ọmọ ènìyàn láìsọ̀rọ̀ kan àìpé. Aláìpé ni a jẹ́ látòkèdélẹ̀, èyí sì máa ń fara hàn nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe pátá. Wàyí o, wá wo ọ̀rọ̀ méjì tó yàtọ̀ pátápátá sí ìyẹn, òun ni “Jèhófà” àti “mímọ́.” Mímọ́ ni Jèhófà jẹ́ tinú-tòde. Gbogbo nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀ títí kan ìwà rẹ̀ ló jẹ́ mímọ́ lọ́nà tó ga jù lọ. A kò lè mọ bí Jèhófà ṣe jẹ́ gan-an àyàfi bí a bá kọ́kọ́ mọ bí ọ̀rọ̀ pàtàkì náà “mímọ́” ṣe jinlẹ̀ tó.

“Ìjẹ́mímọ́ Jẹ́ Ti Jèhófà”

8, 9. Kí ló fi hàn pé Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn aláìpé lọ́wọ́ láti jẹ́ mímọ́ dé ìwọ̀n tó ṣeé fewé mọ́?

8 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tí Jèhófà jẹ́ tinú-tòde gan-an ni ànímọ́ tí à ń pè ní mímọ́, a lè fi ẹ̀tọ́ sọ pé òun ni orísun gbogbo nǹkan mímọ́. Kì í ṣe pé ó dá nìkan ní ànímọ́ iyebíye yìí o; ó jẹ́ kí àwọn mìíràn ní in pẹ̀lú. Kódà ọ̀nà ọ̀làwọ́ ló gbà ń fún wọn pàápàá. Àní sẹ́, nígbà tí Ọlọ́run lo áńgẹ́lì láti bá Mósè sọ̀rọ̀, ńṣe ni ilẹ̀ àyíká ibẹ̀ di mímọ́ nítorí pé Jèhófà lo ibẹ̀!—Ẹ́kísódù 3:5.

9 Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ọmọ ènìyàn aláìpé tipasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Jèhófà di ẹni mímọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ṣùgbọ́n ìjẹ́mímọ́ tiwọn ní ààlà. Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀ láǹfààní dídi “orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ẹ́kísódù 19:6) Ó fi ọ̀nà ìgbàjọ́sìn tó jẹ́ mímọ́ gaara tó sì mọ́ nigínnigín dá wọn lọ́lá. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìjẹ́mímọ́ ń fara hàn lemọ́lemọ́ nínú Òfin Mósè. Àlùfáà àgbà tiẹ̀ máa ń so àwo wúrà kan mọ́ iwájú láwàní rẹ̀, níbi tí gbogbo èèyàn yóò ti máa rí i bó ṣe ń kọ mọ̀nà bí ìmọ́lẹ̀ bá ti tàn sí i. Ohun tí a sì fín sára rẹ̀ ni: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 28:36) Nípa bẹ́ẹ̀ ìjọsìn wọn, àní títí kan ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn ní láti jẹ́ èyí tó mọ́ tónítóní lọ́nà tó dá yàtọ̀. Jèhófà sọ fún wọn pé: “Kí ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.” (Léfítíkù 19:2) Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń sa gbogbo ipá wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn aláìpé, láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run, wọ́n jẹ́ mímọ́ dé ìwọ̀n tó ṣeé fewé mọ́.

10. Tó bá kan ti ìjẹ́mímọ́, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ àti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká?

10 Bí Jèhófà ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́mímọ́ yìí yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀nà tí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká ń gbà jọ́sìn. Àwọn òrìṣà tó jẹ́ pé irọ́ àti ẹ̀tàn làwọn èèyàn fi pilẹ̀ wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè ń jọ́sìn, àti pé bí wọ́n tiẹ̀ ṣe máa ń fi àwọn òrìṣà wọ̀nyí hàn fi hàn pé wọ́n jẹ́ òǹrorò, oníwọra àti oníṣekúṣe. Gbogbo nǹkan wọn pátá kìkì ẹ̀gbin ni. Ńṣe ni ìjọsìn irú àwọn òrìṣà bẹ́ẹ̀ ń sọ àwọn èèyàn di aláìmọ́. Ìyẹn ni Jèhófà fi kìlọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà yìí àti ìjọsìn ẹlẹ́gbin tí wọ́n ń ṣe.—Léfítíkù 18:24-28; 1 Àwọn Ọba 11:1, 2.

