Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí 27

“Wo Bí Oore Rẹ̀ Ti Pọ̀ Tó!”

“Wo Bí Oore Rẹ̀ Ti Pọ̀ Tó!”

1, 2. Báwo ni oore Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó, báwo sì ni Bíbélì ṣe tẹnu mọ́ ànímọ́ yìí?

ÀGBẸ̀ kan bojú wo oko rẹ̀, ó sì rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe rí i pé ojú ọ̀run ṣú dẹ̀dẹ̀, tí òjò àkọ́rọ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ sára àwọn irúgbìn rẹ̀ tí ọ̀gbẹlẹ̀ ti hàn léèmọ̀. Ní ọ̀nà jíjìn sí ibẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ mélòó kan tí wọ́n ti ń bára wọn bọ̀ tipẹ́, jọ ń jẹun pọ̀ ní gbangba òde lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, wọ́n ń fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ tẹ̀ríntẹ̀rín, bí wọ́n ṣe ń fi oòrùn ìrọ̀lẹ́ tó ń dán gológoló ṣèran wò. Níbòmíràn, inú tọkọtaya kan ń dùn ṣìnkìn bí wọ́n ṣe rí ọmọ wọn kékeré tó ń ṣísẹ̀ gáté-gàtè-gáté fúngbà àkọ́kọ́, bó ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìrìn.

2 Yálà olúkúlùkù wọn mọ̀ àbí wọn ò mọ̀, gbogbo wọn ló ń gbádùn ohun kan náà, èyíinì ni oore Jèhófà Ọlọ́run. Àwọn èèyàn tó lẹ́mìí ìsìn sábà máa ń lo gbólóhùn náà “rere ni Olúwa.” Bíbélì tilẹ̀ sọ ọ́ lọ́nà tó túbọ̀ ṣe tààràtà. Ó ní: “Wo bí oore rẹ̀ ti pọ̀ tó!” (Sekaráyà 9:17) Àmọ́, ó jọ pé ṣàṣà ló mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí ní ti gidi lóde òní. Kí ni oore Jèhófà Ọlọ́run wé mọ́ gan-an, báwo sì ni ànímọ́ tí Ọlọ́run ní yìí ṣe lè nípa lórí kálukú wa?

Ó Jẹ́ Apá Títayọ Lára Ìfẹ́ Ọlọ́run

3, 4. Kí ni oore jẹ́, kí sì nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ Jèhófà gan-an lohun tó ń sún un ṣoore?

3 Bíbélì fi hàn pé oore jẹ́ ìwà rere gíga lọ́lá. Fún ìdí yìí, a lè sọ pé gbogbo ọ̀nà Jèhófà ló kún fún oore. Gbogbo ànímọ́ rẹ̀, àní títí kan agbára rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀, jẹ́ ànímọ́ rere látòkèdélẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe kedere pé ìfẹ́ Jèhófà gan-an lohun tó ń sún un ṣoore. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

4 Ẹ̀mí ìṣoore jẹ́ ànímọ́ téèyàn kì í lè pa mọ́ra. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ó ń fa àwọn èèyàn mọ́ra ju òdodo lọ pàápàá. (Róòmù 5:7) Olódodo èèyàn máa ń rọ̀ mọ́ ohun tí òfin wí tímọ́tímọ́. Ṣùgbọ́n ẹni rere ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó máa ń lo ìdánúṣe, ó sì máa ń wá ọ̀nà láti ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Gẹ́gẹ́ bí a ó ti rí i, ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere lọ́nà yìí. Ó ṣe kedere pé ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà ní ló fi jẹ́ irú olóore bẹ́ẹ̀.

5-7. Kí nìdí tí Jésù ò fi gbà kí wọ́n pe òun ní “Olùkọ́ Rere,” kí sì ni òtítọ́ jíjinlẹ̀ tó tipa bẹ́ẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀?

5 Jèhófà jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nínú rere ṣíṣe. Nígbà tí ọjọ́ ikú Jésù ń sún mọ́lé, ọkùnrin kan tọ̀ ọ́ wá, láti bi í ní ìbéèrè kan, ó sì pe Jésù ní “Olùkọ́ Rere.” Jésù fèsì pé: “Èé ṣe tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run.” (Máàkù 10:17, 18) Ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn yẹn rú ọ lójú. Kí nìdí tí Jésù fi bá ọkùnrin náà wí? Jésù kì í ha í ṣe “Olùkọ́ Rere” ní tòótọ́ bí?

