Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí 14

Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”

Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”

1, 2. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ipò tí ọmọ aráyé wà, kí sì ni ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà fún wa?

“GBOGBO ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀.” (Róòmù 8:22) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi gbólóhùn yìí ṣàpèjúwe ipò tó ń bani nínú jẹ́ tá a wà yìí. Lójú ọmọ ènìyàn, ńṣe ló dà bíi pé a ò lè bọ́ lọ́wọ́ ìyà, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ṣùgbọ́n Jèhófà ò dà bí èèyàn ní tirẹ̀, ohun tí apá ènìyàn ò ká apá Ọlọ́run ká a. (Númérì 23:19) Òun, Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo, ti pèsè ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ìpọ́njú yìí fún wa. Ọ̀nà àbáyọ yìí là ń pè ní ìràpadà.

2 Ìràpadà ni ẹ̀bùn gíga jù lọ tí Jèhófà fi fún ọmọ aráyé. Ó mú kí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣeé ṣe fún wa. (Éfésù 1:7) Ìràpadà ló jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ìrètí ìyè ayérayé, ì báà jẹ́ ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 3:16; 1 Pétérù 1:4) Ṣùgbọ́n, kí tilẹ̀ ni ìràpadà? Báwo ló ṣe kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdájọ́ òdodo gíga jù lọ tí Jèhófà ń lò?

Ìdí Tá A Fi Nílò Ìràpadà

3. (a) Kí ló fà á tí ìràpadà fi di dandan? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi yí ìdájọ́ ikú tó wà lórí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù padà sí èyí tó rọjú díẹ̀?

3 Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló fà á tí ìràpadà fi di dandan. Nígbà tí Ádámù ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, àìsàn, ìbànújẹ́, ìrora àti ikú lohun tó kù gẹ́gẹ́ bí ogún tó fi sílẹ̀ fún àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; Róòmù 8:20) Ọlọ́run ò dà á rò kí ó sì yí ìdájọ́ ikú yẹn padà sí ìyà tó rọjú díẹ̀. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ó tẹ òfin ara rẹ̀ lójú nìyẹn, èyí tó sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Bí Jèhófà bá sì ti wá yẹ̀yẹ́ ìlànà ìdájọ́ òdodo ara rẹ̀, ìdàrúdàpọ̀ àti ìwà ta-ni-yóò-mú-mi ni yóò gbòde kan láyé àtọ̀run!

4, 5. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, kí sì nìdí tí Jèhófà fi rí i pé ó yẹ kí òun dáhùn ẹ̀sùn wọ̀nyẹn? (b) Kí ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà adúróṣinṣin?

4 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i ní Orí 12, kékeré ni ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù tiẹ̀ jẹ́ nínú ọ̀ràn ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé wẹ́rẹ́ ní Édẹ́nì. Ńṣe ni Sátánì tàbùkù orúkọ rere Ọlọ́run. Lẹ́nu kan ṣáá, ò fẹ̀sùn irọ́ pípa kan Jèhófà, ó tún ní ó jẹ́ ìkà apàṣẹwàá, tó ń fi òmìnira du àwọn ẹ̀dá rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Bó ṣe dà bíi pé Sátánì dènà ète Ọlọ́run pé kí àwọn olódodo kún orí ilẹ̀ ayé, ńṣe ló dọ́gbọ́n ń fi ìyẹn pe Ọlọ́run ní aláṣetì. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Aísáyà 55:10, 11) Ká ní Jèhófà ò ṣe nǹkan kan nípa àwọn ìpèníjà yìí ni, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀dá rẹ̀ olóye ni ì bá má lè fi gbogbo ara gbẹ́kẹ̀ lé ìṣàkóso rẹ̀ mọ́.

5 Sátánì tún ba àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà adúróṣinṣin lórúkọ jẹ́ pẹ̀lú. Ẹ̀sùn tó fi kàn wọ́n ni pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń mú wọn sin Ọlọ́run àti pé bí wàhálà bá bá wọn, ìkankan nínú wọn ò ní jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. (Jóòbù 1:9-11) Kókó wọ̀nyí ṣe pàtàkì gan-an ju ìṣòro tí àwa ènìyàn ń dojú kọ lọ. Jèhófà rí i pé ó yẹ kí òun dáhùn àwọn ẹ̀sùn ìbanijẹ́ tí Sátánì kà sílẹ̀ yìí. Ṣùgbọ́n báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe yanjú ọ̀ràn wọ̀nyí kí ó sì tún gba aráyé là pẹ̀lú?