11. Báwo ni jíjẹ́ tí ètò Jèhófà ní ọ̀run jẹ́ mímọ́ ṣe hàn lára (a) àwọn áńgẹ́lì? (b) àwọn séráfù? (d) Jésù?

11 Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ tí Jèhófà yàn tilẹ̀ ṣe dáadáa jù lọ pàápàá, ìwọ̀n bíńtín ni wọ́n lè gbé yọ lára ìjẹ́mímọ́ ètò Ọlọ́run ní ọ̀run. Ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá ẹ̀mí tó ń fi ìdúróṣinṣin sin Ọlọ́run ní ọ̀run yìí ni a pè ní “àwọn ẹgbẹẹgbàárùn-ún mímọ́” rẹ̀. (Diutarónómì 33:2; Júúdà 14) Wọ́n ń gbé ògo ìjẹ́mímọ́ Ọlọ́run yọ láìkù síbì kan. Má sì gbàgbé àwọn séráfù tí Aísáyà rí nínú ìran rẹ̀. Ohun tí wọ́n ń kọ lórin jẹ́ kó yéni pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára yìí ń kó ipa pàtàkì nínú sísọ ìjẹ́mímọ́ Jèhófà di mímọ̀ láyé àtọ̀run. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀dá ẹ̀mí kan wà tó ga ju gbogbo wọn lọ. Òun ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí Ọlọ́run ní, ìyẹn Jésù. Òun ló gbé ìjẹ́mímọ́ Jèhófà yọ jù lọ. Ìyẹn ló fi tọ̀nà pé òun la mọ̀ sí “Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”—Jòhánù 6:68, 69.

Orúkọ Mímọ́, Ẹ̀mí Mímọ́

12, 13. (a) Kí nìdí tó fi bá a mu láti sọ pé orúkọ Ọlọ́run jẹ́ mímọ́? (b) Kí nìdí tó fi di dandan láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́?

12 Orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ wá ń kọ́ o? Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i ní Orí 1, kì í ṣe orúkọ oyè tàbí orúkọ àtẹ̀pè lorúkọ yẹn. Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gan-an ni orúkọ yẹn dúró fún, ó sì kó gbogbo ànímọ́ rẹ̀ pọ̀. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ fún wa pé òun ni “orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ mímọ́.” (Aísáyà 57:15) Òfin Mósè sọ pé pípa ni kí á pa ẹni tó bá sí tàbùkù orúkọ Ọlọ́run. (Léfítíkù 24:16) Sì kíyè sí ohun tí Jésù fi ṣáájú nínú àdúrà rẹ̀, ó ní: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Láti sọ ohun kan di mímọ́ túmọ̀ sí pé kí á ya nǹkan yẹn sọ́tọ̀ fún ìlò ọ̀wọ̀ kí a sì bọ̀wọ̀ fún un, kí á kà á sí ohun mímọ́. Ṣùgbọ́n kí nìdí tí a o fi tún ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá sọ orúkọ Ọlọ́run tó ti mọ́ tinú tẹ̀yìn tẹ́lẹ̀ di mímọ́?

13 Ìdí ni pé àwọn ẹ̀dá Ọlọ́run bà á lórúkọ jẹ́, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ yẹn. Sátánì purọ́ mọ́ Jèhófà nínú ọgbà Édẹ́nì, ó sì dọ́gbọ́n sọ pé Jèhófà jẹ́ Ọba Aláṣẹ tí kì í ṣe ẹ̀tọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Láti ìgbà yẹn wá ni Sátánì tó jẹ́ alákòóso ayé aláìmọ́ yìí, ti ń rí sí i pé onírúurú irọ́ ń tàn kálẹ̀ nípa Ọlọ́run. (Jòhánù 8:44; 12:31; Ìṣípayá 12:9) Àwọn ẹ̀sìn ayé yìí sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni tí kì í dúró gbẹ́jọ́, ẹni tó yara ẹ̀ láṣo tàbí tó jẹ́ òǹrorò. Wọ́n ní òun ló ń ti àwọn lẹ́yìn nínú àwọn ogun àjàkú-akátá wọn tí ó kún fún ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀. Kàkà kí wọ́n máa yin Ọlọ́run lógo fún iṣẹ́ àrà tó ṣe nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀, bí wọn ò bá sọ pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kàn ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ ni, wọ́n á ní ẹfolúṣọ̀n ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n mà kúkú tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run jìnnàjìnnà o. Ó yẹ kí orúkọ Ọlọ́run di èyí tí a sọ di mímọ́; kí ògo orúkọ yẹn tún padà máa tàn. Tọkàntara la fi ń retí ìgbà tí orúkọ rẹ̀ yóò di èyí tí a sọ di mímọ́, tí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ yóò sì di èyí tí a dá láre. Inú wa yóò sì dùn láti kópa nínú ète ọlọ́lá ńlá yẹn.

