Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀFIKÚN

Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé

Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé

BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé ó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún lọ tí wòlíì Dáníẹ́lì ti gbé ayé kí wọ́n tó bí Jésù, Ọlọ́run ṣí ohun kan payá fún Dáníẹ́lì tó jẹ́ kó ṣeé ṣe láti mọ ìgbà tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà tàbí Kristi. Ọlọ́run sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Kí o mọ̀, kí o sì ní ìjìnlẹ̀ òye pé láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú, ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta.”—Dáníẹ́lì 9:25.

Láti lè mọ ìgbà tí Mèsáyà yóò dé, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ọdún tí a óò ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìgbà tí yóò dé. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, ó jẹ́ “láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́.” Ọdún wo ni “ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà” wáyé? Nehemáyà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé, ọ̀rọ̀ náà láti tún Jerúsálẹ́mù kọ́ jáde lọ ní “ọdún ogún Atasásítà Ọba.” (Nehemáyà 2:1, 5-8) Àwọn òpìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọdún 474 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (Ṣ.S.K.) ni Atasásítà pé ọdún kan lórí ìtẹ́. Nítorí náà, ọdún 455 Ṣ.S.K. ló pé ogún ọdún tó gorí ìtẹ́. Ní báyìí, a ti mọ̀ pé ọdún 455 Ṣ.S.K. la ti máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣírò ìgbà tí Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò dé.

Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ iye ọdún tó wà láàárín ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣírò ìgbà tí Mèsáyà yóò dé sí ìgbà tí Mèsáyà máa dé. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé yóò jẹ́ ‘ọ̀sẹ̀ méje [7], àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta [62],’ tí àròpọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69]. Báwo ni ìgbà yìí ṣe gùn tó? Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan fi hàn pé wọn kì í ṣe ọ̀sẹ̀ ọlọ́jọ́ méje-méje, àmọ́ wọ́n jẹ́ ọ̀sẹ̀ ọlọ́dún. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ọ̀sẹ̀ kan dúró fún ọdún méje. Àwọn Júù ayé ọjọ́un mọ ọ̀sẹ̀ ọlọ́dún, tàbí ọdún méje-méje tá a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń pa ọdún Sábáàtì mọ́ ní ọdún keje-kéje. (Ẹ́kísódù 23:10, 11) Nítorí náà, nínú àsọtẹ́lẹ̀ ọlọ́sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69] yìí, ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọdún méje-méje, àròpọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin àti mẹ́ta [483] ọdún.

Ìṣirò ló wá kàn tá a máa ṣe báyìí. Tá a bá ka ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin àti mẹ́ta [483] ọdún láti ọdún 455 Ṣ.S.K., yóò mú wa dé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni (S.K.). Ọdún yẹn gan-an ni wọ́n ri Jésù bọmi tó sì di Mèsáyà! * (Lúùkù 3:1, 2, 21, 22) Ǹjẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ṣe nímùúṣẹ ò jọ èèyàn lójú?

^ ìpínrọ̀ 2 Láti ọdún 455 Ṣ.S.K. sí ọdún 1 Ṣ.S.K., iye ọdún tó wà ńbẹ̀ jẹ́ Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta [454] ọdún. Ọdún kan ló wà láàárín ọdún 1 Ṣ.S.K. sí ọdún 1 S.K. (nítorí pé òǹkà kò bẹ̀rẹ̀ látorí òdo, orí oókan ló ti bẹ̀rẹ̀). Ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ló sì wà láàárín ọdún 1 S.K. sí ọdún 29 S.K. Tá a bá ro mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí pọ̀, yóò fún wa ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin àti mẹ́ta [483] ọdún. Àárín ọ̀sẹ̀ ọdún àádọ́rin ni wọ́n ‘ké Jésù kúrò’ tàbí tí wọ́n pa á, ìyẹn sì jẹ́ ní ọdún 33 S.K. (Dáníẹ́lì 9:24, 26) Ka orí kọkànlá ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! àti Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 899 sí 901. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé méjèèjì.