Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸJỌ

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
  • Kí ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

  • Kí ni Ìjọba Ọlọ́run yóò gbé ṣe?

  • Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé?

1. Àdúrà tó lókìkí wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?

Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn káàkiri ayé ní wọ́n mọ àdúrà tá à ń pè ní Bàbá Wa Tí Ń Bẹ ní Ọ̀run, tàbí Àdúrà Olúwa. Orúkọ méjèèjì yìí ni wọ́n fi ń pe àdúrà tó lókìkí tí Jésù kọ́ni gẹ́gẹ́ bí àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ. Àdúrà tó nítumọ̀ làdúrà yìí, tó o bá sì ṣàyẹ̀wò àwọn ohun mẹ́ta àkọ́kọ́ tí àdúrà náà béèrè, wàá túbọ̀ mọ àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an.

2. Kí ni mẹ́ta lára àwọn ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa fàdúrà béèrè?

2 Ní ìbẹ̀rẹ̀ àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ yìí, Jésù sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’” (Mátíù 6:9-13) Kí ni ìtumọ̀ àwọn ohun mẹ́ta tí àdúrà yìí béèrè?

3. Kí la gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

3 A ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. A sì ti kọ́ ohun díẹ̀ nípa ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ìyẹn ohun tó ti ṣe fún aráyé àtohun tó ṣì máa ṣe. Àmọ́, kí ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó ní ká máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé”? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Báwo ni dídé rẹ̀ yóò ṣe sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, tàbí yà á sí mímọ́? Ọ̀nà wo sì ni dídé Ìjọba náà gbà kan ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

OHUN TÍ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN JẸ́

4. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, ta sì ni Ọba rẹ̀?

4 Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan tí Jèhófà Ọlọ́run gbé kalẹ̀, Ọba tí Ọlọ́run yàn ló sì máa ṣàkóso ọ̀hún. Ta ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run? Jésù Kristi ni. Ipò ọba ti Jésù ga ju ti gbogbo àwọn alákòóso èèyàn lọ, nítorí òun ni Bíbélì pè ní “Ọba àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa.” (1 Tímótì 6:15) Jésù lágbára láti ṣe ohun rere ju alákòóso èyíkéyìí tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn lọ, kódà, ó lágbára láti ṣe rere ju ẹni tó ń ṣe dáadáa jù lọ lára wọn.

5. Láti ibo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò ti ṣàkóso, kí ni yóò sì ṣàkóso lé lórí?

5 Láti ibo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò ti ṣàkóso? Ó dára, ibo ni Jésù wà? O ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn èèyàn pa á lórí igi oró, Ọlọ́run sì jí i dìde. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀run. (Ìṣe 2:33) Nítorí náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀run ni Jésù wà, ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run wà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní ‘ìjọba ọ̀run.’ (2 Tímótì 4:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run wà, yóò ṣàkóso lé ilẹ̀ ayé lórí.—Ka Ìṣípayá 11:15.

6, 7. Kí ló mú kí Jésù jẹ́ Ọba tó yàtọ̀ sáwọn tó kù?

6 Kí ló mú kí Jésù jẹ́ Ọba tó yàtọ̀ sáwọn tó kù? Ohun kan tó mú kó yàtọ̀ ni pé kò ní kú láéláé. Nígbà tí Bíbélì ń fi Jésù wé àwọn ọba tó jẹ́ èèyàn, ó pè é ní “ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú, ẹni tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ.” (1 Tímótì 6:16) Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo nǹkan dáadáa tí Jésù bá ṣe á máa wà títí lọ ni. Ó sì dá wa lójú pé yóò ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tí yóò ṣe àwọn èèyàn rẹ̀ láǹfààní.

7 Wo àsọtẹ́lẹ̀ yìí tí Bíbélì sọ nípa Jésù: “Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà; ìgbádùn rẹ̀ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà. Kì yóò sì ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́. Yóò sì fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀, yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 11:2-4) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù Ọba yóò fi òdodo àti ìyọ́nú ṣàkóso àwọn èèyàn orí ilẹ̀ ayé. Ṣé wàá fẹ́ láti ní irú alákòóso bẹ́ẹ̀?

8. Àwọn wo ló máa bá Jésù jọba?

