Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 18

Ǹjẹ́ O Máa Ń Rántí Láti Dúpẹ́?

Ǹjẹ́ O Máa Ń Rántí Láti Dúpẹ́?

ǸJẸ́ o ti jẹun lónìí?— Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó se oúnjẹ náà?— Nínú kó jẹ́ màmá rẹ ló sè é tàbí kó jẹ́ ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n èé ṣe tó fi yẹ kí á dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oúnjẹ yẹn?— Ìdí ni pé Ọlọ́run ló ń mú kí àwọn ewéko hù, kí ó sì mú oúnjẹ tí à ń jẹ jáde. Àmọ́, ó tún yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó se oúnjẹ náà tàbí lọ́wọ́ ẹni tó gbé e fún wa.

Nígbà mìíràn a máa ń gbàgbé láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ó ṣe oore fún wa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Nígbà tí Olùkọ́ Ńlá náà wà ní ayé, àwọn adẹ́tẹ̀ kan wà tí wọ́n gbàgbé láti dúpẹ́.

Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí à ń pè ní adẹ́tẹ̀?— Adẹ́tẹ̀ ni ẹni tó ní àìsàn kan tó ń jẹ́ ẹ̀tẹ̀. Àìsàn yẹn tiẹ̀ lè mú kí apá kan ara èèyàn gé kúrò. Ní ìgbà àtijọ́ tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn adẹ́tẹ̀ kì í gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn ní àárín ìlú. Wọ́n máa ń gbé lọ́tọ̀ ni. Bí adẹ́tẹ̀ bá sì rí èèyàn kan tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní láti tètè sọ fún ẹni náà pé kí ó dúró sọ́hùn-ún kí ó má ṣe dé ọ̀dọ̀ òun. Wọ́n máa ń ṣe èyí torí kí àwọn èèyàn má ṣe sún mọ́ wọn kí àìsàn ẹ̀tẹ̀ náà má bàa ràn wọ́n.

Jésù máa ń ṣàánú àwọn adẹ́tẹ̀ gan-an. Lọ́jọ́ kan tí Jésù ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó gba inú ìlú kékeré kan kọjá. Nígbà tí wọ́n sún mọ́ ìlú náà, adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá jáde wá láti wá bá a. Wọ́n ti gbọ́ pé Ọlọ́run fún Jésù ní agbára láti máa wo onírúurú àìsàn sàn.

Àwọn adẹ́tẹ̀ yìí kò sún mọ́ Jésù o. Wọ́n dúró sí òkèèrè. Ṣùgbọ́n wọ́n gbà pé Jésù lè wo ẹ̀tẹ̀ àwọn sàn. Nítorí náà, nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ yìí rí Olùkọ́ Ńlá náà wọ́n pè é, wọ́n ní: ‘Jésù, Olùkọ́ni, ràn wá lọ́wọ́!’

Ǹjẹ́ àánú àwọn tí àìsàn ń ṣe máa ń ṣe ọ́?— Àánú wọn máa ń ṣe Jésù. Ó mọ̀ pé ó máa ń bani nínú jẹ́ gan-an láti jẹ́ adẹ́tẹ̀. Nítorí náà, ó dá wọn lóhùn, ó sọ pé: “Ẹ lọ fi ara yín han àwọn àlùfáà.”—Lúùkù 17:11-14.

Kí ni Jésù ń sọ fún àwọn adẹ́tẹ̀ yìí pé kí wọ́n ṣe?

Èé ṣe tí Jésù fi ní kí wọ́n lọ fi ara han àwọn àlùfáà? Nítorí òfin tí Jèhófà fún àwọn èèyàn Rẹ̀ nípa àwọn adẹ́tẹ̀ ni. Òfin yìí sọ pé kí àlùfáà Ọlọ́run máa yẹ ara àwọn adẹ́tẹ̀ wò. Àlùfáà yìí ni yóò sọ fún adẹ́tẹ̀ náà tí àrùn náà bá ti fi í sílẹ̀. Tí ara rẹ̀ bá ti yá, ó lè wá máa gbé láàárín àwọn èèyàn ìlú.—Léfítíkù 13:16, 17.

Ṣùgbọ́n àwọn adẹ́tẹ̀ yìí ṣì ní àrùn lára. Nítorí náà, ṣé wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà bí Jésù ṣe sọ fún wọn?— Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti gbà gbọ́ pé Jésù yóò wo àrùn àwọn sàn. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

Ó dára, bí wọ́n ṣe ń lọ sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà ni àìsàn wọn kàn kúrò lára wọn. Ẹran ara wọn tún dára padà. Wọ́n gba ìwòsàn! Wọ́n jèrè nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé Jésù ní agbára tí ó lè wo àwọn sàn. Inú wọn dùn gan-an! Ṣùgbọ́n, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà láti fi hàn pé wọ́n moore? Tó bá jẹ́ ìwọ kí lo máa ṣe?—

Kí ni adẹ́tẹ̀ yìí ò gbàgbé láti ṣe?

Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tó gba ìwòsàn náà padà tọ Jésù lọ. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ògo fún Jèhófà, ó ń sọ nǹkan rere nípa Ọlọ́run. Ohun tí ó yẹ kí ó ṣe nìyẹn, nítorí pé Ọlọ́run ló fún Jésù ní agbára tó fi mú wọn lára dá. Ọkùnrin náà tún kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Olùkọ́ Ńlá náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó dúpẹ́ gan-an fún ohun tí Jésù ṣe fún un.

Àwọn ọkùnrin mẹ́sàn-án tó kù wá ńkọ́? Jésù béèrè pé: ‘Ṣebí àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá ni a mú lára dá, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn mẹ́sàn-án tó kù dà? Ṣé ẹnì kan péré ni ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run ni?’

Òótọ́ ni o. Ọkùnrin kan ṣoṣo nínú àwọn mẹ́wàá ni ó fi ògo, tàbí ìyìn fún Ọlọ́run, tó sì padà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù. Ará Samáríà sì ni ọkùnrin náà, ẹni tó wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn ọkùnrin mẹ́sàn-án tó kù kò dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, wọn kò sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù.—Lúùkù 17:15-19.

Èwo ni o fìwà jọ nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? A fẹ́ láti dà bíi ti ará Samáríà yẹn, àbí?— Nítorí náà, tí ẹnì kan bá ṣe oore fún wa, kí ni ó yẹ kí á rántí láti ṣe?— Ó yẹ kí á dúpẹ́. Àwọn èèyàn sábà máa ń gbàgbé láti dúpẹ́. Ṣùgbọ́n ó dára láti máa dúpẹ́. Tí a bá ń dúpẹ́, ó máa ń dùn mọ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀.

Báwo lo ṣe lè ṣe bíi ti adẹ́tẹ̀ tó pa dà wá sọ́dọ̀ Jésù?

Tí o bá ronú dáadáa, wàá rántí pé àwọn èèyàn ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan dáadáa fún ọ. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ àìsàn ti ṣe ọ́ rí?— Ó lè máà jẹ́ irú àìsàn tí ó ṣe àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá yẹn o, ṣùgbọ́n bóyá orí ti fọ́ ọ rí tàbí tí inú ti run ọ́ rí. Ǹjẹ́ ẹnì kan tọ́jú rẹ?— Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fún ọ lóògùn tàbí kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan mìíràn fún ọ. Ṣé inú rẹ dùn pé wọ́n mú kí ara rẹ yá?—

Ará Samáríà náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù pé ó mú òun lára dá, inú Jésù sì dùn. Ǹjẹ́ o rò pé inú bàbá tàbí ìyá rẹ yóò dùn tí o bá sọ pé ẹ ṣeun nígbà tí wọ́n bá ṣe àwọn ohun kan fún ẹ?— Bẹ́ẹ̀ ni o, inú wọn yóò dùn.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa rántí dúpẹ́?

Àwọn kan máa ń ṣe nǹkan fún ẹ lójoojúmọ́ tàbí ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó lè jẹ́ pé iṣẹ́ wọn ni. Inú wọn tiẹ̀ lè máa dùn láti ṣe é. Ṣùgbọ́n o lè gbàgbé láti sọ fún wọn pé wọ́n ṣeun. Olùkọ́ rẹ lè máa kọ́ ọ dáadáa gan-an kí o lè mọ ìwé. Iṣẹ́ rẹ̀ nìyẹn. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ yóò dùn tí o bá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó ń kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́.

Nígbà mìíràn àwọn èèyàn lè ṣe nǹkan kékeré fún ọ. Ǹjẹ́ ẹnì kan ti di ilẹ̀kùn mú fún ọ rí? Tàbí ǹjẹ́ ẹnì kan ti gbé oúnjẹ fún ọ nígbà oúnjẹ rí? Ó dára láti sọ fún ẹni tí ó ṣe irú àwọn ohun kékeré bẹ́ẹ̀ pé ẹ ṣeun.

Tí a bá ń rántí láti sọ fún àwọn èèyàn nínú ayé pé ẹ ṣeun, nígbà náà a ó máa rántí láti sọ fún Baba wa ọ̀run pé o ṣeun. Ohun tí a lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún sì pọ̀ jaburata! Ó mú kí á wà láàyè, ó sì fún wa ni ohun rere gbogbo tó ń mú kí á gbádùn ayé. Nítorí náà, o yẹ kí á máa fi ògo fún Ọlọ́run, kí á máa sọ ohun rere nípa rẹ̀ lójoojúmọ́.

Nípa pé kí á máa dúpẹ́, ka Sáàmù 92:1; Éfésù 5:20; Kólósè 3:17; àti 1 Tẹsalóníkà 5:18.