14. Kí nìdí tí a fi pe ẹ̀mí Ọlọ́run ní mímọ́, kí sì nìdí tí ìsọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́ fi jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gidigidi?

14 Nǹkan kan tún wà tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbà gbogbo la máa ń pè é ní mímọ́. Òun ni ẹ̀mí tàbí agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Ipá rẹ̀ yìí tí ohunkóhun ò lè dí lọ́wọ́ ló ń lò láti fi mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ń ṣe ló máa ń mọ́ nigínnigín tó sì máa ń mọ́ gaara ní gbogbo ọ̀nà. Ìyẹn ló fi tọ̀nà pé a pe agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ tàbí ẹ̀mí ìjẹ́mímọ́. (Lúùkù 11:13; Róòmù 1:4) Sísọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, èyí tó kan pé kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ máa ṣe ohun tó tako àwọn ète Jèhófà, jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì.—Máàkù 3:29.

Ìdí Tí Ìjẹ́mímọ́ Jèhófà Fi Mú Wa Sún Mọ́ Ọn

15. Kí nìdí tó fi bá a mu láti ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run béèyàn bá ti mọ bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́ tó, kí ló sì wé mọ́ irú ìbẹ̀rù yẹn?

15 Kò ṣòro nígbà náà, láti rí ohun tó fà á tí Bíbélì fi so ìjẹ́mímọ́ Ọlọ́run pọ̀ mọ́ yíyẹ tó yẹ kí ẹ̀dá èèyàn ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 99:3 kà pé: “Kí wọ́n gbé orúkọ rẹ lárugẹ. Títóbi àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ni, mímọ́ ni.” Àmọ́ ṣá, ìbẹ̀rù yìí kì í ṣe irú èyí tí ń rani níyè o. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ ìbẹ̀rù tó ń múni bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an fún Ọlọ́run. Ó sì bá a mu gẹ́ẹ́ kéèyàn ní irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀, nítorí pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà jẹ́ mímọ́ ga ju tiwa lọ dáadáa. Mímọ́ tirẹ̀ ń tàn yanran, ológo sì ni. Síbẹ̀, kò yẹ kí ó lé wa sá o. Dípò ìyẹn, fífi ojú tó tọ́ wo jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, yóò tiẹ̀ mú wa sún mọ́ ọn ni. Kí nìdí rẹ̀?

Bí ẹwà ṣe máa ń wù wá ló ṣe yẹ kó máa wù wá láti jẹ́ mímọ́

16. (a) Báwo ni ìjẹ́mímọ́ ṣe so pọ̀ mọ́ ẹwà? Mú àpẹẹrẹ kan wá. (b) Báwo ni àpèjúwe tí àwọn tó rí Jèhófà lójú ìran ń ṣe fún wa nípa rẹ̀ ṣe máa ń pàfiyèsí sí ìdáṣáká, ìmọ́gaara àti ìmọ́lẹ̀?