8 Ohun mìíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run ni pé: Jésù kò ní dá ṣàkóso. Àwọn mìíràn yóò bá a ṣàkóso. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Bí a bá ń bá a lọ ní fífaradà, a ó jọ ṣàkóso pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ọba.” (2 Tímótì 2:12) Pọ́ọ̀lù, Tímótì àtàwọn olóòótọ́ mìíràn tí Ọlọ́run yàn yóò ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba ọ̀run. Àwọn mélòó ló máa ní àǹfààní bàǹtà-banta yẹn?

9. Àwọn mélòó ló máa bá Jésù jọba, ìgbà wo ni Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí yàn wọ́n?

9 Orí Keje ìwé yìí ṣe fi hàn, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan nínú èyí tó ti rí i tí “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù Kristi] dúró lórí Òkè Ńlá Síónì [tí í ṣe ipò ọba rẹ̀ ní ọ̀run], àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.” Àwọn wo ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì wọ̀nyẹn? Jòhánù fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 14:1, 4) Wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí Ọlọ́run dìídì yàn láti bá Jésù jọba lókè ọ̀run. Lẹ́yìn ikú wọn, ìyè ti ọ̀run ni wọn yóò jí dìde sí, àwọn àti Jésù “yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:10) Látìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì ni Ọlọ́run ti ń yan àwọn Kristẹni tòótọ́ tí yóò lọ sọ́run kí iye wọn bàa lè pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.

10. Báwo ni ètò tí Ọlọ́run ṣe pé kí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ṣàkóso aráyé ṣe fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa?

10 Ọlọ́run ṣètò pé kí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ṣàkóso aráyé. Ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, nítorí pé Jésù ti jẹ́ èèyàn rí ó sì mọ bí ìyà ṣe máa ń rí lára. Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù “kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 4:15; 5:8) Àwọn tí yóò bá a jọba náà ti jìyà nígbà tí wọ́n fi jẹ́ ẹ̀dá èèyàn wọ́n sì ti fara da ìyà. Láfikún, àìpé ti bá wọn fínra, wọ́n sì ti fara da onírúurú àìsàn. Dájúdájú, wọ́n á mọ ìṣòro tó ń kojú ọmọ aráyé!

KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN YÓÒ GBÉ ṢE?

11. Kí ni Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbà ládùúrà nípa ìfẹ́ Ọlọ́run?

11 Nígbà tí Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yin òun máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ó tún sọ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Ọ̀run ni Ọlọ́run wà, kò sì sígbà kan táwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ níbẹ̀. Àmọ́ ní Orí Kẹta ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé áńgẹ́lì búburú kan ṣíwọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ó sì sún Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀. Ní Orí Kẹwàá, a óò mọ ohun púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa áńgẹ́lì búburú náà tá a mọ̀ sí Sátánì Èṣù. Ọlọ́run fàyè gba Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì tí wọ́n pinnu láti tẹ̀ lé e tá à ń pè ni ẹ̀mí èṣù pé kí wọ́n wà ní ọ̀run fúngbà díẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà yẹn, gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́run kọ́ ni wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kò ní rí bẹ́ẹ̀ mọ́ bí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́, ìyẹn Jésù Kristi, yóò gbógun ti Sátánì.—Ka Ìṣípayá 12:7-9.

12. Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì méjì wo ni Ìṣípayá 12:10 mẹ́nu kàn?

12 Àsọtẹ́lẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Mo sì gbọ́ tí ohùn rara kan ní ọ̀run wí pé: ‘Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé àti agbára àti ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀, nítorí pé [Sátánì tí í ṣe] olùfisùn àwọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa!’” (Ìṣípayá 12:10) Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì méjì tí ẹsẹ Bíbélì yẹn mẹ́nu kàn? Àkọ́kọ́ ni pé, Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù jẹ́ Ọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ìkejì ni pé, Jésù ti lé Sátánì kúrò ní ọ̀run wá sórí ilẹ̀ ayé.

13. Kí ni àbájáde lílé tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run?

13 Kí ló ti jẹ́ àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yẹn? A kà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!” (Ìṣípayà 12:12) Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó wà lọ́run yọ̀ nítorí pé Sátánì ò sí lọ́run mọ́, gbogbo àwọn tó wá wà lọ́run báyìí ló jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run. Àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ló wà níbẹ̀. Wọ́n ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀run.

