Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸRIN

Ta Ni Jésù Kristi?

Ta Ni Jésù Kristi?
  • Ipa àrà ọ̀tọ̀ wo ni Jésù ń kó?

  • Ibo ló ti wá?

  • Irú èèyàn wo ló jẹ́ nígbà tó wá sórí ilẹ̀ ayé?

1, 2. (a) Tẹ́nì kan bá kàn mọ orúkọ olókìkí èèyàn kan, kí nìdí tí kò fi túmọ̀ sí pé ó mọ̀ ọ́n délédélé? (b) Kí ni onírúurú nǹkan táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹni tí Jésù jẹ́?

ÀÌMỌYE gbajúmọ̀ èèyàn ló wà láyé. Òdú làwọn kan, wọn kì í ṣàìmọ̀ fólóko ládùúgbò tí wọ́n ń gbé, nílùú wọn tàbí lórílẹ̀-èdè wọn. Ẹni àmọ̀káyé sì làwọn mìíràn. Àmọ́, ti pé ẹnì kan mọ orúkọ olókìkí èèyàn kan kò túmọ̀ sí pé ó mọ̀ ọ́n délédélé. Kò túmọ̀ sí pé o mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ẹni yẹn títí kan irú ẹni tó jẹ́ gan-an.

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbàá ọdún [2,000] sẹ́yìn ni Jésù gbé lórí ilẹ̀ ayé, ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ò mọ ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. Àwọn kan sọ pé èèyàn rere kan ni Jésù wulẹ̀ jẹ́. Àwọn kan sọ pé wòlíì lásán ni. Ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn sì ni pé Ọlọ́run ni Jésù ó sì yẹ kéèyàn máa sìn ín. Kí lèrò tìẹ, ṣé ó yẹ kéèyàn máa sìn Jésù?

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o mọ òtítọ́ nípa Jésù?

3 Ó ṣe pàtàkì pé kó o mọ òtítọ́ nípa Jésù. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Kò sí àní-àní pé, tó o bá ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti Jésù Kristi, wàá ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 14:6) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jésù fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa gbé ìgbésí ayé àti bó ṣe yẹ kéèyàn máa bá àwọn ẹlòmíràn lò. (Jòhánù 13:34, 35) Ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run la jíròrò ní Orí Kìíní ìwé yìí. Ní báyìí, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun ti Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa Jésù Kristi.

MÈSÁYÀ TÍ ỌLỌ́RUN ṢÈLÉRÍ

4. Kí làwọn orúkọ oyè náà “Mèsáyà” àti “Kristi” túmọ̀ sí?

4 Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù ni Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run yóò rán ẹnì kan wá gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà, tàbí Kristi. Àwọn orúkọ oyè méjèèjì náà, “Mèsáyà” (tó wá látinú èdè Hébérù) àti “Kristi” (tó wá látinú èdè Gíríìkì), túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró.” Ọlọ́run yóò fòróró yan Ẹni tó ṣèlérí yìí, ìyẹn ni pé, yóò yàn án sí ipò àrà ọ̀tọ̀ kan. Nínú àwọn orí kan tó ṣì wà níwájú nínú ìwé yìí, a óò kọ́ nípa ipa pàtàkì tí Jésù ń kó nínú mímú ìlérí Ọlọ́run ṣẹ. A óò tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìbùkún tí Jésù lè mú bá wa nísinsìnyí pàápàá. Àmọ́ ṣá o, ó dájú pé, kí wọ́n tó bí Jésù, ọ̀pọ̀ ló ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni yóò jẹ́ Mèsáyà?’

5. Kí ló dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn lójú nípa Jésù?

5 Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ará Násárétì lójú pé Jésù ọ̀gá àwọn ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòhánù 1:41) Láìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n ni ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún Jésù pé: “Ìwọ ni Kristi náà.” (Mátíù 16:16) Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyẹn lójú pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí? Báwo ló ṣe lè dá àwa náà lójú?

6. Ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ran àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè dá Mèsáyà mọ̀.

