Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 23

“Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”

“Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”

1-3. Àwọn nǹkan wo ló mú kí ikú Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn àwa èèyàn?

 LỌ́JỌ́ kan nígbà ìrúwé, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn, wọ́n fẹ̀sùn èké kan ọkùnrin kan, wọ́n dájọ́ ikú fún un, kódà ṣe ni wọ́n dá a lóró títí tó fi kú. Ìyẹn kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa fẹ̀sùn èké kan àwọn èèyàn tí wọ́n á sì pa wọ́n nípa ìkà, ó sì bani nínú jẹ́ pé wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ ikú ọkùnrin yìí ṣàrà ọ̀tọ̀.

2 Bí ọkùnrin yẹn ṣe ń jẹ̀rora tó sì ń kú lọ, ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀run tó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ohun pàtàkì ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀sán gangan ni, ṣe ni òkùnkùn ṣàdédé ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà. Òpìtàn kan tó ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sọ pé, “oòrùn ò ràn.” (Lúùkù 23:44, 45) Àmọ́, ṣáájú kí ọkùnrin náà tó kú, ó sọ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé kan, ó ní: “A ti ṣe é parí!” Bẹ́ẹ̀ ni, ọkùnrin yẹn fi ẹ̀mí ara ẹ̀ rúbọ, èyí sì mú kó ṣe ohun àgbàyanu kan láṣeparí. Ohun tó ṣe yẹn ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an nínú ìtàn àwa èèyàn, ìyẹn sì ni ọ̀nà tó ga jù lọ téèyàn lè gbà fìfẹ́ hàn.​—Jòhánù 15:13; 19:30.

3 Jésù Kristi lọkùnrin tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí. Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe fìyà jẹ Jésù tí wọ́n sì pa á nípa ìkà lọ́jọ́ tá à ń sọ yìí, ìyẹn ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, ohun pàtàkì kan wà tọ́pọ̀ èèyàn ò mọ̀. Òótọ́ ni pé wọ́n fìyà jẹ Jésù gan-an lọ́jọ́ yẹn, síbẹ̀ ẹnì kan wà tó jẹ́ pé ohun tó mú mọ́ra ju ti Jésù lọ. Kódà, ohun kékeré kọ́ lẹni náà yááfì lọ́jọ́ yẹn. Ìfẹ́ tó ní sí wa ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀, kò sì sẹ́ni tó tún lè fìfẹ́ hàn sí wa lọ́nà tó ga jùyẹn lọ láyé àti lọ́run. Kí lẹni náà ṣe? Ìdáhùn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa èyí tó ṣe pàtàkì jù lára àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà, ìyẹn ìfẹ́.

Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ Tí Jèhófà Fi Hàn

4. Báwo ni ọ̀gágun Róòmù kan ṣe rí i pé Jésù kì í ṣe èèyàn lásán, kí ló sì sọ lẹ́yìn náà?

4 Nígbà tí ọ̀gágun Róòmù tó bójú tó bí wọ́n ṣe pa Jésù rí i tí òkùnkùn ṣú, tí ilẹ̀ sì mì tìtì lọ́nà tó lágbára, ẹnu yà á gan-an. Ó wá sọ pé: “Ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run nìyí.” (Mátíù 27:54) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí ọ̀gágun náà rí i pé Jésù kì í ṣe èèyàn lásán. Ó ṣeni láàánú pé ọkùnrin yìí ti bá wọn lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe pa Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run Gíga Jù Lọ! Àmọ́ o, báwo ni ìfẹ́ tó wà láàárín Ọmọ yẹn àti Bàbá ẹ̀ ṣe lágbára tó?

5. Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe iye ọdún tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ti jọ wà?

