Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí 25

“Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run Wa”

“Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run Wa”

1, 2. (a) Kí ni ìyá sábà máa ń ṣe nígbà tí ọmọ rẹ̀ jòjòló bá ń ké? (b) Ìyọ́nú wo ló tún jinlẹ̀ ju ìyọ́nú tí ìyá ní?

ỌMỌ jòjòló kan bẹ̀rẹ̀ sí ké lọ́gànjọ́ òru. Kíá ni ìyá rẹ̀ jí. Kì í kúkú sùn wọra mọ́ látìgbà tó ti bímọ yìí. Kí ọmọ rẹ̀ máà tíì ké ni, á ti mọ ohun tó ń ṣe é. Ó máa ń mọ̀ bóyá oúnjẹ lọmọ tuntun náà ń fẹ́, tàbí kí wọ́n gbé òun mọ́ra ni, tàbí kí wọ́n sáà tọ́jú òun. Àmọ́ ohun yòówù kí ó fa ẹkún ọmọ náà, ìyá rẹ̀ ò ní ṣàì dá a lóhùn. Ojú rẹ̀ ò ní gbà á.

2 Ìyọ́nú tí ìyá ń ní fún ọmọ inú rẹ̀ wà lára ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó jinlẹ̀ jù lọ tí ẹ̀dá ènìyàn ní. Àmọ́, ìyọ́nú kan wà tó tún jinlẹ̀ ju èyí lọ fíìfíì. Èyíinì ni ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Jèhófà, Ọlọ́run wa. Gbígbé ànímọ́ fífanimọ́ra yìí yẹ̀ wò lè jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Fún ìdí yìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí ìyọ́nú jẹ́, ká sì wo bí Ọlọ́run wa ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn.

Kí Ni Ìyọ́nú?

3. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù tá a túmọ̀ sí “fi àánú hàn sí” tàbí “ṣe ojú àánú sí”?

3 Nínú Bíbélì, ìyọ́nú àti àánú kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Àwọn ọ̀rọ̀ mélòó kan ni wọ́n ń lò lédè Hébérù àti Gíríìkì láti fi ṣàlàyé ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ Hébérù náà ra·chamʹ, tá a sábà máa ń túmọ̀ sí “fi àánú hàn sí” tàbí “ṣe ojú àánú sí.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ ìṣe náà ra·chamʹ “ni à ń lò fún ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, tó wá láti ìsàlẹ̀ ikùn, irú èyí tá a máa ń fi hàn nígbà tá a bá rí ipò àìlera tàbí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn wa ọ̀wọ́n tàbí àwọn tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ wa.” Ọ̀rọ̀ Hébérù yìí, tí Jèhófà lò fún ara rẹ̀, tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ilé ọlẹ̀.” A sì tún lè pè é ní “ìyọ́nú tí ìyá ní.” *Ẹ́kísódù 33:19; Jeremáyà 33:26.

“Obirin ha lè gbagbe . . . ọmọ inu rẹ̀??”

4, 5. Báwo ni Bíbélì ṣe lo ìyọ́nú tí ìyá máa ń ní sí ọmọ rẹ̀ jòjòló láti fi jẹ́ ká lóye ìyọ́nú Jèhófà?

4 Bíbélì lo ìyọ́nú tí ìyá máa ń ní fún ọmọ rẹ̀ jòjòló láti fi jẹ́ ká lóye ìyọ́nú Jèhófà. Aísáyà 49:15 kà pé: “Obirin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu [ra·chamʹ] si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ.” (Bibeli Mimọ) Àpèjúwe tó wọni lọ́kàn ṣinṣin yẹn jẹ́ ká rí bí ìyọ́nú tí Jèhófà ní fáwọn èèyàn rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Lọ́nà wo?

