Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí 17

‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’

‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’

1, 2. Kí ni ète Jèhófà nípa ọjọ́ keje, báwo ni a sì ṣe dán ọgbọ́n Ọlọ́run wò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ keje yìí?

ṢÀǸGBÁ fọ́! Ọmọ èèyàn tó jẹ́ adé ògo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ọjọ́ kẹfà bára rẹ̀ kanlẹ̀ poo. Ohun tí Jèhófà wí nípa “ohun gbogbo tí ó ti ṣe” títí kan ọmọ ènìyàn ni pé, “ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ṣùgbọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ keje, Ádámù àti Éfà lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀. Wọ́n wá rì sínú ẹ̀ṣẹ̀, àìpé àti ikú.

2 Ó lè wá dà bíi pé ète Jèhófà nípa ọjọ́ keje ti wọgbó bámúbámú. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sì ni ọjọ́ keje yìí yóò jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó ṣáájú rẹ̀. Ọjọ́ ọlọ́wọ̀ ni Jèhófà pè é, nínú èyí tí gbogbo ilẹ̀ ayé á di Párádísè, tí ìdílé ọmọ èèyàn pípé yóò sì kún inú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:3) Ṣùgbọ́n báwo ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe máa wá ṣeé ṣe lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ burúkú yẹn? Kí ni Ọlọ́run máa ṣe nípa rẹ̀? Ìdánwò tó pabanbarì ko ọgbọ́n Jèhófà lójú wàyí, bóyá èyí gan-an là bá pè ní olórí ìdánwò.

3, 4. (a) Báwo ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà dáhùn sí ìṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà àgbàyanu kan tó gbà ń lo ọgbọ́n rẹ̀? (b) Ó yẹ kí ìrẹ̀lẹ̀ sún wa láti máa rántí òótọ́ ọ̀rọ̀ wo bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò ọgbọ́n Jèhófà?

3 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà dáhùn. Ó ṣèdájọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn ní Édẹ́nì, ó sì lànà ìrètí ìyanu kan lẹ́sẹ̀ kan náà, ìyẹn ète rẹ̀ láti tún gbogbo ìyọnu tí wọ́n dá sílẹ̀ ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ète Jèhófà tó rìn jìnnà yìí nasẹ̀ láti Édẹ́nì la gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìtàn aráyé kọjá títí lọ dé ọjọ́ iwájú kánrin. Ète ọ̀hún kò lọ́jú pọ̀ síbẹ̀ ó jinlẹ̀ débi pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lè fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ máa ṣèwádìí kó sì máa ṣàṣàrò lé e lórí tí kò sì ní yéé rí ẹ̀kọ́ kọ́. Síwájú sí i, ó dájú pé ète Jèhófà ò lè yẹ̀ láé, yóò ṣẹ dandan ni. Yóò fòpin sí gbogbo ìwà ibi, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Yóò sọ àwọn olóòótọ́ nínú aráyé di ẹni pípé. Gbogbo ìwọ̀nyí ni yóò wáyé ṣáájú kí ọjọ́ keje tó parí, tá fi jẹ́ pé, pẹ̀lú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ wọ̀nyẹn, Jèhófà á ṣì mú ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé àti aráyé ṣẹ lásìkò gẹ́lẹ́!

4 Irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ mú kí ẹ̀rù Ọlọ́run bani, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìyẹn ló sún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: ‘Ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n Ọlọ́run mà pọ̀ o!’ (Róòmù 11:33) Bá a ṣe dáwọ́ lé àyẹ̀wò nípa onírúurú ẹ̀ka ànímọ́ Ọlọ́run yìí, ẹ jẹ́ ká fi ìrẹ̀lẹ̀ máa rántí òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí pé, fìrífìrí ibú ọgbọ́n Jèhófà nìkan la kàn lè rí o. (Jóòbù 26:14) Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká sọ ìtumọ̀ ànímọ́ àgbàyanu yìí.

Kí Ni Ọgbọ́n Ọlọ́run?

5, 6. Kí ni ìsopọ̀ tí ń bẹ láàárín ìmọ̀ àti ọgbọ́n, báwo ni ìmọ̀ Jèhófà sì ṣe gbòòrò tó?

