Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 45

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? Bí A Ṣe Lè Fi Hàn Pé À Ń Fẹ́ Ẹ

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? Bí A Ṣe Lè Fi Hàn Pé À Ń Fẹ́ Ẹ

ǸJẸ́ o mọ àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?— Bí o kò bá mọ̀ ọ́n, a lè jọ kà á nínú Bíbélì, ní Mátíù 6:9-13. Nínú àdúrà yìí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń pè ní Àdúrà Olúwa, ni a ti rí ọ̀rọ̀ yìí: “Kí ìjọba rẹ dé.” Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́?—

Ṣé o rí i, ẹnì kan tó ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè tàbí ìlú ńlá kan là ń pè ní ọba. Ìṣàkóso rẹ̀ ni a sì ń pè ní ìjọba. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ààrẹ ni wọ́n ń pe olórí ìjọba wọn. Kí ni à ń pe Alákòóso ìjọba, tàbí ìṣàkóso, tí Ọlọ́run ṣèlérí?— Ọba ni. Ìdí nìyẹn tí a fi ń pe ìṣàkóso tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí ní Ìjọba.

Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run fi jẹ Ọba ìjọba Rẹ̀?— Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi ni. Kí nìdí tí Jésù fi dára ju ẹnikẹ́ni mìíràn tí àwọn èèyàn lè yàn?— Ìdí ni pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀, Jèhófà gan-an. Nítorí náà, ó máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo.

Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí á tó bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ìbí rẹ̀, tó sì sọ pé òun ni Ọlọ́run yóò fi jẹ Ọba. Jẹ́ kí a kà nípa èyí nínú Aísáyà 9:6, 7, nínú Bibeli Yoruba Atọ́ka. Ó sọ pé: “A bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yoo si wà li ejika rẹ̀: a o si maa pe orukọ rẹ̀ ni . . . Ọmọ-Alade Alaafia. Ní ti ìbísí ijọba rẹ ati ti alaafia ki yoo ni ipẹkun.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí wọ́n fi pe Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run ní “Ọmọ-Aládé” níhìn-ín?— Ṣé o rí i, ọmọ aládé jẹ́ ọmọ ọba. Jésù sì jẹ́ Ọmọ Jèhófà, Ọba Ńlá náà. Jèhófà sì tún wá fi Jésù jẹ Ọba ìjọba Rẹ̀, èyí tí yóò ṣàkóso ilẹ̀ ayé fún ẹgbẹ̀rún ọdún. (Ìṣípayá 20:6) Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí ‘wàásù ó ń wí pé: “Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”’—Mátíù 4:17.

Kí ni o rò pé ó jẹ́ ìdí tí Jésù fi ń sọ pé Ìjọba náà ti sún mọ́lé?— Ìdí ni pé Ọba tí yóò ṣàkóso ní ọ̀run nígbà tó bá yá wà pẹ̀lú wọn níbẹ̀ gan-an! Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún àwọn èèyàn pé: “Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.” (Lúùkù 17:21) Ṣé inú rẹ kò ní dùn láti rí Ọba tí Jèhófà yàn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ kí o tiẹ̀ lè fọwọ́ kàn án?—

Wàyí o, sọ fún mi, iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jésù wá ṣe ní ayé?— Bí Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè yẹn rèé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Jésù mọ̀ pé òun nìkan ò ní lè wàásù fún gbogbo èèyàn tán. Nítorí náà, kí ni o rò pé ó ṣe?—

Iṣẹ́ wo ni Jésù wá ṣe lórí ilẹ̀ ayé?