5 Kò ṣeé gbọ́ sétí pé abiyamọ kan sọ pé òun gbàgbé àtifún ọmọ òun lóúnjẹ àti ìtọ́jú. Ó ṣe tán, ìkókó kò lè dá nǹkan kan ṣe; tọ̀sántòru ni ọmọ ọwọ́ ń fẹ́ ìtọ́jú àti ìfẹ́ ìyá rẹ̀. Ó kàn ṣeni láàánú ni, pé àwọn ìyá kan ti ń pa ọmọ inú wọn tì, àgàgà ní “àwọn àkókò lílekoko” yìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní “ìfẹ́ni àdánidá” mọ́. (2 Tímótì 3:1, 3) Àmọ́ Jèhófà sọ pé, “ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ.” Ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà ní fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀. Ó jinlẹ̀ gidigidi ju ìkẹ́ àti ìgẹ̀ tó jinlẹ̀ jù lọ lọ́kàn wa, ìyẹn ìyọ́nú tí abiyamọ máa ń ní sí ọmọ rẹ̀ jòjòló. Abájọ tí alálàyé kan fi sọ nípa Aísáyà 49:15 pé: “Èyí ni ọ̀kan lára gbólóhùn tó tẹ̀wọ̀n jù lọ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn bí gbólóhùn mìíràn bá wà tó tẹ̀wọ̀n tó o nínú Májẹ̀mú Láéláé.”

6. Ojú wo ni ọ̀pọ̀ ẹ̀dá aláìpé fi ń wo ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, àmọ́ ìdánilójú wo ni Jèhófà fún wa?

6 Ṣé àmì àìlera ni ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ jẹ́ ni? Ọ̀pọ̀ ẹ̀dá aláìpé ló rò bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Seneca, onímọ̀ ọgbọ́n orí ará Róòmù nì, tó gbé ayé nígbà tí Jésù wà láyé, tó tún jẹ́ àgbà amòye ní Róòmù, kọ́ni pé “ojú àánú jẹ́ àìlera inú ọkàn.” Seneca jẹ́ alágbàwí ẹ̀kọ́ Sítọ́ìkì, ẹ̀kọ́ tó sọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ máa fi bí nǹkan bá ṣe rí lára rẹ̀ hàn. Seneca sọ pé ọlọgbọ́n lè ṣèrànwọ́ fẹ́ni tó wà nínú wàhálà, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí káàánú, torí pé tó bá bẹ̀rẹ̀ sí káàánú kò ní lè sinmẹ̀dọ̀ mọ́. Èrò máà-kó-tìẹ-bá-mi yẹn kò fàyè gba ìyọ́nú àtọkànwá. Ṣùgbọ́n Jèhófà kì í ṣe irú ẹni bẹ́ẹ̀ rárá! Jèhófà mú un dá wa lójú nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun “jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, [òun] sì jẹ́ aláàánú [tí ìtumọ̀ rẹ̀ ní ṣáńgílítí jẹ́, “oníyọ̀ọ́nú”].” (Jákọ́bù 5:11) Gẹ́gẹ́ bí a ó ti rí i, ìyọ́nú kì í ṣe àìlera bí kò ṣe ànímọ́ alágbára, tó ṣe kókó. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn, bí òbí onífẹ̀ẹ́.

Nígbà Tí Jèhófà Yọ́nú sí Orílẹ̀-Èdè Kan

7, 8. Ìyà wo ló jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Íjíbítì ìgbàanì, kí sì ni Jèhófà ṣe nípa ìyà tó ń jẹ wọ́n?

7 Ìyọ́nú Jèhófà hàn kedere nínú ọwọ́ tó fi mú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Nígbà tó fi máa di apá ìparí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lóko ẹrú ní Íjíbítì ìgbàanì, níbi tí wọ́n ti ń fìyà pá wọn lórí. Àwọn ará Íjíbítì “ń mú ìgbésí ayé korò fún wọn nípa ìsìnrú nínira nídìí àpòrọ́ tí a fi amọ̀ ṣe àti bíríkì.” (Ẹ́kísódù 1:11, 14) Nígbà tí ìyà ọ̀hún wá pọ̀ jù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Kí ni Ọlọ́run oníyọ̀ọ́nú ṣe?