6 Àwọn wòlíì Ọlọ́run tó gbé ayé ṣáájú Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa Mèsáyà. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí ló jẹ́ káwọn èèyàn dá Jésù mọ̀ nígbà tó dé. Jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí: Ká sọ pé wọ́n rán ọ níṣẹ́ pé kó o lọ pàdé ẹnì kan tí o kò mọ̀ rí ní ibùdókọ̀ kan tàbí ní pápákọ̀ òfuurufú. Ǹjẹ́ ìṣòro dídá ẹni náà mọ̀ kò ní dín kù tẹ́nì kan bá ṣàpèjúwe bí ẹni náà ṣe rí fún ọ? Lọ́nà kan náà, Jèhófà ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí a ṣe lè dá Mèsáyà náà mọ̀ nínú Bíbélì, ó ṣe èyí nípa sísọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Mèsáyà náà yóò ṣe àti ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí i. Ṣíṣẹ tí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ṣẹ ló jẹ́ kí àwọn olóòótọ́ èèyàn dá Mèsáyà náà mọ̀ kedere.

7. Kí ni méjì lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sára Jésù?

7 Gbé àpẹẹrẹ méjì péré yẹ̀ wò. Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ ni pé, ní èyí tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún méje lọ kí wọ́n tó bí Ẹni tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí, wòlíì Míkà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ ìlú kékeré kan ní ilẹ̀ Júdà ni wọn óò bí i sí. (Míkà 5:2) Ibo wá ni wọ́n bí Jésù sí? Ìlú yẹn gan-an ni! (Mátíù 2:1, 3-9) Àpẹẹrẹ kejì ni pé, ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù, àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Dáníẹ́lì 9:25 sọ ọdún tí Mèsáyà yóò fara hàn, ìyẹn ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. * Ṣíṣẹ tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn bẹ́ẹ̀ ṣẹ jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí.

Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó di Mèsáyà tàbí Kristi

8, 9. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, kí lohun tó ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé òun ni Mèsáyà?

8 Ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà wáyé nígbà tó kù díẹ̀ kí ọdún 29 Sànmánì Kristẹni parí. Ọdún yẹn ni Jésù lọ bá Jòhánù Olùbatisí ní odò Jọ́dánì pé kó rí òun bọmi. Jèhófà ti ṣèlérí fún Jòhánù tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé yóò rí àmì kan tí yóò fi lè dá Mèsáyà mọ̀. Jòhánù sì rí àmì ọ̀hún nígbà tó ri Jésù bọmi. Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ rèé: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’” (Mátíù 3:16, 17) Lẹ́yìn tí Jòhánù rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, kò ṣiyèméjì kankan nípa pé Ọlọ́run ló rán Jésù. (Jòhánù 1:32-34) Ní ìṣẹ́jú tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí rẹ̀, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ sórí Jésù lọ́jọ́ tó ṣèrìbọmi yẹn ló di Mèsáyà, tàbí Kristi, ẹni tí Ọlọ́run yàn láti jẹ Aṣáájú àti Ọba.—Aísáyà 55:4.

9 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó nímùúṣẹ àti ẹ̀rí tí Ọlọ́run fẹnu ara rẹ̀ jẹ́ fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Ṣùgbọ́n Bíbélì tún dáhùn ìbéèrè pàtàkì méjì mìíràn tá a máa ń béèrè nípa Jésù Kristi. Àwọn ìbéèrè náà ni: Ibo ni Jésù ti wá? Irú èèyàn wo ló sì jẹ́ nígbà tó wá sórí ilẹ̀ ayé?

IBO NI JÉSÙ TI WÁ?

10. Ibo ni Bíbélì fi kọ́ni pé Jésù wà kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé?

10 Bíbélì fi kọ́ni pé ọ̀run ni Jésù ń gbé kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé. Míkà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù la óò bí Mèsáyà sí. O tún sọ pé Mèsáyà ti wà “láti àwọn àkókò ìjímìjí.” (Míkà 5:2) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé ọ̀run ni òun wà kí wọ́n tó bí òun gẹ́gẹ́ bí èèyàn. (Ka Jòhánù 3:13; 6:38, 62; 17:4, 5) Níwọ̀n bó ti jẹ́ ọ̀run ni Jésù ń gbé nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí, ó ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.

11. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé Jésù ni ààyò Ọmọ Jèhófà?