6 Ó hàn gbangba pé ńṣe lọkùnrin yẹn ń lo gbólóhùn náà “Olùkọ́ Rere” bí orúkọ oyè láti fi pọ́n Jésù. Jésù fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ darí ògo yìí sí Baba rẹ̀ ọ̀run, tó jẹ́ ẹni rere lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́. (Òwe 11:2) Ṣùgbọ́n Jésù tún fìdí òtítọ́ jíjinlẹ̀ kan múlẹ̀. Ìyẹn ni pé, Jèhófà nìkan ni ìdíwọ̀n ìwà rere. Òun nìkan ló ní àṣẹ láti pinnu ohun tó jẹ́ rere àti búburú. Ṣe ni Ádámù àti Éfà fẹ́ gba ẹ̀tọ́ yẹn ṣe nígbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀, tí wọ́n jẹ lára èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. Jésù kò dà bíi wọn. Ńṣe lòun ní tirẹ̀ fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé Bàbá òun nìkan ló ni ẹ̀tọ́ yẹn níkàáwọ́.

7 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jésù mọ̀ pé Jèhófà ni orísun gbogbo ohun tó jẹ́ rere ní ti gidi. Òun ni Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Ẹ jẹ́ ká wo bí oore Jèhófà ṣe hàn nínú ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀.

Ẹ̀rí Pé Oore Jèhófà Pọ̀ Rẹpẹtẹ

8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣoore fún gbogbo aráyé?

8 Gbogbo èèyàn tó ti gbé láyé ló ti jàǹfààní nínú oore Jèhófà. Sáàmù 145:9 sọ pé: “Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò.” Kí ni díẹ̀ lára ibú oore rẹ̀ tó kan gbogbo èèyàn? Bíbélì sọ pé: “Kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Ìṣe 14:17) Ǹjẹ́ inú rẹ kì í dùn nígbà tó o bá ń jẹ oúnjẹ aládùn? Ọpẹ́lọpẹ́ oore Jèhófà, èyí tó ṣe nípa dídá ayé yìí lọ́nà tí ìpèsè omi mímọ́ lóló àti “àwọn àsìkò eléso” tí ń lọ yípoyípo fi ń jẹ́ ká ní oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ kì bá sí oúnjẹ. Gbogbo èèyàn sì ni Jèhófà ń ṣoore yẹn fún, kì í ṣe kìkì àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀. Jésù sọ pé: “Ó . . . ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.”—Mátíù 5:45.

Jèhófà “ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso”

9. Báwo ni èso ápù ṣe fi hàn pé olóore ni Jèhófà?

9 Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọyì ìbùkún yanturu tí aráyé ń gbádùn nítorí iṣẹ́ tí oòrùn, òjò àti àwọn àsìkò eléso ń ṣe láìdáwọ́dúró. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo èso ápù. Gbogbo ilẹ̀ olóoru kárí ayé làwọn èèyàn ti mọ èso yìí. Síbẹ̀, ó jẹ́ èso tó jojú ní gbèsè, tó dùn lẹ́nu, tó sì kún fún omi títuni lára àtàwọn èròjà aṣaralóore. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé kárí ayé, oríṣi èso ápù tó wà tó nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún méje ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [7,500], pẹ̀lú ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọ̀ látorí pupa dórí àwọ̀ ìyeyè dórí àwọ̀ ewé, tí wọ́n sì tóbi lóríṣiríṣi, látorí àwọn ápù tó fi díẹ̀ tóbi ju àgbálùmọ̀ dórí àwọn kan tó kù díẹ̀ kó tó àgbọn? Kóró èso ápù tó rí bíńtín lọ́wọ́ ẹni lè dà bí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan. Ṣùgbọ́n kóró yìí ló ń dàgbà di ọ̀kan lára igi tó dára jù lọ láyé. (Orin Sólómọ́nì 2:3) Gbogbo ìgbà ìrúwé ni igi ápù ń yọ òdòdó aláwọ̀ mèremère; gbogbo ìgbà ìkórè ló sì ń sèso. Lọ́dọọdún, ní ìpíndọ́gba, igi ápù kọ̀ọ̀kan ń so èso tó lè kún ogún páálí, ìyẹn páálí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ wúwo tó àpapọ̀ àpò gaàrí mẹ́fà, á sì máa so bẹ́ẹ̀ lọ́dọọdún fún nǹkan bí ọdún márùndínlọ́gọ́rin!

