Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 12

Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”

Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”

“Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró.”—ÉFÉSÙ 4:29.

1-3. (a) Ẹ̀bùn wo ni Jèhófà fún wa, báwo la sì ṣe lè ṣì í lò? (b) Tá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, báwo ló ṣe yẹ ká máa lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ?

BÁWO ló ṣe máa rí lára ẹ tó o bá fún ọ̀rẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn kan tó sì mọ̀ọ́mọ̀ lo ẹ̀bùn náà nílòkulò? Ká sọ pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lo fún un, tó o sì wá gbọ́ pé ńṣe ló ń wà á níwàkuwà tó sì fi ṣe àwọn èèyàn léṣe. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ náà á dùn ẹ́.

2 Jèhófà, olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ló fún wa ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ. (Jákọ́bù 1:17) Ẹ̀bùn tó jẹ́ káwa ẹ̀dá èèyàn yàtọ̀ sáwọn ẹranko yìí ló ń jẹ́ ká lè sọ ohun tá à ń rò lọ́kàn jáde ká sì tún jẹ́ káwọn ẹlòmíì mọ bọ́ràn ṣe rí lára wa. Àmọ́, bíi ti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àwa náà lè ṣi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ lò. Ẹ ò rí bó ti máa dun Jèhófà tó tá a bá ń fi ahọ́n wa sọ̀sọkúsọ tá a sì ń kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìnira bá àwọn ẹlòmíì!

3 Tá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, a ní láti máa lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ bí ẹni tó fún wa ṣe fẹ́ ká lò ó. Jèhófà ò fi irú ọ̀rọ̀ tó máa ń múnú ẹ̀ dùn pa mọ́ fún wa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” (Éfésù 4:29) Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ, irú ọ̀rọ̀ tí ò yẹ kó máa jáde lẹ́nu wa àti bá a ṣe lè máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó “dára fún gbígbéniró.”

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA ṢỌ́ Ọ̀RỌ̀ SỌ

4, 5. Báwo làwọn òwe kan nínú Bíbélì ṣe jẹ́ ká rí i pé ẹyin lohùn?

4 Ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ ni pé ẹyin lohùn. Òwe 15:4 sọ pé: “Ìparọ́rọ́ ahọ́n jẹ́ igi ìyè, ṣùgbọ́n ìfèrúyípo nínú rẹ̀ túmọ̀ sí ìrẹ̀wẹ̀sì nínú ẹ̀mí.” * Bí omi ṣe máa ń mú kí igi rúwé, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ tá a fẹ̀sọ̀ sọ ṣe máa ń tu àwọn tó ń gbọ́ ọ lára. Àmọ́, òdìkejì gbáà ni ọ̀rọ̀ àyídáyidà tí ahọ́n ẹ̀tàn bá sọ, torí ńṣe ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu lè pani ó sì lè lani.—Òwe 18:21.

5 Nígbà tí òwe inú Bíbélì kan máa ṣàlàyé tó ṣe kedere lórí agbára tí ọ̀rọ̀ ní, ó ní: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” (Òwe 12:18) Ọ̀rọ̀ tá a fìkùgbù sọ lè dọ́gbẹ́ síni lọ́kàn, ó sì lè ba àárín ọ̀rẹ́ jẹ́. Ṣé ẹnì kan ti sọ̀rọ̀ tó dọ́gbẹ́ sí ẹ lọ́kàn rí? Òwe tá a sọ lókè yìí tún sọ ohun tó dáa nípa ahọ́n, ó ní: “Ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” Ọ̀rọ̀ tẹ́ni tó ń fọgbọ́n Ọlọ́run hùwà bá sọ máa ń tu ọkàn tó gbọgbẹ́ nínú, ó sì máa ń tún àárín ọ̀rẹ́ ṣe. Ṣó o lè rántí ìgbà tẹ́nì kan bá ẹ sọ̀rọ̀, tọ́rọ̀ náà sì wọ̀ ẹ́ lákínyẹmí ara débi tó fi tù ẹ́ nínú? (Ka Òwe 16:24) Tá a bá mọ̀ pé ẹyin lohùn, ó dájú pé a óò fẹ́ láti máa fi ọ̀rọ̀ wa gbé àwọn èèyàn ró, a kò sì ní fẹ́ máa fi dọ́gbẹ́ sí wọn lọ́kàn.

Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ máa ń tuni lára

6. Kí nìdí tí kíkó ahọ́n wa níjàánu fi gba ìsapá gidigidi?

6 Kò sí bá a ṣe lè gbìyànjú tó, a ò lè kó ahọ́n wa níjàánu délẹ̀délẹ̀. Torí náà, á jẹ́ pé ìdí kejì tá a fi gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa ni pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ẹ̀dá máa ń tì wá gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n ká lè ṣi ọ̀rọ̀ sọ. Ohun tó bá wà lọkàn lẹnú máa ń sọ jáde, ‘ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn sì jẹ́ búburú.’ (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Lúùkù 6:45) Àfi ká yáa sapá gidigidi ká lè máa kó ahọ́n wa níjàánu. (Ka Jákọ́bù 3:2-4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè ṣe ká má ṣi ọ̀rọ̀ sọ, a ṣì lè kọ́ ahọ́n wa láti túbọ̀ máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró. Bí òmùwẹ̀ kan ṣe ní láti jà fitafita kó lè la àárin agbami tí ń ru gùdù kọjá, bẹ́ẹ̀ làwa náà ṣe ní láti bá ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ wa jà ká má bàa ṣi ahọ́n wa lò.

