Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 27

Ta Ni Ọlọ́run Rẹ?

Ta Ni Ọlọ́run Rẹ?

KÍ NÌDÍ tí ìbéèrè náà, Ta ni Ọlọ́run rẹ? fi ṣe pàtàkì?— Ó ṣe pàtàkì nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọ́run ni àwọn èèyàn ń sìn. (1 Kọ́ríńtì 8:5) Ó ṣẹlẹ̀ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo agbára tí Jèhófà fún un láti mú ọkùnrin kan lára dá. Ọkùnrin náà kò tíì rìn rí láti ìgbà tí wọ́n ti bí i. Àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ wá kígbe pé: “Àwọn ọlọ́run ti dà bí ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n sì ti sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ wá wá!” Àwọn èèyàn tí wọ́n kígbe yìí fẹ́ máa jọ́sìn Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ọ̀rẹ́ rẹ̀. Wọ́n pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì wọ́n sì pe Bánábà ní Súúsì. Orúkọ méjèèjì yìí sì jẹ́ orúkọ àwọn òrìṣà.

Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kọ̀, wọn kò jẹ́ kí àwọn èèyàn náà jọ́sìn àwọn. Wọ́n sáré wọ àárín àwùjọ náà, wọ́n sì sọ pé: ‘Ẹ yí padà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.’ (Ìṣe 14:8-15) Ta ni “Ọlọ́run alààyè” náà tí ó dá ohun gbogbo?— Jèhófà, “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé” ni. Jésù pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.” Nítorí náà, ta ni ẹnì kan ṣoṣo tó yẹ ká máa jọ́sìn?— Jèhófà ni!—Sáàmù 83:18; Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 4:11.

Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kò fi gbà kí àwọn èèyàn tẹrí ba fún àwọn?

Àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ló ń sin àwọn ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.” Wọ́n sábà máa ń sin àwọn ohun tí wọ́n fi igi, òkúta, tàbí irin ṣe. (Ẹ́kísódù 32:4-7; Léfítíkù 26:1; Aísáyà 44:14-17) Kódà nígbà mìíràn àwọn èèyàn máa ń pe àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ó jẹ́ akọni, òṣèré tàbí eléré ìje tó jẹ́ olókìkí ní òrìṣà tàbí èèyàn àrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì máa ń júbà wọn. Ṣé ó yẹ kí á máa júbà wọn?—

Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó kọ̀wé pé: ‘Àní ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.’ (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ta ni ọlọ́run yìí?— Sátánì Èṣù ni! Sátánì ti mú kí àwọn èèyàn máa sin àwọn ènìyàn àti onírúurú nǹkan mìíràn.

Nígbà tí Sátánì ń gbìyànjú láti mú kí Jésù tẹrí ba láti sin òun, kí ni Jésù sọ fún Sátánì?— Ó sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Mátíù 4:10) Torí náà, Jésù fi hàn kedere pé ti Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ìjọsìn. Jẹ́ kí á kà nípa àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ó mọ̀ pé ìjọsìn jẹ́ ti Jèhófà nìkan. Orúkọ wọn ni Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò.

Àwọn Hébérù tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́mọdé wọ̀nyí jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run yàn. Ṣe ni wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ Bábílónì. Ọba Bábílónì kan tó ń jẹ́ Nebukadinésárì wá ṣe ère wúrà ńlá kan. Ní ọjọ́ kan, ó pàṣẹ pé nígbà tí gbogbo èèyàn bá gbọ́ ohùn orin kí wọ́n tẹrí ba fún ère náà. Ó kìlọ̀ pé: ‘Ẹnì yòówù tí kò bá tẹrí ba kí ó sì jọ́sìn ni a ó sọ sínú ìléru oníná tí ń jó.’ Kí ni ìwọ ì bá ṣe?—

Kí nìdí tí àwọn ọkùnrin yìí ò fi tẹrí ba fún ère náà?

Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò sábà máa ń ṣe gbogbo ohun tí ọba yìí bá pa láṣẹ. Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀, wọn kò ṣe èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀?— Ìdí ni pé òfin Ọlọ́run sọ pé: ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn yàtọ̀ sí mi. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ kí o sì tẹrí ba fún un.’ (Ẹ́kísódù 20:3-5) Nítorí náà, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ṣe ìgbọràn sí Jèhófà dípò àṣẹ ọba.

Inú bí ọba yìí gan-an, nítorí náà, ó ní kí wọ́n pe àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́mọdé náà wá síwájú òun lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó béèrè pé: ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́ pé ẹ kò sin àwọn ọlọ́run mi? Èmi yóò fún un yín ní àyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Wàyí o, bí ẹ bá ti gbọ́ pé orin ń dún, kí ẹ wólẹ̀ kí ẹ sì jọ́sìn ère tí mo ṣe. Bí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ó sọ yín sínú ìléru oníná tí ń jó. Ta sì ni ọlọ́run yẹn tí ó lè gbà yín sílẹ̀ ní ọwọ́ mi?’