11 Jésù ni ààyò Ọmọ Jèhófà, ó sì nídìí tí Jèhófà fi kà á sí bẹ́ẹ̀. Ìdí kan ni pé Bíbélì pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” nítorí pé òun ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá. * (Kólósè 1:15) Ìdí mìíràn tó mú kí Ọlọ́run ka Ọmọ yìí sí ààyò ni pé, òun ni ‘Ọmọ bíbí kan ṣoṣo’ rẹ̀. (Jòhánù 3:16) Èyí túmọ̀ sí pé Jésù nìkan ni Ọlọ́run fọwọ́ ara rẹ̀ dá ní tààràtà. Òun nìkan tún ni Ọlọ́run lò nígbà tó ń dá gbogbo ohun mìíràn. (Kólósè 1:16) Bákan náà, a tún ń pe Jésù ní “Ọ̀rọ̀ náà.” (Jòhánù 1:14) Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run nípa jíjẹ́ iṣẹ́ tí Bàbá rẹ̀ rán an sáwọn ọmọ rẹ̀ mìíràn, àtẹ̀dá ẹ̀mí àtẹ̀dá èèyàn.

12. Báwo la ṣe mọ̀ pé àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run kò bá Ọlọ́run dọ́gba?

12 Ǹjẹ́ àkọ́bí Ọmọ yìí bá Ọlọ́run dọ́gba, bí àwọn kan ṣe rò? Bíbélì ò kọ́ wa bẹ́ẹ̀ o. Nínú àwọn ìpínrọ̀ tó ṣáájú, a ti rí i pé ńṣe ni Ọlọ́run dá Ọmọ tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe kedere pé Ọmọ yìí ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tó sì jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ní tiẹ̀ kò níbẹ̀rẹ̀ kò sì lópin. (Sáàmù 90:2) Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí ò tiẹ̀ gbìyànjú ẹ̀ rí láti bá Bàbá rẹ̀ dọ́gba, oko kò sáà lè jẹ́ ti baba tọmọ kó máà láàlà. Bíbélì fi kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere pé Bàbá tóbi ju Ọmọ lọ. (Ka Jòhánù 14:28; 1 Kọ́ríńtì 11:3) Jèhófà nìkan ni “Ọlọ́run Olódùmarè.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:1) Nítorí náà, kò sẹ́ni kankan tó lè bá a dọ́gba. *

13. Bíbélì sọ pé Ọmọ Ọlọ́run jẹ́ “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí,” kí nìyẹn túmọ̀ sí?

13 Àìlóǹkà ọdún ṣáájú kí Ọlọ́run tó dá ọ̀run, ìràwọ̀ àti ilẹ̀ ayé ni Jèhófà àti àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ fi jọ wà pa pọ̀. O ò rí i pé wọ́n á fẹ́ràn ara wọn gan-an ni! (Jòhánù 3:35; 14:31) Ààyò Ọmọ yìí jọ Bàbá rẹ̀ púpọ̀. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé Ọmọ yìí ni “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí.” (Kólósè 1:15) Gẹ́gẹ́ bí ọmọ èèyàn kan ṣe lè fàwọn ohun kan jọ bàbá rẹ̀ gan-an, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ tó ń gbé lọ́run yìí jọ Bàbá rẹ̀ nítorí pé ó ní àwọn ànímọ́ tí Bàbá rẹ̀ ní, ó sì fìwà jọ ọ́.

14. Báwo ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà ṣe di ẹni tí wọ́n bí gẹ́gẹ́ bí èèyàn?

14 Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà yìí fínnúfíndọ̀ fi ọ̀run sílẹ̀ ó sì wá gbé orí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn. Ṣùgbọ́n o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni wọ́n ṣe lè bí ẹ̀dá ẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí èèyàn?’ Iṣẹ́ ìyanu ni Jèhófà fi ṣe èyí. Ńṣe ló mú àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ yìí kúrò lọ́run tó sì fi ìwàláàyè rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà. Ẹ̀dá èèyàn kankan kò bá Màríà ní ìbálòpọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni pípé ni ọmọ tí Màríà bí, ó sì sọ ọ́ ní Jésù.—Lúùkù 1:30-35.

IRÚ ÈÈYÀN WO NI JÉSÙ NÍGBÀ TÓ WÁ SÓRÍ ILẸ̀ AYÉ?

15. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ipasẹ̀ Jésù la gbà mọ Jèhófà dunjú?

