Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KÌÍNÍ

Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?

Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ ní ti gidi?

  • Irú ẹni wo gan-an ni Ọlọ́run jẹ́? Ṣé ó lórúkọ?

  • Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run?

1, 2. Kí nìdí tó fi sábà máa ń dára kéèyàn béèrè ìbéèrè?

ǸJẸ́ o ti kíyè sí bí àwọn ọmọdé ṣe máa ń béèrè ìbéèrè rí? Ọ̀pọ̀ ọmọdé ló máa ń béèrè ìbéèrè ní gbàrà tí wọ́n bá ti mọ̀rọ̀ọ́ sọ. Wọ́n á gbójú sókè wọ́n á sì máa wo ẹni tí wọ́n ń bi ní ìbéèrè bíi pé kó tètè dáhùn. Wọ́n á wá máa béèrè ìbéèrè bíi: Kí ló dé tójú ọ̀run fi funfun? Kí ló dé táwọn ẹyẹ fi ń ké? Wọ́n á nàka sí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run lálẹ́, wọ́n á béèrè pé, Kí làwọn ohun tó wà lókè yẹn? Ó lè wù ọ́ láti tẹ́ àwọn ọmọdé lọ́run nípa dídáhùn ìbéèrè wọn, àmọ́ kì í fìgbà gbogbo rọrùn torí bó o ṣe ń dáhùn ọ̀kan ni òmíràn á máa tẹ̀ lé e, wọ́n á máa béèrè pé: Kí ló ṣe igbá, kí ló ṣe àwo?

2 Àwọn ọmọdé nìkan kọ́ ló máa ń béèrè ìbéèrè o. Ti pé a ti dàgbà kò ní ká má béèrè ìbéèrè mọ́. Ìdí tá a sì fi ń béèrè ìbéèrè ni pé ká lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe, ká lè mọ ewu tó yẹ ká sá fún tàbí ká lè rí ìdáhùn sí ohun tá à ń wádìí rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dà bí ẹni pé bí ọ̀pọ̀ ti ń dàgbà, wọn kì í béèrè ìbéèrè mọ́, pàápàá àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jú lọ. Wọn kì í wá ìdáhùn sí ìbéèrè wọn mọ́.

3. Kí ló fà á tí ọ̀pọ̀ kò fi gbìyànjú mọ́ láti wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì?

3 Ronú nípa ìbéèrè tó wà ní èèpo ẹ̀yìn ìwé yìí tàbí àwọn èyí tá a béèrè nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú, tàbí àwọn èyí tá a béèrè ní ìbẹ̀rẹ̀ Orí yìí. Ìwọ̀nyẹn jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ tó ṣeé ṣe kí ìwọ náà máa béèrè. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò gbìyànjú mọ́ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí. Kí ló fà á? Ǹjẹ́ Bíbélì lè dáhùn àwọn ìbéèrè náà? Àwọn kan rò pé àwọn ìdáhùn tó wà nínú Bíbélì ṣòroó lóye. Ìtìjú ni kì í jẹ́ káwọn mìíràn lè béèrè ohun tí wọn kò mọ̀. Àwọn kan sì rò pé àwọn aṣáájú ìsìn tàbí àwọn olùkọ́ nìkan ló lè dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Ìwọ ńkọ́, kí lèrò rẹ?

4, 5. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè pàtàkì tá a lè béèrè nígbèésí ayé, kí sì nìdí tó fi yẹ ká wá ìdáhùn sí wọn?

4 Ó ṣeé ṣe kí ìwọ pàápàá fẹ́ mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì téèyàn máa ń béèrè nígbèésí ayé. Ó dájú pé o máa ń ṣe kàyéfì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé: ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá èèyàn sáyé? Ṣé téèyàn bá ti kú láyé tá a wà yìí, ó parí náà nìyẹn? Irú ẹni wo ni Ọlọ́run tiẹ̀ jẹ́ gan-an?’ Àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn bọ́gbọ́n mu, ó sì yẹ kó o máa wádìí títí tí wàá fi rí ìdáhùn tó jóòótọ́ tó sì tẹ́ ọ lọ́rùn. Jésù Kristi, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí olùkọ́ni sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.”—Mátíù 7:7.

