Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 47

Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Pé Amágẹ́dọ́nì Ti Sún Mọ́lé

Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Pé Amágẹ́dọ́nì Ti Sún Mọ́lé

ṢEBÍ o mọ ohun tí àmì jẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Ní Orí 46 inú ìwé yìí, a kà nípa àmì tí Ọlọ́run pèsè láti fi hàn pé òun kò ní fi ìkún omi pa ayé run mọ́. Bákan náà, àwọn àpọ́sítélì béèrè àmì tí àwọn yóò fi mọ̀ pé Jésù ti padà dé àti èyí tí wọ́n yóò fi mọ̀ pé òpin ayé, tàbí ètò àwọn nǹkan, ti sún mọ́lé.—Mátíù 24:3.

Níwọ̀n bí Jésù yóò tí wà ní ọ̀run, tí a kò ní lè fojú rí i, àwọn èèyàn nílò àmì tí wọ́n lè fojú rí tí wọn yóò fi mọ̀ pé ó tí bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso. Nítorí náà Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó yẹ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa retí lórí ilẹ̀ ayé níbí. Tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá ti ń ṣẹlẹ̀ á jẹ́ pé Jésù ti padà dé àti pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí Ọba.

Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti wà lójú fò, nítorí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fiyè sí igi ọ̀pọ̀tọ́ àti gbogbo igi yòókù: Nígbà tí wọ́n bá ti rudi, nípa ṣíṣàkíyèsí rẹ̀, ẹ̀yin mọ̀ fúnra yín pé nísinsìnyí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé.” O máa ń mọ̀ bí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn bá ti sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wàá mọ̀ pé Amágẹ́dọ́nì ti sún mọ́lé bí o bá ti rí i tí àwọn nǹkan tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ń ṣẹlẹ̀.—Lúùkù 21:29, 30.

Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù ń kọ́ wa nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa igi ọ̀pọ̀tọ́?

Ní ojú ewé yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a óò máa wo àwòrán àwọn nǹkan tí Jésù sọ pé yóò jẹ́ ara àmì tí yóò fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé. Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ti ṣẹlẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi jẹ́ Alákòóso rẹ̀ yóò fọ́ gbogbo àwọn ìjọba yòókù túútúú, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Orí 46 inú ìwé yìí.

Nítorí náà, fara balẹ̀ wo àwọn àwòrán tó wà lójú ewé méjèèjì tó ṣáájú eléyìí, nítorí a óò sọ̀rọ̀ nípa wọn. O lè ka ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí o rí nínú àwọn àwòrán yìí nínú Mátíù 24:6-14 àti Lúùkù 21:9-11. Bákan náà, kíyè sí nọ́ńbà tí a kọ sára àwòrán kọ̀ọ̀kan. Ìwọ yóò rí nọ́ńbà kan náà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpínrọ̀ tó ṣàlàyé àwòrán náà. Wàyí o, jẹ́ ká wò ó bóyá púpọ̀ lára àmì tí Jésù sọ yìí ń ṣẹ lóde òní.

(1) Jésù sọ pé: “Ẹ óò gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun; . . . orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” Ǹjẹ́ o tíì gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun?— Wọ́n ja Ogun Àgbáyé Kìíní ní ọdún 1914 sí 1918, lẹ́yìn náà wọ́n tún ja Ogun Àgbáyé Kejì ní ọdún 1939 sí 1945. Ṣáájú ogun méjèèjì yìí kò tíì sí ogun àgbáyé rí o! Àmọ́ nísinsìnyí, jákèjádò ayé ni ogun ti ń jà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ là ń gbọ́ ìròyìn nípa ogun lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò tàbí kí a kà á nínú ìwé ìròyìn.

(2) Jésù sì tún sọ pé: “Àìtó oúnjẹ . . . yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.” Ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń rí oúnjẹ jẹ tó. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń kú lójoojúmọ́ nítorí pé wọn kò rí oúnjẹ jẹ tó.

(3) Jésù tún sọ pé: ‘Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ń jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn?— Àìsàn ni o, èyí tó máa ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú kan tó ń jẹ́ àrùn gágá pa nǹkan bí ogún mílíọ́nù èèyàn láàárín nǹkan bí ọdún kan péré. Lóde òní, ó ṣeé ṣe kí àrùn éèdì tiẹ̀ pa iye àwọn èèyàn tó pọ̀ ju ìyẹn lọ pàápàá. Àwọn àrùn bí àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ọkàn àti àwọn àrùn mìíràn sì wà pẹ̀lú, tó ń pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́dọọdún.

