Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 23

Ìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Ṣàìsàn

Ìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Ṣàìsàn

ǸJẸ́ o mọ ẹnì kan tó ń ṣàìsàn?— Ó ṣeé ṣe kí ìwọ gan-an ṣàìsàn nígbà mìíràn. Orí lè máa fọ́ ọ tàbí kí inú máa run ọ́. Àìsàn àwọn ẹlòmíràn máa ń pọ̀ gan-an. Wọn ò tiẹ̀ ní lè dìde dúró fúnra wọn láìjẹ́ pé ẹlòmíràn ràn wọ́n lọ́wọ́. Èyí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ti darúgbó.

Gbogbo èèyàn ló máa ń ṣàìsàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á tí àwọn èèyàn fi máa ń ṣàìsàn, tí wọ́n ń darúgbó, tí wọ́n sì ń kú?— Lọ́jọ́ kan, wọ́n gbé ọkùnrin kan tí kò lè rìn wá sọ́dọ̀ Jésù. Ìgbà yẹn ni Jésù fi ohun tó fà á tí àwọn èèyàn fi ń ṣàìsàn tí wọ́n sì ń kú hàn. Jẹ́ kí n sọ ìtàn náà fún ọ.

Jésù dé sí ilé kan ní ìlú kan tó wà létí Òkun Gálílì. Àwọn èrò púpọ̀ wá láti rí i. Àwọn èèyàn tó wá síbẹ̀ pọ̀ gan-an débi pé kò sí àyè fún àwọn mìíràn láti wọ inú ilé náà. Wọn ò tiẹ̀ rí àyè sún mọ́ ibi ilẹ̀kùn pàápàá. Síbẹ̀, àwọn èèyàn púpọ̀ ṣì ń wá! Àwọn èèyàn kan gbé ọkùnrin kan tí ó ní àrùn ẹ̀gbà, tí kò tiẹ̀ lè rìn rárá wá. Odindi ọkùnrin mẹ́rin ló gbé e wá lórí ibùsùn kékeré tàbí àkéte rẹ̀ tí ó wà.

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí wọ́n fi fẹ́ gbé ọkùnrin aláìsàn yìí wá sọ́dọ̀ Jésù?— Wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé Jésù lè ràn án lọ́wọ́. Wọ́n gbà gbọ́ pé Jésù lè wo àìsàn rẹ̀ sàn. Ǹjẹ́ o mọ bí wọ́n ṣe gbé ọkùnrin náà dé ọ̀dọ̀ Jésù bí èrò tó wà nínú ilé yẹn ṣe pọ̀ tó?—

Ó dára, àwòrán tí o rí níbí yìí fi bí wọ́n ṣe ṣe é hàn. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n gbé ọkùnrin náà gun orí òrùlé. Ó jẹ́ òrùlé tó tẹ́ pẹrẹsẹ. Lẹ́yìn náà, wọ́n dá ihò ńlá kan lu sí òrùlé náà. Níkẹyìn, wọ́n fi àkéte ọkùnrin aláìsàn náà gbé e sọ̀ kalẹ̀ gba inú ihò yẹn bọ́ sínú yàrá nísàlẹ̀. Ìgbàgbọ́ wọn mà pọ̀ o!

Ẹnu ya gbogbo àwọn èèyàn tó wà nínú ilé nígbà tí wọ́n rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Àárín wọn gan-an ni ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà tó wà lórí àkéte náà sọ̀ kalẹ̀ sí. Ṣé Jésù bínú nígbà tí ó rí ohun tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣe?— Rárá o! Inú rẹ̀ dùn gan-an láti rí i pé wọ́n ní ìgbàgbọ́. Ó sọ fún alárùn ẹ̀gbà náà pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.”

Kí ni Jésù sọ pé kí ọkùnrin tó ní àrùn ẹ̀gbà náà ṣe?

Àwọn èèyàn kan ò rò pé ó tọ́ kí Jésù sọ bẹ́ẹ̀. Wọn ò rò pé ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini. Nítorí náà, láti fi hàn pé òun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini lóòótọ́, Jésù sọ fún ọkùnrin náà pé: “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé rẹ.”

Bí Jésù ṣe sọ bẹ́ẹ̀, a mú ọkùnrin náà lára dá! Apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rọ mọ́. Nísinsìnyí, ó lè dìde dúró fúnra rẹ̀ kí ó sì máa rìn. Ẹnu ya àwọn èèyàn tó rí iṣẹ́ ìyanu yìí gan-an. Wọn ò tíì rí ohun ìyanu tí ó tó bẹ́ẹ̀ rí láyé wọn! Wọ́n yin Jèhófà lógo pé ó fún àwọn ní Olùkọ́ Ńlá yìí, tó jẹ́ pé ó lè wo àwọn èèyàn sàn nínú àìsàn wọn.—Máàkù 2:1-12.

Kí ni iṣẹ́ ìyanu yìí kọ́ wa?

Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu yìí?— A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù ní agbára láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini àti láti mú àwọn aláìsàn lára dá. Ṣùgbọ́n a tún kọ́ ohun mìíràn, ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an. A kẹ́kọ̀ọ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ ló ń mú kí àwọn èèyàn máa ṣàìsàn.