Ìràpadà Gbọ́dọ̀ Dọ́gba

6. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò láti fi ṣàpèjúwe ohun tí Ọlọ́run lò láti fi gba aráyé là?

6 Ojútùú tí Jèhófà pèsè jẹ́ aláàánú àti èyí tó bá ìdájọ́ òdodo mu lọ́nà tó ga jù lọ. Ó jẹ́ ojútùú tọ́mọ èèyàn ò tiẹ̀ lè wéwèé láéláé. Síbẹ̀, ó ṣe kedere kò sì lọ́jú pọ̀ rárá. Oríṣiríṣi nǹkan là ń pè é, a pè é ní rírà, ìpadàrẹ́, ìtúnràpadà, ẹbọ ìpẹ̀tù, àti ètùtù. (Sáàmù 49:8; Dáníẹ́lì 9:24; Gálátíà 3:13; Kólósè 1:20; Hébérù 2:17) Ṣùgbọ́n gbólóhùn tó dà bíi pé ó ṣàpèjúwe ọ̀ràn yìí jù lọ ni gbólóhùn tí Jésù fúnra rẹ̀ lò. Ó ní: “Ọmọ ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà [Gíríìkì, lyʹtron] ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”—Mátíù 20:28.

7, 8. (a) Kí ni gbólóhùn náà “ìràpadà” túmọ̀ sí nínú Ìwé Mímọ́? (b) Ọ̀nà wo ni ìbáradọ́gba gbà wọ ọ̀ràn ìràpadà?

7 Kí ni ìràpadà? Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí a lò níhìn-ín wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí “láti tú sílẹ̀, láti dá sílẹ̀.” Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti fi ṣàpèjúwe owó tí a máa ń san gẹ́gẹ́ bí pàṣípààrọ̀ fún ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ ogun tí a bá mú lẹ́rú. Nípa bẹ́ẹ̀, a kúkú lè sọ pé ìràpadà túmọ̀ sí ohun tí a san láti fi ra nǹkan padà. Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò (ìyẹn koʹpher) tí a túmọ̀ sí “ìràpadà,” wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí “fi [nǹkan] bò.” Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé kí ó “fi” ọ̀dà bítúmẹ́nì “bo” ọkọ̀ áàkì (“fi bò” tó jẹ́ irú ọ̀rọ̀ kan náà tá a tú sí ìràpadà). (Jẹ́nẹ́sísì 6:14) Èyí mú kó yé wa pé ìràpadà tún túmọ̀ sí pé ká fi nǹkan bo ẹ̀ṣẹ̀.—Sáàmù 65:3.

8 Ó gbàfiyèsí pé, ìwé Theological Dictionary of the New Testament sọ pé ọ̀rọ̀ yìí (koʹpher) “máa ń fìgbà gbogbo túmọ̀ sí ìbáradọ́gba,” tàbí ohun tó ṣe rẹ́gí. Òun ló fi jẹ́ pé, bí àpótí ẹ̀rí gan-an ṣe rí nírìísí ni ìdérí tó bò ó náà ṣe rí. Bákan náà, láti lè ṣe ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀, tàbí láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó di dandan láti san ohun tí yóò dọ́gba pẹ̀lú ìpalára tí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tàbí ohun tí yóò bò ó mọ́lẹ̀ pátápátá. Ìyẹn ni Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì fi sọ pé: “Ọkàn fún ọkàn, ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀.”—Diutarónómì 19:21.

9. Kí nìdí táwọn ẹni ìgbàgbọ́ fi ń fi ẹran rúbọ, irú ojú wo ni Jèhófà sì fi wo irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀?

9 Láti ìgbà ayé Ébẹ́lì wá làwọn ẹni ìgbàgbọ́ ti máa ń fi àwọn ẹran rúbọ sí Ọlọ́run. Ohun tí ẹbọ tí wọ́n ń rú yìí sì ń fi hàn ni pé wọ́n mọ̀ pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó nílò ìràpadà àti pé wọ́n ń fi hàn pé àwọn gba ìlérí ìdáǹdè tí Ọlọ́run sọ pé yóò dé nípasẹ̀ “irú-ọmọ” òun gbọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 4:1-4; Léfítíkù 17:11; Hébérù 11:4) Jèhófà tẹ́wọ́ gba irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀, ó sì ka irú àwọn olùjọsìn bẹ́ẹ̀ sí ẹni rere. Ṣùgbọ́n ìwọ̀nba ṣíún ni gbogbo ẹbọ tí a bá fi ẹran rú lè ṣe. A ò lè fi ẹranko bo ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ èèyàn mọ́lẹ̀ rárá, nítorí wọ́n rẹlẹ̀ sí ẹ̀dà èèyàn. (Sáàmù 8:4-8) Ìyẹn ni Bíbélì fi sọ pé: “Kò ṣeé ṣe fún ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.” (Hébérù 10:1-4) Àpẹẹrẹ, tàbí àmì tó ń ránni létí ẹbọ ìràpadà ọjọ́ iwájú ni ẹbọ wọ̀nyẹn kàn jẹ́.