Bí wọ́n ṣe lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run mú ègbé bá ilẹ̀ ayé. Àwọn wàhálà yẹn máa tó dópin

14. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé nítorí pé wọ́n lé Sátánì kúrò ní ọ̀run?

14 Àmọ́, ilẹ̀ ayé ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Ohun tó ń bí Sátánì nínú ni lílé tí wọ́n lé e kúrò lọ́run àti bó ṣe jẹ́ pé àkókò kúkúrú ló kù fún un. Nínú ìbínú rẹ̀, ó ń fa “ègbé” fún ilẹ̀ ayé. A óò mọ̀ sí i nípa ègbé yẹn ní orí tó kàn. Ṣùgbọ́n tá a bá ronú lórí bí Sátánì tí wọ́n ti lé kúrò lọ́run ṣe ń mú wàhálà bá ilẹ̀ ayé, èyí lè mú ká béèrè pé: Báwo ló ṣe máa lè ṣeé ṣe kí Ìjọba Ọlọ́run mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé?

15. Kí ni ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ilẹ̀ ayé?

15 Tóò, rántí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé, tó o kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Kẹta. Ní Édẹ́nì, Ọlọ́run fi hàn pé ohun tóun ní lọ́kàn tóun fi dá ilẹ̀ ayé ni pé kó di Párádísè tí àwọn èèyàn olódodo tí kò ní kú yóò kún inú rẹ̀. Sátánì mú kí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ ìyẹn kò yí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé padà, kò kàn jẹ́ kó tètè nímùúṣẹ ni. Ohun tí Jèhófà ṣì ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé ni pé: ‘Kí àwọn olódodo jogún ilẹ̀ ayé, kí wọn sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.’ (Sáàmù 37:29) Ìjọba Ọlọ́run yóò sì mú kó rí bẹ́ẹ̀. Báwo ni yóò ṣe ṣe é?

16, 17. Kí ni Dáníẹ́lì 2:44 jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

16 Gbé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Dáníẹ́lì 2:44 yẹ̀ wò. Ó kà pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Kí lèyí jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

17 Àkọ́kọ́, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run yóò gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ “ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn,” tàbí nígbà tí àwọn ìjọba mìíràn bá ṣì ń ṣàkóso. Ìkejì, ó ń sọ fún wa pé Ìjọba Ọlọ́run yóò wà títí láé. Ìjọba mìíràn ò ní ṣẹ́gun rẹ̀, òmíràn ò sì ní rọ́pò rẹ̀. Ìkẹta, ó jẹ́ ká rí i pé ogun yóò wà láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn ìjọba ayé yìí. Ṣùgbọ́n Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣẹ́gun. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni yóò máa ṣàkóso aráyé. Ìgbà náà làwọn èèyàn yóò gbádùn ìṣàkóso tó dára jù lọ tí wọn ò rírú ẹ̀ rí.

18. Kí ni orúkọ ogun tí yóò wáyé kẹ́yìn láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn ìjọba ayé yìí?

18 Bíbélì ní ohun púpọ̀ láti sọ nípa ogun tí yóò wáyé kẹ́yìn láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti ìjọba èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì fi kọ́ni pé bí òpin bá ṣe ń sún mọ́lé, àwọn ẹ̀mí búburú yóò máa tan irọ́ kálẹ̀ láti fi tan “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” jẹ. Nítorí kí ni? Ó jẹ́ “láti kó wọn [ìyẹn àwọn ọba] jọpọ̀ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Wọn yóò kó àwọn ọba ayé jọ pọ̀ sí “ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Nítorí ohun tí ẹsẹ méjèèjì wọ̀nyẹn sọ, ìjà tó máa wáyé kẹ́yìn láàárín àwọn ìjọba èèyàn àti Ìjọba Ọlọ́run là ń pè ní ogun Ha-Mágẹ́dọ́nì, tàbí Amágẹ́dọ́nì.

19, 20. Kí ni kò jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí?