Kóró bíńtín yìí ló ń dàgbà di igi tó ń pèsè oúnjẹ, tó sì ń fi adùn kún ayé àwọn èèyàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún

10, 11. Báwo ni àwọn agbára ìmòye wa ṣe ń fi hàn pé olóore ni Ọlọ́run?

10 Nínú ọ̀pọ̀ yanturu oore rẹ̀, Jèhófà ṣẹ̀dá ara wa “tìyanu-tìyanu,” pẹ̀lú àwọn agbára ìmòye tó lè jẹ́ ká mòye àwọn iṣẹ́ rẹ̀, ká sì gbádùn wọn. (Sáàmù 139:14) Tún ronú nípa àwọn àpèjúwe tá a mú wá ní ìbẹ̀rẹ̀ àkòrí yìí. Kí ni àwọn ohun tá a rí tó jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn fúnni láyọ̀? Ẹ̀rẹ̀kẹ́ mùkẹ̀mukẹ ọmọ tínú rẹ̀ ń dùn. Ọwọ́ ọ̀wààrà òjò tó ń rọ̀ sórí oko náà. Àwọ̀ pupa, ti ìyeyè àti pípọ́n roro tí oòrùn yọ bó ṣe ń wọ̀ lọ. Ọlọ́run dá ojú èèyàn lọ́nà tó fi lè dá oríṣi àwọ̀ tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] mọ̀ yàtọ̀! Agbára ìgbọràn wa sì ń jẹ́ ká gbádùn àrà oríṣiríṣi tí olóhùn iyọ̀ kan ń fi ohùn rẹ̀ dá, ìró ẹ̀fùfùlẹ̀lẹ̀ tó ń fẹ́ kọjá lára àwọn igi àti ẹ̀rín kèékèé ọmọdé. Kí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe ká rí nǹkan wọ̀nyẹn, ká sì gbọ́ ìró wọ̀nyẹn? Bíbélì sọ pé: “Etí ìgbọ́ àti ojú ìrí—Jèhófà ni ó ṣe àwọn méjèèjì.” (Òwe 20:12) Àmọ́ méjì péré nìyẹn lára agbára ìmòye wa.

11 Agbára ìgbóòórùn tún jẹ́ ẹ̀rí oore Jèhófà. Imú ènìyàn lè gbọ́ oríṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá òórùn. Sáà ronú nípa ìwọ̀nba díẹ̀ lára wọn: ìtasánsán oúnjẹ tó o kúndùn tó ń sọ kutu lórí iná, òórùn òdòdó, òórùn àwọn ewé tó já bọ́ sílẹ̀, òórùn èéfín tí ń yọ fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ látinú iná tó ń jó wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Agbára mímọ̀ pé a fara kan nǹkan kàn máa ń jẹ́ kó o mọ ìgbà tí atẹ́gùn títuni lára bá fẹ́ yẹ́ẹ́ sí ọ lójú, ó tún ń jẹ́ kí inú rẹ dùn nígbà tí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ rẹ bá gbá ọ mọ́ra, ó tún ń jẹ́ kó o mọ̀ bí ara èso tó o mú lọ́wọ́ ti jọ̀lọ̀ tó. Agbára ìtọ́wò rẹ á sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà tó o bá bu èso náà sẹ́nu. Wàá bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn rẹ̀ lẹ́nu, bí ahọ́n rẹ ṣe ń fìyàtọ̀ sáàárín onírúurú adùn tí àwọn èròjà inú èso náà ń gbé jáde. Dájúdájú, ìdí púpọ̀ wà fún fífi ìtara sọ nípa Jèhófà pé: “Oore rẹ mà pọ̀ yanturu o, èyí tí o ti tò pa mọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ!” (Sáàmù 31:19) Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe ‘to oore pa mọ́’ fáwọn tó bẹ̀rù rẹ̀?

Oore Tó Ṣeni Láǹfààní Títí Ayérayé

12. Èwo ló ṣe pàtàkì jù lọ lára àwọn ìpèsè Jèhófà, èé sì ti ṣe?

