Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí 21

Jésù Fi “Ọgbọ́n Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” Hàn

Jésù Fi “Ọgbọ́n Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” Hàn

1-3. Ìhà wo ni àwọn tó fìgbà kan jẹ́ aládùúgbò Jésù kọ sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, kí sì ni wọn ò mọ̀ nípa rẹ̀?

ÌYÀLẸ́NU ńláǹlà ló jẹ́ fún àwùjọ yìí bí wọ́n ṣe ń wo ọ̀dọ́mọkùnrin náà Jésù tó dúró níwájú wọn nínú sínágọ́gù tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Kì í ṣe ẹni àjèjì tí wọn ò mọ̀ rí. Ìlú wọn yìí ló gbé dàgbà, ó sì ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe iṣẹ́ káfíńtà níbẹ̀. Bóyá Jésù tiẹ̀ wà lára àwọn tó kọ́ ilé tí òmíràn lára wọn ń gbé, tàbí kó jẹ́ pé òun ló tiẹ̀ ṣe ohun ìtúlẹ̀ àti àjàgà tí wọ́n ń lò ní oko wọn. * Àmọ́, ìhà wo ni wọ́n wá fẹ́ kọ sí ẹ̀kọ́ káfíńtà tẹ́lẹ̀ rí yìí?

2 Háà ṣe ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n fi ń béèrè pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí?” Ṣùgbọ́n wọ́n tún ń sọ pé: “Èyí ni káfíńtà náà ọmọkùnrin Màríà.” (Mátíù 13:54-58; Máàkù 6:1-3) Ó mà ṣe o, ńṣe làwọn tó fìgbà kan jẹ́ aládùúgbò Jésù yìí ń ṣe hẹ̀ẹ̀ rẹ̀ lọ́kàn wọn pé, ‘Ṣebí káfíńtà àdúgbò wa yẹn náà ni, kí ló wá fẹ́ kọ́ wa?’ Pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe kọ́ni lọ́gbọ́n tó, wọ́n kẹ̀yìn sí i. Ṣé wọn ò kúkú mọ̀ pé ọgbọ́n ara rẹ̀ kọ́ ló ń kọ́ wọn.

3 Ibo gan-an ni Jésù ti rí ọgbọ́n yìí lóòótọ́? Jésù ní: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù “ti di ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún wa.” (1 Kọ́ríńtì 1:30) Jèhófà tipasẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn. Ọ̀rọ̀ yìí sì jóòótọ́ débi tí Jésù fi lè sọ pé: “Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.” (Jòhánù 10:30) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́ta tí Jésù ti fi “ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” hàn.

Ohun Tó Fi Kọ́ni

4. (a) Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù Jésù, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì gidigidi? (b) Kí nìdí tí ìmọ̀ràn Jésù fi máa ń wúlò nígbà gbogbo, tí yóò sì fi ṣe àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láǹfààní gan-an?

4 Àkọ́kọ́, wo ohun tí Jésù fi kọ́ni. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43) Èyí ṣe pàtàkì gan-an nítorí ipa tí Ìjọba náà yóò kó nínú dídá ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre àti nínú mímú ìbùkún tó wà pẹ́ títí wá fún aráyé. Jésù tún fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ fúnni nímọ̀ràn ọlọ́gbọ́n lórí ọ̀ràn ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun ni “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn” tí àsọtẹ́lẹ̀ wí lóòótọ́. (Aísáyà 9:6) Ọ̀nà dà tí ìmọ̀ràn rẹ̀ ò tiẹ̀ fi ní jẹ́ àgbàyanu? Ó mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀-jinlẹ̀, ó mọ bí ẹ̀dá èèyàn ṣe jẹ́ dáadáa, ó sì fẹ́ràn ọmọ ènìyàn gan-an. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìmọ̀ràn tó wúlò, tí yóò ṣe àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láǹfààní gan-an ló ń fún wọn nígbà gbogbo. Ọ̀rọ̀ ẹnu Jésù jẹ́ “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” Dájúdájú, téèyàn bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀, á tipa bẹ́ẹ̀ rí ìgbàlà.—Jòhánù 6:68.

5. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn kókó pàtàkì tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Ìwàásù Lórí Òkè?

5 Ìwàásù Lórí Òkè jẹ́ àpẹẹrẹ kan tó tayọ ní ti ọgbọ́n ńláǹlà tí ẹ̀kọ́ Jésù ń kọ́ni. Bí ìwàásù yìí ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Mátíù 5:3-7:27, bóyá ló fi máa gbà ju ogún ìṣẹ́jú lọ téèyàn ó fi sọ ọ́. Àmọ́ ìmọ̀ràn inú rẹ̀ wúlò títí gbére, nítorí gẹ́lẹ́ bó ṣe wúlò láyé ìgbà tó kọ́kọ́ sọ ọ́ náà ló ṣì ṣe wúlò lóde òní. Onírúurú kókó pàtàkì ni Jésù sọ̀rọ̀ lé lórí, títí kan béèyàn ṣe lè mú kí àárín òun àtàwọn èèyàn túbọ̀ dára sí i (5:23-26, 38-42; 7:1-5, 12), béèyàn ṣe lè jìnnà sí ìṣekúṣe (5:27-32), àti béèyàn yóò ṣe gbé ìgbésí ayé rere (6:19-24; 7:24-27). Ṣùgbọ́n Jésù ò kàn mẹ́nu kan àwọn ìwà tó bọ́gbọ́n mu láti máa hù létí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ nìkan; ó tún fi hàn wọ́n ní ti pé ó ṣàlàyé wọn ó sì fi ẹ̀rí tì í lẹ́yìn.

6-8. (a) Ìdí pàtàkì wo ni Jésù sọ pé ó fi yẹ ká yẹra fún àníyàn ṣíṣe? (b) Kí ló fi hàn wá pé ìmọ̀ràn Jésù gbé ọgbọ́n Ọlọ́run yọ?

6 Bí àpẹẹrẹ, wo ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Jésù fúnni nípa bí a ṣe lè bójú tó ọ̀ràn ṣíṣàníyàn nípa nǹkan ìní ti ara nínú àlàyé rẹ̀ tó wà nínú Mátíù orí kẹfà. Jésù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀.” (Ẹsẹ 25) Kòṣeémánìí loúnjẹ àti aṣọ jẹ́, nítorí náà èèyàn ò lè ṣàì ṣàníyàn nípa bó ṣe máa ní wọn. Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé ká “dẹ́kun ṣíṣàníyàn” nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. * Èé ṣe?

7 Fetí sílẹ̀ gbọ́ bí Jésù ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yẹn yékéyéké. Ó ní ṣebí Jèhófà ló dá ìwàláàyè àti ara wa, ṣé kò wá ní lè pèsè oúnjẹ láti gbé ẹ̀mí yẹn ró àti aṣọ láti fi bo ara yẹn ni? (Ẹsẹ 25) Bí Ọlọ́run bá lè pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ tó sì fi ẹwà dáṣọ ró àwọn òdòdó, ó dájú pé á tọ́jú àwọn èèyàn tó sìn ín jù bẹ́ẹ̀ lọ! (Ẹsẹ 26, 28-30) Ní tòdodo, ṣíṣàníyàn láìyẹ kò da nǹkan kan fúnni. Kò lè fi ìwọ̀n ṣíún kún ìgbésí ayé wa rárá. * (Ẹsẹ 27) Ǹjẹ́ báwo la ṣe lè yàgò fún àníyàn ṣíṣe o? Ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa ni pé: Sáà ti máa bá a lọ láti fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo nígbèésí ayé. Kí àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ sì fọkàn balẹ̀, nítorí pé gbogbo kòṣeémánìí wọn ojoojúmọ́ wọn ni Baba wọn ọ̀run “yóò fi kún un” fún wọn. (Ẹsẹ 33) Lákòótán, Jésù wá fúnni ní àbá kan tó wúlò jù lọ, ìyẹn ni pé ọ̀ràn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni ká máa bójú tó lẹ́ẹ̀kan. Nítorí náà, èé ṣe tí wàá fi máa da àníyàn ti ọ̀la pọ̀ mọ́ tòní? (Ẹsẹ 34) Yàtọ̀ sí ìyẹn, èé ṣe tí wàá tiẹ̀ fi máa ṣàníyàn nípa ohun tó lè má ṣẹlẹ̀ rárá pàápàá? Tí a bá fi irú ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n bẹ́ẹ̀ sílò, á yọ wá nínú ọ̀pọ̀ ìrora ọkàn nínú ayé oníhílàhílo yìí.