5 Bíbélì pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Èyí fi hàn pé Ọmọ Ọlọ́run ti wà kí ayé àtọ̀run tó wà. Báwo ni àkókò tí Ọmọ àti Bàbá ti jọ wà pa pọ̀ ṣe gùn tó? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan fojú bù ú pé á ti tó bílíọ̀nù mẹ́tàlá ọdún tí ayé àtọ̀run ti wà. Ṣé o mọ bí ọdún yẹn ṣe gùn tó? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ohun kan káwọn èèyàn lè lóye iye ọdún tí wọ́n sọ pé ayé àtọ̀run ti wà. Wọ́n ṣe ilé ńlá kan tí wọ́n fi ṣàfihàn bí àgbáálá ayé yìí ṣe rí, wọ́n wá fa ìlà kan tó gùn tó àádọ́fà (110) mítà sínú ilé náà. Wọ́n sọ pé táwọn tó wá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ bá dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlà náà, ẹsẹ̀ kan tí wọ́n bá gbé máa dúró fún nǹkan bíi mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin (75) ọdún. Lápá ìparí ìlà náà, wọ́n fa ìlà bíńtín kan tí kò gùn ju fọ́nrán irun kan ṣoṣo, wọ́n sì sọ pé ó dúró fún gbogbo iye ọdún téèyàn ti wà. Ìyẹn mà ga o! Àmọ́, ká tiẹ̀ sọ pé òótọ́ lohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ yìí, gbogbo ọdún yẹn ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ iye ọdún tí Ọmọ Ọlọ́run ti wà! Iṣẹ́ wo ló ń ṣe ní gbogbo àkókò yẹn?

6. (a) Iṣẹ́ wo ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣe lọ́run kó tó wá sí ayé? (b) Báwo ni ìfẹ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó?

6 Ńṣe ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30) Bíbélì sọ pé: “Láìsí [Ọmọ], kò sí nǹkan kan tó wà.” (Jòhánù 1:3) Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jọ ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan tó kù. Ó dájú pé inú wọn máa dùn gan-an bí wọ́n ṣe ṣiṣẹ́ pa pọ̀! Gbogbo wa la mọ̀ pé ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín òbí àtọmọ máa ń jinlẹ̀ gan-an. Ìfẹ́ sì jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Torí náà, ìfẹ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Jésù jinlẹ̀ gan-an torí àìmọye ọdún ni wọ́n ti jọ wà pa pọ̀. Ká sòótọ́, kò sí ìfẹ́ tó lágbára tó ìfẹ́ àárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.

7. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, kí ni Jèhófà sọ tó fi hàn pé inú ẹ̀ dùn sí i?

7 Síbẹ̀, Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé, kí wọ́n lè bí i bí ọmọ ọwọ́ tó jẹ́ èèyàn. Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Jésù ò fi sí lọ́dọ̀ Jèhófà lọ́run, ó sì dájú pé àárò ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n yìí máa sọ ọ́ gan-an. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà ń wo Jésù látọ̀run, tó sì ń kíyè sí i bó ṣe ń dàgbà di ọkùnrin pípé. Nǹkan bí ẹni ọgbọ̀n ọdún ni Jésù nígbà tó ṣèrìbọmi. Ó dájú pé inú Jèhófà dùn sí Ọmọ rẹ̀ yìí gan-an. Kódà, Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Gbogbo nǹkan tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa ṣe ló ṣe, ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ pé kó ṣe ló sì máa ń ṣe. Ó dájú pé Jésù múnú Jèhófà dùn gan-an!​—Jòhánù 5:36; 17:4.

8, 9. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jésù fara dà lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, báwo ló sì ṣe rí lára Baba rẹ̀? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ jìyà, kó sì kú?

8 Àmọ́, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ṣe rí lára Jèhófà? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n da Jésù, táwọn jàǹdùkú sì wá mú un lóru ọjọ́ yẹn? Ṣé o rò pé inú Jèhófà máa dùn nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Jésù sá lọ, táwọn èèyàn sì mú un lọ síbi tí wọ́n ti gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀ lọ́nà tí kò bófin mu? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí wọ́n ń fi Ọmọ ẹ̀ ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń tutọ́ sí i lára, tí wọ́n sì ń gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń na Ọmọ ẹ̀ lẹ́gba, tí ẹgba náà sì dá egbò sí i lẹ́yìn yánnayànna? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń fi ìṣó kan ọwọ́ àtẹsẹ̀ Ọmọ rẹ̀ mọ́ òpó igi, táwọn èèyàn sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ bó ṣe wà lórí igi oró? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ń jẹ̀rora, tó sì ké jáde pé kí Bàbá òun ran òun lọ́wọ́? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Jésù mí èémí ìkẹyìn, tó wá di pé fúngbà àkọ́kọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, Ọmọ Rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣaláìsí?​—Mátíù 26:14-16, 46, 47, 56, 59, 67; 27:38-44, 46; Jòhánù 19:1.