5 Tó o bá ń “bá a nìṣó ní wíwá” ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì wọ̀nyẹn, wàá rí i pé ìwádìí náà yóò lérè. (Òwe 2:1-5) Àwọn kan tiẹ̀ ti lè sọ fún ọ tẹ́lẹ̀ pé kò sí ìdáhùn, àmọ́, ìdáhùn wà, o sì rí àwọn ìdáhùn náà nínú Bíbélì. Àwọn ìdáhùn tó wà nínú Bíbélì kò ṣòroó lóye. Àní ńṣe ni wọ́n tiẹ̀ ń jẹ́ ká ní ìrètí àti ayọ̀. Wọ́n á jẹ́ kó o ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn nígbèésí ayé rẹ nísinsìnyí. Jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ báyìí nípa ṣíṣàyẹ̀wò ìbéèrè kan tó ń jà gùdù lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn.

ṢÉ ALÁÌLÁÀÁNÚ ÀTI ẸNI TÍ KÒ BÌKÍTÀ NI ỌLỌ́RUN?

6. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ fi lérò pé Ọlọ́run ò bìkítà nípa gbogbo ohun tí ojú ẹ̀dá èèyàn ń rí?

6 Ọ̀pọ̀ ló máa dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ ni, sí ìbéèrè yẹn. Wọ́n lè rò pé, ‘ká ní Ọlọ́run bìkítà nípa wa ni, ṣé ayé á rí bó ti rí yìí?’ Nígbà tá a wo gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, a rí i pé ogun, ìkórìíra àti ìnira ló kún inú ayé. Nínú àwa èèyàn, kò sẹ́ni tí kì í ṣàìsàn, kò sẹ́ni tí kì í níṣòro, kò sì sẹ́ni táwọn èèyàn rẹ̀ kì í kú. Ìyẹn ló fà á tí ọ̀pọ̀ fi ń sọ pé, ‘Ká ní Ọlọ́run bìkítà nípa wa ni, ṣé kò ní wá nǹkan ṣe kí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn má bàa ṣẹlẹ̀?’

7. (a) Báwo ni àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ṣe mú kí ọ̀pọ̀ lérò pé aláìláàánú ni Ọlọ́run? (b) Kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa àwọn nǹkan búburú tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ sí wa?

7 Èyí tó tiẹ̀ burú jù ni pé, àwọn tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn máa ń mú kí wọ́n ronú pé aláìláàánú ni Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Nígbà tí nǹkan ìbànújẹ́ bá ṣẹlẹ̀, wọ́n á sọ fún àwọn èèyàn pé àmúwá Ọlọ́run ni. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni irú àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ ń dá Ọlọ́run lẹ́bi pé òun ló ń fa àwọn láabi tó ń ṣẹlẹ̀. Ṣé Ọlọ́run ló ń fa láabi wọ̀nyẹn lóòótọ́? Kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an? Jákọ́bù 1:13 dáhùn pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” Nítorí náà, Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn láabi tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé o. (Ka Jóòbù 34:10-12) Òótọ́ ni pé ó ń fàyè gba àwọn ohun búburú pé kó ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn fàyè gba nǹkan kan pé kó ṣẹlẹ̀ àti kéèyàn nǹkan ọ̀hún.

8, 9. (a) Kí lo lè fi ṣe àkàwé ìyàtọ̀ tó wà láàárín fífa ìwà ibi àti fífàyè gbà á? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa rò pé kò dára bí Ọlọ́run ṣe fàyè gbà á pé kí aráyé máa tọ ọ̀nà búburú?