5 Ọgbọ́n àti ìmọ̀ kì í ṣe ohun kan náà o. Ilé ìmọ̀ ni ẹ̀rọ̀ kọ̀ǹpútà jẹ́, ṣùgbọ́n bóyá la ó fi rẹ́ni tó máa sọ pé irú ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọlọgbọ́n. Àmọ́ ṣá, ìmọ̀ àti ọgbọ́n wé mọ́ra. (Òwe 10:14) Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ń fẹ́ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n nípa irú oògùn tó o máa lò sí àìsàn kan, ṣé ẹni tí kò mọ̀ nípa ìṣègùn rárá lo máa tọ̀ lọ? Rárá o! Nítorí náà, ìmọ̀ pípéye ṣe kókó fẹ́ni tó ní ọgbọ́n tòótọ́.

6 Ìmọ̀ tí Jèhófà ní kò lópin. Níwọ̀n bó ti jẹ́ “Ọba ayérayé,” òun nìkan ni ẹni tó ti ń bẹ láti ayérayé wá. (Ìṣípayá 15:3) Gbogbo ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ láti ọdún gbọ́nhan yẹn wá ló sì mọ̀ pátápátá. Bíbélì ní: “Kò sì sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13; Òwe 15:3) Nítorí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, gbogbo ohun tó dá ló mọ̀ dunjú-dunjú, gbogbo ìgbòkègbodò ọmọ aráyé sì ṣojú rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Ó ń ṣàyẹ̀wò ọkàn olúkúlùkù èèyàn pátá, láìfo ẹnikẹ́ni dá. (1 Kíróníkà 28:9) Dídá tó dá wa ní ẹ̀dá tó lómìnira láti yan ìwà tó fẹ́ hù máa ń jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn sí wa bí a bá ń ṣe ìpinnu ọlọ́gbọ́n. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni “Olùgbọ́ àdúrà,” ọ̀kẹ́ àìmọye ọ̀rọ̀ ló ń gbọ́ lẹ́ẹ̀kan náà! (Sáàmù 65:2) Ó sì dájú pé agbára ìrántí pípé ni Jèhófà ní.

7, 8. Báwo ni Jèhófà ṣe fi òye, ìfòyemọ̀ àti ọgbọ́n hàn?

7 Ìmọ̀ nìkan kọ́ ni Jèhófà ní o, ohun tó ní jù ìmọ̀ lọ. Ó tún máa ń rí bí àwọn ọ̀ràn ṣe wé mọ́ra, á sì fòye mọ ohun tí ọ̀kẹ́ àìmọye tòtòpinni ọ̀ràn para pọ̀ já sí. Ó máa ń díwọ̀n ọ̀ràn, a sì ṣèpinnu, ní fífi ìyàtọ̀ sáàárín rere àti búburú, sáàárín ohun tó ṣe pàtàkì àti èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan. Ẹ̀wẹ̀, ìrísí ẹni nìkan kọ́ ló ń wò, ó máa ń ṣàyẹ̀wò ohun tí ń bẹ nínú ọkàn ẹni pẹ̀lú. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Nípa báyìí, Jèhófà ní òye àti ìfòyemọ̀, ànímọ́ wọ̀nyẹn sì tẹ̀wọ̀n ju ìmọ̀ lọ. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tilẹ̀ tún ju gbogbo ìwọ̀nyẹn lọ pátápátá.

8 Ńṣe ni ọgbọ́n máa ń pa ìmọ̀, ìfòyemọ̀ àti òye pọ̀ láti fi ṣàṣeyọrí nǹkan kan. Kódà àwọn ọ̀rọ̀ kan tá a túmọ̀ sí “ọgbọ́n” látinú èdè tá a fi kọ Bíbélì nípilẹ̀ṣẹ̀ ní ṣáńgílítí túmọ̀ sí “kí nǹkan gbéṣẹ́” tàbí “ọgbọ́n tó ṣeé múlò.” Nítorí náà, ọgbọ́n Jèhófà kì í ṣe bíi tẹni tó ń fẹnu ròfọ́ lásán. Ọgbọ́n tó gbéṣẹ́, tó sì ṣeé mú lò ni. Bí Jèhófà bá ti gbé ọ̀ràn karí ìmọ̀ ńláǹlà tó ní àti òye rẹ̀ jíjinlẹ̀, ìpinnu tó dára jù lọ láyé lọ́run ló máa ń ṣe, á sì mú un ṣẹ lọ́nà tó dára jù lọ. Ìyẹn gan-an lọba ọgbọ́n! Jèhófà gbé òótọ́ inú ọ̀rọ̀ Jésù yẹn yọ, èyí tó sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà láyé àti lọ́run jẹ́ ẹ̀rí alágbára pé ọlọgbọ́n ni.