8 Ó ṣe kedere nígbà náà pé bí ìmọ̀ràn tí Jésù fúnni ṣe wúlò ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn ló sì ṣe wúlò lóde òní. Ẹ̀rí pé Jésù ní ọgbọ́n Ọlọ́run ha kọ́ yẹn? Èyí tó tiẹ̀ dára jù lọ lára ìmọ̀ràn àwọn agbaninímọ̀ràn nínú ọmọ aráyé pàápàá lè di aláìbágbàmu mọ́, á wá di dandan pé kí wọ́n ṣàtúnṣe rẹ̀ tàbí kí wọ́n fi òmíràn rọ́pò rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀kọ́ Jésù, kò di ògbólógbòó bẹ́ẹ̀ ni kò ṣàìbágbàmu rí títí di báyìí. Kò sì yẹ kí èyíinì yà wá lẹ́nu, nítorí pé “àwọn àsọjáde Ọlọ́run” ló ń jáde wá látẹnu Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn yìí.—Jòhánù 3:34.

Ọ̀nà Tó Ń Gbà Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

9. Kí làwọn ọmọ ogun kan sọ nípa ẹ̀kọ́ Jésù, kí sì nìdí tí èyí ò fi jẹ́ àsọdùn?

9 Ọ̀nà kejì tí Jésù tún ti gbé ọgbọ́n Ọlọ́run yọ ni ọ̀nà tó gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà kan, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n rán lọ mú Jésù padà lọ́wọ́ òfo, wọ́n ní: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” (Jòhánù 7:45, 46) Àsọdùn kọ́ lọ́rọ̀ wọn yìí. Nínú gbogbo èèyàn tó ti ń gbé láyé, Jésù tó ti “àwọn ilẹ̀ àkóso òkè” wá ló ní ibú ìmọ̀ àti ìrírí gíga jù lọ tó lè fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. (Jòhánù 8:23) Lóòótọ́ kò sì sí ẹ̀dá èèyàn mìíràn tó tún lè kọ́ni lọ́nà tó gbà kọ́ni. Wo méjì péré nínú ọ̀nà tí ọlọ́gbọ́n Olùkọ́ni yìí gbà kọ́ni.

“Háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀”

10, 11. (a) Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jésù gbà ń lo àkàwé ò fi lè ṣàì yani lẹ́nu? (b) Kí ni àkàwé, àpẹẹrẹ wo ló sì jẹ́ ká rí ìdí tí àwọn àkàwé Jésù fi múná dóko?

10 Lílo àpèjúwe lọ́nà tó múná dóko. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Jésù fi àwọn àpèjúwe [sọ̀rọ̀] fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe.” (Mátíù 13:34) Ọ̀nà àìláfiwé tó fi mọ bá a ṣe ń lo àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tá à ń rí lójoojúmọ́ láti fi kọ́ni ní òótọ́ ọ̀rọ̀ tó jinlẹ̀ yani lẹ́nu púpọ̀. Àgbẹ̀ tó ń fúnrúgbìn, obìnrin tó ń múra àtiṣe búrẹ́dì, àwọn ọmọ tó ń ṣeré níbi ọjà, àwọn apẹja tó ń fa àwọ̀n sókè látinú omi, olùṣọ́ àgùntàn tó ń wá àgùntàn tó sọ nù, jẹ́ ohun táwọn olùgbọ́ rẹ̀ ti rí láìmọye ìgbà. Tá a bá sì ti fi nǹkan téèyàn mọ̀ dunjú ṣàlàyé òótọ́ ọ̀rọ̀ fúnni, kíá ló máa ń wọni lọ́kàn ṣinṣin, tá ò sì ní gbàgbé.—Mátíù 11:16-19; 13:3-8, 33, 47-50; 18:12-14.

