Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 25

Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Padà?

Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Padà?

ǸJẸ́ kò ní dára púpọ̀ bí gbogbo èèyàn bá ń ṣe ohun rere?— Àmọ́ kò sí ẹni náà tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló ń ṣe ohun rere. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo wa ló ń ṣe ohun tí kò dára nígbà mìíràn, àní nígbà tí a bá tiẹ̀ fẹ́ ṣe ohun rere pàápàá?— Ohun tó fà á ni pé gbogbo wa ni a bí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn kan máa ń ṣe àwọn ohun búburú tó pọ̀ gan-an. Wọn yóò kórìíra àwọn èèyàn mìíràn, wọn yóò sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣe àwọn nǹkan láti pa wọ́n lára. Ǹjẹ́ o rò pé wọ́n lè yí padà kí wọ́n sì di ẹni tó ń ṣe rere?—

Wo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ṣọ́ ẹ̀wù àwọn tó ń ju òkúta lu Sítéfánù nínú àwòrán yìí. Sọ́ọ̀lù ni orúkọ rẹ̀ ní èdè Hébérù, ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù ni orúkọ rẹ̀ lédè àwọn ará Róòmù. Inú rẹ̀ dùn pé wọ́n fẹ́ pa Sítéfánù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Olùkọ́ Ńlá náà. Jẹ́ ká wo ìdí tí Sọ́ọ̀lù fi ń ṣe irú ohun búburú bẹ́ẹ̀.

Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìsìn àwọn Júù kan tí wọ́n ń pè ní Farisí. Àwọn Farisí ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ tí àwọn kan lára àwọn aṣáájú ìsìn wọn ń kọ́ni ni wọ́n máa ń fiyè sí jù lọ. Èyí ló mú kí Sọ́ọ̀lù máa ṣe àwọn ohun búburú.

Nígbà tí wọ́n fi òfin mú Sítéfánù ní Jerúsálẹ́mù, Sọ́ọ̀lù wà níbẹ̀. Wọ́n gbé Sítéfánù lọ sílé ẹjọ́, níbi tí àwọn kan lára àwọn onídàájọ́ ti jẹ́ Farisí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ ohun búburú nípa Sítéfánù, òun kò bẹ̀rù rárá. Ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀, ó sì sọ ohun rere tó pọ̀ gan-an nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù fún àwọn onídàájọ́ náà.

Ṣùgbọ́n inú àwọn onídàájọ́ yẹn kò dùn sí ohun tí wọ́n gbọ́. Wọ́n ti mọ̀ nípa Jésù dáadáa tẹ́lẹ̀. Àní nígbà díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn gan-an ni wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jésù! Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n pa Jésù, Jèhófà mú un padà lọ sí ọ̀run. Nísinsìnyí, dípò kí àwọn onídàájọ́ yẹn yí ìwà wọn padà, ṣe ni wọ́n ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù jà.

Àwọn onídàájọ́ yìí gbá Sítéfánù mú, wọ́n sí fà á lọ sí ẹ̀yìn ìlú náà. Wọ́n lù ú bolẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ju òkúta lù ú. Bí o sì ṣe rí i nínú àwòrán yìí, Sọ́ọ̀lù wà níbẹ̀, tó ń wò wọ́n. Ó rò pé ó tọ́ láti pa Sítéfánù.

Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi rò pé ó tọ́ láti pa Sítéfánù?

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó mú kí Sọ́ọ̀lù ronú bẹ́ẹ̀?— Ṣé o rí i, Farisí ni Sọ́ọ̀lù láti ìgbà ọmọdé wá, ó sì gbà gbọ́ pé ẹ̀kọ́ àwọn Farisí tọ̀nà. Ó ka àwọn Farisí sí àpẹẹrẹ rere, ó sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.—Ìṣe 7:54-60.

Lẹ́yìn tí wọ́n pa Sítéfánù tán, kí ni Sọ́ọ̀lù ṣe?— Ńṣe ló tún ń sa gbogbo agbára rẹ̀ láti pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yòókù run! Ó ń wọ inú ilé wọn ní tààràtà láti fà wọ́n jáde, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Yóò sọ pé kí wọ́n jù wọ́n sí ẹ̀wọ̀n. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ló kúrò ní Jerúsálẹ́mù nítorí ìyẹn, ṣùgbọ́n wọn kò ṣíwọ́ ìwàásù wọn nípa Jésù.—Ìṣe 8:1-4.

Èyí mú kí Sọ́ọ̀lù tún kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sí i. Nítorí náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Káyáfà Àlùfáà Àgbà láti gba àṣẹ láti fi òfin mú àwọn Kristẹni tó bá wà ní ìlú Damásíkù. Sọ́ọ̀lù fẹ́ mú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n wá sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè fìyà jẹ wọ́n. Ṣùgbọ́n nígbà tó ń lọ lójú ọ̀nà Damásíkù, ohun ìyanu kan ṣẹlẹ̀.

Ta ló ń bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀, kí sì ni ẹni náà rán Sọ́ọ̀lù pé kó ṣe?

Ìmọ́lẹ̀ kan tàn yòò láti ọ̀run, ohùn kan sì sọ pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Jésù ni ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run! Ìmọ́lẹ̀ yẹn mọ́lẹ̀ débi pé ó fọ́ ojú Sọ́ọ̀lù, àwọn tó wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù ni ó fà á lọ́wọ́ lọ sí Damásíkù.

Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, Jésù fara han Ananíà tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú ìran, ó ń gbé ní Damásíkù. Jésù sọ fún Ananíà pé kí ó lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, kí ó lọ ṣe é kí ojú rẹ̀ tí ó fọ́ tún ríran padà, kí ó sì wàásù fún un. Nígbà tí Ananíà wàásù fún Sọ́ọ̀lù, ó tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ tí ó gbọ́ nípa Jésù. Ojú rẹ̀ tí ó fọ́ sì padà là, ó wá ń ríran. Ó yí gbogbo ìwà àti ìṣe rẹ̀ padà, ó sì di olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run.—Ìṣe 9:1-22.

Ǹjẹ́ o ti wá lóye ìdí tí Sọ́ọ̀lù fi kọ́kọ́ ń ṣe ohun búburú?— Ó jẹ́ nítorí pé wọ́n ti kọ́ ọ ní àwọn ẹ̀kọ́ tó lòdì tẹ́lẹ̀. Àwọn èèyàn tí kò jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ló ń bá rìn. Ó sì dara pọ̀ mọ́ àwùjọ èèyàn kan tó máa ń ka èrò ènìyàn sí pàtàkì ju Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí Sọ́ọ̀lù fi yí ìwà àti ìṣe rẹ̀ padà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe rere, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Farisí yòókù ṣì ń bá Ọlọ́run jà?— Ó jẹ́ nítorí pé Sọ́ọ̀lù kò kórìíra òtítọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí a wá kọ́ ọ ní ohun tó jẹ́ òtítọ́, kíákíá ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é.

Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Sọ́ọ̀lù wá dà nígbà tó yá?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó di ẹni tí a mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì tí Jésù yàn. Sì rántí o, nínú iye ìwé tí ẹnì kọ̀ọ̀kan kọ nínú Bíbélì èyí tí Pọ́ọ̀lù kọ lò pọ̀ jù.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà tó lè yí padà bíi ti Sọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n èyí kò rọrùn láti ṣe nítorí pé ẹnì kan wà tó ń fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe ohun tí yóò mú kí àwọn èèyàn máa ṣe nǹkan burúkú. Ǹjẹ́ o mọ ẹni náà?— Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí Jésù fara han Sọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà Damásíkù. Lójú ọ̀nà yẹn, Jésù sọ̀rọ̀ láti ọ̀run sí Sọ́ọ̀lù pé: ‘Èmi ń rán ọ kí o lọ la ojú àwọn èèyàn, láti yí wọn padà láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ àti kúrò lábẹ́ àṣẹ Sátánì sí Ọlọ́run.’—Ìṣe 26:17, 18.

Bẹ́ẹ̀ ni o, Sátánì Èṣù ló ń gbìyànjú láti mú kí gbogbo èèyàn máa ṣe àwọn nǹkan burúkú. Ǹjẹ́ ó máa ń nira fún ọ nígbà mìíràn láti ṣe ohun tó tọ́?— Gbogbo wa ló máa ń nira fún. Sátánì máa ń jẹ́ kó nira. Ṣùgbọ́n ìdí mìíràn tún wà tí kì í jẹ́ kó rọrùn fún wa láti ṣe ohun tó tọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà?— Ó jẹ́ nítorí pé a bí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ wa.

Ẹ̀ṣẹ̀ yìí ló máa ń jẹ́ kí ó rọrùn fún wa láti ṣe ohun tí ó lòdì ju kí á ṣe ohun tí ó tọ́ lọ. Nítorí náà, kí ni ó yẹ kí á ṣe?— A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti ṣe ohun tó tọ́. Tí a bá sapá láti ṣe ohun tó tọ́, ó dájú pé Jésù, ẹni tó fẹ́ràn wa, yóò ràn wá lọ́wọ́.

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun fẹ́ràn àwọn èèyàn tó ti ń ṣe ohun búburú tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí wọ́n yí padà. Ó mọ bí ó ṣe nira tó fún wọn láti yí padà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin kan wà tí wọ́n ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ṣe ìṣekúṣe. Èyíinì sì lòdì. Bíbélì pe irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní aṣẹ́wó tàbí kárùwà.

Kí nìdí tí Jésù fi dárí ji obìnrin yìí tó ti ṣe àwọn ohun tó burú?

Nígbà kan, obìnrin tó jẹ́ irú èèyàn bẹ́ẹ̀ gbọ́ nípa Jésù, ó wá sí ibi tí Jésù wà nínú ilé Farisí kan. Ó da òróró sí ẹsẹ̀ Jésù ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu omijé ojú rẹ̀ tó ń dá sí ẹsẹ̀ Jésù kúrò. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ dùn ún gan-an, nítorí náà Jésù dárí jì í. Ṣùgbọ́n àwọn Farisí ò rò pé ó yẹ kí Jésù dárí jì í.—Lúùkù 7:36-50.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jésù sọ fún àwọn kan lára àwọn tó jẹ́ Farisí?— Ó sọ fún wọn pé: “Àwọn aṣẹ́wó ń lọ sínú ìjọba Ọlọ́run ṣáájú yín.” (Mátíù 21:31) Jésù sọ èyí nítorí pé àwọn aṣẹ́wó yìí gba Jésù gbọ́, wọ́n sì yí padà kúrò nínú ìwà burúkú wọn. Ṣùgbọ́n àwọn Farisí ń bá a lọ láti ṣe ohun búburú sí àwọn àpọ́sítélì Jésù.

Nítorí náà, nígbà tí Bíbélì bá fi hàn pé ohun tí à ń ṣe kò dára, ó yẹ kí á tètè yí padà. Nígbà tí a bá sì mọ ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí á ṣe, ó yẹ kí á tara ṣàṣà láti ṣe é. Nígbà náà, inú Jèhófà yóò dùn sí wa, yóò sì fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun.

Láti ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe ohun tó burú, jẹ́ kí á jọ ka Sáàmù 119:9-11; Òwe 3:5-7; àti 12:15.