19 Kí ni Ìjọba Ọlọ́run yóò fi ogun Amágẹ́dọ́nì gbé ṣe? Tún ronú nípa ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ fún ilẹ̀ ayé. Ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé ni pé kó kún fún àwọn èèyàn olódodo, tí wọ́n jẹ́ pípé, tí wọn yóò sì máa sìn ín nínú Párádísè. Kí nìdí tí ayé kò fi rí bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí? Ìdí kan ni pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, à ń ṣàìsàn, a sì ń kú. Ṣùgbọ́n a kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Karùn-ún pé Jésù kú fún wa ká lè wà láàyè títí láé. Ó ṣeé ṣe kó o rántí àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìhìn Rere Jòhánù, tó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

20 Ìṣòro mìíràn ni pé olubi lọ̀pọ̀ èèyàn. Wọ́n ń parọ́, wọ́n ń rẹ́ni jẹ, wọ́n sì ń hùwàkiwà. Wọn ò fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn èèyàn tó ń ṣe ohun búburú yóò pa run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ka Sáàmù 37:10) Ìdí mìíràn tí ìfẹ́ Ọlọ́run kò fi tíì di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé ni pé ìjọba èèyàn kò fún àwọn tó wà lábẹ́ wọn níṣìírí láti máa ṣe é. Ọ̀pọ̀ ìjọba ni kò lágbára tó láti darí àwọn èèyàn, òǹrorò làwọn ìjọba kan, àwọn mìíràn sì ya oníwà ìbàjẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.

21. Báwo ni Ìjọba náà yóò ṣe mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé?

21 Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, abẹ́ ìjọba kan péré laráyé á wà, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba yẹn yóò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run yóò sì mú àwọn ìbùkún àgbàyanu wá. Bí àpẹẹrẹ, yóò mú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù kúrò lójú ọpọ́n. (Ìṣípayá 20:1-3) Ọlọ́run yóò lo agbára tó wà nínú ẹbọ ìràpadà Jésù tí àwọn èèyàn olóòótọ́ ò fi ní máa ṣàìsàn, tí wọn ò sì ní kú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti wà láàyè títí láé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. (Ka Ìṣípayá 22:1-3) Ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè. Nípa bẹ́ẹ̀, Ìjọba náà yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sì pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo àwọn tó ń gbé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni yóò máa bọ̀wọ̀ fún orúkọ Jèhófà.

ÌGBÀ WO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN YÓÒ MÚ KÍ ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN DI ṢÍṢE LÓRÍ ILẸ̀ AYÉ?

22. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ò dé nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé tàbí ní gbàrà lẹ́yìn tó jíǹde?

22 Nígbà ti Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé “kí ìjọba rẹ dé,” ó ṣe kedere pé Ìjọba náà ò tíì dé nígbà yẹn. Ṣé ìgbà tí Jésù lọ sí ọ̀run ni Ìjọba náà dé? Rárá o, nítorí pé àpọ́sítélì Pétérù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé lẹ́yìn tí Jésù jí dìde, àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 110:1 ṣẹ sára rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ náà ni pé: “Àsọjáde Jèhófà fún Olúwa mi ni pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.’” (Ìṣe 2:32-34; Hébérù 10:12, 13) Jésù dúró fún àkókò kan.

Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run

23. (a) Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso? (b) Kí la óò kẹ́kọ̀ọ́ nínú orí tó kàn?

23 Báwo ni àkókò tí Jésù fi dúró ṣe gùn tó? Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ ṣírò pé, àkókò tí Jésù fi ń dúró yóò dópin ní ọdún 1914. (Nípa déètì yìí, wo Àfikún, “Ọdún 1914—Ọdún Pàtàkì Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì”.) Àwọn ohun tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láti ọdún 1914 fi hàn pé ìṣirò táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ wọ̀nyẹn ṣe tọ̀nà. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó nímùúṣẹ fi hàn pé ní 1914, Kristi di Ọba, Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso. Nítorí náà, “sáà àkókò kúkúrú” tó ṣẹ́ kù fún Sátánì la wà yìí. (Ìṣípayá 12:12; Sáàmù 110:2) A sì tún lè fi ìdánilójú sọ pé láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ o ka èyí sí àgbàyanu ìhìn rere? Ṣé o gbà gbọ́ pé òótọ́ ni? Orí tó kàn yóò jẹ́ kó o rí i pé òótọ́ ni Bíbélì fi àwọn ohun wọ̀nyí kọ́ni.