9 A ò lè sọ bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó ń wo ọmọ ẹ̀ báwọn èèyàn ṣe ń fìyà jẹ ẹ́, tí wọ́n sì pa á. Àmọ́, a mọ̀ pé ó ní láti ní ìdí pàtàkì kan tí Jèhófà fi gbà kí gbogbo nǹkan yẹn ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ẹ̀. Kí nìdí tí Jèhófà fi ní láti fara da gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó mú kóun fara dà á nínú Jòhánù 3:16. Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe pàtàkì gan-an débi táwọn kan fi sọ pé òun ló ṣàkópọ̀ Ìwé Ìhìn Rere. Ẹsẹ náà sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Èyí fi hàn pé ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà ṣe ohun tó ṣe yẹn. Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni Jèhófà fún wa bó ṣe rán Ọmọ ẹ̀ wá sáyé, kó lè jìyà, kó sì kú nítorí wa. Èyí ni ìfẹ́ tó ga jù lọ!

“Ọlọ́run . . . fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni”

Kí Ni Ìfẹ́ Túmọ̀ Sí?

10. Kí lohun táwa èèyàn nílò jù lọ, kí nìdí táwọn èèyàn ò fi lè ṣàlàyé ohun tí “ìfẹ́” jẹ́ gan-an?

10 Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” túmọ̀ sí? Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìfẹ́ lohun táwa èèyàn nílò jù lọ. Látìgbà tí wọ́n ti bí àwa èèyàn títí dọjọ́ ikú la máa ń fẹ́ kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí wa. Kódà, ó le débi pé tí wọn ò bá fìfẹ́ hàn sẹ́nì kan, ayé lè sú u kó sì kú. Àmọ́, pẹ̀lú bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó yìí, ó yani lẹ́nu pé èèyàn ò lè ṣàlàyé ohun tí ìfẹ́ jẹ́. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ ìfẹ́ kì í wọ́n lẹ́nu àwọn èèyàn. Àìmọye ìwé, orin àti ewì ni wọ́n ti kọ nípa ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò tíì lè sọ ohun tí ìfẹ́ jẹ́ gan-an. Kódà, bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” lóríṣiríṣi ọ̀nà ti mú kó túbọ̀ ṣòro fáwọn èèyàn láti mọ ohun tó túmọ̀ sí gan-an.

11, 12. (a) Ibo la ti lè rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nípa ìfẹ́, kí sì nìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? (b) Ọ̀rọ̀ mélòó ni wọ́n lò fún “ìfẹ́” nínú èdè Gíríìkì àtijọ́, ọ̀rọ̀ wo la sì lò jù fún “ìfẹ́” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (d) Tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà a·gaʹpe nínú Bíbélì, kí ló sábà máa ń túmọ̀ sí?

11 Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí ìfẹ́ jẹ́. Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: “Ohun tẹ́nì kan bá ṣe ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lóòótọ́.” Bíbélì jẹ́ ká mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣoore fáwa èèyàn, ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìfẹ́ tó ga jù lọ tó fi hàn nígbà tó yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ kó lè kú torí wa. Ká sòótọ́, kò sọ́nà míì téèyàn tún lè gbà fìfẹ́ hàn ju ohun tí Jèhófà ṣe yẹn! Nínú àwọn orí tó wà níwájú, a máa rí oríṣiríṣi ọ̀nà tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn. Bákan náà, a lè túbọ̀ mọ ohun tí ìfẹ́ jẹ́ tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “ìfẹ́” nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n lò fún “ìfẹ́” nínú èdè Gíríìkì àtijọ́. a Nínú ọ̀rọ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà, èyí tí wọ́n lò jù nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni a·gaʹpe. Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé a·gaʹpe ni “ọ̀rọ̀ tó lágbára jù lọ téèyàn lè lò fún ìfẹ́.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