12 Jésù sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’” (Mátíù 4:4) Ní tòótọ́, àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ti ṣe fún wa lè ṣe wá lóore ju àwọn ìpèsè tara lọ, nítorí pé àwọn ìpèsè tẹ̀mí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ní Orí Kẹjọ ìwé yìí, a ṣàlàyé pé ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, Jèhófà ti lo agbára ìmúbọ̀sípò tó ní láti fi mú kí párádísè tẹ̀mí wà. Ohun pàtàkì nínú Párádísè yẹn ni ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí.

13, 14. (a) Kí ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, kí sì ni ó túmọ̀ sì fún wa lóde òní? (b) Kí ni àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè tí Jèhófà ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?

13 Nínú ọ̀kan lára àsọtẹ́lẹ̀ gíga lọ́lá nípa ìmúbọ̀sípò tí Bíbélì sọ, a fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì ní ìran tẹ́ńpìlì kan tá a mú bọ̀ sípò, tá a sì ṣe lógo. Odò kan ń ṣàn látinú tẹ́ńpìlì yẹn, tó ń fẹ̀, tó sì ń jìn sí i bó ṣe ń ṣàn lọ, títí ó fi di “ọ̀gbàrá . . . tí ó pọ̀ ní ìlọ́po méjì.” Ìbùkún ni òdo náà ń mú dé gbogbo ibi tó ń ṣàn dé. Àwọn igi eléso tí ń pèsè oúnjẹ àti ìmúniláradá ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lẹ́bàá odò náà. Odò náà tilẹ̀ mú ìyè wá, àní ó tún mú kí àwọn ohun abẹ̀mí máa gbá yìn-ìn nínú Òkun Òkú tí kò ní ohun ẹlẹ́mìí kankan tẹ́lẹ̀! (Ìsíkíẹ́lì 47:1-12) Ṣùgbọ́n kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí?

14 Ìran náà túmọ̀ sí pé Jèhófà yóò mú ètò tí ó ṣe fún ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò. Ohun tí tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí dúró fún nìyí. Gẹ́gẹ́ bí odò tó rí nínú ìran náà, ńṣe ni ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe pé ká fi rí ìyè yóò túbọ̀ máa ṣàn yàà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀. Látìgbà tí Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò lọ́dún 1919 ló ti ń pèsè àwọn ẹ̀bùn tí ń fúnni ní ìyè fáwọn èèyàn rẹ̀. Lọ́nà wo? Bíbélì, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìpàdé àtàwọn àpéjọ ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti lóye àwọn òtítọ́ tó ṣe kókó. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni Jèhófà ti lò láti kọ́ àwọn èèyàn nípa ẹ̀bùn rẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó lè múni rí ìyè, èyíinì ni ẹbọ ìràpadà Kristi, tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fúnni láti wà ní ipò mímọ́ lójú Jèhófà, kí gbogbo àwọn tó fẹ́ràn Ọlọ́run tí wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀ látọkànwá lè ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. * Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn èèyàn Jèhófà ń gbádùn àsè tẹ̀mí ní gbogbo ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí tébi tẹ̀mí ń han aráyé léèmọ̀.—Aísáyà 65:13.

15. Báwo ni oore Jèhófà yóò ṣe máa ṣàn dé ọ̀dọ̀ ìran ènìyàn olóòótọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi?

15 Ṣùgbọ́n odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran kò ní yéé ṣàn nígbà tí ètò àwọn nǹkan ògbólógbòó yìí bá dópin. Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò tilẹ̀ túbọ̀ máa ṣàn gbùrúgbùrú nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. Nígbà yẹn, Jèhófà yóò tipasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà lo ìtóye ẹbọ Jésù ní kíkún, yóò sì mú ìran ènìyàn olóòótọ́ dé ìjẹ́pípé ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Oore Jèhófà yóò mà mú wa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà yẹn o!

Ìhà Mìíràn Lára Oore Jèhófà

16. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé oore Jèhófà tún ní àwọn ànímọ́ mìíràn nínú, kí sì ni díẹ̀ lára wọn?