11 Jésù sábà máa ń lo àkàwé, ìyẹn ìtàn kúkúrú tá a lè rí ẹ̀kọ́ ìwà rere tàbí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tẹ̀mí kọ́ nínú rẹ̀. Ìtàn máa ń tètè yéni, a kì í sì í gbàgbé rẹ̀ bí àwọn ọ̀rọ̀ gbẹrẹfu tí ò lákàwé. Ìdí nìyẹn tí àkàwé fi ń mú kí ẹ̀kọ́ Jésù má ṣeé gbàgbé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkàwé ni Jésù fi ṣàpèjúwe Baba rẹ̀ lọ́nà téèyàn á máa rántí títí. Bí àpẹẹrẹ, ta ni kókó inú àkàwé ọmọ onínàákúnàá ò ní yé, pé bí ẹni tó ṣáko lọ bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà á ṣàánú rẹ̀, á sì fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ gbà á padà?—Lúùkù 15:11-32.

12. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ń lo ìbéèrè tó bá ń kọ́ni? (b) Báwo ni Jésù ṣe pa àwọn tó ń bi í bóyá ó gbàṣẹ tàbí kò gbàṣẹ lẹ́nu mọ́?

12 Fífòye lo ìbéèrè. Jésù lo ìbéèrè láti mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ rójú ọ̀rọ̀ fúnra wọn, kí wọ́n ronú wọn wò, kí wọ́n wá ṣèpinnu. (Mátíù 12:24-30; 17:24-27; 22:41-46) Nígbà tí àwọn aṣáájú ìsìn ń bi Jésù ní ìbéèrè ní ti bóyá Ọlọ́run ló fún un láṣẹ tàbí òun kọ́, Jésù fèsì pé: “Ìbatisí láti ọwọ́ Jòhánù, ṣé láti ọ̀run ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?” Ìbéèrè yìí ṣe wọ́n ní kàyéfì, wọ́n wá ń sọ láàárín ara wọn pé: “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ yóò sọ fún wa pé, ‘Èé ṣe, nígbà náà, tí ẹ kò gbà á gbọ́?’ Ṣùgbọ́n, bí àwa bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ ẹ̀rù ogunlọ́gọ̀ yìí ń bà wá, nítorí gbogbo wọn ka Jòhánù sí wòlíì.” Níkẹyìn, wọ́n dáhùn pé: “Àwa kò mọ̀.” (Máàkù 11:27-33; Mátíù 21:23-27) Ìbéèrè tí Jésù béèrè wẹ́rẹ́ yìí mẹ́nu wọn wọhò, ó sì táṣìírí àdàkàdekè ọkàn wọn.

13-15. Báwo ni àkàwé ará Samáríà aládùúgbò rere ṣe fi ọgbọ́n Jésù hàn?

13 Nígbà mìíràn Jésù máa ń lo onírúurú ọ̀nà ìgbàkọ́ni pa pọ̀, bíi pé kó béèrè ìbéèrè tó gbàrònú láàárín àkàwé rẹ̀. Nígbà tí Júù amòfin kan bi Jésù nípa ohun tó yẹ ní ṣíṣe kí òun fi lè rí ìyè àìnípẹ̀kun, Jésù tọ́ka rẹ̀ sí Òfin Mósè tó pàṣẹ pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì rẹ̀. Amòfin yìí wá fẹ́ fi ara rẹ̀ hàn ní olódodo, ó béèrè pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Ni Jésù bá sọ ìtàn kan láti fi dáhùn ìbéèrè rẹ̀. Ó ní ọkùnrin Júù kan ń rìnrìn àjò lọ lóun nìkan làwọn ọlọ́ṣà bá kọ lù ú, wọ́n pa á lápaàpatán. Júù méjì bá a níbẹ̀. Àlùfáà lèyí àkọ́kọ́, ọmọ Léfì sì ni ìkejì. Àwọn méjèèjì ò yà sí tirẹ̀. Kò pẹ́ ni ará Samáríà kan débẹ̀. Bẹ́ẹ̀ làánú ṣe é, ló bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tọ́jú egbò ọ̀gbẹ́ni yẹn, ó sì fìfẹ́ gbé e lọ síbi ààbò nínú ilé èrò kan títí yóò fi sàn. Níparí ìtàn yẹn Jésù bi oníbèéèrè náà pé: “Ta ni nínú àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ó ṣe ara rẹ̀ ní aládùúgbò fún ọkùnrin tí ó bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà?” Èsì kan ṣoṣo tí amòfin yẹn lè sọ kò ju pé: “Ẹni tí ó hùwà sí i tàánú-tàánú.”—Lúùkù 10:25-37.

