Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 29

Ǹjẹ́ Gbogbo Àpèjẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?

Ǹjẹ́ Gbogbo Àpèjẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?

Kí nìdí tí inú Ọlọ́run fi dùn sí àríyá yìí?

ǸJẸ́ o máa ń fẹ́ lọ sí ibi àpèjẹ?— Ìgbádùn máa ń wà níbẹ̀ gan-an. Ǹjẹ́ o rò pé Olùkọ́ Ńlá náà yóò fẹ́ kí á máa lọ sí ibi àpèjẹ?— Bẹ́ẹ̀ ni, Olùkọ́ Ńlá náà pàápàá lọ sí ibi tí a lè pè ní àpèjẹ nígbà kan tí ẹnì kan ṣe ìgbéyàwó, àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀ lé e lọ. Jèhófà ni “Ọlọ́run aláyọ̀,” nítorí náà inú rẹ̀ máa dùn tí a bá ń gbádùn ara wa ní àwọn ibi àpèjẹ tí ó dára.—1 Tímótì 1:11; Jòhánù 2:1-11.

Ojú ewé 29 nínú ìwé yìí sọ fún wa pé Jèhófà pín Òkun Pupa níyà kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gba ibẹ̀ kọjá. Ǹjẹ́ o ṣì rántí ìtàn yẹn?— Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn náà kọjá tán, wọ́n ń kọrin, wọ́n ń jó, wọ́n sì ń fi ọpẹ́ fún Jèhófà. Bí àpèjẹ ló ṣe rí. Inú àwọn èèyàn náà dùn gan-an, ó sì dájú pé inú Ọlọ́run dùn pẹ̀lú.—Ẹ́kísódù 15:1, 20, 21.

Ní nǹkan bí ogójì [40] ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ibi àpèjẹ ńlá mìíràn. Lọ́tẹ̀ yìí, àwọn tó pè wọ́n sí ibi àpèjẹ kì í sin Jèhófà rárá. Àní àwọn tó pè wọ́n láti wá jẹ àpèjẹ náà tiẹ̀ máa ń bọ òrìṣà, wọ́n sì máa ń ṣe ìṣekúṣe pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn. Ṣé o rò pé ó tọ́ láti lọ sí irú ibi àpèjẹ bẹ́ẹ̀?— Ṣé o rí i, inú Jèhófà kò dùn sí i, ó sì fi ìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí rẹ̀.—Númérì 25:1-9; 1 Kọ́ríńtì 10:8.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjì. Ṣé ọ̀kan nínú wọn jẹ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Olùkọ́ Ńlá náà?— Rárá o. Àpèjẹ ọjọ́ ìbí méjèèjì jẹ́ ti àwọn ọkùnrin kan tí kò sin Jèhófà. Ọ̀kan jẹ́ àpèjẹ ọjọ́ ìbí ọba Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Òun ni ó ń ṣàkóso ẹkùn Gálílì nígbà tí Jésù ń gbé níbẹ̀.

Hẹ́rọ́dù Ọba ṣe àwọn ohun búburú púpọ̀ gan-an. Ó gba ìyàwó arákùnrin rẹ̀. Hẹrodíà ni orúkọ obìnrin náà. Jòhánù Oníbatisí, tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, sọ fún Hẹ́rọ́dù pé ohun tí ó ṣe yìí kò dára. Inú Hẹ́rọ́dù kò dùn sí ohun tí ó sọ. Nítorí náà, ó ní kí wọ́n fi Jòhánù sí ẹ̀wọ̀n.—Lúùkù 3:19, 20.

Nígbà tí Jòhánù wà nínú ẹ̀wọ̀n, ọjọ́ pé láti ṣe ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù. Hẹ́rọ́dù pe àpèjẹ ńlá kan. Ó pe àwọn èèyàn pàtàkì tó pọ̀ gan-an wá síbẹ̀. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì gbádùn ara wọn. Ọmọbìnrin Hẹ́rọ́dù tún wọlé wá ó sì jó fún wọn. Inú gbogbo èèyàn dùn sí ijó rẹ̀ débi pé Hẹ́rọ́dù Ọba fẹ́ fún un ní ẹ̀bùn pàtàkì kan. Ó sọ fún un pé: “Ohun yòówù tí o bá béèrè lọ́wọ́ mi, èmi yóò fi í fún ọ, títí kan ìdajì ìjọba mi.”

Kí ni ọmọbìnrin náà yóò béèrè? Ṣé owó ni? àbí àwọn aṣọ tó dára? àbí ààfin tó máa jẹ́ tirẹ̀? Ọmọbìnrin náà kò mọ ohun tó yẹ kó sọ. Nítorí náà ó lọ bá Hẹrodíà ìyá rẹ̀, ó sọ pé: ‘Kí ni kí n béèrè?’

Wàyí o, Hẹrodíà kórìíra Jòhánù Oníbatisí gan-an. Nítorí náà, ó sọ fún ọmọbìnrin rẹ̀ yìí pé kí ó béèrè orí Jòhánù. Ọmọbìnrin náà padà wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Jòhánù Oníbatisí nínú àwo pẹrẹsẹ ní báyìí-báyìí.”