(4) Jésù sọ apá mìíràn lára àmì yẹn, ó ní: “Ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.” Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ń jẹ́ ìsẹ̀lẹ̀?— Ìsẹ̀lẹ̀ máa ń mú kí ilẹ̀ tí o dúró lé lórí bẹ̀rẹ̀ sí mì jìgìjìgì. Àwọn ilé máa ń wó lulẹ̀, ó sì sábà máa ń pa àwọn èèyàn. Láti ọdún 1914, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ ló ń wáyé lọ́dọọdún. Ǹjẹ́ o tíì gbọ́ ìròyìn nípa ìsẹ̀lẹ̀ rí?—

(5) Jésù sọ pé apá mìíràn lára àmì náà ni pé ‘ìwà búburú yóò máa pọ̀ sí i.’ Ìdí nìyẹn tí olè jíjà àti ìwà ipá fi pọ̀ bẹ́ẹ̀. Ibi gbogbo ni àwọn èèyàn ti máa ń bẹ̀rù pé àwọn olè lè wá fọ́ ilé àwọn. Kò tíì sí ìgbà kankan rí tí ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá púpọ̀ wà níbi gbogbo láyé bíi ti ìsinsìnyí.

(6) Jésù sọ apá pàtàkì kan lára àmì yẹn nígbà tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Bí o bá gbà pé “ìhìn rere” yìí jẹ́ nǹkan pàtàkì, nígbà náà ó yẹ kí o máa sọ ọ́ fún àwọn èèyàn. Lọ́nà yìí, ìwọ yóò lè wà lára àwọn tó ń mú apá yìí ṣẹ nínú àmì náà.

Àwọn èèyàn kan lè sọ pé ṣebí àwọn ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ yìí ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ṣúgbọ̀n kò tíì ṣẹlẹ̀ rí pé kí gbogbo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ pa pọ̀ nígbà kan náà ní àwọn ibi tó pọ̀ tó báyìí káàkiri ayé. Nítorí náà, ǹjẹ́ o mọ ohun tí àmì yẹn túmọ̀ sí?— Ó túmọ̀ sí pé tí a bá ti rí i pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀, kò ní pẹ́ tí ayé tuntun Ọlọ́run yóò fi rọ́pò ayé búburú yìí.

Nígbà tí Jésù sọ àmì yìí, ó tún sọ̀rọ̀ nípa àkókò pàtàkì kan nínú ọdún. Ó sọ pé: “Ẹ máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù.” (Mátíù 24:20) Kí lo rò pé ó fẹ́ kí á mọ̀ tó fi sọ bẹ́ẹ̀?—

Ó dára, tí ẹnì kan bá fẹ́ sá àsálà kúrò níbi ewu nígbà òtútù, tí ojú ọjọ́ sábà máa ń jẹ́ kí ó ṣòro tàbí kí ó tiẹ̀ léwu láti rìnrìn àjò, kí ló lè ṣẹlẹ̀?— Tí onítọ̀hún kò bá kú sí i, yóò jẹ ìyà tó pọ̀ gan-an. Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun ìbànújẹ ni yóò jẹ́, pé kí èèyàn kú sínú ìjì ìgbà òtútù kìkì nítorí pé ó fi àwọn nǹkan mìíràn dí ara rẹ̀ lọ́wọ́ tí kò fi rí àyè láti tètè gbéra ìrìn àjò rẹ̀ ṣáájú ìgbà náà?—

Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa sísá àsálà nígbà òtútù, ẹ̀kọ́ wo ló ń kọ́ wa?

Ǹjẹ́ o lóye ohun pàtàkì tí Jésù ń sọ fún wa nígbà tí ó sọ pé kí á má ṣe dúró de ìgbà òtútù kí á tó sá àsálà?— Ohun tó ń sọ fún wa ni pé nígbà tí a ti mọ̀ pé Amágẹ́dọ́nì sún mọ́lé, kí á má ṣe jáfara láti bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọ́run láti lè fi hàn pé a fẹ́ràn rẹ̀. Bí a bá jáfara, ó ṣeé ṣe kí a má lè sin Jèhófà mọ́. Èyí á wá mú kí àwa náà dà bí ti àwọn èèyàn tó wà ní ayé nígbà Ìkún Omi, tí wọ́n gbọ́ ìkìlọ̀ Nóà, ṣùgbọ́n tí wọn kò wọnú ọkọ̀ áàkì.

Nísinsìnyí, jẹ́ kí á wá sọ̀rọ̀ nípa bí ayé yóò ṣe rí lẹ́yìn tí ogun Amágẹ́dọ́nì bá parí. A óò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún gbogbo àwa tó fẹ́ràn rẹ̀ tí a sì ń sìn ín nísinsìnyí.

Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí tún jẹ́ ká mọ̀ pé Amágẹ́dọ́nì ti sún mọ́lé: 2 Tímótì 3:1-5; 2 Pétérù 3:3, 4.