15 Àwọn ohun tí Jésù sọ àtàwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ká mọ̀ ọ́n dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, ipasẹ̀ Jésù la gbà mọ Jèhófà dunjú. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Rántí pé Ọmọ yìí jọ Bàbá rẹ̀ láìkù síbì kan. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:9) Àwọn ìwé Bíbélì mẹ́rin tá a mọ̀ sí àwọn ìwé Ìhìn Rere, ìyẹn Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìgbésí ayé Jésù Kristi, ìgbòkègbodò rẹ̀ àti ìwà rẹ̀.

16. Kí ni lájorí iṣẹ́ Jésù, ti ta sì ni iṣẹ́ ọ̀hún?

16 “Olùkọ́” làwọn èèyàn mọ Jésù sí. (Jòhánù 1:38; 13:13) Kí ló fi kọ́ni? Lájorí iṣẹ́ rẹ̀ ni “ìhìn rere ìjọba náà,” tí í ṣe Ìjọba Ọlọ́run tó wà lọ́run tí yóò ṣàkóso gbogbo ayé, tí yóò sì mú ìbùkún tí kò lópin bá àwọn èèyàn tó bá ṣègbọràn. (Mátíù 4:23) Ta ló ni iṣẹ́ tí Jésù ṣe yìí? Ohun tí Jésù fẹnu ara rẹ̀ sọ ni pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi,” ìyẹn Jèhófà. (Jòhánù 7:16) Jésù mọ̀ pé Bàbá òun fẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ní Orí Kẹjọ, a óò kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí yóò gbé ṣe.

17. Ibo ni Jésù ti máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kí sì nìdí tó fi lo ara rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn?

17 Ibo ni Jésù ti máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Ibikíbi tó bá ti rí wọn ni, ì bàá jẹ́ ní àrọko, nínú ìlú ńlá tàbí ní abúlé, ní ọjà tàbí ní ilé àwọn èèyàn. Jésù ò retí pé káwọn èèyàn wá bá òun. Ńṣe ló lọ bá wọn fúnra rẹ̀. (Máàkù 6:56; Lúùkù 19:5, 6) Kí ló dé tí Jésù fi lo ara rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó sì lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ̀ láti wàásù àti láti kọ́ àwọn èèyàn? Ìdí ni pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe nìyẹn. Gbogbo ìgbà sì ni Jésù máa ń ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀. (Jòhánù 8:28, 29) Ṣùgbọ́n, ìdí mìíràn wà tí Jésù fi wàásù. Ìdí náà ni pé tó bá rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n wá bá a, ńṣe ni àánú wọn máa ń ṣe é. (Ka Mátíù 9:35, 36) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn tó yẹ kí wọ́n máa kọ́ wọn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe pa wọ́n tì, wọ̀n ò kọ́ wọn. Jésù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí àwọn èèyàn náà gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

18. Nínu àwọn ànímọ́ Jésù, èwo lo wù ọ́ jù?

18 Ọlọ́yàyà èèyàn ni Jésù ó sì lójú àánú. Abájọ táwọn èèyàn fi máa ń sún mọ́ ọn. Ó tún jẹ́ onínúure. Kódà, ńṣe lara àwọn ọmọdé máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀. (Máàkù 10:13-16) Jésù kì í ṣe ojúsàájú ẹnì kankan. Ó kórìíra ìwà ìbàjẹ́ àti kéèyàn máa gbé ẹ̀bi fún aláre. (Mátíù 21:12, 13) Lákòókò táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ buyì fún àwọn obìnrin, tó sì jẹ́ pé ìwọ̀nba àǹfààní díẹ̀ làwọn obìnrin máa ń ní láwùjọ, ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn obìnrin lò ní tiẹ̀ buyì kún wọn. (Jòhánù 4:9, 27) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jésù kì í ṣe ti ojú ayé lásán. Nígbà kan, ó fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, iṣẹ́ tó jẹ pé àwọn ìránṣẹ́ tó rẹlẹ̀ ló máa ń ṣe é.

Jésù wàásù fún àwọn èèyàn níbikíbi tó bá ti rí wọn

19. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jésù máa ń mọ ìṣòro àwọn ẹlòmíràn lára?