8 Àánú ṣe Jèhófà. Ó sọ pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.” (Ẹ́kísódù 3:7) Jèhófà kò lè rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ tàbí kí ó gbọ́ igbe ẹkún wọn láìmọ̀ ọ́n lára. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i ní Orí 24 ìwé yìí, Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Gẹ́gẹ́ bí a sì ti mọ̀, ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ni mímọ ẹdùn ọkàn àwọn ẹlòmíràn lára, tí í ṣe ànímọ́ tó tan mọ́ ìyọ́nú. Àmọ́ kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe pé Jèhófà mọ ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ lára nìkan ni; ó gbé ìgbésẹ̀ fún ire wọn. Aísáyà 63:9 sọ pé: “Nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti nínú ìyọ́nú rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ tún wọn rà.” Jèhófà wá fi “ọwọ́ líle” dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì. (Diutarónómì 4:34) Lẹ́yìn ìyẹn ló pèsè oúnjẹ fún wọn lọ́nà ìyanu, tó sì mú wọn dé ilẹ̀ wọn ọlọ́ràá.

9, 10. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi dá Ísírẹ́lì nídè léraléra lẹ́yìn tí wọ́n tẹ̀ dó sí Ilẹ̀ Ìlérí? (b) Nígbà ayé Jẹ́fútà, inú wàhálà wo ni Jèhófà ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ló sì sún un gbà wọ́n?

9 Jèhófà kò fi ìyọ́nú rẹ̀ mọ síbẹ̀ o. Nígbà tí Ísírẹ́lì tẹ̀ dó sí Ilẹ̀ Ìlérí tán, léraléra ni wọ́n ń hùwà àìṣòótọ́. Ìyà sì ń jẹ wọ́n nítorí èyí. Àmọ́ tó bá tún ṣe sàà, orí àwọn èèyàn náà á pé wálé, wọ́n á sì tún ké pe Jèhófà. Léraléra ló ń dá wọn nídè. Èé ṣe? “Nítorí pé ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀.”—2 Kíróníkà 36:15; Àwọn Onídàájọ́ 2:11-16.

10 Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jẹ́fútà yẹ̀ wò. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀rìṣà, Jèhófà jẹ́ kí àwọn ọmọ Ámónì ṣe wọ́n bọ́ṣẹ ṣe ń ṣojú fún ọdún méjìdínlógún. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pìwà dà. Bíbélì sọ fún wa pé: “Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè kúrò ní àárín wọn, wọ́n sì ń sin Jèhófà, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ kò fi lélẹ̀ nítorí ìdààmú Ísírẹ́lì.” * (Àwọn Onídàájọ́ 10:6-16) Gbàrà táwọn èèyàn Jèhófà fi hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà látọkànwá, ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́ kí ìyà ṣì máa jẹ wọ́n. Nítorí náà, Ọlọ́run oníyọ̀ọ́nú fún Jẹ́fútà lágbára láti gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.—Àwọn Onídàájọ́ 11:30-33.

11. Kí ni ọwọ́ tí Jèhófà fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ wa nípa ìyọ́nú?

11 Kí ni ọwọ́ tí Jèhófà fi mú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kọ́ wa nípa ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́? Ẹ̀kọ́ kan tá a rí kọ́ ni pé ìyọ́nú Jèhófà kò mọ sórí wíwulẹ̀ ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn lásán nítorí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn. Rántí àpẹẹrẹ ìyá tí ìyọ́nú rẹ̀ sún un láti tọ́jú ọmọ rẹ̀ tó ń ké. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà kì í ṣàìbìkítà nípa igbe àwọn èèyàn rẹ̀. Ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ máa ń sún un láti gbà wọ́n lọ́wọ́ ìyà. Ẹ̀kọ́ mìíràn ni pé, ọwọ́ tí Jèhófà fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká mọ̀ pé ìyọ́nú kì í ṣe àìlera rárá, nítorí pé ànímọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ yìí ló sún un láti gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára, tó jẹ́ ti akíkanjú, fún ire àwọn èèyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lápapọ̀ nìkan ni Jèhófà ń fi ìyọ́nú hàn sí ni?