8 Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bàbá kan tó jẹ́ olóye àti onífẹ̀ẹ́ tí ọmọkùnrin rẹ̀ kan tó ti dàgbà ṣì ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí ọmọ yẹn bá lọ yàyàkuyà tó sì wá sọ pé òun fẹ́ kúrò nílé, bàbá yìí ò ní dá a dúró pé kó má lọ. Tọ́mọ yìí bá wá lọ bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé burúkú tó sì kó sínú ìjàngbọ̀n, ṣé a lè sọ pé bàbá rẹ̀ ló àwọn ìṣòro tó kó sí? Rárá o. (Lúùkù 15:11-13) Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run ò dá ẹ̀dá èèyàn dúró pé kí wọ́n má tọ ọ̀nà tí àwọn fúnra wọn yàn láti máa tọ̀. Àmọ́, a ò lè sọ pé Ọlọ́run ló fa àwọn ìṣòro tó tìdí ọ̀nà tí àwọn fúnra wọn yàn láti máa tọ̀, yọ. Nítorí náà, kò tọ́ ká máa dá Ọlọ́run lẹ́bi pé òun ló ń fa wàhálà tó ń bá ọmọ aráyé.

9 Ó nídìí tí Ọlọ́run fi fàyè gba kí aráyé máa tọ ọ̀nà búburú. Àmọ́, kì í ṣe ọ̀ranyàn pé kó sọ ìdí rẹ̀ fún wa níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa tó sì jẹ́ ọlọgbọ́n àti alágbára. Síbẹ̀, ó ṣì sọ ìdí rẹ̀ nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Wàá túbọ̀ mọ̀ nípa ìdí yìí ní Orí Kọkànlá ìwé yìí. Àmọ́, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro wa o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fún wa ní ìrètí ohun tó máa jẹ́ ojútùú sí àwọn ìṣòro wa!—Aísáyà 33:2.

10. Kí nìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé yóò mú gbogbo ohun tí ìwà ibi ti fà kúrò?

10 Síwájú sí i, Ọlọ́run jẹ́ mímọ́. (Aísáyà 6:3) Ìyẹn túmọ̀ sí pé ó mọ́ pátápátá láìkù síbì kan. Kò sí ìwà ibi kankan lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí náà, a lè gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Ṣùgbọ́n a ò lè gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn pátápátá o, nítorí pé èèyàn máa ń di oníwà ìbàjẹ́ nígbà mìíràn. Kódà ẹni tó ń ṣòótọ́ jù lára àwọn ọmọ aráyé tó wà nípò àṣẹ kò lè tún ohun táwọn ẹni ibi bá bà jẹ́ ṣe. Àmọ́, alágbára gbogbo ni Ọlọ́run ní tiẹ̀. Ó lágbára láti mú gbogbo ohun tí ìwà ibi ti fà fún ọmọ aráyé kúrò, á sì mú un kúrò. Bí Ọlọ́run bá dá sí i báyìí, ńṣe ni ohun tó bá ṣe á mú kí ìwà ibi dópin títí láé!—Ka Sáàmù 37:9-11.

OJÚ WO NÍ ỌLỌ́RUN FI Ń WO ÌWÀ ÌRẸ́JẸ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń HÙ?

11. (a) Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù? (b) Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ?

11 Ní báyìí, ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àtohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ? Ṣó o rí i, Bíbélì kọ́ni pé Ọlọ́run jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Sáàmù 37:28) Ìdí nìyẹn tí ọ̀ràn ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fi jẹ ẹ́ lógún gan-an. Ó kórìíra gbogbo onírúurú ìwà ìrẹ́jẹ. Bíbélì sọ pé nígbà kan tí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ibi, ‘ó dun Ọlọ́run dọ́kàn.’ (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6) Ọlọ́run ò sì tíì yí padà. (Málákì 3:6) Ó ṣì kórìíra ìjìyà tó wà káàkiri ayé lónìí. Kò sì wù ú kéèyàn máa jìyà. Bíbélì sọ pé: “Ó bìkítà fún yín.”—Ka 1 Pétérù 5:7.

