Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 18

Ọgbọ́n Wà Nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”

Ọgbọ́n Wà Nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”

1, 2. “Lẹ́tà” wo ni Jèhófà kọ sí wa, kí sì nìdí rẹ̀?

ǸJẸ́ o rántí lẹ́tà tó o gbà kẹ́yìn látọ̀dọ̀ ojúlùmọ̀ rẹ kan tó wà ní ìlú òkèèrè? Ṣàṣà nǹkan ló lè mú inú wa dùn bíi pé ká gba lẹ́tà ayọ̀ látọ̀dọ̀ ẹni ọ̀wọ́n kan. Ó máa ń dùn mọ́ wa láti gbúròó àlàáfíà rẹ̀, bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún un àtàwọn nǹkan tó ń gbèrò láti ṣe. Irú ìgbúròó ara ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí àwọn ojúlùmọ̀ túbọ̀ fà mọ́ra, bí ọ̀nà wọn tiẹ̀ jìn síra.

2 Kí ni ì bá tún wá dùn mọ́ wa bíi pé kí Ọlọ́run tá a fẹ́ràn kọ̀wé sí wa? Lọ́nà kan, Jèhófà ti kọ “lẹ́tà” kan sí wa o, ìyẹn Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Inú rẹ̀ ló ti sọ irú ẹni tóun jẹ́ fún wa, ohun tóun ti ṣe, èyí tóun fẹ́ ṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jèhófà fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí ó ń fẹ́ ká sún mọ́ òun. Ọ̀nà tó dára jù lọ ni Ọlọ́run wa, ọba ọgbọ́n, sì yàn láti fi bá wa sọ̀rọ̀. Ọ̀nà ọgbọ́n tí kò láfiwé la gbà kọ Bíbélì àti ohun tó wà nínú rẹ̀.

Kí Nìdí Tó Fi Kọ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Sílẹ̀?

3. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi Òfin ṣọwọ́ sí Mósè?

3 Àwọn kan lè máa rò ó pé, ‘Jèhófà ò ṣe lo ọ̀nà àràmàǹdà kan láti fi bá ọmọ ènìyàn sọ̀rọ̀, bíi pé kó fọhùn látọ̀runwá?’ Ká sòótọ́, àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà ti gbẹnu àwọn áńgẹ́lì aṣojú rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀runwá. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó fún Ísírẹ́lì ní Òfin. (Gálátíà 3:19) Ohùn àtọ̀runwá yẹn milẹ̀ jìnjìn, tí ẹ̀rù fi ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì débi pé wọ́n ní kí Jèhófà má tipa bẹ́ẹ̀ bá àwọn sọ̀rọ̀ mọ́, pé kó máa tipasẹ̀ Mósè bá àwọn sọ̀rọ̀. (Ẹ́kísódù 20:18-20) Ìyẹn ló fi di pé ẹnu la fi sọ Òfin tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta fún Mósè lọ́kọ̀ọ̀kan.

4. Ṣàlàyé ìdí tí ọ̀rọ̀ àtẹnudẹ́nu kì í fi í ṣe ọ̀nà tó ṣeé gbára lé láti gbà fi àwọn òfin Ọlọ́run ṣọwọ́ síni.

4 Àmọ́ ká wá ní a ò kọ Òfin yẹn sílẹ̀ rárá ńkọ́? Ṣé Mósè á lè rántí gbogbo ọ̀rọ̀ inú ọ̀kọ̀ọ̀kan òfin kíkún rẹ́rẹ́ yẹn gẹ́lẹ́ bó ṣe wà níbẹ̀, kí ó sì tún un sọ láìyingin fún ìyókù orílẹ̀-èdè náà? Ìrandíran ẹ̀yìn ìgbà náà ńkọ́? Ṣé àtẹnudẹ́nu nìkan ni wọn yóò máa gbọ́ Òfin yẹn ni? Ìyẹn ò ní jẹ́ ọ̀nà tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé láti máa gbà fúnni ní àwọn òfin Ọlọ́run. Fojú inú wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ká ní àwọn èèyàn tò sórí ìlà gígùn kan, o wá sọ ìtàn kan fẹ́ni àkọ́kọ́ lórí ìlà ọ̀hún pé kí wọ́n máa sọ ọ́ látẹnu dẹ́nu títí á fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tó kẹ́yìn lórí ìlà yẹn. Ohun tí ẹni tó gbẹ̀yìn ìlà ọ̀hún yóò gbọ́ á ti yàtọ̀ gan-an sí ohun tó o sọ fún ẹni àkọ́kọ́. Irú ewu bẹ́ẹ̀ kò sí fún ọ̀rọ̀ inú Òfin Ọlọ́run ní tirẹ̀.