Ìyọ́nú Jèhófà fún Olúkúlùkù Èèyàn

12. Báwo ni Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé Jèhófà ní ìyọ́nú fún olúkúlùkù ènìyàn?

12 Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi hàn pé ó ní ìyọ́nú fún olúkúlùkù èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí bó ṣe ń ṣàníyàn nípa àwọn òtòṣì. Jèhófà mọ̀ pé àwọn ipò àìròtẹ́lẹ̀ lè yọjú, tó lè mú kí ọmọ Ísírẹ́lì kan di tálákà. Ọwọ́ wo ló yẹ kí wọ́n fi mú àwọn òtòṣì? Jèhófà pa á láṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sé ọkàn-àyà rẹ le tàbí kí ó háwọ́ sí arákùnrin rẹ tí ó jẹ́ òtòṣì. Kí o fi fún un lọ́nàkọnà, kí ọkàn-àyà rẹ má sì ṣahun nínú fífi fún un, nítorí pé ní tìtorí èyí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò ṣe bù kún ọ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ.” (Diutarónómì 15:7, 10) Jèhófà sì tún pa á láṣẹ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì má ṣe kórè eteetí oko wọn tán. Bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe ṣa irè oko tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀ rárá. Irú èéṣẹ́ bẹ́ẹ̀ wà fáwọn aláìní. (Léfítíkù 23:22; Rúùtù 2:2-7) Nígbà tí orílẹ̀-èdè náà tẹ̀ lé òfin tó gba tàwọn òtòṣì àárín wọn rò yìí, àwọn aláìní ní Ísírẹ́lì kò di atọrọjẹ. Èyí kì í ha á ṣe ẹ̀rí pé Jèhófà jẹ́ oníyọ̀ọ́nú?

13, 14. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ Dáfídì ṣe mú un dá wa lójú pé Jèhófà kò fi ọ̀ràn kálukú wa ṣeré rárá? (b) Àpèjúwe wo la lè mú wá láti fi hàn pé Jèhófà wà nítòsí àwọn ‘oníròbìnújẹ́ ọkàn’ tàbí ‘àwọn tí ẹ̀mí wọ́n wó palẹ̀’?

13 Lónìí pẹ̀lú, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ kò fi ọ̀ràn kálukú wa ṣeré rárá. Dájúdájú, ó ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ wá. Dáfídì onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́. Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:15, 18) Ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ alálàyé Bíbélì sọ nípa àwọn tí ibí yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Oníròbìnújẹ́ àti aláròdùn ni wọ́n, ìyẹn àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ ti kó ìrònú bá, tí wọn ò sì ka ara wọn séèyàn gidi mọ́; wọn ò níyì lójú ara wọn, wọn ò sì ní láárí lójú ara wọn mọ́.” Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè gbà pé Jèhófà jìnnà réré sí àwọn, àti pé kò lè rójú ráyè tàwọn, níwọ̀n bí wọn ò ti já mọ́ nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọ̀rọ̀ Dáfídì mú un dá wa lójú pé Jèhófà kò jẹ́ pa “àwọn tí kò níyì lójú ara wọn” tì. Ọlọ́run wa oníyọ̀ọ́nú mọ̀ pé ìgbà tá a bá wà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ la nílò òun ju ti ìgbàkígbà rí lọ, kò sì ní jìnnà sí wa.

14 Ẹ jẹ́ ká gbé ìrírí kan yẹ̀ wò. Ìyá kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sáré gbé ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ọdún méjì lọ sílé ìwòsàn, nítorí pé akọ èfù ń ṣe é. Lẹ́yìn táwọn dókítà yẹ ọmọ náà wò, wọ́n sọ fún ìyá rẹ̀ pé àwọn á dá ọmọ náà dúró sílé ìwòsàn dọjọ́ kejì. Ibo ni ìyá ọmọ náà wà mọ́jú? Orí àga inú ilé ìwòsàn lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì ọmọ rẹ̀ ni o! Nítorí pé ara ọmọ rẹ̀ kékeré ò yá, kò lè fi í sílẹ̀. Dájúdájú, a lè retí pé kí Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ! Ó ṣe tán, àwòrán rẹ̀ ló dá wa. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:18 tó wọni lọ́kàn ṣinṣin jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí a bá jẹ́ ‘oníròbìnújẹ́ ọkàn’ tàbí tí ‘ẹ̀mí wa wó palẹ̀,’ Jèhófà “wà nítòsí” gẹ́gẹ́ bí òbí onífẹ̀ẹ́, gẹ́gẹ́ bí oníyọ̀ọ́nú, ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣèrànwọ́.

15. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ran olúkúlùkù wa lọ́wọ́?

15 Báwo wá ni Jèhófà ṣe ń ran olúkúlùkù wa lọ́wọ́? Kì í ṣe ìgbà gbogbo ló máa ń mú ohun tó ń fa ìjìyà wa kúrò. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti ṣètò ohun púpọ̀ fáwọn tó ń ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń fún wa ní ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó lè ṣèrànwọ́. Nínú ìjọ, Jèhófà fún wa ní àwọn alábòójútó tó tóótun nípa tẹ̀mí, tí ń sapá láti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú bíi tirẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ran àwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́. (Jákọ́bù 5:14, 15) Gẹ́gẹ́ bí “Olùgbọ́ àdúrà,” ó ń “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 65:2; Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí yẹn lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ká lè fara dà á dìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìṣòro tí ń kó ìdààmú báni kúrò. (2 Kọ́ríńtì 4:7) A kò ha mọrírì gbogbo ìpèsè wọ̀nyí bí? Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé ìwọ̀nyí jẹ́ ara ẹ̀rí ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Jèhófà.

16. Kí ni àpẹẹrẹ ìyọ́nú Jèhófà tó ga jù lọ, báwo ló sì ṣe kan olúkúlùkù wa?

16 Àmọ́ o, àpẹẹrẹ aláìlẹ́gbẹ́ nípa ìyọ́nú Jèhófà ni fífi tó fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n fún wa láti rà wá padà. Ìfẹ́ ló sún Jèhófà láti fún wa ní ẹ̀bùn bàǹtàbanta yìí, tó ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wa. Rántí pé olúkúlùkù wa ni ẹ̀bùn ìràpadà wà fún. Abájọ tí Sekaráyà, bàbá Jòhánù Olùbatisí fi sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹ̀bùn yìí jẹ́ ẹ̀rí “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run wa.”—Lúùkù 1:78.

Nígbà Tí Jèhófà Bá Fawọ́ Ìyọ́nú Rẹ̀ Sẹ́yìn

17-19. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé ìyọ́nú Jèhófà láàlà? (b) Kí ló fà á tí ìyọ́nú Jèhófà sáwọn èèyàn rẹ̀ fi dópin?

17 Ṣé ohun tí à ń sọ ni pé ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Jèhófà kò láàlà? Ó tì o, Bíbélì fi hàn kedere pé Jèhófà máa ń fawọ́ ìyọ́nú rẹ̀ sẹ́yìn fáwọn tó bá ń tàpá sí ọ̀nà òdodo rẹ̀. (Hébérù 10:28) Láti rí ìdí tó fi ń gbé ìgbésẹ̀ yẹn, gbé àpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yẹ̀ wò.

18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé léraléra ni Jèhófà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ọ̀tá, ìyọ́nú rẹ̀ dópin nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Àwọn olóríkunkun wọ̀nyẹn ń bọ̀rìṣà, àní wọ́n tilẹ̀ ń gbé àwọn òrìṣà wọn tí ń kóni nírìíra wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà! (Ìsíkíẹ́lì 5:11; 8:17, 18) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Wọ́n ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà, títí ìhónú Jèhófà fi jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.” (2 Kíróníkà 36:16) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá a débi tó fi wá di pé wọn ò yẹ ní ẹni tí à ń fi ìyọ́nú hàn sí mọ́, ìbínú Jèhófà wá ru sí wọn lọ́nà tó tọ́. Kí ni ìyọrísí rẹ̀?