16 Oore Jèhófà kò mọ sórí ìwà ọ̀làwọ́. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Èmi fúnra mi yóò mú kí gbogbo oore mi kọjá níwájú rẹ, èmi yóò sì polongo orúkọ Jèhófà níwájú rẹ.” Lẹ́yìn náà ni àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Jèhófà sì kọjá níwájú rẹ̀ ní pípolongo pé: ‘Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.’” (Ẹ́kísódù 33:19; 34:6) Èyí fi hàn pé oore Jèhófà tún ní àwọn ànímọ́ àtàtà mìíràn nínú. Ẹ jẹ́ ká gbé méjì péré lára ànímọ́ wọ̀nyí yẹ̀ wò.

17. Ọwọ́ wo ni Jèhófà fi ń mú àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé lásánlàsàn, ànímọ́ wo ló sì ń jẹ́ kó máa ṣe bẹ́ẹ̀?

17 “Olóore ọ̀fẹ́.” Ànímọ́ yìí tí Jèhófà ní máa ń jẹ́ kó fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn ẹ̀dá rẹ̀, kí ó sì kóni mọ́ra. Dípò kí Jèhófà máa sọ̀rọ̀ síni ṣàkàṣàkà, tàbí kí ó máa kanra, tàbí kí ó jẹ́ òǹrorò, bí àwọn alágbára ti sábà máa ń ṣe, Jèhófà jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ àti onínúure. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Ábúrámù pé: “Gbé ojú rẹ sókè, jọ̀wọ́, kí o sì wo ìhà àríwá àti ìhà gúúsù àti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, láti ibi tí o wà.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:14) Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ ló yọ ọ̀rọ̀ náà “jọ̀wọ́” sọ nù. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ṣàkíyèsí pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ẹ̀yán ọ̀rọ̀ kan tó sọ gbólóhùn náà di ọ̀rọ̀ ọ̀wọ̀ dípò kí ó jẹ́ àṣẹ. Àwọn àpẹẹrẹ irú rẹ̀ mìíràn wà nínú Bíbélì. (Jẹ́nẹ́sísì 31:12; Ìsíkíẹ́lì 8:5) Àbí ẹ ò rí nǹkan, Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run ń sọ pé “jọ̀wọ́” fún ẹ̀dá èèyàn lásánlàsàn! Nínú ayé tí gbígbójú mọ́ni, ìwà jàgídíjàgan àti ìwà àfojúdi ti wọ́pọ̀ yìí, ǹjẹ́ kò tuni lára láti ronú nípa bí Jèhófà, Ọlọ́run wa olóore ọ̀fẹ́ ṣe jẹ́ onínúure àti akónimọ́ra?

18. Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà ‘pọ̀ yanturu ní òtítọ́,’ kí sì nìdí tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi ń fini lọ́kàn balẹ̀?

18 ‘Ó pọ̀ yanturu ní òtítọ́.’ Àìṣòótọ́ gba ilé ayé kan lóde òní. Ṣùgbọ́n Bíbélì rán wa létí pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn tí yóò fi purọ́.” (Númérì 23:19) Kódà, Títù 1:2 sọ pé “Ọlọ́run . . . kò lè purọ́.” Ìwà rere Jèhófà kò lè jẹ́ kí irọ́ tẹnu rẹ̀ jáde. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé gbogbo ìlérí Jèhófà ló ṣeé gbára lé pátápátá; ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní ṣaláì ṣẹ. Bíbélì tilẹ̀ pe Jèhófà ní “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sáàmù 31:5) Yàtọ̀ sí pé irọ́ kì í tẹnu rẹ̀ jáde rárá, òótọ́ pọ́ńbélé ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kì í ṣe nǹkan ní bòńkẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò dinú; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fi ibú ọgbọ́n rẹ̀ la àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lóye. * Ó tiẹ̀ ń kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa fi òtítọ́ tí òun ń ṣí payá fún wọn ṣèwà hù, kí wọ́n lè máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 3) Ipa wo ló wá yẹ kí oore Jèhófà ní lórí olúkúlùkù wa pátá?

“Máa Tàn Yinrin Nítorí Oore Jèhófà”

19, 20. (a) Báwo ni Sátánì ṣe dọ́gbọ́n jin ìgbẹ́kẹ̀lé tí Éfà ní nínú oore Jèhófà lẹ́sẹ̀, kí sì ni àbájáde rẹ̀? (b) Ipa wo ló yẹ kí oore Jèhófà ní lórí wa, èé sì ti ṣe?