“Ìràpadà Tí Ó Ṣe Rẹ́gí”

10. (a) Ta ni olùràpadà ní láti bá dọ́gba, kí sì nìdí rẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé èèyàn kan ṣoṣo ló ń béèrè pé ká fi rúbọ?

10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo ènìyàn . . . ń kú nínú Ádámù.” (1 Kọ́ríńtì 15:22) Nípa bẹ́ẹ̀, bí ìràpadà yóò bá wáyé, ẹnì kan tó bá Ádámù dọ́gba rẹ́gí, ìyẹn èèyàn pípé kan, yóò ní láti kú. (Róòmù 5:14) Kò sí oríṣi ẹ̀dà mìíràn tá a lè lò tí yóò bá a dọ́gba lórí òṣùwọ̀n ìdájọ́ òdodo. Kìkì èèyàn pípé tí kò sí lábẹ́ ìdálẹ́bi ikú Ádámù ló lè pèsè “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí,” tó jẹ́ pé yóò bá Ádámù dọ́gba. (1 Tímótì 2:6) Ìyẹn ni kò fi ní já sí pé a ó máa fi ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn kọ̀ọ̀kan rúbọ láti lè rí iye tí yóò dọ́gba rẹ́gí pẹ̀lú irú ọmọ Ádámù kọ̀ọ̀kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) “Níwọ̀n bí ikú ti wá nípasẹ̀ ènìyàn kan,” Ọlọ́run pẹ̀lú pèsè ìràpadà aráyé “nípasẹ̀ ènìyàn kan.” (1 Kọ́ríńtì 15:21) Lọ́nà wo?

“Ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn”

11. (a) Báwo ni olùràpadà yóò ṣe dẹni tó “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn”? (b) Kí nìdí tí Ádámù àti Éfà ò fi ní jàǹfààní ìràpadà náà? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

11 Jèhófà ṣètò pé kí ọkùnrin pípé kan fínnú fíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. Gẹ́gẹ́ bí Róòmù 6:23 sì ṣe wí, “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” Bí olùràpadà bá ti lè fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ, ó ti “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn” nìyẹn. A jẹ́ pé ó ti san owó ọ̀yà ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù nìyẹn. (Hébérù 2:9; 2 Kọ́ríńtì 5:21; 1 Pétérù 2:24) Ohun tí ìyẹn yóò túmọ̀ sí lọ́nà ti òfin pọ̀ gan-an ni. Tí ìràpadà bá ti wá sọ ìdájọ́ ikú tí ń bẹ lórí irú ọmọ Ádámù dòfo, ó fa gbòǹgbò agbára tí ẹ̀ṣẹ̀ fi ń ṣekú pani tu nìyẹn. *Róòmù 5:16.

12. Ṣàpèjúwe bí sísan gbèsè kan ṣoṣo ṣe lè ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ èèyàn.