5, 6. Kí ni Jèhófà ní kí Mósè ṣe nípa Ọ̀rọ̀ òun, kí sì nìdí tí wíwà tí Ọ̀rọ̀ Jèhófà wà ní kíkọ sílẹ̀ fi ṣe wá lóore?

5 Jèhófà fi ọgbọ́n pinnu pé kí á kọ ọ̀rọ̀ òun sílẹ̀. Ó fún Mósè ní ìtọ́ni pé: “Kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀ fún ara rẹ, nítorí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni mo bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.” (Ẹ́kísódù 34:27) Bí Bíbélì kíkọ ṣe bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa nìyẹn o. Fún ẹgbẹ̀jọ ó lé mẹ́wàá [1,610] ọdún tó tẹ̀ lé e, nǹkan bí ogójì èèyàn tó jẹ́ òǹkọ̀wé ni Jèhófà ‘bá sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà àti lọ́pọ̀ ọ̀nà,’ tí àwọn wọ̀nyẹn sì wá kọ Bíbélì. (Hébérù 1:1) Láàárín àkókò yìí, àwọn adàwékọ alákitiyan sapá gidigidi láti ṣe àwọn àdàkọ rẹ̀ tó péye kí Ìwé Mímọ́ má bàa pa rẹ́.—Ẹ́sírà 7:6; Sáàmù 45:1.

6 Oore ńláǹlà ni Jèhófà ṣe fún wa tó fi kọ ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá wa sọ sílẹ̀. Ǹjẹ́ o tíì gba lẹ́tà kan tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an rí, bóyá nítorí ìtùnú tó fún ọ, tó o wá tọ́jú rẹ̀ láti máa kà á ní àkàtúnkà? Bí “lẹ́tà” tí Jèhófà kọ sí wa ṣe rí nìyẹn. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní kíkọ sílẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa kà á déédéé, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó sọ. (Sáàmù 1:2) A lè máa tipa bẹ́ẹ̀ gba “ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́” nígbàkigbà tá a bá kà á.—Róòmù 15:4.

Kí Nìdí Tó Fi Lo Èèyàn Láti Kọ Ọ́?

7. Báwo ni lílò tí Jèhófà lo àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé ṣe fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn?

7 Jèhófà fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn bó ṣe lo àwọn èèyàn láti fi kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Gbé èyí yẹ̀ wò ná: Ká ní àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà lò láti fi kọ Bíbélì, ṣé o rò pé bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe fani mọ́ra yìí náà ló ṣe máa fani mọ́ra? Lóòótọ́, àwọn áńgẹ́lì ì bá gbé Jèhófà yọ lọ́nà ọlọ́lá ńlá bí àwọn ṣe mọ̀ ọ́n, wọ́n á ṣàlàyé báwọn ṣe ń fọkàn sìn ín, wọ́n á sì tún sọ ìtàn àwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ìmọ̀, ìrírí àti agbára àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí pípé ti ju tiwa lọ fíìfíì ǹjẹ́ ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn nǹkan á bá tiwa mu?—Hébérù 2:6, 7.

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí”

8. Báwo ni Ọlọ́run ṣe gba àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì láyè láti lo làákàyè wọn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé pẹ̀lú.)

8 Bí Jèhófà ṣe lo àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé yìí, ohun tá a nílò gẹ́lẹ́ ló fi èyí pèsè, ìyẹn àkọsílẹ̀ kan tí “Ọlọ́run mí sí” síbẹ̀ táwọn ànímọ́ ọmọ ènìyàn ṣì hàn nínú rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Báwo ló ṣe rí èyí ṣe? Ó hàn gbangba pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ó máa ń jẹ́ kí àwọn òǹkọ̀wé náà lo làákàyè wọn láti fúnra wọn yan “àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.” (Oníwàásù 12:10, 11) Abájọ tí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ onírúurú fi wà nínú Bíbélì; ipò tí olúkúlùkù òǹkọ̀wé náà wà àti ànímọ́ wọn látilẹ̀wá hàn nínú àwọn àkọsílẹ̀ yẹn. * Síbẹ̀, ńṣe làwọn èèyàn yìí “sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pétérù 1:21) Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé tí wọ́n kọ lódindi jẹ́ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ní tòótọ́.—1 Tẹsalóníkà 2:13.