19 Jèhófà ò wá yọ́nú sáwọn èèyàn rẹ̀ mọ́. Ó kéde pé: “Èmi kì yóò fi ìyọ́nú hàn, tàbí kí n káàánú, èmi kì yóò sì ní àánú tí kì yóò jẹ́ kí n run wọ́n.” (Jeremáyà 13:14) Ìdí nìyẹn tí Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ fi pa run, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Ẹ ò rí i pé ó báni nínú jẹ́ gan-an pé ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè bá ìwà ọ̀tẹ̀ wọn débi tí Ọlọ́run yóò ti fawọ́ ìyọ́nú rẹ̀ sẹ́yìn!—Ìdárò 2:21.

20, 21. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìyọ́nú Ọlọ́run bá dópin lọ́jọ́ tiwa? (b) Ẹ̀bùn oníyọ̀ọ́nú wo látọ̀dọ̀ Jèhófà ni a óò ṣàlàyé rẹ̀ ní àkòrí tó tẹ̀ lé e?

20 Lónìí ńkọ́? Jèhófà kò yí padà o. Nínú ìyọ́nú rẹ̀, ó ti rán àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ pé kí wọ́n máa “wàásù ìhìn rere ìjọba” náà ní gbogbo apá ilẹ̀ ayé tí à ń gbé. (Mátíù 24:14) Nígbà táwọn èèyàn tó ní ọkàn títọ́ bá tẹ́tí sílẹ̀, Jèhófà máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ìhìn rere Ìjọba náà. (Ìṣe 16:14) Àmọ́ iṣẹ́ yìí kò ní máa bá a lọ títí láé. Kò ní fi hàn pé Jèhófà ní ìyọ́nú, bó bá jẹ́ kí ayé búburú yìí, pẹ̀lú gbogbo wàhálà àti ìyà inú rẹ̀, máa bá a lọ títí lọ gbére. Nígbà tí ìyọ́nú Jèhófà bá dópin, yóò mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ètò àwọn nǹkan yìí. Nígbà yẹn pàápàá, ìyọ́nú ló máa sún un gbé ìgbésẹ̀, ìyẹn ìyọ́nú fún “orúkọ mímọ́” rẹ̀ àti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùfọkànsìn. (Ìsíkíẹ́lì 36:20-23) Jèhófà yóò mú ìwà ibi kúrò pátápátá, yóò sì mú ayé tuntun òdodo wá. Ohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn olubi ni pé: “Ojú mi kì yóò káàánú, èmi kì yóò sì fi ìyọ́nú hàn. Dájúdájú, èmi yóò mú ọ̀nà wọn wá sórí wọn.”—Ìsíkíẹ́lì 9:10.

21 Kó tó dìgbà yẹn, Jèhófà ń fi ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn, kódà sáwọn tí ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé lórí. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà tọkàntọkàn lè jàǹfààní nínú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn oníyọ̀ọ́nú jù lọ tí Jèhófà ń fi fúnni, ìyẹn ni ìdáríjì. Ní àkòrí tó tẹ̀ lé, a óò jíròrò àwọn àpèjúwe àtàtà látinú Bíbélì tó ń fi hàn pé ńṣe ni Jèhófà máa ń dárí jini pátápátá láìní fọ̀rọ̀ ẹni sínú mọ́.

^ ìpínrọ̀ 3 Àmọ́, ó yẹ fún àfiyèsí pé ní Sáàmù 103:13, ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà ra·chamʹ tọ́ka sí irú àánú, tàbí ìyọ́nú, tí bàbá ń fi hàn sáwọn ọmọ rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 10 Gbólóhùn náà ‘ọkàn rẹ̀ kò lélẹ̀’ ní ṣáńgílítí túmọ̀ sí “ọkàn rẹ̀ ò gbà á; sùúrù rẹ̀ dópin.” Bí The New English Bible ṣe túmọ̀ rẹ̀ ni pé: “Ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́ kí ìyà máa jẹ Ísírẹ́lì.” Bíbélì Tanakh—A New Translation of the Holy Scriptures sì túmọ̀ rẹ̀ sí pé: “Kò lè fara dà á mọ́ kí ìyà máa jẹ Ísírẹ́lì.”