12 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà a·gaʹpe sábà máa ń túmọ̀ sí ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà. Torí náà, kì í ṣe ìfẹ́ tá a ní sẹ́nì kan torí bí ọ̀rọ̀ ẹni yẹn ṣe rí lára wa. Ńṣe la máa ń dìídì fi irú ìfẹ́ yìí hàn sí gbogbo èèyàn, torí a mọ̀ pé ohun tó tọ́ nìyẹn. Ohun tó mú kí ìfẹ́ yìí wúni lórí jù ni pé, ẹni tó bá ń fi irú ìfẹ́ yìí hàn kì í ro tara ẹ̀ nìkan. Bí àpẹẹrẹ, tún wo Jòhánù 3:16 lẹ́ẹ̀kan sí i. “Ayé” wo ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ débi pé ó fún un ní Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo? Ọ̀rọ̀ náà “ayé” ń tọ́ka sí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ jàǹfààní ìràpadà Jésù. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn yìí ló jẹ́ pé ìgbé ayé wọn ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ṣé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ sí Jèhófà bíi ti Ábúráhámù olóòótọ́? (Jémíìsì 2:23) Rárá o, àmọ́ Jèhófà ń fìfẹ́ ṣoore fún gbogbo èèyàn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun ńlá ló ná an. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí pa dà. (2 Pétérù 3:9) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì ń fayọ̀ sọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

13, 14. Kí ló fi hàn pé a·gaʹpe jẹ́ ìfẹ́ tó tọkàn wá?

13 Àmọ́, èrò tí kò tọ́ làwọn kan ní lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa a·gaʹpe. Wọ́n rò pé kì í ṣe ìfẹ́ tó tọkàn wá, pé ìfẹ́ tó tutù ni. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, torí pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ni, ó sì máa ń tọkàn wá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jòhánù kọ̀wé pé, “Baba nífẹ̀ẹ́ Ọmọ,” ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ a·gaʹpe ló lò. Ṣé a lè sọ pé irú ìfẹ́ yìí ò jinlẹ̀? Ẹ kíyè sí i pé nígbà tí Jésù sọ pé, “Baba ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọmọ,” ọ̀rọ̀ tó lò jẹ mọ́ phi·leʹo. (Jòhánù 3:35; 5:20) Jèhófà máa ń fìfẹ́ hàn lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Àmọ́, kì í ṣe bọ́rọ̀ ẹnì kan ṣe rí lára Jèhófà nìkan ló máa ń pinnu bóyá ó máa fìfẹ́ hàn sẹ́ni yẹn. Ìlànà òdodo rẹ̀ tó bọ́gbọ́n mu ló máa ń lò láti ṣe bẹ́ẹ̀.

14 Bá a ṣe rí i, gbogbo ìwà àti ìṣe Jèhófà ló wúni lórí, tó sì fani mọ́ra. Àmọ́, ìfẹ́ ló fani mọ́ra jù nínú gbogbo wọn. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa lohun pàtàkì tó mú ká sún mọ́ ọn. Inú wa sì dùn pé ìfẹ́ ló gbawájú lára àwọn ànímọ́ rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”

15. Kí ni Bíbélì sọ nípa ànímọ́ Jèhófà náà ìfẹ́, tí kò sọ nípa àwọn ànímọ́ ẹ̀ tó kù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

15 Nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà mẹ́rin tó gbawájú, Bíbélì sọ nǹkan kan nípa ìfẹ́ tí kò sọ nípa àwọn mẹ́ta tó kù. Ìwé Mímọ́ kò sọ pé Ọlọ́run jẹ́ agbára tàbí pé Ọlọ́run jẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ọgbọ́n. Ó àwọn ànímọ́ yẹn ni, òun ni Orísun wọn, ọ̀nà tó sì ń gbà lò wọ́n ló dáa jù. Àmọ́, Bíbélì sọ ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ànímọ́ kẹrin. Ó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” b (1 Jòhánù 4:8) Kí lọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?

16-18. (a) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́”? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu pé èèyàn ni Jèhófà fi ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́?