Jésù mú àwọn èèyàn kan dání, ó sì kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà. Àwọn tí ó kọ́kọ́ kọ́ ni àwọn méjìlá tí ó yàn ṣe àpọ́sítélì. (Mátíù 10:5, 7) Ṣùgbọ́n ṣé àwọn àpọ́sítélì yìí nìkan ni Jésù kọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ yìí? Rárá o, Bíbélì sọ pé Jésù kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn kí wọ́n lè máa wàásù. Nígbà tí ó yá, ó rán àwọn àádọ́rin [70] ọmọ ẹ̀yìn mìíràn ní méjì-méjì pé kí wọ́n máa wàásù nìṣó níwájú òun. Kí ni wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn?— Jésù sọ pé: “Ẹ sì máa bá a lọ ní sísọ fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ tòsí yín.’” (Lúùkù 10:9) Èyí ń mú kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa ìjọba tí Ọlọ́run ṣèlérí.

Nígbà àtijọ́ ní Ísírẹ́lì, ẹni tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jọba máa ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú ìlú láti fi ara rẹ̀ han àwọn èèyàn. Èyí ni Jésù ṣe nígbà tí ó wá sí Jerúsálẹ́mù kẹ́yìn. Ṣé o mọ̀, Jésù ni yóò di Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn ń fẹ́ kí ó jẹ́ Ọba àwọn?—

Ó dára, bí ó ṣe ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn èrò tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀. Àwọn mìíràn ń gé ẹ̀ka igi, wọ́n ń fi sí ojú ọ̀nà. Wọ́n ń ṣe èyí láti fi hàn pé àwọn ń fẹ́ kí Jésù jẹ́ Ọba àwọn. Wọ́n ń kígbe pé: “Alábùkún ni Ẹni tí ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà!” Ṣùgbọ́n inú gbogbo èèyàn kọ́ ló dùn o. Kódà, àwọn aṣáájú ìsìn kan tiẹ̀ sọ fún Jésù pé, ‘Sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n dákẹ́.’—Lúùkù 19:28-40.

Kí ló mú kí àwọn èèyàn yí ọkàn pa dà pé àwọn ò fẹ́ kí Jésù jẹ́ Ọba àwọn mọ́?

Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn náà, wọ́n fàṣẹ ọba mú Jésù, wọ́n sì mú un lọ sínú ilé ńlá kan, kí o lọ jẹ́jọ́ níwájú Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà. Àwọn ọ̀tá Jésù sọ pé Jésù ń sọ pé ọba ni òun àti pé ó ń tàpá sí ìjọba Róòmù. Nítorí náà Pílátù béèrè nípa èyí lọ́wọ́ Jésù. Jésù fi hàn pé kì í ṣe pé òun fẹ́ gba ìjọba wọn. Ó sọ fún Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 18:36.

Pílátù wá jáde, ó sọ fún àwọn èèyàn náà pé òun kò rí ìwà búburú kankan tí Jésù hù. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà kò sáà fẹ́ kí Jésù jẹ́ Ọba àwọn. Wọn kò fẹ́ kí Pílátù fi Jésù sílẹ̀. (Jòhánù 18:37-40) Lẹ́yìn tí Pílátù tún bá Jésù sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ó dá a lójú pé Jésù kò hùwà àìtọ́ kankan. Nítorí náà, Pílátù mú Jésù jáde fún ìgbà ìkẹyìn, ó sọ pé: “Wò ó! Ọba yín!” Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà kígbe pé: “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́gi!”

Pílátù bi wọ́n pé: “Ṣé kí n kan ọba yín mọ́gi ni?” Àwọn olórí àlùfáà dáhùn pé: “Àwa kò ní ọba kankan bí kò ṣe Késárì.” O ò rí nǹkan bí? Àwọn àlùfáà burúkú yìí ti yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà pé kí wọ́n kọ Jésù!—Jòhánù 19:1-16.

Bí o ṣe ṣẹlẹ̀ nígbà àtijọ́ yẹn náà ló ṣe ń ṣẹlẹ̀ lóde òní pẹ̀lú. Àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ni kò fẹ́ kí Jésù jẹ́ Ọba àwọn. Wọ́n lè sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ o, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ kí Ọlọ́run tàbí Kristi máa sọ ohun tó yẹ kí àwọn ṣe fún àwọn. Wọ́n fẹ́ máa dá ìjọba ara wọn ṣe lórí ilẹ̀ ayé níbí.