19 Jésù máa ń mọ ìṣòro àwọn ẹlòmíràn lára. Ó máa ń hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí nígbà tó bá wo àwọn èèyàn sàn lọ́nà iṣẹ́ ìyanu bí ẹ̀mí Ọlọ́run ti fún un lágbára. (Mátíù 14:14) Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù ó sì sọ fún un pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Jésù mọ ìrora tí ọkùnrin yìí ní lára. Àánú rẹ ṣe é, ló bá na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kan án, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Bí ara ọkùnrin náà ṣe yá nìyẹn o! (Máàkù 1:40-42) Ǹjẹ́ o lè sọ bí inú ọkùnrin yẹn á ṣe dùn tó?

Ó JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ TÍTÍ DÓPIN

20, 21. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run láìyẹsẹ̀?

20 Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ tó bá kan ọ̀ràn ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run láìyẹsẹ̀. Nínú gbogbo onírúurú ipò tó bá ara rẹ̀ àti onírúurú àtakò táwọn èèyàn gbé kò ó lójú àti ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, ó jẹ́ olóòótọ́ sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Nígbà tí Sátánì dẹ Jésù wò, gbọn-in gbọn-in ni Jésù dúró, kò gbà kí ìdẹwò Sátánì borí òun. (Mátíù 4:1-11) Nígbà kan, àwọn ìbátan Jésù ò gbà á gbọ́, wọ́n tiẹ̀ sọ pé “Orí rẹ̀ ti yí.” (Máàkù 3:21) Ṣùgbọ́n Jésù ò jẹ́ kí wọ́n darí òun, iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán an ló ń ṣe lọ. Táwọn alátakò Jésù bá rí Jésù fín tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́, ńṣe ló máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu, kò gbìyànjú rẹ̀ rí láti gbẹ̀san lára àwọn alátakò rẹ̀.—1 Pétérù 2:21-23.

21 Jésù jẹ́ olóòótọ́ títí táwọn ọ̀tá rẹ̀ fi fi ikú oró pa á. (Ka Fílípì 2:8) Tiẹ̀ ronú ná nípa ohun tí Jésù fara dà ní ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n fàṣẹ ọba mú un, àwọn ẹlẹ́rìí èké fẹ̀sùn irọ́ kàn án, àwọn adájọ́ onímàgòmágó dá a lẹ́bi, àwọn èèyàn fi ṣe ẹlẹ́yà, àwọn sójà sì dá a lóró. Jésù mí èémí ìkẹyìn lórí igi oró tí wọ́n kàn án mọ́, ó sì kígbe pé: “A ti ṣe é parí!” (Jòhánù 19:30) Àmọ́, ní ọjọ́ kẹta tó kú, Bàbá rẹ̀ ọ̀run jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. (1 Pétérù 3:18) Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ó padà sí ọ̀run. Nígbà tó débẹ̀, ó “jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run” ó sì ń dúró di ìgbà tí Ọlọ́run yóò sọ ọ́ di ọba.—Hébérù 10:12, 13.

22. Àǹfààní wo ni jíjẹ́ tí Jésù jẹ olóòótọ́ títí tó fi kú mú wá?

22 Àǹfààní wo ni jíjẹ́ tí Jésù jẹ olóòótọ́ títí tó fi kú mú wá? Ikú Jésù ló mú kí àǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ṣeé ṣe, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀. Bí ikú Jésù ṣe mú kí ìyẹn ṣeé ṣe la óò gbé yẹ̀ wò nínú orí tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 7 Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tó ṣẹ sára Jésù, wo Àfikún, “Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé.”

^ ìpínrọ̀ 11 Ìdí tá a fi ń pe Jèhófà ní Bàbá ni pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa tó dá wa. (Aísáyà 64:8) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá Jésù, Ọmọ Ọlọ́run là ń pè é. Ìdí yẹn náà ni Bíbélì fi pe àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó kù ní ọmọ Ọlọ́run. Kódà, Bíbélì pe Ádámù tó jẹ èèyàn ní ọmọ Ọlọ́run.—Jóòbù 1:6; Lúùkù 3:38.

^ ìpínrọ̀ 12 Wo Àfikún, “Òtítọ́ Nípa Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́” kó o lè rí àfikún ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọmọ Ọlọ́run kò bá Ọlọ́run dọ́gba.