Àwọn Ẹ̀rí Tó Fi Ọgbọ́n Ọlọ́run Hàn

9, 10. (a) Irú ọgbọ́n wo ni Jèhófà fi hàn, báwo ló sì ṣe fi í hàn? (b) Báwo ni kinní bíńtín tó para pọ̀ di ara wa ṣe jẹ́rìí sí ọgbọ́n Jèhófà?

9 Ǹjẹ́ o tíì rí i kí oníṣẹ́ ọwọ́ kan fi làákàyè ṣe ẹ̀rọ tó ń dá bírà lọ́nà tó yà ọ́ lẹ́nu rí? Irú ọgbọ́n kan tó wúni lórí nìyẹn. (Ẹ́kísódù 31:1-3) Jèhófà gan-an ni orísun àti ẹni tó ni èyí tó ga jù lọ nínú irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀. Dáfídì Ọba sọ nípa Jèhófà pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.” (Sáàmù 139:14) Ká sòótọ́, bá a bá ṣe kọ́ nípa ara èèyàn tó ni ọgbọ́n Jèhófà ṣe máa ń jẹ́ àgbàyanu tó lójú wa.

10 Àpèjúwe ọ̀rọ̀ ọ̀hún rèé: Kinní kan bíńtín báyìí, ìyẹn ẹyin kan láti ara ìyá rẹ tí àtọ̀ bàbá rẹ mú fẹ́ra kù ló pilẹ̀ ìwàláàyè rẹ. Láìpẹ́, kinní bíńtín náà bẹ̀rẹ̀ sí pín sí ọ̀nà púpọ̀. Ìgbà tí kinní bíńtín ọ̀hún fi máa di ìwọ yìí lódindi, ó ti pín sọ́nà ìlọ́po ìlọ́po ọ̀kẹ́ àìmọye. Tín-tìn-tín báyìí ni wọ́n o. Tá a bá kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá rẹ̀ jọ, kò ní ju orí abẹ́rẹ́ lásán lọ. Síbẹ̀, nǹkan tí ń bẹ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kúrò ní kèrémí. Ọ̀nà tí a gbà ṣètò ohun tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan kinní bíńtín ọ̀hún díjú pọ̀ ju ẹ̀rọ tàbí ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ èyíkéyìí tí ọmọ èèyàn tíì ṣe lọ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ńṣe ni kinní bíńtín kọ̀ọ̀kan yìí dà bí ìlú olódi kan, tó ní ọ̀nà àbáwọlé àti àbájáde tí à ń ṣí tí a sì ń tì, tó ní ìṣètò fífi ọkọ̀ kẹ́rù, ètò ìbánisọ̀rọ̀, ìpèsè iná mànàmáná, ilé iṣẹ́ ìpèsè nǹkan èlò, ètò ìpalẹ̀ pàǹtírí mọ́ àti ṣíṣe àlòtúnlò nǹkan, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò, àní tó tiẹ̀ ní ohun tó dà bí ètò ìṣèjọba níbi tó jọ ààfin láàárín rẹ̀. Síwájú sí i, àní kinní bíńtín kọ̀ọ̀kan lè ṣe ẹ̀dà ara rẹ̀ gẹ́lẹ́ látòkèdélẹ̀ láàárín wákàtí mélòó kan!

11, 12. (a) Kí ló ń mú kí àwọn nǹkan bíńtín ara yà sẹ́nu iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó bá fẹ́ di ọlẹ̀, báwo lèyí sì ṣe bá ohun tí Sáàmù 139:16 wí mu? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni ọpọlọ èèyàn gbà fi hàn pé a ‘ṣẹ̀dá wa tìyanutìyanu’?