14 Ọ̀nà wo ni òwe yìí gbà gbé ọgbọ́n Jésù yọ? Nígbà ayé Jésù, àwọn tó bá ń pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ mọ́ nìkan làwọn Júù kà sí “aládùúgbò” wọn, wọn ò sì ka àwọn ará Samáríà kún irú àwọn bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 4:9) Ká ní ará Samáríà ni Jésù fi ṣe ẹni tó gbọgbẹ́ ni, pé Júù kan sì ràn án lọ́wọ́, ṣé ìyẹn á mú ẹ̀mí ẹ̀tanú àwọn Júù yìí kúrò? Jésù lo ọgbọ́n, ó sọ ìtàn yẹn lọ́nà tó fi jẹ́ pé ará Samáríà ló ṣàánú tó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tọ́jú Júù yẹn. Tún kíyè sí ìbéèrè tí Jésù béèrè lópin ìtàn yẹn. Jésù darí òye wọn nípa gbólóhùn náà, “aládùúgbò” sí ìhà mìíràn. Ohun tí amòfin náà ń béèrè ní ti gidi ni pé: ‘Ta ni kí n kà sí aládùúgbò mi tí máa fìfẹ́ hàn sí?’ Ṣùgbọ́n Jésù béèrè pé: “Ta ni nínú àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ó ṣe ara rẹ̀ ní aládùúgbò?” Kì í ṣe ẹni tá a ṣe lóore, ìyẹn ẹni tó gbọgbẹ́, ni Jésù pàfiyèsí sí bí kò ṣe ẹni tó ṣe oore, ìyẹn ará Samáríà náà. Ẹni tó jẹ́ aládùúgbò tòótọ́ máa ń lo ìdánúṣe láti fìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì rẹ̀ láìka ẹ̀yà tónítọ̀hún ti wá sí. Kódà, ọ̀nà tó múná dóko jù lọ láti gbà gbé kókó yìí yọ ni Jésù lò yìí.

15 Ọ̀nà dà tí háà ò fi ní máa ṣe àwọn èèyàn sí “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Jésù kí wọ́n sì máa fà mọ́ ọn? (Mátíù 7:28, 29) Nígbà kan pàápàá, “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan” ò tiẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jésù fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko, àní láìlóúnjẹ pàápàá!—Máàkù 8:1, 2.

Irú Ìgbésí Ayé Tó Gbé

16. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ‘fi ẹ̀rí hàn lọ́nà tó gbéṣẹ́’ pé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń darí òun?

16 Ọ̀nà kẹta tí Jésù ti gbé ọgbọ́n Jèhófà yọ ni ìgbésí ayé tó gbé. Ọgbọ́n gbéṣẹ́; ó sì wúlò. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù béèrè pé: “Ta ní jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú yín?” Ó wá dáhùn ìbéèrè yìí fúnra rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí ìwà rere rẹ̀ fi ẹ̀rí èyí hàn lọ́nà tó gbéṣẹ́.” (Jákọ́bù 3:13, The New English Bible) Ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà ‘fi ẹ̀rí hàn lọ́nà tó gbéṣẹ́’ pé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń darí rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe lo òye tó yè kooro nínú ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ àti ọ̀nà tó gbà bá àwọn èèyàn lò.