Níwọ̀n bí gbogbo wa ti máa ń ṣàìsàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣé ó fi hàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa ni?— Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì sọ pé a bí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ gbogbo wa. Tí a bá sọ pé a bí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ènìyàn, ǹjẹ́ o mọ ohun tó túmọ̀ sí?— Ó túmọ̀ sí pé a bí wa ní aláìpé. Nígbà mìíràn, a máa ń ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tí kò dára, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ bí gbogbo wa ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀?—

A di ẹlẹ́ṣẹ̀ nítorí pé Ádámù ọkùnrin kìíní ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ó dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó rú òfin Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ sì ran gbogbo wa láti ọ̀dọ̀ Ádámù. Ǹjẹ́ o mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ràn wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀? Jẹ́ kí n gbìyànjú láti ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tí ó lè yé ọ.

Báwo ni gbogbo wa ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀?

Bóyá o ti bá ẹnì kan ṣe búrẹ́dì tàbí mọ́ínmọ́ín alágolo rí. Kí ni ó máa ṣẹlẹ̀ sí ara búrẹ́dì tàbí mọ́ínmọ́ín yẹn tí agolo tí wọ́n fi ṣe é bá tẹ̀ sínú ní ẹ̀gbẹ́ kan? Ǹjẹ́ o mọ̀?— Àmì yẹn kan náà máa hàn lára gbogbo búrẹ́dì tàbí mọ́ínmọ́ín tó o bá fi agolo yẹn ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—

Ádámù dà bí agolo yẹn, àwa sì dà bí búrẹ́dì tàbí mọ́ínmọ́ín yẹn. Nígbà tí ó rú òfin Ọlọ́run, ó di aláìpé. Ó dà bí agolo tó tẹ̀ sínú ní ẹ̀gbẹ́ kan tàbí tí ó ní àmì tí kò dára lára. Nítorí náà, nígbà tí ó ní àwọn ọmọ, irú ọmọ wo ni wọ́n máa jẹ́?— Gbogbo ọmọ rẹ̀ ni yóò gba àmì àìpé kan náà yìí.

Àwọn ọmọ tó pọ̀ jù lọ ni kì í ní àmì àìpé ńlá tí o lè fojú rí kedere nígbà tí wọ́n bá bí wọn. Ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn lè pé pérépéré. Ṣùgbọ́n àìpé tiwọn lè burú débi pé wọn yóò ṣàìsàn, wọn yóò sì kú níkẹyìn.

Lóòótọ́, àwọn èèyàn kan máa ń ṣàìsàn púpọ̀ ju àwọn mìíràn lọ. Kí ló fà á? Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ tí a bí mọ́ wọn pọ̀ ju tàwọn yòókù lọ ni?— Rárá o, ìwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ kan náà ni a bí mọ́ gbogbo èèyàn. Gbogbo wa ni a bí ní aláìpé. Nítorí náà, bópẹ́ bóyá, gbogbo èèyàn ni àìsàn kan tàbí òmíràn máa ṣe. Àní àwọn tó tiẹ̀ ń gbìyànjú láti pa gbogbo òfin Ọlọ́run mọ́ tí wọn kò ṣe ohunkóhun tó fi bẹ́ẹ̀ burú, ṣì lè ṣàìsàn.

Irú ìlera wo la máa ní lẹ́yìn tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá kúrò lára wa?

Nígbà náà, kí ló fà á tí àwọn èèyàn kan fi máa ń ṣàìsàn púpọ̀ ju àwọn èèyàn yòókù lọ?— Ohun púpọ̀ ló lè fà á. Ó lè jẹ́ pé wọn kì í rí oúnjẹ jẹ tó. Tàbí wọ́n lè má jẹ oúnjẹ tí ó yẹ kí wọ́n jẹ. Ó lè jẹ́ oúnjẹ dídùn-dídùn tí kò dára fún ara ni wọ́n ń jẹ. Ìdí mìíràn tún lè jẹ́ pé wọ́n máa ń pẹ́ kí wọ́n tó sùn ní alẹ́, wọn ò sì ní sùn púpọ̀ tó. Tàbí wọ́n lè má wọ aṣọ tó móoru kí wọ́n tó lọ ṣeré níta lákòókò otútù. Àwọn èèyàn kan kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára, nítorí náà ara wọn kò lè borí àìsàn kódà bí wọ́n tiẹ̀ gbìyànjú láti tọ́jú ara wọn.

Ǹjẹ́ ìgbà kankan máa wà tí a kò ní máa ṣàìsàn mọ́? Ǹjẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ máa kúrò lára wa láéláé?— Ó dára, kí ni Jésù ṣe fún ọkùnrin tó ní àrùn ẹ̀gbà náà?— Jésù dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í, o sì wò ó sàn. Ní ọ̀nà yẹn, Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí òun yóò ṣe lọ́jọ́ ọ̀la fún gbogbo àwọn tó bá sapá gan-an láti ṣe ohun tí ó tọ́.

Bí a bá fi hàn pé a kò fẹ́ máa dá ẹ̀ṣẹ̀ àti pé a kórìíra ohun tó burú, Jésù yóò wò wá sàn. Lọ́jọ́ ọ̀la, yóò mú àìpé tí ó wà lára wa báyìí kúrò. Òun yóò ṣe èyí nítorí pé ó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Kò ní mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá lára wa lẹ́ẹ̀kan náà o. Yóò máa mú un kúrò díẹ̀díẹ̀ fún àkókò kan ni títí yóò fi tán. Tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá ti kúrò pátápátá, a ò ní ṣàìsàn mọ́. Gbogbo wa yóò ní ìlera pípé. Èyí á mà dùn mọ́ni o!

Láti lè rí àlàyé síwájú sí i nípa ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ ń fà bá gbogbo èèyàn, ka Jóòbù 14:4; Sáàmù 51:5; Róòmù 3:23; 5:12; àti 6:23.