Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 46

Omi Pa Ayé kan Run—Ǹjẹ́ Irú Ẹ̀ Tún Lè Ṣẹlẹ̀ Mọ́?

Omi Pa Ayé kan Run—Ǹjẹ́ Irú Ẹ̀ Tún Lè Ṣẹlẹ̀ Mọ́?

ǸJẸ́ o tíì gbọ́ kí ẹnì kan sọ pé òpin ayé ń bọ̀ rí?— Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lóde òní. Àwọn èèyàn kan rò pé ogun kan ló máa bẹ́ sílẹ̀, tí àwọn èèyàn yóò wá lo bọ́ǹbù átọ́míìkì olóró èyí tí yóò pa ayé rẹ́. Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run yóò pa ilẹ̀ ayé wa ẹlẹ́wà àti ojú ọ̀run tó fani mọ́ra àti àwọn ìràwọ̀ tó ń tàn lójú ọ̀run yìí run?—

A ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sẹ́yìn pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa òpin ayé. Bíbélì sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ.” (1 Jòhánù 2:17) Ǹjẹ́ o rò pé òpin ayé yóò jẹ́ òpin ilẹ̀ ayé wa yìí?— Rárá o. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé yìí “kí a lè máa gbé inú rẹ̀,” àní sẹ́, kí àwọn èèyàn máa gbé inú rẹ̀ kí wọ́n sì gbádùn rẹ̀ dáadáa. (Aísáyà 45:18) Sáàmù 37:29 sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Èyí ló mú kí Bíbélì tún sọ pé ilẹ̀ ayé yóò wà títí láé.—Sáàmù 104:5; Oníwàásù 1:4.

Nítorí náà, bí òpin ayé kò bá jẹ́ òpin ilẹ̀ ayé, kí ló jẹ́ nígbà náà?— A lè mọ ohun tó jẹ́ bí a bá fara balẹ̀ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà. Bíbélì sọ pé: “Ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi [tàbí ìkún omi] bò ó mọ́lẹ̀.”—2 Pétérù 3:6.

Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni la Àkúnya, tàbí Ìkún Omi, yẹn já nígbà ayé Nóà?— Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 2:5.

Kí ni ayé tí Ọlọ́run pa run nígbà ayé Nóà?

Nítorí náà, kí ni ayé tó wá sí òpin nígbà yẹn? Ṣé ilẹ̀ ayé ni, tàbí àwọn èèyàn burúkú?— Bíbélì sọ pé “ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” ni. Tún kíyè sí i pé a pe Nóà ní “oníwàásù.” Orí kí ni o rò pé ìwàásù rẹ̀ dá lé?— Ńṣe ni Nóà ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa òpin “ayé ìgbà yẹn.”

Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa Ìkún Omi ńlá yẹn, ó sọ ohun tí àwọn èèyàn ń ṣe lásìkò tí òpin yẹn dé fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ohun tó sọ fún wọn nìyí: “Ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, [àwọn èèyàn] ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” Jésù wá sọ pé bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni àwọn èèyàn yóò máa ṣe pẹ̀lú lásìkò tí òpin ayé ìsinsìnyí yóò dé.—Mátíù 24:37-39.

Ọ̀rọ̀ Jésù yìí fi hàn pé a lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú ohun tí àwọn èèyàn ń ṣe ṣáájú Ìkún Omi. Látinú ohun tí o kà ní Orí 10 nínú ìwé yìí, ǹjẹ́ o rántí ohun tí àwọn èèyàn yẹn ṣe?— Àwọn ọkùnrin kan jẹ́ òṣìkà tó ń bú mọ́ni, tó sì ń ṣe àwọn nǹkan burúkú. Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ni kò tiẹ̀ fetí sílẹ̀ rárá nígbà tí Ọlọ́run rán Nóà kí ó lọ wàásù fún wọn.