17. Kí làwọn nǹkan tó fi hàn pé Jésù wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì délẹ̀ nígbèésí ayé rẹ̀?

17 Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé àwọn èèyàn tí kì í lo òye sábà máa ń ṣe àṣejù? Ní tòdodo, ó gba ọgbọ́n kéèyàn tó lè wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Jésù gbé ọgbọ́n Ọlọ́run yọ, ní ti pé ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì délẹ̀ nínú ohun gbogbo. Èyí tó tayọ ni pé nǹkan tẹ̀mí ló gba iwájú nígbèésí ayé rẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ dí gidigidi lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Ó ní: “Fún ète yìí ni mo ṣe jáde lọ.” (Máàkù 1:38) Àwọn nǹkan ti ara kọ́ ló gba iwájú lọ́dọ̀ tirẹ̀; ó jọ pé kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan ti ara. (Mátíù 8:20) Àmọ́ kò gbé ìgbé ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́. Bíi ti Baba rẹ̀, tó jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀” náà ni Jésù ṣe jẹ́ aláyọ̀, ó sì tún fi ayọ̀ kún ayọ̀ àwọn èèyàn. (1 Tímótì 1:11; 6:15) Nígbà tó lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan, tí wọ́n sábà máa ń ṣe tìlù torin, tí ibẹ̀ á máa sọkutuyọ̀yọ̀, kò débẹ̀ lọ paná ayọ̀ ayẹyẹ ọ̀hún. Nígbà tí ọtí wáìnì tiẹ̀ tán, ṣe ló sọ omi di wáìnì tó jíire, èyí tó “ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀.” (Sáàmù 104:15; Jòhánù 2:1-11) Wọ́n pe Jésù síbi onírúurú àsè, ó sì lọ, ó tún máa ń lo irú àsìkò bẹ́ẹ̀ láti fi kọ́ni.—Lúùkù 10:38-42; 14:1-6.

18. Báwo ni Jésù ṣe lo òye tó jinlẹ̀ lọ́nà tó gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò?

18 Jésù lo òye tó jinlẹ̀ lọ́nà tó gbà bá àwọn èèyàn lò. Ìjìnlẹ̀ òye tó ní nípa ọmọ ènìyàn jẹ́ kó mọ ìwọ̀n òye àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dáadáa. Ó mọ̀ dáadáa pé aláìpé ni wọ́n. Síbẹ̀, ó fòye mọ ànímọ́ rere wọn. Ó mọ̀ pé àwọn tí Jèhófà pè yìí á gbé nǹkan ṣe tó bá yá. (Jòhánù 6:44) Pẹ̀lú gbogbo kùdìẹ̀-kudiẹ wọn, Jésù ṣé tán láti fọkàn tán wọn. Ó fi èyí hàn nígbà tó gbé ẹrù iṣẹ́ bàǹtà-banta lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́. Ó rán wọn láti lọ wàásù ìhìn rere, ó sì ní ìdánilójú pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ yẹn yọrí. (Mátíù 28:19, 20) Ìwé Ìṣe jẹ́rìí pé wọ́n mú iṣẹ́ yẹn ṣe lójú méjèèjì lóòótọ́. (Ìṣe 2:41, 42; 4:33; 5:27-32) Ìyẹn wá fi hàn pé ìwà ọlọ́gbọ́n ni Jésù hù bó ṣe gbẹ́kẹ̀ lé wọn.

19. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” lòun?

19 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ní Orí 20, Bíbélì so ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù pọ̀ mọ́ ọgbọ́n. Ó sì dájú pé, ní ti èyí, Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀. Jésù wá ńkọ́? Ó wúni lórí láti rí irú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ń hù sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Jésù ta wọ́n yọ jìnnà-jìnnà nítorí ẹni pípé lòun. Síbẹ̀ kò ka àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sí aláìjámọ́-nǹkankan. Kò gbìyànjú nígbàkigbà láti ṣe ohun tí wọ́n á fi rí i pé àṣé òpè aláìmọ̀kan lásánlàsàn làwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọ ibi tí agbára wọn mọ, ó sì ní sùúrù fún wọn. (Máàkù 14:34-38; Jòhánù 16:12) Àbí ẹ ò rí i pé nǹkan gidi ló jẹ́ pé ọkàn àwọn ọmọdé pàápàá máa ń balẹ̀ láti wà lọ́dọ̀ Jésù? Ó sì dájú pé ohun tó mú wọn fà mọ́ Jésù ni pé wọ́n rí i pé ó jẹ́ “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà.”—Mátíù 11:29; Máàkù 10:13-16.