Hẹ́rọ́dù Ọba kò fẹ́ pa Jòhánù nítorí ó mọ̀ pé Jòhánù jẹ́ èèyàn rere. Ṣùgbọ́n Hẹ́rọ́dù ti jẹ́ ẹ̀jẹ́, ó sì ń bẹ̀rù ohun tí àwọn yòókù tó wà ní ibi àpèjẹ náà yóò rò bí òun bá yí ọkàn padà. Nítorí náà, ó rán ọkùnrin kan lọ sínú ẹ̀wọ̀n láti lọ gé orí Jòhánù wá. Láìpẹ́, ọkùnrin náà padà dé. Ó gbé orí Jòhánù sínú àwo pẹrẹsẹ, ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Ọmọbìnrin náà wá gbé e fún ìyá rẹ̀.—Máàkù 6:17-29.

Àpèjẹ ọjọ́ ìbí kejì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ burú bíi ti èyí tí a kọ́kọ́ sọ. Ó jẹ́ ti ọjọ́ ìbí ọba kan ní Íjíbítì. Nígbà àpèjẹ ọjọ́ ìbí yìí pẹ̀lú, ọba náà ní kí wọ́n gé ẹnì kan lórí. Lẹ́yìn ìyẹn, ó so ọkùnrin náà rọ̀ kí àwọn ẹyẹ máa jẹ ara rẹ̀! (Jẹ́nẹ́sísì 40:19-22) Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run fọwọ́ sí àpèjẹ méjèèjì yẹn?— Ṣé ìwọ ì bá fẹ́ láti wà ní ibi àwọn àpèjẹ náà?—

Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà àpèjẹ ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù?

A mọ̀ pé gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì wà níbẹ̀ fún ète kan. Àpèjẹ ọjọ́ ìbí méjì péré ni Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀. Nínú àpèjẹ méjèèjì yìí ni wọ́n sì ti ṣe ohun búburú. Nítorí náà, kí ni o rò pé Ọlọ́run ń sọ fún wa nípa àpèjẹ ọjọ́ ìbí? Ǹjẹ́ Ọlọ́run ń fẹ́ kí á máa ṣe àpèjẹ ọjọ́ ìbí?—

Lóòótọ́ wọn kì í gé ẹnikẹ́ni lórí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀ lóde òní. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn tí kò sin Ọlọ́run tòótọ́ ni ó dá ṣíṣe àpèjẹ ọjọ́ ìbí sílẹ̀. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan ń sọ nípa àwọn àpèjẹ ọjọ́ ìbí tí Bíbélì mẹ́nu kàn, ó sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nìkan ṣoṣo . . . ni ó ṣe àjọyọ̀ ńlá nítorí ọjọ́ tí a bí wọn.” (The Catholic Encyclopedia) Ṣé àwa fẹ́ dà bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ náà?—

Olùkọ́ Ńlá náà ńkọ́? Ṣé ó ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀?— Rárá o, Bíbélì ò sọ ohunkóhun nípa ṣíṣe àpèjẹ ọjọ́ ìbí Jésù. Kódà àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ayé àtijọ́ kò ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí àwọn èèyàn fi yàn láti máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù ní December 25?—

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé wọ́n yan ọjọ́ yẹn nítorí pé “àwọn ará Róòmù ti ń ṣe Àjọyọ̀ Òrìṣà Sátọ̀n lọ́jọ́ yẹn, wọ́n fi ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí oòrùn.” (The World Book Encyclopedia) Nítorí náà, o ò rí i pé ọjọ́ tí àwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe ọdún ni àwọn èèyàn yàn láti máa ṣe ọjọ́ ìbí Jésù!

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí kò fi lè jẹ́ oṣù December ni wọ́n bí Jésù?— Ìdí náà ni pé Bíbélì sọ pé nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣì wà ní pápá ní òru. (Lúùkù 2:8-12) Wọn kò sì ní lè wà ní ìta gbangba ní pápá nínú oṣù December tó jẹ́ ìgbà òtútù àti òjò.

Kí ló fi hàn pé kò lè jẹ́ December 25 ni wọ́n bí Jésù?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn mọ̀ pé kì í ṣe ọjọ́ ìbí Jésù ni Kérésìmesì jẹ́. Wọ́n tiẹ̀ mọ̀ pé ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ tí àwọn abọ̀rìṣà ń ṣe ayẹyẹ kan tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ṣì ń ṣe Kérésìmesì. Oúnjẹ jíjẹ àti nǹkan mímu tó máa ń wáyé wù wọ́n ju pé kí wọ́n wádìí ohun tí Ọlọ́run rò nípa ayẹyẹ yẹn lọ. Ṣùgbọ́n àwa fẹ́ ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—

Nítorí náà, tí a bá pe àpèjẹ, a fẹ́ rí i dájú pé ó jẹ́ àpèjẹ rere ní ojú Jèhófà. Ìgbà tó bá wù wá láàárín ọdún ni a lè ṣe àpèjẹ. A kò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ dúró de ọjọ́ pàtàkì kan. A lè jẹ oúnjẹ pàtàkì kí a sì ṣe eré ìdárayá tó gbádùn mọ́ni. Ǹjẹ́ ìwọ yóò fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?— Bóyá o lè sọ fún àwọn òbí rẹ, kí wọ́n bá ọ ṣètò àpèjẹ kan. Èyíinì yóò dára, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Ṣùgbọ́n kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò àpèjẹ kan, ó yẹ kí o rí i dájú pé ó jẹ́ ohun tí inú Ọlọ́run yóò dùn sí o.

Báwo la ṣe lè rí i dájú pé inú Ọlọ́run dùn sí àpèjẹ wa?

Bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí á máa ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí ní gbogbo ìgbà fara hàn nínú Òwe 12:2; Jòhánù 8:29; Róòmù 12:2; àti 1 Jòhánù 3:22.