16 Ìdí kan ni pé, Bíbélì so ìjẹ́mímọ́ pọ̀ mọ́ ẹwà. Aísáyà 63:15 ṣàpèjúwe ọ̀run pé ó jẹ́ “ibùjókòó . . . gíga fíofío ti ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà.” Ẹwà máa ń fà wá mọ́ra ni. Bí àpẹẹrẹ, wo àwòrán tó wà lójú ewé 33. Ǹjẹ́ bí ibẹ̀ ṣe rí kò fà ọ́ mọ́ra? Kí ló jẹ́ kó wù ọ́ tó bẹ́ẹ̀? Wo bí omi ibẹ̀ ṣe tòrò minimini. Kódà, ó dájú pé atẹ́gùn ibẹ̀ á mọ́ lóló, nítorí ojú sánmà ibẹ̀ mọ́ roro bí ìgbà tí oòrùn là lẹ́yìn òjò àrọ̀mọ́jú, ó sì dà bíi pé ìmọ́lẹ̀ ibẹ̀ pàápàá ń dán yinrin. Wàyí o, jẹ́ ká sọ pé wọ́n wá yí ojú ibi tí à ń wò yẹn padà, kí pàǹtírí kún ojú omi yẹn, kí á ti fi oríṣiríṣi ìkọkúkọ ba ara àwọn igi àti òkúta ibẹ̀ jẹ́, kí èéfín sì gba gbogbo afẹ́fẹ́ ibẹ̀ kan, kò ní wù wá mọ́; a ò ní fẹ́ wò ó lẹ́ẹ̀mejì. Ohun tó máa ní ẹwà lójú wa sábà máa ń jẹ́ ohun tó dá ṣáká, tó mọ́ gaara tó sì ní ìmọ́lẹ̀. A lè lo àwọn ọ̀rọ̀ kan náà yìí láti fi ṣàpèjúwe jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ mímọ́. Abájọ tí ohun tí àwọn tó rí Jèhófà lójú ìran máa ń ṣàpèjúwe fún wa nípa rẹ̀ fi máa ń jẹ́ àwọn nǹkan àgbàyanu tó fani mọ́ra gidigidi! Wọ́n máa ń rí ohun tó ń tan ìmọ́lẹ̀ yanran, ohun tó ń dán gbinrin bí àwọn òkúta iyebíye, tó ń tàn yòò bí iná tàbí tó dà bí àwọn nǹkan iyebíye tó dára jù lọ tó sì ń tàn yinrin jù lọ. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ni wọ́n fi máa ń ṣàkàwé ẹwà Ọlọ́run wa mímọ́.—Ìsíkíẹ́lì 1:25-28; Ìṣípayá 4:2, 3.

17, 18. (a) Báwo ni ìran tí Aísáyà rí ṣe kọ́kọ́ rí lára rẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe lo séráfù láti tu Aísáyà nínú, kí ni ohun tí séráfù yẹn ṣe sì túmọ̀ sí?

17 Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó yẹ kí jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ mú ká rí ara wa bí aláìjámọ́ nǹkan kan ní ìfiwéra pẹ̀lú rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, a ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà rárá. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí mímọ̀ tí a mọ ìyẹn wá mú wa kẹ̀yìn sí i? Wo ohun tí Aísáyà ṣe nígbà tó gbóhùn àwọn séráfù tí ń pòkìkí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́. Ó ní: “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: ‘Mo gbé! Nítorí, kí a sáà [kúkú] sọ pé a ti pa mí lẹ́nu mọ́, nítorí pé ọkùnrin aláìmọ́ ní ètè ni mí, àárín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ètè sì ni mo ń gbé; nítorí pé ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, tìkára rẹ̀!’” (Aísáyà 6:5) Bẹ́ẹ̀ ni o, jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ mímọ́ lọ́nà tí kò láfiwé mú kí Aísáyà rántí bí òun ṣe jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé tó. Ìyẹn kọ́kọ́ da ọkùnrin olóòótọ́ yìí lọ́kàn rú. Àmọ́ Jèhófà kò dá a dá ìṣòro rẹ̀.

18 Kíá ni séráfù kan wá láti tu wòlíì yìí nínú. Báwo ló ṣe tù ú nínú? Áńgẹ́lì alágbára yìí fò lọ síbi pẹpẹ, ó mú ẹyín iná kan níbẹ̀ ó sì fi kan ètè Aísáyà. A lè rò pé ńṣe ni iná yìí máa jó o létè dípò kó tù ú nínú. Ṣùgbọ́n, ká rántí pé ìran la pè é, onírúurú nǹkan ìṣàpẹẹrẹ tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ sì kún fún ìtumọ̀. Aísáyà tó jẹ́ Júù olóòótọ́ mọ̀ dáadáa pé ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ní tẹ́ńpìlì láti fi ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀. Séráfù yìí sì wá rán Aísáyà létí tìfẹ́tìfẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìpé lóòótọ́, ìyẹn “aláìmọ́ ní ètè,” ó ṣì lè dẹni tí Ọlọ́run kà sí ẹni tó mọ́. * Jèhófà ṣe tán láti ka èèyàn aláìpé, ẹlẹ́ṣẹ̀, sí ẹni tó jẹ́ mímọ́ dé ìwọ̀n kan tó ṣeé fewé mọ́.—Aísáyà 6:6, 7.

19. Bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́ mímọ́ dé ìwọ̀n àyè kan?

19 Bákan náà ló ṣe jẹ́ lóde òní. Gbogbo ẹbọ tí wọ́n ń rú lórí pẹpẹ ní Jerúsálẹ́mù kàn jẹ́ òjìji ni, òjìji ohun ńlá kan tó ju ẹbọ wọ̀nyẹn lọ, ìyẹn sì ni ẹbọ pípé kan ṣoṣo tí Jésù Kristi rú lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa. (Hébérù 9:11-14) Bí a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tí a jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́ tí à ń hù, tí a sì lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Kristi yìí, Ọlọ́run yóò dárí jì wá. (1 Jòhánù 2:2) Ọlọ́run lè ka àwa náà sí ẹni tó mọ́. Ìyẹn ni àpọ́sítélì Pétérù fi rán wa létí pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.’” (1 Pétérù 1:16) Kíyè sí i pé Jèhófà sọ pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ gẹ́lẹ́ bí òun ṣe jẹ́ mímọ́. Kì í retí pé kí á ṣe ohun tí agbára wa ò gbè láé. (Sáàmù 103:13, 14) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ní kí á jẹ́ mímọ́ nítorí pé òun jẹ́ mímọ́. “Gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” a máa ń sa gbogbo ipá tí àwa, ẹ̀dá aláìpé, lè sà láti ṣàfarawé rẹ̀. (Éfésù 5:1) Nípa bẹ́ẹ̀, ìsapá láti jẹ́ ẹni mímọ́ kò lópin, ìgbésẹ̀ tí yóò máa bá a lọ ni. Bí a ṣe ń dàgbà dénú sí i nípa tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe máa ṣiṣẹ́ kára láti “máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé” lójoojúmọ́.—2 Kọ́ríńtì 7:1.

20. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì fún wa láti lóye pé a lè jẹ́ ẹni tó mọ́ lójú Ọlọ́run wa mímọ́? (b) Nígbà tí Aísáyà gbọ́ pé a ti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ òun, kí ni ipa tó ní lórí rẹ̀?

20 Jèhófà fẹ́ràn ohun adúróṣánṣán tó sì jẹ́ mímọ́. Ó kórìíra ẹ̀ṣẹ̀. (Hábákúkù 1:13) Àmọ́ o, kò kórìíra àwa ọmọ ènìyàn. Bí a bá sáà ti ń fojú kan náà bíi tirẹ̀ wo ẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn ni pé kí á kórìíra ohun búburú, kí á nífẹ̀ẹ́ ohun rere, kí á sì máa sapá láti tọ ipasẹ̀ Kristi Jésù, Jèhófà yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Ámósì 5:15; 1 Pétérù 2:21) Bí òye bá ti yé wa pé a lè jẹ́ ẹni tó mọ́ lójú Ọlọ́run wa mímọ́, a ó máa ṣe gudugudu méje láti jẹ́ bẹ́ẹ̀. Rántí pé ìjẹ́mímọ́ ti Jèhófà kọ́kọ́ mú kí Aísáyà rántí bí òun ṣe jẹ́ aláìmọ́ tó. Ìyẹn ló fi kígbe pé: “Mo gbé!” Àmọ́ gbàrà tó mọ̀ pé a ti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ òun, ọkàn rẹ̀ balẹ̀. Nígbà tí Jèhófà wá sọ pé òun fẹ́ kí ẹnì kan yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ kan, kíá ni Aísáyà yọ̀ǹda ara rẹ̀ láìtiẹ̀ tíì mọ ohun tí iṣẹ́ yẹn máa gbà. Ó sọ lóhùn rara pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”—Aísáyà 6:5-8.

21. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pé a lè dẹni tó jẹ́ mímọ́?

21 Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, ó fún wa ní àwọn ànímọ́ tí a ó máa fi ṣèwà hù, ó sì fi ẹ̀mí ìjọsìn sí wa lọ́kàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Gbogbo wa pátá la lè di ẹni mímọ́. Bí a ṣe ń bá a lọ láti fi ìjẹ́mímọ́ kọ́ra, inú Jèhófà máa ń dùn láti ràn wá lọ́wọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wa á tún mú kí a máa sún mọ́ Ọlọ́run wa mímọ́ sí i. Síwájú sí i, bí a óò ṣe máa gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yẹ̀ wò nínú àwọn orí tí ń bẹ́ níwájú a óò rí i pé àwọn ìdí tó lágbára wà tó fi yẹ ká sún mọ́ ọn!

^ ìpínrọ̀ 18 Gbólóhùn náà, “aláìmọ́ ní ètè,” bá a mu gan-an, nítorí pé Bíbélì sábà máa ń lo ètè láti fi dúró fún ọ̀rọ̀ tàbí èdè kan. Ní ti àwa ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, ọ̀rọ̀ ẹnu wa ló máa ń sún wa gbẹ̀ṣẹ̀ jù lọ.—Òwe 10:19; Jákọ́bù 3:2, 6.