Ó wá di ọjọ́ kan, Jèhófà sọ fún Nóà pé Òun yóò fi ìkún omi pa àwọn èèyàn búburú run. Omi yẹn yóò bo gbogbo ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀, àti àwọn òkè pàápàá. Jèhófà sọ fún Nóà pé kí ó kan ọkọ̀ áàkì ńlá kan. Ọkọ̀ yìí dà bí àpótí ńlá kan tó gùn gbọọrọ. O lè rí àwòrán rẹ̀ tí o bá ṣí ìwé rẹ sí àwòrán tó wà lójú ewé 238.

Ọlọ́run sọ pé kí Nóà kan ọkọ̀ áàkì náà tóbi gan-an kí inú rẹ̀ lè gba òun àti ìdílé rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko mìíràn. Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣiṣẹ́ gidigidi. Wọ́n gé àwọn igi ńláńlá lulẹ̀, wọ́n wá fi àwọn igi yìí kan ọkọ̀ áàkì náà. Iṣẹ́ yìí gba ọdún púpọ̀ kí wọ́n tó parí rẹ̀ nítorí ọkọ̀ áàkì náà tóbi gan-an.

Ǹjẹ́ o rántí ohun mìíràn tí Nóà tún ń ṣe láàárín àwọn ọdún tó ń kan ọkọ̀ áàkì náà?— Ó ń wàásù, ó ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa Ìkún Omi tó ń bọ̀. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn gba ìkìlọ̀ náà? Kò sí ẹnikẹ́ni tó gbọ́ o, àfi ìdílé Nóà nìkan. Àwọn èèyàn yòókù kò fetí sí i rárá nítorí àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ń ṣe. Ǹjẹ́ o rántí ohun tí Jésù sọ pé wọ́n ń ṣe?— Ohun tí wọ́n ń ṣe ni pé wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fúnni. Wọn kò rò pé ìwà àwọn burú, wọn kò sì wá àyè láti fetí sí ọ̀rọ̀ Nóà. Nítorí náà, jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Nígbà tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ti wọnú ọkọ̀ áàkì náà, Jèhófà ti ilẹ̀kùn ọkọ̀ náà pa. Àwọn èèyàn tó wà lóde kò gbà síbẹ̀síbẹ̀ pé Ìkún Omi yóò dé. Ṣùgbọ́n lójijì, omi bẹ̀rẹ̀ sí dà láti ojú ọ̀run! Kò rọra rọ̀ gẹ́gẹ́ bí òjò lásán ṣe máa ń rọ̀ o. Ńṣe ni omi náà ń dà yàà-yàà-yàà! Láìpẹ́ omi yìí di odò ńláńlá, tó ń pariwo púpọ̀ gan-an. Odò wọ̀nyí ń bi àwọn igi ńlá wó, wọ́n ń ti àwọn òkúta ńláńlá lọ bíi pé wọ́n jẹ́ òkúta wẹ́wẹ́ lásán. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn tí kò sí nínú ọkọ̀ áàkì?— Jésù sọ pé: ‘Ìkún omi dé, ó sì gbá gbogbo wọn lọ.’ Gbogbo àwọn tí kò sí nínú ọkọ̀ áàkì ló kú dà nù. Kí ló fà á?— Jésù sọ pé, ‘wọn kò fiyè sí i.’ Wọn kò fetí sílẹ̀!—Mátíù 24:39; Jẹ́nẹ́sísì 6:5-7.

Èé ṣe tí kò fi yẹ kí á kàn máa ronú nípa bí a óò ṣe máa jẹ̀gbádùn nìkan ṣáá?

Wàyí o, rántí pé Jésù sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn náà jẹ́ ẹ̀kọ́ fún wa lónìí. Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ lára wọn?— Ṣé o rí i, kì í ṣe kìkì ìwà búburú tí àwọn èèyàn náà ń hù nìkan ló jẹ́ kí wọ́n pa run. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló pa run nítorí pé ọwọ́ wọn ti dí jù débi pé wọn kò rí àyè láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. A ní láti ṣọ́ra kí á má ṣe dà bíi tiwọn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—

Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run yóò tún fi omi pa ayé yìí run?— Rárá o, Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun kò tún ní fi omi pa ayé run mọ́. Ọlọ́run sọ pé: “Òṣùmàrè mi ni mo fi sí àwọsánmà, yóò sì jẹ́ àmì.” Jèhófà sọ pé òṣùmàrè náà yóò jẹ́ àmì pé “a kì yóò fi àkúnya omi ké gbogbo ẹran ara kúrò mọ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 9:11-17.

