Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀFIKÚN

Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì?

Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì?

IYE ìgbà díẹ̀ ni Bíbélì mẹ́nu kan Máíkẹ́lì tó jẹ́ orúkọ ẹ̀dá ẹ̀mí kan. Àmọ́ ní iye ìgbà díẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn án ọ̀hún, akọ iṣẹ́ ló ń ṣe. Nínú ìwé Dáníẹ́lì, Máíkẹ́lì bá àwọn áńgẹ́lì búburú wọ̀yá ìjà; nínú lẹ́tà Júdà, ó bá Sátánì ṣawuyewuye; nínú ìwé Ìṣípayá sì rèé, ó bá Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jagun. Bí Máíkẹ́lì ṣe ń gbè sẹ́yìn ìṣàkóso Jèhófà tó sì ń bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run jà, orúkọ rẹ̀ ló ń rò ó, èyí tó túmọ̀ sí, “Ta Ní Dà Bí Ọlọ́run?” Àmọ́, ta ni Máíkẹ́lì yìí?

Àìmọye èèyàn ló jẹ́ pé orúkọ kan ṣoṣo kọ́ ni wọ́n ń jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Jékọ́bù baba ńlá tún ń jẹ́ Ísírẹ́lì, àpọ́sítélì Pétérù sì tún ń jẹ́ Símónì. (Jẹ́nẹ́sísì 49:1, 2; Mátíù 10:2) Lọ́nà kan náà, Bíbélì fi hàn pé Máíkẹ́lì jẹ́ orúkọ mìíràn tí Jésù Kristi ń jẹ́ kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé àti lẹ́yìn tó kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Jẹ́ ká wo ìdí tá a fi gbà bẹ́ẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́.

Olú-Áńgẹ́lì. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Máíkẹ́lì tó jẹ́ “olú-áńgẹ́lì.” (Júúdà 9) “Olú-áńgẹ́lì” túmọ̀ sí “olórí àwọn áńgẹ́lì.” Kíyè sí i pé olú-áńgẹ́lì la pe Máíkẹ́lì. Èyí fi hàn pé méjì irú áńgẹ́lì bẹ́ẹ̀ ò sí. Bákan náà, ní gbogbo ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa “olú-áńgẹ́lì,” ẹnì kan ṣoṣo ló pè bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ẹni méjì. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù ni Bíbélì sábà máa ń fi sí ipò olú-áńgẹ́lì. Ìwé Tẹsalóníkà Kìíní 4:16 sọ nípa Jésù tó ti jíǹde pé: “Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì.” Ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé ohùn Jésù jẹ́ ohùn olú-áńgẹ́lì. Nípa bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Jésù fúnra rẹ̀ ni olú-áńgẹ́lì.

Olórí Ogun. Bíbélì sọ pé ‘Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jagun.’ (Ìṣípayá 12:7) Èyí fi hàn pé Máíkẹ́lì jẹ́ Olórí ẹgbẹ́ ogun àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́. Ìwé Ìṣípayá tún fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí Olórí ẹgbẹ́ ogun àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́. (Ìṣípayá 19:14-16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ̀rọ̀ nípa “Jésù Olúwa” àti “àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára.” (2 Tẹsalóníkà 1:7; Mátíù 16:27; 24:31; 1 Pétérù 3:22) Nípa bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Máíkẹ́lì àti “àwọn áńgẹ́lì rẹ̀” ó sì tún sọ̀rọ̀ nípa Jésù àti “àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” (Mátíù 13:41) Níwọ̀n bí Bíbélì kò sì ti fi hàn pé ẹgbẹ́ ogun àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó wà lọ́run pé méjì, tí kò sọ pé Máíkẹ́lì jẹ́ Olórí ẹgbẹ́ kan tí Jésù sì jẹ́ Olórí ẹgbẹ́ kejì, ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pé, Máíkẹ́lì ni Jésù tó ń kó ipa tí Ọlọ́run yàn fún un ní ọ̀run. *

^ ìpínrọ̀ 1 Àlàyé síwájú sí i tó fi hàn pé Ọmọ Ọlọ́run ni orúkọ náà, Máíkẹ́lì, ń tọ́ka sí wà nínú ìwé Insight on the Scriptures, ojú ìwé 393 àti 394. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.