12 Bí àpẹẹrẹ: Fojú inú wò ó pé ò ń gbé ìlú kan tí ọ̀pọ̀ jù lọ aráàlú yẹn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ilé iṣẹ́ ńlá kan. Nítorí iṣẹ́ yín, ilé iṣẹ́ yìí ń sanwó ńlá fún ìwọ àti aládùúgbò rẹ, nǹkan sì ń rọ̀ṣọ̀mù fún yín. Lọ́jọ́ kan ni wọ́n ti ilé iṣẹ́ ọ̀hún pa nítorí tí kò sówó mọ́. Kí ló sì fà á? Ọ̀gá ilé iṣẹ́ ti ṣe gbogbo owó báṣubàṣu, ló bá di pé ilé iṣẹ́ náà wọko gbèsè tó sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹnu kọlẹ̀. Bó ṣe di pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ìwọ àti aládùúgbò rẹ lójijì tí ẹ ò rí owó ilé, owó iná, owó omi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ san mọ́ nìyẹn. Ọ̀ràn di pé kí tọkọtaya àtàwọn ọmọ àtàwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè wá máa jìyà nítorí ìwà ìbàjẹ́ ẹnì kan ṣoṣo yẹn. Ǹjẹ́ ojútùú kankan wà fún ọ̀ràn náà? Bẹ́ẹ̀ ni o! Olówó kan tó lójú àánú dá sí ọ̀ràn ọ̀hún. Olówó yìí mọ bí ilé iṣẹ́ yẹn ṣe wúlò tó. Àánú àwọn èèyàn rẹpẹtẹ tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ àti ìdílé wọn ṣe é pẹ̀lú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣètò láti san gbèsè tí ilé iṣẹ́ yẹn jẹ, ó sì tún ṣí ilé iṣẹ́ yìí. Sísan tó san gbèsè kan ṣoṣo yìí á mú ìtura bá àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ àti ìdílé wọn àtàwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni sísan gbèsè Ádámù ṣe ṣàǹfààní fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn.

Ta Ló Pèsè Ìràpadà Náà?

13, 14. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà fún aráyé? (b) Ta ni a san ìràpadà yẹn fún, kí sì nìdí tó fi yẹ láti san ìràpadà yìí?

13 Àfi Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè pèsè “Ọ̀dọ́ Àgùntàn . . . tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòhánù 1:29) Ṣùgbọ́n o, Ọlọ́run ò kàn rán áńgẹ́lì kan ṣá láti wá kó aráyé yọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ẹni tó jẹ́ pé ó máa lè dáhùn ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà parí pátápátá ló rán wá. Ohun tó ga jù lọ lèyí ná Jèhófà. Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, “ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe” ló rán wá. (Òwe 8:30) Ọmọ Ọlọ́run yìí fínnú fíndọ̀ “sọ ara rẹ̀ di òfìfo,” ó bọ́ gbogbo ògo ẹ̀dá ọ̀run tó ní sílẹ̀ pátá. (Fílípì 2:7) Jèhófà wá fi ọ̀nà àrà tàtaré ìwàláàyè àti ànímọ́ àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ ọ̀run sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà. (Lúùkù 1:27, 35) Jésù ni wọ́n sọ ọ́ nígbà tí wọ́n bí i sáyé. Ṣùgbọ́n lọ́nà ti òfin, Ádámù kejì ni a lè pè é nítorí pé ńṣe ló bá Ádámù dọ́gba rẹ́gí. (1 Kọ́ríńtì 15:45, 47) Ìyẹn ni Jésù fi lè fi ara rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún ọmọ aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀.

14 Ta ni a máa san ìràpadà yẹn fún? Sáàmù 49:7 sọ ọ́ kedere pé a ó san ìràpadà yẹn “fún Ọlọ́run.” Àmọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ ha kọ́ ló ṣètò ìràpadà yẹn ni? Òun ni lóòótọ́, ṣùgbọ́n ìyẹn kò sọ ìràpadà yẹn di ohun kan tí kò nítumọ̀, bíi pé ẹní kan mú owó jáde nínú àpò kan tó sì sọ ọ́ sínú àpò kejì. Kí ó yé wa pé ìràpadà yìí kì í wúlẹ̀ ì ṣe pàṣípààrọ̀ ohun kan tó ṣe é fojú rí. Ìdúnàádúrà lọ́nà òfin ni. Bí Jèhófà ṣe pèsè nǹkan kan láti fi san ìràpadà yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun ribiribi ló ná an, ńṣe ló ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun kì í yà kúrò nínú ìdájọ́ òdodo pípé òun lọ́nàkọnà.—Jẹ́nẹ́sísì 22:7, 8, 11-13; Hébérù 11:17; Jákọ́bù 1:17.