Nítorí náà, kí ó dá wa lójú pé Ọlọ́run kò tún ní fi ìkún omi pa ayé run mọ́. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, Bíbélì sọ fún wa dájúdájú pé òpin ayé ń bọ̀. Nígbà tí Ọlọ́run bá máa pa ayé yìí run, ta ni Ọlọ́run kò ní pa run?— Ṣé àwọn èèyàn tó ti fẹ́ràn àwọn nǹkan mìíràn jù débi pé wọn kò fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run rárá ni? Ṣé àwọn tí ọwọ́ wọn ti dí jù tí wọn kò ráyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni? Kí ni èrò rẹ?—

A fẹ́ wà lára àwọn tí Ọlọ́run yóò gbà là, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ohun tó dùn mọ́ wa gan-an bí ìdílé wa bá lè dà bíi ti Nóà kí Ọlọ́run lè gba gbogbo wa là?— Bí a bá máa la òpin ayé já, ó yẹ kí á mọ bí Ọlọ́run ṣe máa pa ayé run àti bí yóò ṣe mú ayé tuntun òdodo rẹ̀ dé. Jẹ́ kí á wo bí ó ṣe máa ṣe é.

Bíbélì sọ bí ó ṣe máa ṣe é fún wa nínú Dáníẹ́lì orí kejì, ẹsẹ ìkẹrìnlélógójì [44]. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tiwa yìí nígbà tí ó sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”

Ǹjẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí yé ọ?— Bíbélì sọ pé ìjọba Ọlọ́run yóò pa gbogbo ìjọba ayé yìí run. Kí nìdí rẹ̀?— Ìdí ni pé wọn kò ṣègbọràn sí Ẹni tí Ọlọ́run fi jẹ Ọba. Ta sì ni ẹni náà?— Jésù Kristi ni o!

Jésù Kristi, ẹni tí Ọlọ́run fi jẹ Ọba, yóò pa ayé yìí run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì

Jèhófà Ọlọ́run ní ẹ̀tọ́ láti pinnu irú ìjọba tó yẹ kí ó máa ṣàkóso, ó sì ti fi Jésù Ọmọ rẹ̀ jẹ Ọba. Láìpẹ́, Jésù Kristi, Alákòóso tí Ọlọ́run yàn, yóò ṣáájú àwọn áńgẹ́lì láti wá pa gbogbo ìjọba ayé yìí run. Bíbélì ṣàpèjúwe bí Jésù yóò ṣe ṣe èyí nínú Ìṣípayá orí ìkọkàndínlógún [19], ẹsẹ ìkọkànlá [11] sí ìkẹrìndínlógún [16], bí o ṣe rí i nínú àwòrán yìí. Ogun tí Ọlọ́run yóò fi pa àwọn ìjọba ayé run ni Bíbélì pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì, tàbí Amágẹ́dọ́nì.

Wàyí o, Ọlọ́run sọ pé Ìjọba òun yóò pa ìjọba àwọn èèyàn run. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó sọ pé àwa ní kí á pa wọ́n run?— Rárá o. Ohun tí Bíbélì pe Amágẹ́dọ́nì ni “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Bẹ́ẹ̀ ni o, ogun Ọlọ́run ni Amágẹ́dọ́nì jẹ́, ó sì ti yan Jésù Kristi láti kó àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ agbo ọmọ ogun ọ̀run wá láti ja ogun yẹn. Ǹjẹ́ ogun Amágẹ́dọ́nì ti sún mọ́lé bí? Jẹ́ kí á wo bí a ṣe lè mọ̀.

Jẹ́ kí á jọ kà nípa ìgbà tí Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn èèyàn burúkú run, tí yóò sì gba àwọn tó ń sìn ín là, nínú Òwe 2:21, 22; Aísáyà 26:20, 21; Jeremáyà 25:31-33; àti Mátíù 24:21, 22.