11 Àwọn kinní bíńtín tí à ń wí yìí yàtọ̀ síra ṣá o. Bó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà láti di ọlẹ̀ ni olúkúlùkù wọn yóò ti máa yà sẹ́nu iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn kan á di iṣan; àwọn mìíràn á di eegun, ẹ̀jẹ̀, tàbí ẹyinjú. Gbogbo ìlànà bí wọ́n ṣe máa yà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ yìí la ti ṣètò ní sẹpẹ́ sínú “ibi ìkówèésí” ti apilẹ̀ àbùdá inú rẹ̀ tí à ń pè ní ásíìdì DNA. Ó dùn mọ́ni pé Dáfídì gba ìmísí tó fi sọ fún Jèhófà pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀.”—Sáàmù 139:16.

12 Àwọn ẹ̀ya ara kan díjú pọ̀ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Wo ọpọlọ èèyàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan. Àwọn kan sọ pé nínú ìwádìí tọ́mọ èèyàn ti ń ṣe, ọpọlọ làwọn rí tó ṣì díjú jù lọ láyé ńbí. Nǹkan bíi bílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún àwọn nǹkan bíńtín tó ń di iṣan ọpọlọ ló wà nínú rẹ̀, ńṣe ló pọ̀ bí iye ìràwọ̀ tí ń bẹ nínú ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tá a wà nínú rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan bíńtín inú ara yìí sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún okùn ìdè tó fi so mọ́ àwọn nǹkan bíńtín yòókù. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tiẹ̀ sọ pé ọpọlọ èèyàn lè gba gbogbo ìsọfúnni tí ń bẹ nínú ibi ìkówèésí tí ń bẹ láyé yìí pátá àti pé bóyá ni àyè ìkó-nǹkan-sí tí ọpọlọ ní á ṣeé díwọ̀n pàápàá. Láìka ọ̀pọ̀ ọdún tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sì ti ń ṣèwádìí lórí ẹ̀ya ara tá a ‘ṣẹ̀dá tìyanu-tìyanu’ yìí, wọ́n ṣì gbà pé ó lè má ṣeé ṣe fáwọn láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa bó ṣe ń ṣiṣẹ́.

13, 14. (a) Báwo ni àwọn èèrà àti ìṣẹ̀dá mìíràn ṣe fi hàn pé wọ́n ní “ọgbọ́n àdámọ́ni,” kí ni ìyẹn sì kọ́ wa nípa Ẹlẹ́dàá wọn? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà “fi ọgbọ́n ṣe” àwọn ìṣẹ̀dá bí aláǹtakùn?

13 Ṣùgbọ́n àpẹẹrẹ kan ṣoṣo ni ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo ọgbọ́n ìṣẹ̀dá rẹ̀. Sáàmù 104:24 sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.” Ọgbọ́n Jèhófà hàn kedere nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tó wà yí wa ká. Bí àpẹẹrẹ, èèrà ní “ọgbọ́n àdámọ́ni.” (Òwe 30:24) Ní tòdodo, bí àwọn agbo èèrà ṣe ń ṣètò ara wọn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bùáyà. Àwọn agbo èèrà kan máa ń sin oríṣi kòkòrò kan tó ń mu oje igi bí ẹní sin ẹran ọ̀sìn. Wọ́n á ṣe ilé fún un, wọ́n á máa bọ́ ọ, wọ́n á sì máa fa oúnjẹ aṣaralóore lára rẹ̀ bí ẹní fún wàrà. Àwọn èèrà mìíràn máa ń ṣe bí àgbẹ̀, wọ́n máa ń “ṣọ̀gbìn” olú. Ọ̀pọ̀ àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn pẹ̀lú ní ohun àrà tó jẹ́ àdámọ́ni tiwọn tí wọ́n ń ṣe. Bírà tí eṣinṣin lásán máa ń dá tó bá ń fò, ọmọ èèyàn ò tíì ní ọkọ̀ òfuurufú tó lè dán an wò. Àwọn ẹyẹ aṣíkiri máa ń fi ibi tí àwọn ìràwọ̀ kan wà mọ ipa ìrìn wọn, tàbí kí wọ́n lo ìlànà agbára òòfà ilẹ̀ ayé, tàbí oríṣi àwòrán ojú ilẹ̀ tí ń bẹ lágbárí wọn. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè máa fi ń ṣèwádìí nípa ìṣesí tó díjú pọ̀ tá a dá mọ́ àwọn ìṣẹ̀dá wọ̀nyí. Ọgbọ́n Ọlọ́run tó dá nǹkan wọ̀nyẹn mọ́ wọn á mà kúkú pọ̀ o!