Àwa ńkọ́? Nígbà tí a kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti gbogbo àwọn ohun ìyanu tí yóò ṣe, báwo ló ṣe mú kí ọkàn wa rí sí Ọlọ́run?— A fẹ́ràn rẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Báwo ni a ṣe lè wá fi han Ọlọ́run pé a fẹ́ràn rẹ̀ lóòótọ́ àti pé à ń fẹ́ kí Ìjọba rẹ̀ máa ṣàkóso wa?—

Kí nìdí tí Jésù fi ṣe ìrìbọmi, báwo ni Ọlọ́run sì ṣe fi hàn pé òun fọwọ́ sí i?

A lè mú kí Ọlọ́run mọ èrò ọkàn wa bí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Kí ni Jésù ṣe láti fi hàn pé òun fẹ́ràn Jèhófà?— Jésù ṣàlàyé pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:29) Dájúdájú, ńṣe ni Jésù wá sí ayé láti wá ṣe ‘ìfẹ́ Ọlọ́run’ àti “láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Hébérù 10:7; Jòhánù 4:34) Wo ohun tí Jésù ṣe kí ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀.

Jésù sọ̀ kalẹ̀ lọ bá Jòhánù Oníbatisí nínú Odò Jọ́dánì. Nígbà tí wọ́n wọnú omi náà, Jòhánù ri Jésù bọ inú omi náà pátápátá, ó sì gbé e sókè padà. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jòhánù fi ri Jésù bọ omi?—

Ibo ni a ti lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

Jésù ló sọ pé kí Jòhánù ri òun bọmi. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ń fẹ́ kí Jésù ṣe ìrìbọmi?— A mọ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí pé nígbà tí Jésù jáde wá látinú omi, ó gbọ́ ohùn Ọlọ́run láti ọ̀run tí ó sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.” Ọlọ́run tiẹ̀ rán ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ wá ní àwọ̀ àdàbà, tí ó sì bà lé Jésù lórí. Nítorí náà, bí Jésù ṣe ṣe ìrìbọmi, ńṣe ló ń fi hàn pé òun fẹ́ láti fi gbogbo ìgbésí ayé òun sin Jèhófà, àní títí láé.—Máàkù 1:9-11.

Nísinsìnyí, ọmọdé ṣì ni ọ́. Ṣùgbọ́n kí lo máa ṣe bí o bá dàgbà?— Ṣé wàá ṣe bíi ti Jésù kí o ṣe ìrìbọmi?— Ó yẹ kí o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, nítorí Bíbélì sọ pé “ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Nígbà tí ìwọ náà bá ṣe ìrìbọmi, ò ń fi hàn nìyẹn pé o fẹ́ kí Ìjọba Ọlọ́run ṣàkóso rẹ. Ṣùgbọ́n ṣíṣe ìrìbọmi nìkan kò tó o.

A ní láti ṣègbọràn sí gbogbo ohun tí Jésù ń kọ́ni. Jésù sọ pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ “apá kan ayé.” Ṣé à ń ṣègbọràn sí Jésù tí a bá ń lọ́wọ́ sí àwọn ìwà àti ìṣe ayé yìí? Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ yẹra fún irú àwọn nǹkan ti ayé bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 17:14) Kí ni wọ́n wá ṣe dípò ìyẹn?— Wọ́n ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ka iṣẹ́ yẹn sí iṣẹ́ pàtàkì nínú ìgbésí ayé wọn. Ṣé àwa náà lè ṣe iṣẹ́ yẹn pẹ̀lú?— Bẹ́ẹ̀ ni o, a óò kúkú ṣe é tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn là ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé.

Jọ̀wọ́ wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn tí ó sọ ohun tí a lè ṣe láti fi hàn pé a fẹ́ kí Ìjọba Ọlọ́run dé: Mátíù 6:24-33; 24:14; 1 Jòhánù 2:15-17 àti 5:3.