Bíbélì kọ́ni pé Jèhófà ní Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ tó dá ọ̀run òun ayé

12, 13. (a) Kí nìdí tá a fi ní ànímọ́ rere bí ìfẹ́, nítorí ìfẹ́ tá a sì ní yìí, báwo ni àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ṣe rí lára wa? (b) Kí nìdí tó fi lè dá ọ lójú pé Ọlọ́run á ṣe nǹkan kan nípa àwọn ìṣòro tó wà láyé?

12 Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé kò wu Ọlọ́run kí ìyà máa jẹ ọmọ aráyé? Ẹ̀rí mìíràn tún wà. Bíbélì fi kọ́ni pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Nítorí pé Ọlọ́run tó dá wa ní ànímọ́ rere làwa náà ṣe ní ànímọ́ rere, ó ṣe tán, ẹní bí ni làá jọ. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó máa ń dùn ọ́ tó o bá rí i tí aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ń jìyà? Tó bá jẹ́ pé o kórìíra irú ìwà ìrẹ́jẹ bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run tiẹ̀ tún wá kórìíra rẹ̀ ju bó o ṣe kórìíra rẹ̀ lọ.

13 Ọ̀kan lára àwọn ohun tó dára jù lára àwa ẹ̀dá èèyàn ni pé a lè nífẹ̀ẹ́. Ńṣe nìyẹn náà fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́. Bíbélì fi kọ́ni pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Nítorí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ làwa náà ṣe nífẹ̀ẹ́. Ká sọ pé o ní agbára láti fòpin sí ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, ǹjẹ́ ìfẹ́ tó o ní á mú kó o fòpin sí i? Ó dájú pé wàá fòpin sí i! Jẹ́ kó dá ọ lójú pé bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìjìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ. Àwọn ìlérí tá a mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé yìí kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ tàbí ìrètí asán o. Ó dájú hán-únhán-ún pé àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò nímùúṣẹ! Láti lè ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí wọ̀nyẹn, o ní láti túbọ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run tó ṣe àwọn ìlérí ọ̀hún.

ỌLỌ́RUN FẸ́ KÓ O MỌ ẸNI TÓUN JẸ́

Tó o bá fẹ́ kẹ́nì kan mọ̀ ọ́, ǹjẹ́ o ò ní sọ orúkọ rẹ fún un? Ọlọ́run sọ orúkọ ara rẹ̀ fún wa nínú Bíbélì

14. Kí ni orúkọ Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa lò ó?

14 Tó o bá fẹ́ kẹ́nì kan mọ̀ ọ́, kí ni wàá ṣe? Ǹjẹ́ o ò ní sọ orúkọ rẹ fún un? Ó dára, ṣé Ọlọ́run ní orúkọ? Ọ̀pọ̀ ìsìn ló sọ pé “Ọlọ́run” tàbí “Olúwa” ni orúkọ rẹ̀, àmọ́, Ọlọ́run tàbí Olúwa kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-an. Orúkọ oyè ni wọ́n, bí “ọba” àti “ààrẹ” ṣe jẹ́ orúkọ oyè. Bíbélì fi kọ́ni pé orúkọ oyè tí Ọlọ́run ní pọ̀. “Ọlọ́run” àti “Olúwa” wà lára àwọn orúkọ oyè náà. Ṣùgbọ́n Bíbélì tún kọ́ni pé Ọlọ́run ní orúkọ. Orúkọ rẹ̀ ni Jèhófà. Sáàmù 83:18 sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Bí o kò bá rí Jèhófà nínú ìtumọ̀ Bíbélì tí o ní, wo Àfikún “Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò Ó”, kó o lè mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì tó ti pẹ́. Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kó o mọ orúkọ òun ó sì fẹ́ kó o máa lò ó. Ká kúkú sọ pé ńṣe ni Jèhófà ń lo Bíbélì láti fi sọ ẹni tó jẹ́ fún ọ.