9, 10. Kí nìdí tí lílò tí Ọlọ́run lo ọmọ ènìyàn láti fi kọ Bíbélì fi jẹ́ kó wọni lọ́kàn kí ó sì fani mọ́ra?

9 Bí Ọlọ́run ṣe lo èèyàn láti kọ Bíbélì jẹ́ kó wọni lọ́kàn kó sì fani mọ́ra gidigidi. Ẹlẹ́ran ara bíi tiwa náà làwọn tó kọ ọ́. Bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìpé, onírúurú àdánwò àti pákáǹleke làwọn pẹ̀lú dojú kọ bíi tiwa. Nígbà mìíràn, ẹ̀mí Jèhófà mí sí wọn láti ṣàkọsílẹ̀ bí ọ̀ràn ṣe rí lára wọn àti ìjàkadì tí wọ́n ń jà. (2 Kọ́ríńtì 12:7-10) Nípa bẹ́ẹ̀, bí ọ̀ràn ṣe rí lára wọn gẹ́lẹ́ ni wọ́n ṣe kọ ọ́ sílẹ̀, èyí tí áńgẹ́lì kankan kì bá lè ṣe rárá.

10 Wo àpẹẹrẹ ti Dáfídì ọba Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú jáì, ó kọ sáàmù kan tó fi tú èrò ọkàn rẹ̀ síta, tó ń tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Wẹ̀ mí mọ́ àní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn ìrélànàkọjá mi, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo. Wò ó! Pẹ̀lú ìṣìnà ni a bí mi nínú ìrora ìbímọ, nínú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi lóyún mi. Má ṣe gbé mi sọnù kúrò níwájú rẹ; ẹ̀mí mímọ́ rẹ ni kí o má sì gbà kúrò lára mi. Àwọn ẹbọ sí Ọlọ́run ni ẹ̀mí tí ó ní ìròbìnújẹ́; ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.” (Sáàmù 51:2, 3, 5, 11, 17) Ǹjẹ́ o kò mọ ẹ̀dùn ọkàn òǹkọ̀wé yìí lára? Yàtọ̀ sí ẹ̀dá aláìpé, ta ni ì bá tún lè sọ irú ọ̀rọ̀ arò bẹ́ẹ̀ látọkànwá?

Èé Ṣe Tí Ìwé Yìí Fi Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn?

11. Irú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn ní ti gidi wo ni a kọ sínú Bíbélì “fún ìtọ́ni wa”?

11 Ohun mìíràn tún wà tó mú kí Bíbélì fani mọ́ra. Ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tó wà nínú ìwé náà ló dá lórí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn, àwọn tó gbé ayé ní ti gidi là ń wí o, àwọn tó ń sin Ọlọ́run àtàwọn tí kò sìn ín. A kà nípa ìrírí wọn, ìnira wọn àti ìdùnnú wọn. A rí àbájáde àwọn ohun tí wọ́n dáwọ́ lé nígbèésí ayé. Ìtàn wọ̀nyẹn sì wà níbẹ̀ “fún ìtọ́ni wa.” (Róòmù 15:4) Jèhófà lo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn ní ti gidi wọ̀nyí láti fi kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí yóò wọ̀ wá lọ́kàn. Àwọn àpẹẹrẹ kan rèé.

12. Ọ̀nà wo làwọn ìtàn tí Bíbélì sọ nípa àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn máa ń gbà ràn wá lọ́wọ́?

12 Bíbélì sọ ìtàn àwọn aláìṣòótọ́ àtàwọn èèyàn burúkú pàápàá títí kan ìyọnu tó bá wọn. Ìtàn wọ̀nyẹn jẹ́ ká rí bí ìwà burúkú ṣe jẹ́, ó sì mú kó rọrùn fún wa láti mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, báwo la ṣe fẹ́ kìlọ̀ fúnni nípa ìwà àìdúróṣinṣin tí yóò lè wọni lọ́kàn tó ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n téèyàn rí látinú bí Júdásì ṣe hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Jésù? (Mátíù 26:14-16, 46-50; 27:3-10) Àwọn ìtàn bí èyí túbọ̀ máa ń wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn ànímọ́ tí kò dára mọ̀ ká sì yẹra fún un.

13. Ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà mú ká lóye àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra?

13 Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. A kà nípa ìfọkànsìn wọn àti ìdúróṣinṣin wọn. A rí àpẹẹrẹ tàwọn èèyàn tó lo àwọn ànímọ́ tó yẹ ká fi kọ́ra láti lè sún mọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ ká fi ìgbàgbọ́ ṣe àpẹẹrẹ. Bíbélì sọ ìtumọ̀ ìgbàgbọ́, ó sì sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní in láti lè wu Ọlọ́run. (Hébérù 11:1, 6) Ṣùgbọ́n a tún rí àpẹẹrẹ àwọn tó lo ìgbàgbọ́ ní ti gidi nínú Bíbélì. Ronú nípa irú ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù lò nígbà tó gbìyànjú láti fi Ísákì rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì orí 22; Hébérù 11:17-19) Irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí ọ̀rọ̀ náà, “ìgbàgbọ́,” túbọ̀ ní ìtumọ̀ síni, kí ó sì túbọ̀ rọrùn láti lóye. Ó mà bọ́gbọ́n mu o pé yàtọ̀ sí pé Jèhófà ń rọ̀ wá pé ká fi àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra kọ́ra, ó tún jẹ́ ká rí àwọn tó lò wọ́n ní ti gidi tá a lè fi ṣe àwòkọ́ṣe!

14, 15. Kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa obìnrin kan tó wá sí tẹ́ńpìlì, kí sì ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà?

14 Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn, tó wà nínú Bíbélì sábà máa ń kọ́ wa ní nǹkan kan nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Wo àpẹẹrẹ ohun tí a kà nípa obìnrin kan tí Jésù kíyè sí nínú tẹ́ńpìlì. Bí Jésù ṣe jókòó sí ìtòsí àpótí ọrẹ, ó ń wo bí àwọn èèyàn ṣe ń sọ ọrẹ wọn síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ wá síbẹ̀, wọ́n sọ owó sínú rẹ̀ “láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn.” Ṣùgbọ́n Jésù kíyè sí òtòṣì opó kan dáadáa. ‘Ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an’ ni obìnrin náà rí sọ sínú rẹ̀. * Gbogbo ohun tó ní mọ nìyẹn. Jésù, tó fi irú ojú tí Jèhófà fi ń wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ hàn gẹ́lẹ́, sọ pé: “Òtòṣì opó yìí sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra náà.” Bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe fi hàn, ohun tí obìnrin náà sọ síbẹ̀ ju ti gbogbo àwọn yòókù lápapọ̀ lọ.—Máàkù 12:41-44; Lúùkù 21:1-4; Jòhánù 8:28.

15 Ǹjẹ́ kò wúni lórí pé nínú gbogbo àwọn èèyàn tó wá sí tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ yẹn, opó yìí nìkan ṣoṣo la mẹ́nu kàn láàárín wọn nínú Bíbélì? Jèhófà lo àpẹẹrẹ yìí láti fi kọ́ wa pé Ọlọ́run onímọrírì lòun. Ó ń fi ìdùnnú tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn àtọkànwá tá a ní bó ti wù kó kéré tó lẹ́gbẹ̀ẹ́ tàwọn ẹlòmíràn. Bóyá ni ọ̀nà mìíràn tó dáa tó yìí wà tí Jèhófà tún fi lè kọ́ wa ní òtítọ́ pàtàkì yìí!

Ohun Tí Bíbélì Ò Sọ

16, 17. Báwo ni àwọn ohun tí Jèhófà ò kọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gan-an ṣe jẹ́ ká rí ọgbọ́n rẹ̀?

16 Bí o bá ń kọ lẹ́tà sí ojúlùmọ̀ rẹ kan, kì í ṣe gbogbo nǹkan lo máa lè sọ sínú ẹ̀ tán. Nítorí náà, ńṣe lo máa ń fi ọgbọ́n pinnu èyí tó o máa sọ. Bí ti Jèhófà ṣe rí náà nìyẹn, àwọn kan àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ló pinnu láti mẹ́nu kàn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìgbà gbogbo ni Bíbélì máa ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn wọ̀nyí látòkèdélẹ̀. (Jòhánù 21:25) Bí àpẹẹrẹ, tí Bíbélì bá ń sọ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run, ohun tó máa wí lè máà dáhùn gbogbo ìbéèrè wa tán pátá. Àwọn ohun tí Jèhófà ò kọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí gan-an jẹ́ ká rí ọgbọ́n rẹ̀. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