16 Nígbà tí Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run àti ìfẹ́ dọ́gba. Ó ṣe tán, a ò lè yí ọ̀rọ̀ yẹn pa dà ká wá sọ pé “ìfẹ́ jẹ́ Ọlọ́run.” Jèhófà kọjá ẹni tá a lè fi wé ìwà àti ìṣe lásánlàsàn. Ọlọ́run wà lóòótọ́, ó máa ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára, ó sì ní oríṣiríṣi ànímọ́ míì láfikún sí ìfẹ́. Àmọ́, ìfẹ́ làkọ́kọ́ lára ìwà àti ìṣe Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì fi sọ nípa ẹsẹ yìí pé: “Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń ṣe ló ń fi ìfẹ́ hàn.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Òótọ́ ni pé agbára tí Jèhófà ní ló fi máa ń ṣe nǹkan, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ ló sì máa ń darí ẹ̀ tó bá ń ṣe nǹkan náà. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló máa ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Ìfẹ́ rẹ̀ sì máa ń hàn nínú bó ṣe ń lo àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù.

17 A sábà máa ń sọ pé Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá di pé ká fìfẹ́ hàn. Torí náà, ọ̀nà tó dáa jù téèyàn lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ ni pé kó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àwa èèyàn náà máa ń fìfẹ́ hàn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ kíyè sóhun tí Jèhófà sọ fún Ọmọ rẹ̀ nígbà tó fẹ́ dá àwa èèyàn, ó sọ pé: “Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa, kí wọ́n jọ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá sí ayé, àwa èèyàn nìkan la lè pinnu pé a máa fìfẹ́ hàn, ìyẹn ló sì jẹ́ ká fìwà jọ Baba wa ọ̀run. Jèhófà fi onírúurú ohun alààyè ṣàpẹẹrẹ àwọn ìwà àti ìṣe pàtàkì tó ní. Àmọ́, Jèhófà lo àwa èèyàn, tó jẹ́ èyí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lára àwọn ohun tó dá sáyé, láti ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́, tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù.​—Ìsíkíẹ́lì 1:10.

18 Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn tá ò sì mọ tara wa nìkan, ńṣe là ń gbé ìfẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lára ànímọ́ Jèhófà yọ. Bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ó ní: “A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Àmọ́, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa?

Jèhófà Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa

19. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà dá àwọn nǹkan?

19 Ọjọ́ pẹ́ tí ìfẹ́ ti wà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Rò ó wò ná, kí lo rò pé ó mú kí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan? Ṣé torí pé ó dá nìkan wà ni, àbí torí pé ó ń wá ẹni tí wọ́n á jọ máa ṣe nǹkan? Rárá o! Jèhófà pé pérépéré, láìkù síbì kan, kò sì nílò olùrànlọ́wọ́ kankan. Àmọ́ torí pé ó ní ìfẹ́, ó dá àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn ká lè máa gbádùn àwọn nǹkan tó dá, ká sì máa láyọ̀. Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ni “ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.” (Ìfihàn 3:14) Lẹ́yìn ìyẹn, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí di Àgbà Òṣìṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, Jèhófà sì lò ó láti dá gbogbo nǹkan tó kù, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 38:4, 7; Kólósè 1:16) Jèhófà fún àwọn áńgẹ́lì yìí ní òmìnira, làákàyè àti ìmọ̀lára, èyí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti mú ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn. Àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, wọ́n máa ń di ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 3:17) Torí náà, a lè sọ pé àwọn áńgẹ́lì yìí nífẹ̀ẹ́ torí pé Jèhófà ti kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wọn.

20, 21. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Ádámù àti Éfà, àmọ́ kí ni wọ́n ṣe?

