Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀFIKÚN

Òtítọ́ Nípa Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́

Òtítọ́ Nípa Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́

ÀWỌN tó gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ sọ pé ẹni mẹ́ta ló para pọ̀ di Ọlọ́run. Wọ́n sọ pé àwọn ẹni mẹ́ta náà ni Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n tún sọ pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bára wọn dọ́gba, pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló jẹ́ olódùmarè, wọn kò sì ní ìbẹ̀rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan ń sọ ni pé, Baba jẹ́ Ọlọ́run, Ọmọ jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀, Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ ló gbà pé àwọn ò lè ṣàlàyé rẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n ṣì máa ń rò pé ẹ̀kọ́ Bíbélì ni. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀rọ̀ náà “Mẹ́talọ́kan” ò sí nínú Bíbélì rárá. Àmọ́, ṣé ohun kan wà nínú Bíbélì tó ṣeé ṣe kéèyàn rò pé Mẹ́talọ́kan ló ń tọ́ka sí ni? Láti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, jẹ́ ká wo ẹsẹ Bíbélì kan táwọn tó gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ sábà máa ń fi ti ẹ̀kọ́ náà lẹ́yìn.

‘ỌLỌRUN LI Ọ̀RỌ NA’

Jòhánù 1:1 sọ pé: “Li àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na.” (Bibeli Mimọ) Ní ọwọ́ ìsàlẹ̀ nínú orí Bíbélì yìí kan náà, àpọ́sítélì Jòhánù fi hàn kedere pé Jésù ni “Ọ̀rọ̀ náà.” (Jòhánù 1:14) Nítorí pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ni Ọ̀rọ̀ náà, àwọn kan sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni Baba àti Ọmọ jọ wà nínú Ọlọ́run kan ṣoṣo.

Àmọ́ ṣá o, fi sọ́kàn pé èdè Gíríìkì lẹni tó kọ ẹsẹ Bíbélì yìí fi kọ ọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn làwọn olùtumọ̀ wá túmọ̀ rẹ̀ sí àwọn èdè mìíràn. Àmọ́, àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan túmọ̀ gbólóhùn náà, “Ọlọrun si li Ọ̀rọ na,” lọ́nà tó yàtọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ní ìmọ̀ nípa èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Ìyẹn ló mú kí wọ́n gbà pé ó yẹ káwọn túmọ̀ gbólóhùn náà lọ́nà tó yàtọ̀. Báwo wá ni wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀? Àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé: “Logos [Ọ̀rọ̀] náà jẹ́ ẹni ti ọ̀run.” (A New Translation of the Bible) “Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ọlọ́run kan.” (The New Testament in an Improved Version) “Ọ̀rọ̀ náà wà pẹ̀lú Ọlọ́run ó sì jẹ́ ẹni ẹ̀mí bíi tirẹ̀.” (The Translator’s New Testament) Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyí fi hàn pé Ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe Ọlọ́run. * Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n pe Ọ̀rọ̀ náà ní “ọlọ́run kan” nítorí pé ipò gíga ló wà láàárín àwọn ẹ̀dá Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ náà, “ọlọ́run” táwọn olùtumọ̀ lò nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí “ẹni alágbára.”

GBÉ ÀWỌN Ẹ̀RÍ MÌÍRÀN YẸ̀ WÒ

Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò mọ èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Báwo wá lo ṣe lè mọ ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù ní lọ́kàn gan-an? Tóò, ronú nípa àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé olùkọ́ kan kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní nǹkan kan. Ká sọ pé nígbà tó yá, òye táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní lórí ohun tí olùkọ́ wọn kọ́ wọn yìí kò dọ́gba. Kí ló yẹ kí wọ́n ṣe? Wọ́n lè padà lọ bá olùkọ́ náà pé kó túbọ̀ ṣàlàyé rẹ̀ fáwọn. Ó dájú pé tí wọ́n bá tún gbọ́ àlàyé sí i, ẹ̀kọ́ náà yóò túbọ̀ yé wọn. Bíi tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí, bí ìwọ náà bá fẹ́ mọ ohun tí Jòhánù 1:1 túmọ̀ sí gan-an, o lè wonú Ìhìn Rere Jòhánù fún àlàyé síwájú sí i. Tó o bá túbọ̀ rí àlàyé sí i lórí ọ̀rọ̀ Mẹ́talọ́kan, wàá lè mọ òtítọ́.

Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Jòhánù tún kọ ní Jòhánù orí 1 ẹsẹ 18. Ó kà pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run [Olódùmarè] nígbà kankan rí.” Àmọ́, àwọn èèyàn ti rí Jésù tó jẹ́ Ọmọ rí, nítorí Jòhánù sọ pé: “Ọ̀rọ na [Jésù] si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.” (Jòhánù 1:14, Bíbélì Mímọ́ ) Báwo wá ni Ọmọ ṣe lè jẹ́ apá kan Ọlọ́run Olódùmarè? Jòhánù tún sọ pé Ọ̀rọ̀ náà “wà pẹ̀lú Ọlọ́run.” Àmọ́, ṣé ó lè ṣeé ṣe pé kẹ́nì kan wà pẹ̀lú ẹnì kan kó sì tún wá jẹ́ pé òun lẹni náà? Yàtọ̀ síyẹn, ní Jòhánù 17:3, Jésù fi hàn kedere pé ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni òun àti Bàbá òun tó wà lọ́run. Ó pe Bàbá rẹ̀ ní “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.” Nígbà tí Ìhìn Rere Jòhánù sì ń parí lọ, ohun tí Jòhánù fi ṣe àkópọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni pé: “Ìwọ̀nyí ni a ti kọ sílẹ̀ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 20:31) Kíyè sí i pé Ọmọ Ọlọ́run ló pe Jésù, kì í ṣe Ọlọ́run. Àwọn àlàyé mìíràn tá a rí látinú Ìhìn Rere Jòhánù yìí fi bó ṣe yẹ ká lóye Jòhánù 1:1 hàn wá. Jésù tí Bíbélì pè ní Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ “ọlọ́run kan” nítorí pé ipò gíga ló wà, àmọ́ òun kọ́ ni Ọlọ́run Olódùmarè.

WÁ Ẹ̀RÍ KÚN ÀWỌN Ẹ̀RÍ WỌ̀NYÍ KÓ LÈ TÚBỌ̀ DÁ Ọ LÓJÚ

Tún ronú nípa àpẹẹrẹ olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé yẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan. Ká sọ pé àwọn kan nínú wọn ṣì ń ṣiyè méjì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ àlàyé sí i lẹ́nu olùkọ́ náà, kí tún ni wọ́n lè ṣe? Wọ́n lè lọ bá olùkọ́ mìíràn pé kó ṣàlàyé ẹ̀kọ́ náà síwájú sí i fáwọn. Tí olùkọ́ kejì bá lè ṣàlàyé sí i fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé òótọ́ ni ohun tí olùkọ́ wọn kọ́ wọn, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ni kò ní ṣiyè méjì mọ́. Lọ́nà kan náà, tí ohun tí Jòhánù ń sọ gan-an nípa bí Jésù àti Ọlọrun Olódùmarè ṣe jẹ́ síra wọn kò bá dá ọ lójú, wo ohun tí ẹlòmíràn tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Mátíù kọ. Ó kọ ohun tí Jésù sọ nípa òpin ètò àwọn nǹkan yìí pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Báwo lèyí ṣe fi hàn pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè?

Jésù sọ pé Bàbá mọ̀ ju Ọmọ lọ. Àmọ́ ká ní Jésù jẹ́ apá kan Ọlọ́run Olódùmarè ni, ì bá mọ gbogbo nǹkan tí Bàbá rẹ̀ mọ̀. Èyí fi hàn pé Ọmọ àti Bàbá kò bára wọn dọ́gba. Síbẹ̀, àwọn kan ṣì máa sọ pé: ‘Ẹni ẹ̀mí ni Jésù tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kó tó di èèyàn, ìgbà tó sì wà léèyàn ló sọ̀rọ̀ yìí.’ Àmọ́ ká tiẹ̀ sọ pé ohun tó ń sọ ni pé ìgbà tòun jẹ́ èèyàn nìkan lòun ò mọ ohun kan tí Bàbá òun mọ̀, ẹ̀mí mímọ́ ńkọ́? Tó bá jẹ́ pé apá kan Ọlọ́run Olódùmarè ni ẹ̀mí mímọ́, kí ló dé tí Jésù ò fi sọ pé ẹ̀mí mímọ́ mọ ohun tí Bàbá mọ̀?

Bó o ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ nìṣó, wàá máa rí àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn tó sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ẹsẹ Bíbélì náà sọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọn ò bára dọ́gba.—Sáàmù 90:2; Ìṣe 7:55; Kólósè 1:15.

^ ìpínrọ̀ 3 Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ìlànà èdè Gíríìkì tí wọ́n lò fún Jòhánù 1:1, wo Àpilẹ̀kọ, “Ṣé “Ọlọ́run” Ni Ọ̀rọ̀ Náà àbí Ọ̀rọ̀ Náà Jẹ́ “ọlọ́run kan”?” nínu Ilé Ìṣọ́ November 1, 2008, Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.