19 Nígbà tí Sátánì dán Éfà wò nínú ọgbà Édẹ́nì, ńṣe ló fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ jin ìgbẹ́kẹ̀lé tí Éfà ní nínú oore Jèhófà lẹ́sẹ̀. Ohun tí Jèhófà sọ fún Ádámù ni pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn.” Lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún igi tó bẹwà kún ọgbà náà, ọ̀kan péré ni Jèhófà kà léèwọ̀. Ṣùgbọ́n wo ọ̀nà tí Sátánì gbé ìbéèrè àkọ́kọ́ tó béèrè lọ́wọ́ Éfà gbà. Ó ní: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 16; 3:1) Sátánì gbé ọ̀rọ̀ Jèhófà gbòdì, láti lè mú kí Éfà ronú pé Jèhófà ń fawọ́ ohun rere kan sẹ́yìn. Ó bani nínú jẹ́ pé ó rí Éfà mú. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ èèyàn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ń ṣe lẹ́yìn náà, Éfà bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa oore Ọlọ́run, ẹni tó fún un ní gbogbo ohun tó ní.

20 A kúkú mọ ìbànújẹ́ àti ìyà ńlá tí irú iyèméjì bẹ́ẹ̀ ti kó wa sí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Jeremáyà 31:12, pé: “Dájúdájú, wọn yóò . . . máa tàn yinrin nítorí oore Jèhófà.” Ṣe ló yẹ kí oore Jèhófà máa mú wa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Kò sídìí fún ṣíṣe iyèméjì rárá nípa ète Ọlọ́run wa, aṣoore-má-ṣìkà. A lè gbára lé e pátápátá, torí pé ire àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ló ń wá.

21, 22. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí wàá fẹ́ gbà fi hàn pé o mọyì oore Jèhófà? (b) Ànímọ́ wo la ó ṣàlàyé ní àkòrí tó kàn, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí oore?

21 Síwájú sí i, inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá ní àǹfààní láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa oore Ọlọ́run. Sáàmù 145:7 sọ nípa àwọn èèyàn Jèhófà pé: “Wọn yóò máa fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ yanturu oore rẹ.” Gbogbo ọjọ́ ayé wa là ń jàǹfààní oore Jèhófà lọ́nà kan tàbí òmíràn. O ò ṣe sọ ọ́ dàṣà láti máa dìídì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ fún oore rẹ̀, kó o sì sọ oore yẹn ní pàtó? Ríronú nípa ànímọ́ yìí, dídúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ nítorí rẹ̀ àti sísọ fáwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀ yóò jẹ́ ká fìwà jọ Ọlọ́run wa olóore. Ńṣe la óò túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, bá a ṣe ń wá ọ̀nà láti máa ṣe rere, ní àfarawé rẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù arúgbó nì, kọ̀wé pé: “Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, má ṣe jẹ́ aláfarawé ohun búburú, bí kò ṣe ohun rere. Ẹni tí ó bá ń ṣe rere pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—3 Jòhánù 11.

22 Oore Jèhófà tún tan mọ́ àwọn ànímọ́ mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run “pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́,” ìyẹn ìfẹ́ dídúróṣinṣin. (Ẹ́kísódù 34:6) Ànímọ́ yìí yàtọ̀ sí oore ṣíṣe ní ti pé ó lójú àwọn tó wà fún. Kìkì àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ni Jèhófà ń fi ànímọ́ yìí hàn sí. A ó mọ bó ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn sí wọn ní àkòrí tó tẹ̀ lé e.

^ ìpínrọ̀ 14 Ìràpadà ni àpẹẹrẹ oore títóbi jù lọ tí Jèhófà ṣe fún wa. Láàárín ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá ẹ̀mí tí Jèhófà lè yàn, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n, ló yàn pé kí ó wá kú fún wa.

^ ìpínrọ̀ 18 Ó bá a mu wẹ́kú pé Bíbélì fi hàn pé òtítọ́ tan mọ́ ìmọ́lẹ̀. Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde.” (Sáàmù 43:3) Jèhófà ń tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí mímọ́lẹ̀ yòò sórí àwọn tó bá fẹ́ gbẹ̀kọ́, tàbí tó bá fẹ́ kí ó la àwọn lóye.—2 Kọ́ríńtì 4:6; 1 Jòhánù 1:5.