20 Bọ́rọ̀ àwa náà ṣe rí nìyẹn. Àtìgbà tí Jèhófà ti dá Ádámù àti Éfà ló ti ń fìfẹ́ hàn sí wọn lónírúurú ọ̀nà. Gbogbo ibi tí wọ́n bá yíjú sí nínú Párádísè ni wọ́n ti ń rí ẹ̀rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wá gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì, ní apá ìlà oòrùn; ó sì fi ọkùnrin tó dá síbẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8) Ṣé o ti wọnú ọgbà kan tó rẹwà gan-an rí? Kí lo fẹ́ràn jù nínú ọgbà náà? Ṣé ìmọ́lẹ̀ tó ń yọ láàárín àwọn ewé tó wà lórí igi ni? Ṣé àwọn òdòdó tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ rírẹwà ni? Ṣé ìró omi tó ń dún bó ṣe ń ṣàn lọ àti orin àwọn ẹyẹ àtàwọn kòkòrò tó ń kùn ni? Àbí òórùn dídùn tó ń jáde láti ara àwọn igi, èso àti òdòdó lo fẹ́ràn jù? Ká sòótọ́ àwọn ọgbà máa ń rẹwà gan-an, àmọ́ kò sí ọgbà kankan lónìí tó rẹwà tó ọgbà Édẹ́nì. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

21 Ìdí ni pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló gbin ọgbà náà! Ó dájú pé ó máa rẹwà kọjá sísọ. Oríṣiríṣi igi tó rẹwà àtàwọn èso tó dùn gan-an ló wà níbẹ̀. Ọgbà náà tóbi, àwọn odò tó ń sàn wà níbẹ̀, oríṣiríṣi ẹranko tó fani mọ́ra ló sì wà níbẹ̀. Ádámù àti Éfà ní gbogbo nǹkan tó lè mú kí ayé wọn dùn, títí kan iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀. Wọ́n sì tún láyọ̀ bí wọ́n ṣe wà pa pọ̀. Jèhófà ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì yẹ káwọn náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Dípò kí wọ́n ṣègbọràn sí Baba wọn ọ̀run torí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ńṣe ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i torí pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì, orí 2.

22. Báwo lohun tí Jèhófà ṣe lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ ṣe fi hàn pé ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀?

22 Ó dájú pé ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe máa dun Jèhófà gan-an! Àmọ́, ṣéyẹn wá mú kí Jèhófà kórìíra àwọn èèyàn? Rárá o! Rántí pé “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.” (Sáàmù 136:1) Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà fìfẹ́ ṣètò ìràpadà fún àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà tó bá jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, tó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bá a ṣe sọ ṣáájú, ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà ṣe láti gba àwa èèyàn là ni bó ṣe fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣe ẹbọ ìràpadà fún wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—1 Jòhánù 4:10.

23. Kí ni ọ̀kan lára ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ìbéèrè pàtàkì wo la máa dáhùn nínú orí tó kàn?

23 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà ti ń ṣe ohun tó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì ti ṣe tó fi hàn pé “òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká láyọ̀ ká sì wà níṣọ̀kan. Abájọ tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Àmọ́, o lè máa rò ó pé, ‘Ṣé Jèhófà tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi?’ A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú orí tó kàn.

a Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà phi·leʹo láti ṣàpèjúwe ìfẹ́ tó wà láàárín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí ọmọ ìyá, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n lo ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ọ̀rọ̀ náà stor·geʹ túmọ̀ sí ìfẹ́ tẹ́nì kan ní sáwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìdílé. Ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n lò ní 2 Tímótì 3:3, ẹsẹ náà sì sọ pé irú ìfẹ́ yìí máa ṣọ̀wọ́n láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ọ̀rọ̀ náà Eʹros túmọ̀ sí ìfẹ́ tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Wọn ò lo ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa irú ìfẹ́ yẹn.​—Òwe 5:15-20.

b Àwọn gbólóhùn míì nínú Ìwé Mímọ́ fara jọ èyí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀” àti pé “Ọlọ́run . . . jẹ́ iná tó ń jóni run.” (1 Jòhánù 1:5; Hébérù 12:29) Àmọ́, ó ṣe kedere pé ńṣe ni Bíbélì kàn ń fi Jèhófà wé àwọn nǹkan yẹn. Jèhófà dà bí ìmọ́lẹ̀, torí pé ó jẹ́ mímọ́ àti adúróṣinṣin. Kò sí “òkùnkùn,” ìyẹn àìmọ́, nínú rẹ̀ rárá. A sì tún lè fi Jèhófà wé iná torí bó ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti fi pa nǹkan run.