Kí ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà yóò ṣe nísinsìnyí? Kí ni ìwọ ì bá ṣe?— Wọ́n sọ fún ọba pé: ‘Ọlọ́run wa, ẹni tí àwa ń sìn lè gbà wá sílẹ̀. Ṣùgbọ́n bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, àwọn ọlọ́run rẹ kọ́ ni àwa yóò sìn. Àwa kò sì ní tẹrí ba fún ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.’

Ìbínú ọba yìí wá ru. Ó pàṣẹ pé: ‘Ẹ mú kí ìléru yẹn gbóná sí i ní ìlọ́po méje ju ti tẹ́lẹ̀ lọ!’ Ó wá pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ alágbára pé kí wọ́n de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kí wọ́n sì jù wọ́n sínú ìléru náà! Ìléru náà gbóná gan-an débi pé ọwọ́ iná náà pa àwọn ìránṣẹ́ ọba náà fúnra rẹ̀! Àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wá ńkọ́?

Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò balẹ̀ sí àárín iná náà gan-an. Ṣùgbọ́n wọ́n tún dìde dúró! Wọn kò fara pa rárá. Kò sì sí nǹkan kan tí ó dè wọ́n mọ́. Báwo ni èyí ṣe ṣẹlẹ̀?— Ọba yìí wo inú iná ìléru náà, ohun tí ó rí sì bà á lẹ́rù. Ó wà béèrè pé: ‘Àwọn ọkùnrin mẹ́ta kọ́ ni a jù sínú iná ni?’ Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ọba.”

Báwo ni Jèhófà ṣe gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìléru oníná tó ń jó?

Ọba yìí wá sọ pé: ‘Wò ó! Ọkùnrin mẹ́rin ni mo ń wò tí wọ́n ń rìn káàkiri nínú rẹ̀ yìí, iná kò sì jó èyíkéyìí nínú wọn.’ Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kẹrin tó wà pẹ̀lú wọn?— Áńgẹ́lì Jèhófà ni. Ó dáàbò bo àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà kí wọ́n má bàa fara pa.

Nígbà tí ọba rí èyí, ó wá sí ẹnu ọ̀nà ìléru náà, ó sì kígbe pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, ẹ jáde síta kí ẹ sì máa bọ̀!” Nígbà tí wọ́n jáde wá, gbogbo èèyàn rí i pé iná ò jó wọn rárá. Iná ò tiẹ̀ rùn ní ara wọn rárá. Nígbà náà, ọba sọ pé: ‘Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, tí ó rán áńgẹ́lì rẹ̀, tí ó sì gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé wọn kò jọ́sìn ọlọ́run èyíkéyìí rárá bí kò ṣe Ọlọ́run tiwọn.’—Dáníẹ́lì, orí kẹta.

Àwọn ère wo ni àwọn èèyàn ń fògo fún lónìí?

A rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún. Kódà lónìí, àwọn èèyàn máa ń gbé àwọn ère kalẹ̀, àti àwòrán àti àwọn ohun mìíràn tí wọ́n ń júbà bí òrìṣà, wọ́n máa ń sìn wọ́n. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé: “Àsíá jẹ́ mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àgbélébùú ṣe jẹ́ mímọ́.” (Encyclopedia Americana) Àwọn èèyàn lè gbé igi, òkúta, irin tàbí aṣọ kalẹ̀ kí wọ́n máa júbà rẹ̀ bí ère. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láyé àtijọ́ kọ̀ láti júbà ọba ńlá tó wà ní ìlú Róòmù. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Daniel P. Mannix sì sọ pé ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú ti “ẹnì kan tó kọ̀ láti kí àsíá tàbí láti ka ẹ̀jẹ́ ìfọkànsin orílẹ̀-èdè.”

Nítorí náà, tí èèyàn bá gbé ère bíi àwòrán, aṣọ, igi, òkúta tàbí irin kalẹ̀ tó ń sìn ín, ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run ka ìyẹn sí ohunkóhun?— Ṣé ó tọ̀nà kí ìránṣẹ́ Jèhófà máa júbà níwájú irú àwọn ère bẹ́ẹ̀?— Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kọ̀, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà sì dùn sí wọn. Báwo ni ìwọ náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?—

Àwọn tó ń sin Jèhófà kò lè jọ́sìn èèyàn tàbí ohunkóhun mìíràn. Ka ohun tí Bíbélì sọ nípa èyí nínú Jóṣúà 24:14, 15, 19-22; Aísáyà 42:8; 1 Jòhánù 5:21; àti Ìṣípayá 19:10.