14 Ẹ̀kọ́ kékeré kọ́ làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti rí kọ́ láti ara ọgbọ́n ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní. Àní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ẹ̀rọ kan wà tó jẹ mọ́ ìgbékalẹ̀ ara ìṣẹ̀dá àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́ (biomimetics), tí wọ́n fi ń gbìyànjú láti wo ìgbékalẹ̀ ọnà ìṣẹ̀dá láti fi ṣe èyí tó jọ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti ṣàkíyèsí àrà tí aláǹtakùn ń fi okùn rẹ̀ dá kí ó sì yà ọ́ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n ní tí onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, ohun tí yóò yà á lẹ́nu ni ọ̀nà tó gbà ń ta okùn náà. Òmíràn tó dà bíi pé ó ṣe tín-ín-rín jù lára okùn aláǹtakùn yẹn lágbára ju irin líle lọ, ó sì yi ju àwọn fọ́nrán òwú ara ẹ̀wù ayẹta ti òyìnbó lọ. Báwo ló tiẹ̀ ṣe lágbára tó ná? Jẹ́ ká sọ pé wọ́n sọ àwọ̀n okùn aláǹtakùn di títóbi títí ó fi wá nípọn bí àwọ̀n tí wọ́n ń dè mọ́ ọkọ̀ ojú omi láti fi pẹja. Tí wọ́n bá ta á dínà ọkọ̀ òfuurufú akérò tó ń fi gbogbo agbára fò lọ, ṣìnkún ló máa mú ọkọ̀ yẹn! Dájúdájú, Jèhófà “fi ọgbọ́n ṣe” gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn lóòótọ́.

Ta ló dá “ọgbọ́n àdámọ́ni” mọ́ àwọn ìṣẹ̀dá inú ayé?

Ọgbọ́n Rẹ̀ Hàn Nínú Ìsálú Ọ̀run Pẹ̀lú

15, 16. (a) Ẹ̀rí wo ni ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ fi hàn nípa ọgbọ́n Jèhófà? (b) Báwo ni ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Alákòóso Àgbà lórí ọ̀kẹ́ àìmọye ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn áńgẹ́lì tó pọ̀ lọ salalu ṣe jẹ́rìí sí ọgbọ́n Alákòóso yìí?

15 Ọgbọ́n Jèhófà hàn nínú iṣẹ́ rẹ̀ kárí ayé òun ìsálú ọ̀run. Ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀, tá a ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa rẹ̀ ní Orí 5, kò kàn ṣe rúdurùdu o. Nítorí “ilana-ilana ọ̀run” tí Jèhófà fi ọgbọ́n là kalẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ́ tó gbayì ni àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ojú ọ̀run pín sí, a sì wá to ẹgbẹẹgbẹ́ yìí sí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, tí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ náà sì tún wà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. (Jóòbù 38:33, Bibeli Mimọ) Abájọ tí Jèhófà fi pe àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run ní “ẹgbẹ́ ọmọ ogun”! (Aísáyà 40:26) Ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan wà ṣá o, tó tiẹ̀ tún fi ọgbọ́n Jèhófà hàn kedere ju ìwọ̀nyí lọ.