17 Ọ̀nà tí a gbà kọ Bíbélì máa ń dán ohun tí ń bẹ lọ́kàn wa wò. Hébérù 4:12 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ [tàbí, ìsọfúnni] Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa ń wọni lákínyẹmí ara, á wá túdìí ohun tó jẹ́ ìrònú àti ète ọkàn wa lóòótọ́. Àwọn tó ń fi ọkàn ìṣelámèyítọ́ ka Bíbélì sábà máa ń ko ìṣòro nígbà tí wọ́n bá ń ka àwọn ìtàn tí kò fún wọn ní ìsọfúnni tó bí wọ́n ṣe ń fẹ́. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn pé bóyá ni Jèhófà jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ọlọ́gbọ́n àti onídàájọ́ òdodo lóòótọ́.

18, 19. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dààmú bí ìtàn Bíbélì kan bá rú wa lójú tá ò sì rí ojútùú rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? (b) Kí ló gbà ká tó lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, báwo lèyí sì ṣe jẹ́ ẹ̀rí ọgbọ́n ńlá Jèhófà?

18 Ní ìyàtọ̀ sí èyí, tí a bá fara balẹ̀ fi òótọ́ inú kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a ó mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ látinú ọ̀nà tí gbogbo Bíbélì lódindi gbà fi í hàn. Ìyẹn la ò fi ní dààmú bí ìtàn kan pàtó bá rú wa lójú tá ò sì rí ojútùú rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. A mọ̀ pé tí a bá ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ a ó mọ irú Ọlọ́run tí Jèhófà jẹ́. Ká tiẹ̀ wá ní ìtàn kan kọ́kọ́ rú wa lójú, tàbí pé a ò rí bí ìtàn náà ṣe bá ànímọ́ Ọlọ́run mu, ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́ á ti jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà gan-an débi tá a ó fi rí i pé kò sóhun tó lè mú kó máà jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, aṣẹ̀tọ́ àti onídàájọ́ òdodo.

19 Nítorí náà, ká tó lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ní láti fi òótọ́ ọkàn kà á ká sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láìsí ẹ̀tanú. Ǹjẹ́ èyí kì í ṣe ẹ̀rí pé ọgbọ́n ńlá ni Jèhófà ní? Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lè kọ̀wé tó jẹ́ pé kìkì “àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye” ló máa yé. Ṣùgbọ́n ní ti ṣíṣe ìwé kan tó jẹ́ pé kìkì àwọn tí ọkàn wọn wà nípò tó tọ́ ló máa yé, ọgbọ́n Ọlọ́run nìkan nìyẹn gbà o!—Mátíù 11:25.

Ìwé “Ọgbọ́n Tó Gbéṣẹ́”

20. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè sọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé fún wa, kí ló sì wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́?

20 Jèhófà sọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Òun gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa mọ ohun tá a nílò jù wá lọ. Ohun táwọn èèyàn sì nílò láyé kò yí padà rí, títí kan bó ṣe máa ń wù wá ká ní ẹni tó máa nífẹ̀ẹ́ wa, bá a ṣe fẹ́ jẹ́ aláyọ̀, ká sì ní àjọṣe tó dán mọ́rán. Bíbélì ní ibú “ọgbọ́n tó gbéṣẹ́” tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó dáa. (Òwe 2:7) Ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ò ń kà yìí ní orí kan tó ń fi bí a ṣe lè lo ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí ń bẹ nínú Bíbélì hàn, ṣùgbọ́n jẹ́ ká kàn gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò níhìn-ín.

21-23. Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ríránró àti bíbániṣọ̀tá?

21 Ǹjẹ́ o tíì ṣàkíyèsí rí pé, àwọn èèyàn tó ń di kùnrùngbùn tí wọ́n sì ń báni ṣọ̀tá máa ń ṣèpalára fún ara wọn ni? Téèyàn bá ń báni ṣọ̀tá, ẹrù tó wúwo ló gbé rù. Bí a bá gba ẹ̀mí yẹn láyè, ńṣe ló máa ń gbani lọ́kàn, tọ́kàn onítọ̀hún ò ní balẹ̀, tí kò sì ní láyọ̀. Ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fi hàn pé téèyàn bá ń ránró, ìyẹn lè fa àrùn ọkàn àti àìmọye àìsàn burúkú mìíràn báni. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sì ni Bíbélì ti sọ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n yìí pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀.” (Sáàmù 37:8) Ṣùgbọ́n báwo lèèyàn ṣe lè ṣe é?