20. Báwo ni Jésù ṣe lo ìfòyebánilò lọ́nà tó gbà hùwà sí obìnrin Kèfèrí tí ẹ̀mí èṣù gbé ọmọ rẹ̀ dè burúkú-burúkú?

20 Jésù ṣì tún gbé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Ọlọ́run yọ lọ́nà pàtàkì mìíràn. Ó ń fòye báni lò, tàbí pé ó ń yí ọwọ́ padà nígbà tí àánú bá yẹ. Àpẹẹrẹ kan rèé, rántí ìgbà tí obìnrin kan tó jẹ́ Kèfèrí bẹ Jésù pé kó wo ọmọ òun tí ẹ̀mí èṣù gbé dè burúkú-burúkú sàn. Ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù kọ́kọ́ gbà fi hàn pé òun ò ní bá a ṣe ohun tó ń fẹ́ yìí. Àkọ́kọ́, kò kọ́kọ́ dá a lóhùn; ìkejì, ó sọ fún un kedere pé àwọn Júù la rán òun sí kì í ṣe àwọn Kèfèrí; ẹ̀kẹta, ó sọ àpèjúwe kan láti tún fi tẹ kókó kan náà mọ́ ọn létí. Síbẹ̀ obìnrin yìí ò dẹ̀yìn. Èyí sì fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ bùáyà. Nígbà tí ọ̀ràn obìnrin yìí ti wá yàtọ̀ wàyí, kí ni Jésù ṣe? Ohun tó ti sọ pé òun ò ní ṣe yẹn gan-an ló padà ṣe o. Ó wo ọmọ obìnrin yẹn sàn. (Mátíù 15:21-28) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó ga lọ́lá nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Sì rántí o, ìrẹ̀lẹ̀ ni ìpìlẹ̀ ojúlówó ọgbọ́n.

21. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà, ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù?

21 A mà dúpẹ́ o, pé àwọn ìwé Ìhìn Rere fi ìwà àti ìṣe ẹni tó gbọ́n jù lọ nínú gbogbo èèyàn tó tíì gbé láyé rí hàn wá! Àmọ́, ẹ jẹ́ ká rántí o, pé ńṣe ni Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ lọ́nà pípé. Bí a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà, ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù, ọgbọ́n Ọlọ́run la fi ń kọ́ra yẹn. Ní orí tó tẹ̀ lé e a óò rí bá a ṣe lè mú ọgbọ́n Ọlọ́run lò nínú ìgbésí ayé wa.

^ ìpínrọ̀ 1 Láyé ìgbà tí a kọ Bíbélì, wọ́n máa ń gba àwọn káfíńtà láti bá wọn kọ́lé, láti bá wọn kan àwọn nǹkan bí àga, tábìlì, tàbí àwọn ohun èlò ìroko. Justin Martyr tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa kọ̀wé nípa Jésù pé: “Ó máa ń ṣe iṣẹ́ káfíńtà nígbà tó ń gbé láàárín àwọn èèyàn, tí yóò máa bá wọn ṣe ohun ìtúlẹ̀ àti àjàgà.”

^ ìpínrọ̀ 6 Ọ̀rọ̀ ìṣe inú èdè Gíríìkì tí a tú sí “ṣíṣàníyàn” túmọ̀ sí “láti ní ìpínyà ọkàn.” Ní ọ̀nà tá a gbà lò ó nínú Mátíù 6:25, ó túmọ̀ sí ìdààmú tó ń fa ìpínyà ọkàn àti àìbalẹ̀ ọkàn, tí kì í jẹ́ kéèyàn gbádùn ayé.

^ ìpínrọ̀ 7 Kódà ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fi hàn pé àpọ̀jù àníyàn ṣíṣe àti pákáǹleke lè múni lùgbàdì àrùn ọkàn-àyà àti òpó ẹ̀jẹ̀, àti onírúurú àìsàn mìíràn tó lè dá ẹ̀mí ẹni légbodò.