Ìsọ̀rí 1
Ó ‘Ní Agbára Ńlá’
Ní ìsọ̀rí yìí, a ó ṣàyẹ̀wò àwọn ìtàn inú Bíbélì tó jẹ́rìí sí agbára ìṣẹ̀dá, agbára ìpanirun, agbára ìdáàbòboni àti agbára ìmúbọ̀sípò tí Jèhófà ní. Bí a bá mọ bí Jèhófà Ọlọ́run, tó ní ‘agbára ńlá,’ ṣe ń lo “okun rẹ̀ alágbára gíga,” ẹ̀rù Ọlọ́run á bà wà dọ́kàn.—Aísáyà 40:26.
NÍ APÁ YÌÍ
ORÍ 4
“Jèhófà . . . Tóbi ní Agbára”
Ṣé ó yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run nítorí agbára rẹ̀? A lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ní, ká sì tún sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́.
ORÍ 5
Agbára Ìṣẹ̀dá—“Olùṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ilẹ̀ Ayé”
Gbogbo nǹkan tí Jèhófà dá, látorí òórùn tó tóbi dé orí ẹyẹ akùnyùnmù tó kéré gan-an, ló ń kọ́ wa ní nǹkan pàtàkì nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́.
ORÍ 7
Agbára Ìdáàbòboni—‘Ọlọ́run Jẹ́ Ibi Ìsádi fún Wa’
Ọ̀nà méjì ni Ọlọ́run ń gbà dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ ọ̀kan ṣe pàtàkì jù.
ORÍ 8
Agbára Ìmúbọ̀sípò—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
Jèhófà ti mú ìjọsìn tòótọ́ bọ̀ sípò. Kí làwọn ohun tó máa mú bọ̀ sípò lọ́jọ́ iwájú?
ORÍ 10
“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run” Nípa Bí Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára
O lè lágbára ju bó o ṣe rò lọ—báwo lo ṣe lè lò ó lọ́nà tó dáa?