15. Kí ni orúkọ Ọlọ́run fi hàn nípa irú ẹni tó jẹ́?

15 Orúkọ tí Ọlọ́run fún ara rẹ̀ yìí ní ìtumọ̀ tó kún rẹ́rẹ́. Orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, túmọ̀ sí pé ó lè mú ìlérí èyíkéyìí tó bá ṣe ṣẹ ó sì lè ṣe ohunkóhun tó bá ní lọ́kàn. * Àrà ọ̀tọ̀ lorúkọ Ọlọ́run, kò sírú ẹ̀. Òun nìkan ló ń jẹ́ orúkọ náà. Láwọn ọ̀nà kan, Jèhófà ò láfiwé. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

16, 17. Kí ni àwọn orúkọ oyè Jèhófà wọ̀nyí lè kọ́ wa nípa Jèhófà: (a) “Olódùmarè”? (b) “Ọba ayérayé”? (d) “Ẹlẹ́dàá”?

16 A rí i lẹ́ẹ̀kan, pé Sáàmù 83:18 sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Bákan náà, Jèhófà nìkan ni Bíbélì pè ní “Olódùmarè.” Ìṣípayá 15:3 sọ pé: “Títóbi àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé.” Orúkọ oyè náà, “Olódùmarè” jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló lágbára jù lọ láyé àti lọ́run. Kò sẹ́ni tó lágbára tó o. Orúkọ oyè náà, “Ọba ayérayé” sì rán wa létí pé Jèhófà ò lẹ́gbẹ́ lọ́nà mìíràn. Òun nìkan ló ti wà láti ayérayé. Sáàmù 90:2 sọ pé: “Àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.” Ìyẹn jọ èèyàn lójú gan-an, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

17 Jèhófà ò tún láfiwé nítorí pé òun nìkan ni Ẹlẹ́dàá. A kà nínú Ìṣípayá 4:11 pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Gbogbo ohun tó ṣeé ṣe kó o ronú kàn, látorí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tá ò lè rí tó wà lọ́run, àtàwọn ìràwọ̀ tó máa ń kún ojú ọ̀run ní alẹ́, tó fi mọ́ àwọn èso tó ń so lórí igi, àtàwọn ẹja tó ń wẹ̀ lágbami òkun àti láwọn odò, gbogbo wọn wà nítorí pé Jèhófà tí í ṣe Ẹlẹ́dàá dá wọn!

ǸJẸ́ O LÈ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ?

18. Kí ló mú káwọn kan rò pé àwọn ò lè sún mọ́ Ọlọ́run láéláé, àmọ́ kí ni Bíbélì fi kọ́ni?

18 Nígbà táwọn kan gbọ́ nípa ànímọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí Jèhófà ní, àyà wọ́n já. Ohun tó já wọ́n láyà ni pé Ọlọ́run ti tóbi jù lọ́ba, pé àwọn ò lè sún mọ́ ọn láéláé àti pé, àwọn ò tiẹ̀ já mọ́ ǹkan kan lójú irú Ọlọ́run tó tóbi lọ́ba bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ṣé èrò yìí tọ̀nà? Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni yàtọ̀ sí èyí. Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Kódà Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.

19. (a) Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ Ọlọ́run, èrè wo la ó sì rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Nínú àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní, àwọn wo ló fà ọ́ mọ́ra jù lọ?

19 Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o máa tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ò ń kọ́ yìí. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Bó ṣe rí nìyẹn o, Bíbélì fi kọ́ni pé tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù Kristi, èyí á sìn wá lọ sí “ìyè àìnípẹ̀kun”! Bá a sì ṣe sọ ṣáájú, “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:16) Jèhófà tún ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ mìíràn tó dára tó sì ń fani sún mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) Ó jẹ́ ‘ẹni rere ó sì ṣe tán láti dárí jini.’ (Sáàmù 86:5) Ọlọ́run ní sùúrù. (2 Pétérù 3:9) Ó jẹ́ adúróṣinṣin. (Ìṣípayá 15:4) Bó o ti ń ka Bíbélì, wàá rí i bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ ànímọ́ tó fani mọ́ra mìíràn tó ní.