16 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ní Orí 4, a máa ń pe Ọlọ́run ní orúkọ oyè náà “Jèhófà ẹgbẹ́ ọmọ ogun” nítorí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alákòóso Àgbà lórí gbogbo ọ̀kẹ́ àìmọye ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó pọ̀ lọ salalu. Èyí fi ẹ̀rí bí agbára Jèhófà ṣe tó hàn. Báwo wá ni ọgbọ́n rẹ̀ ṣe wọnú ọ̀rọ̀ yìí? Ọ̀rọ̀ kan rèé: Ọwọ́ Jèhófà àti Jésù kò dilẹ̀ rí. (Jòhánù 5:17) Ìyẹn fi hàn pé ẹnu iṣẹ́ pẹrẹu làwọn áńgẹ́lì tó ń jíṣẹ́ fún Ọ̀gá Ògo yóò máa wà pẹ̀lú nígbà gbogbo. Sì rántí pé wọ́n ga ju èèyàn lọ, òye wọn bùáyà, agbára wọn sì kàmàmà. (Hébérù 1:7; 2:7) Síbẹ̀, láti àìmọye bílíọ̀nù ọdún wá ni Jèhófà ti ń rí sí i pé ọwọ́ wọn ò dilẹ̀, pé wọ́n ń fi ìdùnnú ṣiṣẹ́ tó nítumọ̀, tí wọ́n “ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́” tí wọ́n sì “ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 103:20, 21) Áà, ọgbọ́n Alákòóso yìí á mà kọyọyọ o!

Jèhófà Ni “Ẹnì Kan Ṣoṣo Tí Ó Gbọ́n”

17, 18. Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,” kí sì nìdí tí ọgbọ́n rẹ̀ fi mú kí ẹ̀rù Ọlọ́run bà wá gidigidi?

17 Lójú àwọn ẹ̀rí bí èyí, ó ha yani lẹ́nu pé Bíbélì fi hàn pé ọgbọ́n Jèhófà ló ga jù lọ pátápátá bí? Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.” (Róòmù 16:27) Ká sòótọ́, Jèhófà nìkan ṣoṣo ló gbọ́n tán. Òun ni orísun gbogbo ọgbọ́n tòótọ́. (Òwe 2:6) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, bí Jésù tilẹ̀ jẹ́ ẹni tó gbọ́n jù lọ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Jèhófà, kò gbára lé ọgbọ́n ara rẹ̀. Bí Bàbá rẹ̀ ṣe ní kó sọ̀rọ̀ ló ṣe ń sọ ọ́.—Jòhánù 12:48-50.

18 Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ọgbọ́n àrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà ní rèé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” (Róòmù 11:33) Fífi tí Pọ́ọ̀lù fi ohùn ìyanu sọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ ọ̀hún wọ̀ ọ́ lákínyẹmí ara, àní ẹ̀rù Ọlọ́run bà á gidigidi. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lò fún ọ̀rọ̀ náà “ìjìnlẹ̀” tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá gbé àwòrán kan yọ síni lọ́kàn. Ìyẹn ni pé bí a bá ń ronú nípa ọgbọ́n Jèhófà, ṣe ni yóò dà bí ìgbà tá à ń yọjú wo ọ̀gbun jìngòdò kan tí kò nísàlẹ̀, tó jẹ́ pé, gbígbòòrò rẹ̀ lásán tayọ òye ọmọ aráyé, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé kí ẹnì kan fẹ́ máa wá ya ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwòrán rẹ̀ sílẹ̀. (Sáàmù 92:5) Ǹjẹ́ èyí gan-an ò kani láyà?

19, 20. (a) Kí nìdí tí idì fi jẹ́ àmì tó bá a mu fún ọgbọ́n Ọlọ́run? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun lè rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la?

19 Ọ̀nà mìíràn tún wà tó ti hàn pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.” Ìyẹn ni pé Òun nìkan ṣoṣo ló lè rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Rántí pé idì tó ń ríran jìnnà ni Jèhófà lò gẹ́gẹ́ bí àmì ọgbọ́n Ọlọ́run. Idì aláwọ̀ wúrà lè má wọ̀n ju kìlógíráàmù márùn-ún lásán lórí òṣùwọ̀n, ṣùgbọ́n ẹyinjú rẹ̀ yóò tóbi ju ti géńdé ọkùnrin lọ. Ojú idì ríran ketekete lọ́nà àgbàyanu tó fi jẹ́ pé ẹyẹ yìí lè rí ohun kékeré kan tó fẹ́ pa jẹ láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún mítà lófuurufú, àní ó tiẹ̀ lè rí èyí tó wà ní ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ sí i pàápàá! Nígbà kan Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ nípa idì pé: “Ojú rẹ̀ ń wo ọ̀nà jíjìn.” (Jóòbù 39:29) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà lè wo àkókò tó ṣì wà ní “ọ̀nà jíjìn,” ó rí ọjọ́ ọ̀la!