15. Kí nìdí tó fi pọn dandan kí Jésù jìyà kí ó sì kú?

15 Nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Tiwa yìí, Jésù Kristi fínnú fíndọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ìjìyà ńlá tó jálẹ̀ sí sísan ìràpadà yẹn. Ó gbà kí wọ́n fi àṣẹ ọba mú òun lórí àwọn ẹ̀sùn èké, kí wọ́n dá òun lẹ́bi, kí wọ́n sì kan òun mọ́ igi ìpànìyàn. Ṣé ó wá pọn dandan kí Jésù jẹ adúrú ìyà yẹn ni? Bẹ́ẹ̀ ni o, nítorí a ní láti yanjú ọ̀ràn pípa ìwà títọ́ mọ́ ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú. Ká rántí pé Ọlọ́run ò jẹ́ kí Hẹ́rọ́dù rí Jésù pa nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé. (Mátíù 2:13-18) Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù wá dàgbà tán, ó lè fara gba gbogbo ìyọnu tí Sátánì bá gbé wá, yóò sì tún ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. * Bí Jésù sì ṣe jẹ́ “adúróṣinṣin, aláìlẹ́tàn, aláìlẹ́gbin, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀” lójú gbogbo ìyà ńlá tí wọ́n fi jẹ ẹ́, ó ti fẹ̀rí ńlá tó parí ọ̀ràn hàn pé láìsí tàbí ṣùgbọ́n, Jèhófà láwọn ìránṣẹ́ tó ń dúró gbọn-in lójú inúnibíni. (Hébérù 7:26) Abájọ nígbà náà tí Jésù fi kígbe ìṣẹ́gun ní kété ṣáájú kó tó kú, pé: “A ti ṣe é parí!”—Jòhánù 19:30.

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìràpadà Rẹ̀ Parí

16, 17. (a) Báwo ni Jésù ṣe tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìràpadà rẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi pọn dandan fún Jésù láti fara hàn “níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa”?

16 Síbẹ̀, Jésù ò tí ì ṣe iṣẹ́ ìràpadà rẹ̀ parí. Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ikú Jésù, Jèhófà jí i dìde kúrò nínú òkú. (Ìṣe 3:15; 10:40) Jíjí tí Jèhófà jí Ọmọ rẹ̀ dìde lọ́nà ìyanu yìí kì í ṣe láti fi san èrè iṣẹ́ tó fi ìṣòtítọ́ ṣe nìkan ni, ó tún jẹ́ ọ̀nà láti gbà fún un láyè láti parí iṣẹ́ ìràpadà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà fún Ọlọ́run. (Róòmù 1:4; 1 Kọ́ríńtì 15:3-8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Nígbà tí Kristi dé gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà . . . , ó wọlé sínú ibi mímọ́, rárá, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù, bí kò ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé, ó sì gba ìdáǹdè àìnípẹ̀kun fún wa. Nítorí tí Kristi kò wọlé sí ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe, tí ó jẹ́ ẹ̀dà ti òtítọ́, bí kò ṣe sí ọ̀run, nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.”—Hébérù 9:11, 12, 24.

17 Kristi ò lè gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gidi lọ sí ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:50) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ̀jẹ̀ yẹn dúró fún ló gbé lọ: ìyẹn ohun tó jẹ́ ìtóye ẹbọ tó fi ìwàláàyè èèyàn pípé rẹ̀ rú tí a bá gbé e karí òfin. Lẹ́yìn náà, ó wá gbé ìtóye ìwàláàyè yẹn kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún ọmọ aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀. Ǹjẹ́ Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni o. Èyí sì hàn kedere nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, tí a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sórí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 2:1-4) Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wúni lórí ní tòótọ́, àmọ́, ìbẹ̀rẹ̀ ni ìyẹn kàn jẹ́ lára àwọn àǹfààní àgbàyanu tí a máa rí gbà nípasẹ̀ ìràpadà.

Àwọn Àǹfààní Ìràpadà

18, 19. (a) Àwùjọ méjì wo ló jàǹfààní nínú ìràpadà tí ẹ̀jẹ̀ Kristi mú kó ṣeé ṣe? (b) Ní tàwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní ìràpadà tí wọ́n ń jẹ nísinsìnyí àti èyí tí wọn yóò jẹ lọ́jọ́ iwájú?

18 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kólósè pé Ọlọ́run rí i pé ó dára láti tipasẹ̀ Kristi mú kí gbogbo nǹkan yòókù padà bá Òun rẹ́. Ó sì ṣe èyí nípa mímú kí àlàáfíà wà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ta sílẹ̀ lórí igi oró. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwùjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ ìpadàrẹ́ yìí kàn, ìyẹn “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” àti “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Kólósè 1:19, 20; Éfésù 1:10) Àwọn tó wà nínú àwùjọ àkọ́kọ́ ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ àwọn Kristẹni tá a fún ní ìrètí pé wọ́n á jẹ́ àlùfáà ní ọ̀run àti pé wọn yóò bá Kristi Jésù jọba lé ayé lórí. (Ìṣípayá 5:9, 10; 7:4; 14:1-3) A óò wá tipasẹ̀ wọn máa lo àwọn àǹfààní ìràpadà ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé fáwọn onígbọràn nínú aráyé láàárín àkókò tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún.—1 Kọ́ríńtì 15:24-26; Ìṣípayá 20:6; 21:3, 4.