22 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n yìí pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Ìjìnlẹ̀ òye ni pé kéèyàn má wo kìkì ohun tó fara hàn sí ojútáyé nìkan, ṣùgbọ́n kí ó tún rí ohun tí kò hàn síta pẹ̀lú. Ìjìnlẹ̀ òye máa ń múni lo làákàyè, nítorí á jẹ́ kéèyàn lè fòye mọ ìdí tí ẹnì kan fi sọ̀rọ̀ tàbí tó fi hùwà lọ́nà kan pàtó. Tá a bá gbìyànjú láti lóye ẹ̀mí tó ń sún un ṣe ohun tó ń ṣe, bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ̀ àti irú ipò tó wà, ìyẹn lè mú ká yéé dá a lẹ́bi ká má sì bínú sí i mọ́.

23 Ìmọ̀ràn yìí tún wà nínú Bíbélì pẹ̀lú pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.” (Kólósè 3:13) Gbólóhùn náà, “ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì” ń sọ fún wa pé ká máa ní sùúrù fún ọmọnìkejì wa, ká fara da àwọn ànímọ́ tó lè máa bí wa nínú. Irú ẹ̀mí sùúrù bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ká máa di kùnrùngbùn lórí nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Kí á máa “dárí jì,” ń túmọ̀ sí pé ká má ṣe báni ṣọ̀tá rárá. Ọlọ́run wa ọlọ́gbọ́n mọ̀ pé dandan ni pé ká dárí ji ọmọnìkejì wa bí ìdí pàtàkì bá wà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe fún àǹfààní tiwọn nìkan, ṣùgbọ́n ó tún wà fún ìbàlẹ̀ ọkàn tiwa pẹ̀lú. (Lúùkù 17:3, 4) Áà, ọgbọ́n tí ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mà kàmàmà o!

24. Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ tá a bá ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù?

24 Ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí Jèhófà ní ló mú kó fẹ́ láti bá wa sọ̀rọ̀. Ó wá yan ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà ṣe é. Ó lo àwọn èèyàn láti kọ “lẹ́tà” kan, ó sì fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wọn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ọgbọ́n Jèhófà tìkára rẹ̀ wà nínú ìwé náà látòkèdélẹ̀. Ọgbọ́n yìí sì jẹ́ “aṣeégbẹ́kẹ̀lé gan-an.” (Sáàmù 93:5) Bí a ṣe ń fi í ṣèwà hù tí a sì ń wàásù rẹ̀ fáwọn èèyàn, ńṣe lá máa mú wa sún mọ́ Ọlọ́run wa ọba ọgbọ́n. Ní orí tó tẹ̀ lé èyí, a ó ṣàlàyé nípa àpẹẹrẹ mìíràn nínú ọgbọ́n tó ń ríran jìnnà tí Jèhófà ní: ìyẹn agbára rẹ̀ láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la àti láti mú ète rẹ̀ ṣẹ.

^ ìpínrọ̀ 8 Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, lo àpẹẹrẹ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn darandaran. (Sáàmù 23) Mátíù tó jẹ́ agbowó òde mẹ́nu kan owó àti iye owó lọ́pọ̀ ìgbà. (Mátíù 17:27; 26:15; 27:3) Lúùkù, tó jẹ́ oníṣègùn, lo àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ẹni tó mọ̀ nípa ìṣègùn ni.—Lúùkù 4:38; 14:2; 16:20.

^ ìpínrọ̀ 14 Lẹ́bítọ̀nù, tí í ṣe ẹyọ owó àwọn Júù tó kéré jù lọ tí wọ́n ń ná nígbà yẹn ni ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan yìí. Tí a bá pín owó ọ̀yà ọjọ́ kan sí ọ̀nà mẹ́rìnlélọ́gọ́ta, ìdá kan nínú rẹ̀ ni Lẹ́bítọ̀nù méjì jẹ́. Ẹyọ owó méjèèjì yìí kò tiẹ̀ tó láti fi ra ẹyọ ológoṣẹ́ kan ṣoṣo, èyí tí í ṣe ẹyẹ tí owó rẹ̀ kéré jù lọ táwọn òtòṣì máa ń rà jẹ.