20 Ẹ̀rí pọ̀ rẹpẹtẹ nínú Bíbélì tó fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ yìí rí lóòótọ́. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àsọtẹ́lẹ̀, tàbí ìtàn bí ohun tó ṣì ń bẹ lọ́jọ́ iwájú ṣe máa ṣẹlẹ̀ wà nínú Bíbélì. Ohun tó máa jẹ́ àbáyọrí àwọn ogun kan, ìdìde àti ìṣubú àwọn agbára ayé, kódà àti ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ogun tí àwọn ọ̀gágun yóò lò lójú ogun ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pátá, àní nígbà mìíràn yóò ti sọ ọ́ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀.—Aísáyà 44:25-45:4; Dáníẹ́lì 8:2-8, 20-22.

21, 22. (a) Kí nìdí tí kò fi sídìí láti gbà pé gbogbo ohun tó o máa yàn láti ṣe láyé ni Jèhófà ti rí pátá ṣáájú? Mú àpèjúwe wá. (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ọgbọ́n Jèhófà kì í ṣe èyí tí kò láàánú tàbí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò?

21 Ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti rí gbogbo ohun tó o máa yàn láti ṣe nígbèésí ayé? Àwọn tó ń fi àyànmọ́ kọ́ni sọ pé kò sí àní-àní pé ó ti rí i. Ṣùgbọ́n ńṣe ni èrò yẹn ń bu ọgbọ́n Jèhófà kù, torí ó ń fi hàn pé kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu tó bá kan ti agbára rẹ̀ láti rí ọjọ́ ọ̀la. Àpèjúwe kan rèé: Tí o bá jẹ́ olóhùn ìyọ ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, ṣé ó wá túmọ̀ sí pé bóofẹ́bóokọ̀ ó ní láti máa kọrin ní gbogbo ìgbà? Ìyẹn ò ní bọ́gbọ́n mu! Bákan náà, Jèhófà lágbára tó fi lè mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà kọ́ ló ń lò ó. Tó bá ń lò ó ní gbogbo ìgbà, ìyẹn lè máa ṣèdíwọ́ fún òmìnira ìwà híhù tí a ní, bẹ́ẹ̀ ẹ̀bùn iyebíye tí Jèhófà ò ní fagi lé mọ́ wa lọ́wọ́ láéláé ni.—Diutarónómì 30:19, 20.

22 Èyí tó tiẹ̀ burú jù ni pé, ẹ̀kọ́ àyànmọ́ ń fi hàn pé kò sí àánú, ìfẹ́, ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tàbí ìyọ́nú nínú ọgbọ́n Jèhófà. Ṣùgbọ́n irọ́ gbuu nìyẹn o! Bíbélì kọ́ni pé Jèhófà jẹ́ “ọlọ́gbọ́n ní ọkàn-àyà.” (Jóòbù 9:4) Kì í ṣe pé ó ní ọkàn tó ń lù kìkì bí tiwa o. Ṣùgbọ́n Bíbélì sábà máa ń lo gbólóhùn yẹn nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tẹ́nì kan jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, títí kan ẹ̀mí tó ń sún un ṣe nǹkan àti ìṣarasíhùwà rẹ̀, irú bí ìfẹ́. Nítorí náà, ńṣe ni ọgbọ́n Jèhófà rí bí àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù, ìfẹ́ ló ń darí rẹ̀.—1 Jòhánù 4:8.

23. Gíga tí ọgbọ́n Jèhófà ga jù lọ yẹ kó sún wa láti ṣe kí ni?

23 Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní sísọ pé ọgbọ́n Jèhófà ṣeé gbíyè lé pátápátá. Ó ju ọgbọ́n tiwa lọ fíìfíì débi pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá tìfẹ́tìfẹ́ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Ẹ jẹ́ ká wá dáwọ́ lé àyẹ̀wò ọgbọ́n Jèhófà wàyí, ká bàa lè sún mọ́ Ọlọ́run wa ọlọ́gbọ́n gbogbo.