20-22. (a) Ǹjẹ́ bá ò ṣe lè rí Ọlọ́run sọ pé ká má lè sún mọ́ ọn? Ṣàlàyé. (b) Kí ni àwọn èèyàn kan tí wọ́n rò pé ire rẹ làwọn ní lọ́kàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ọ́ pé kó o ṣe?

20 Òótọ́ ni pé o ò lè rí Ọlọ́run nítorí pé ẹni ẹ̀mí téèyàn ò lè rí ni. (Jòhánù 1:18; 4:24; 1 Tímótì 1:17) Àmọ́ tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nínú Bíbélì, o lè mọ ẹni tó jẹ́. Bí onísáàmù ṣe sọ, o lè “rí adùn Jèhófà.” (Sáàmù 27:4; Róòmù 1:20) Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tó ni wàá túbọ̀ máa mọ̀ pé ẹni gidi ni, tí wàá sì máa rí ìdí tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kó o sì sún mọ́ ọn.

Kékeré ni ìfẹ́ tí baba rere kan ní sáwọn ọmọ rẹ̀ tá a bá fi wé ìfẹ́ tí Baba wa ọ̀run ní sí wa

21 Díẹ̀díẹ̀, wàá máa lóye ìdí tí Bíbélì fi kọ́ wa pé ká mọ Jèhófà ní Bàbá. (Mátíù 6:9) Kì í ṣe pé Jèhófà fún wa ní ìwàláàyè nìkan ni, àmọ́ ó tún fẹ́ kí ayé wa dára gan-an, bí bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ á ṣe fẹ́ káyé àwọn ọmọ rẹ̀ dára. (Sáàmù 36:9) Bíbélì tún kọ́ni pé àwa èèyàn lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 2:23) O ò rí i pé àǹfààní ńlá ni pé kó o di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé!

22 Bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn kan tí wọ́n rò pé ire rẹ làwọn ń wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ọ́ pé kó o jáwọ́ nínú irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè máa ṣàníyàn pé ìgbàgbọ́ rẹ á yàtọ̀ sí tàwọn. Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí ọ lọ́wọ́ láti ní ọ̀rẹ́ tó dára jù lọ.

23, 24. (a) Kí nìdí tó fi yẹ́ kó o máa béèrè ìbéèrè nípa àwọn ohun tí kò yé ọ? (b) Kí ni a óò kẹ́kọ̀ọ́ nínú orí tó kàn?

23 Òótọ́ ni pé àwọn ohun kan á wà tí kò ní kọ́kọ́ yé ọ. Ó lè gba ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó o tó lè béèrè pé kẹ́nì kan ṣàlàyé ohun tí o ò mọ̀ fún ọ, àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ìtìjú mú ọ fà sẹ́yìn láti béèrè ìbéèrè. Jésù sọ pé ó dára kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bí ọmọ kékeré. (Mátíù 18:2-4) Bá a sì ṣe mọ̀, àwọn ọmọdé máa ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Ọlọ́run fẹ́ kó o mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ. Bíbélì yin àwọn èèyàn kan tí wọ́n hára gàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Àwọn èèyàn náà fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ láti rí i dájú pé òtítọ́ lohun táwọn ń kọ́.—Ka Ìṣe 17:11.

24 Ọ̀nà tó dára jù lọ tẹ́nì kan lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ni pé kó ṣàyẹ̀wò Bíbélì. Ó yàtọ̀ sí gbogbo ìwé mìíràn. Ọ̀nà wo ló fi yàtọ̀ sí wọn? Orí tó kàn ní yóò ṣàlàyé.

^ ìpínrọ̀ 15 Àlàyé síwájú sí i lórí ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run àti bá a ṣe ń pè é wà nínú Àfikún tó wà ní ẹ̀yìn ìwé yìí ní ojú ìwé 195 sí 197.