19 “Àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” ni àwọn èèyàn tó ń retí láti gbádùn ìwàláàyè pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ìṣípayá 7:9-17 ṣàpèjúwe wọn pé wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí yóò la “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ já. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé wọ́n ní láti dúró di ẹ̀yìn ìpọ́njú ńlá yẹn kí wọ́n tó lè jàǹfààní ìràpadà yẹn o. Wọ́n “ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Nítorí pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà yìí, wọ́n ti ń jẹ àwọn àǹfààní tẹ̀mí látinú ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí nísinsìnyí. Kódà, wọ́n ti dẹni tá a pè ní olódodo, pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! (Jákọ́bù 2:23) Ẹbọ ìràpadà Jésù mú kí wọ́n lè “sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.” (Hébérù 4:14-16) Tí wọ́n bá ṣẹ̀, wọ́n máa ń rí ìdáríjì tó dájú gbà. (Éfésù 1:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì jẹ́ aláìpé, wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tí a wẹ̀ mọ́. (Hébérù 9:9; 10:22; 1 Pétérù 3:21) Nípa bẹ́ẹ̀, dídi ẹni tó padà bá Ọlọ́run rẹ́ kì í ṣe ohun tí a ṣì ń retí pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú o, ó ń ṣẹlẹ̀ ní báyìí! (2 Kọ́ríńtì 5:19, 20) Nígbà Ẹgbẹ̀rúndún, díẹ̀díẹ̀ wọ́n á dẹni tá a “dá . . . sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́,” wọn yóò sì gba “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run” níkẹyìn.—Róòmù 8:21.

20. Ipa wo ni ṣíṣàṣàrò nípa ìràpadà ní lórí ìwọ fúnra rẹ?

20 “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi” pé ó pèsè ìràpadà yìí o! (Róòmù 7:25) Òótọ́ ni pé ọ̀nà tí ìlànà rẹ̀ gbà ṣiṣẹ́ kò lọ́jú pọ̀, síbẹ̀ ohun àgbàyanu ńláǹlà ló jẹ́ fún wa. (Róòmù 11:33) Tí a bá sì fi ìmọrírì àtọkànwá ṣàṣàrò nípa ìràpadà yìí, á túbọ̀ wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin, yóò sì mú ká túbọ̀ fà mọ́ Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo sí i. Bíi ti onísáàmù náà, a nídìí tó pọ̀ láti máa yin Jèhófà lógo pé ó jẹ́ “olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.”—Sáàmù 33:5.

^ ìpínrọ̀ 11 Kò lè ṣeé ṣe fún Ádámù àti Éfà láti jàǹfààní ìràpadà náà. Ìlànà tí Òfin Mósè fi lélẹ̀ nípa ẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn ni pé: “Kí ẹ má sì gba ìràpadà fún ọkàn òṣìkàpànìyàn tí ó yẹ kí ó kú.” (Númérì 35:31) Dájúdájú, ikú tọ́ sí Ádámù àti Éfà nítorí pé ńṣe ni wọ́n fínnú fíndọ̀ tí wọ́n sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ gbé àǹfààní ìyè ayérayé tí wọ́n ní sọ nù.

^ ìpínrọ̀ 15 Kí Jésù tó lè sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù dòfo, géńdé ọkùnrin pípé ló ní láti jẹ́ nígbà tó bá máa kú, kì í ṣe ọmọdé pípé. Rántí pé ṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, ó sì mọ gbogbo nǹkan tí ìgbésẹ̀ òun yẹn àti àbájáde rẹ̀ túmọ̀ sí dáadáa. Nítorí náà, kí Jésù tó lè di “Ádámù ìkẹyìn” kí ó sì bo ẹ̀ṣẹ̀ yẹn mọ́lẹ̀, ó ní láti jẹ́ ẹni tó dàgbà dénú nígbà tó pinnu láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ sí Jèhófà, kí ó sì mọ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí. (1 Kọ́ríńtì 15:45, 47) Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo bí Jésù ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́, àní títí kan ikú ìrúbọ tó kú, ló para pọ̀ jẹ́ “ìṣe ìdáláre kan.”—Róòmù 5:18, 19.