7, 8. Dé ìwọ̀n àyè wo la fi máa jíhìn bá a ṣe ń lo ahọ́n wa fún Jèhófà?

7 Ìdí kẹta tá a fi gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa ni pé a máa jíhìn bá a bá ṣe ń lo ahọ́n wa fún Jèhófà. Bá a ṣe ń lo ahọ́n wa kan àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ó sì tún ń nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ìwé Jákọ́bù 1:26 sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.” * Bá a ṣe kà á nínú orí tó ṣáájú, ìjọsìn wa àti ọ̀rọ̀ ẹnu wa jọ ń rìn pọ̀ ni. Bí a kì í bá kó ahọ́n wa níjàánu, tó wá di pé a bẹ̀rẹ̀ sí fọ̀rọ̀ ẹnu wa ba àwọn èèyàn lọ́kàn jẹ́, tá a sì fi ń kó bá wọn, ńṣe ni Ọlọ́run máa gbàgbé gbogbo iṣẹ́ rere wa. Àbẹ́ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí gbèrò?—Jákọ́bù 3:8-10.

8 Ó ti wá hàn kedere báyìí pé ìdí wà tá ò fi gbọ́dọ̀ ṣi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ lò. Ká tó mẹ́nu ba àwọn ọ̀rọ̀ gbígbámúṣé tó ń gbéni ró, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tí ò gbọ́dọ̀ máa jáde lẹ́nu Kristẹni tòótọ́.

Ọ̀RỌ̀ TÍ KÒ BUYÌ KÚNNI

9, 10. (a) Irú ọ̀rọ̀ wo ni kò wọ́n lẹ́nu àwọn èèyàn inú ayé tá a wà yìí? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká kórìíra ọ̀rọ̀ rírùn? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

9 Ọ̀rọ̀ rírùn. Èpè, ìsọkúsọ àtàwọn ọ̀rọ̀ rírùn míì kò wọ́n lẹ́nu àwọn èèyàn inú ayé tá a wà yìí. Àwọn èèyàn máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ aṣa láti ṣàpọ́nlé ohun tí wọ́n ń sọ tàbí tí wọn ò bá mọ ọ̀rọ̀ tó yẹ kí wọ́n lò. Àwọn aláwàdà máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ rírùn àtàwọn ọ̀rọ̀ oníṣekúṣe pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín. Àmọ́ ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ rírùn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀rín rárá. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti gba àwọn ará tó wà ní Kólósè nímọ̀ràn pé kí wọ́n dẹ́kun sísọ “ọ̀rọ̀ rírùn.” (Kólósè 3:8) Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará ní Éfésù pé ‘ẹ̀fẹ̀ rírùn’ wà lára àwọn ohun ‘tí kò yẹ ká máa mẹ́nu kàn’ láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́.—Éfésù 5:3, 4.

10 Inú Jèhófà kì í dùn sí ọ̀rọ̀ rírùn, kò sì yẹ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ máa fọ̀rọ̀ rírùn ṣayọ̀. Ká sòótọ́, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló máa jẹ́ ká kórìíra ọ̀rọ̀ rírùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù to “ìwà àìmọ́” mọ́ àwọn “iṣẹ́ ti ara,” èyí sì lè ní ọ̀rọ̀ rírùn nínú. (Gálátíà 5:19-21) Ọ̀rọ̀ pàtàkì lèyí o! Bí ẹnikẹ́ni bá kọtí ikún sí ìbáwí lórí ọ̀ràn lílo ọ̀rọ̀ rírùn, ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ tí ò buyì kúnni, ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́. *

11, 12. (a) Kí ni òfófó, ìgbà wo ni ṣíṣòfófó sì léwu? (b) Kí nìdí táwọn olùjọ́sìn Jèhófà ò fi gbọ́dọ̀ máa fọ̀rọ̀ èké bani jẹ́?

11 Òfófó tí ń pani lára, ìbanilórúkọjẹ́. Béèyàn bá ń yọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ sọ létí ẹlòmíì, òfófó ló ń ṣe yẹn. Ṣé gbogbo òfófó ló burú ni? Rárá o, pàápàá jù lọ bí ohun tá à ń sọ nípa onítọ̀hún bá jẹ́ àwọn ohun tó yẹ káwọn ẹlòmíì mọ̀, irú bí ọ̀rọ̀ nípa ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tàbí ẹni tó yẹ ká gbà níyànjú. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kì í fọ̀rọ̀ ara wọn ṣeré, wọ́n sì máa ń sọ ọ̀rọ̀ tó bá yẹ kí wọ́n sọ nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn fáwọn ẹlòmíì. (Éfésù 6:21, 22; Kólósè 4:8, 9) Àmọ́ ṣá o, òfófó lè burú tó bá lọ jẹ́ pé irọ́ là ń tàn kálẹ̀ nípa onítọ̀hún tàbí kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àṣírí ẹni náà la tú síta. Ohun tó burú jù nínú ẹ̀ ni pé, ó lè yọrí sí ìbanilórúkọjẹ́ èyí tó máa ń pani lára ní gbogbo ìgbà. Ìbanilórúkọjẹ́ ni “fífi ẹ̀sùn èké kanni, èyí tó lè buni kù tó sì ń sọni dèèyàn burúkú.” Bí àpẹẹrẹ, àwọn Farisí gbìdánwò láti fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ba Jésù lórúkọ jẹ́. (Mátíù 9:32-34; 12:22-24) Ìbanilórúkọjẹ́ sábà máa ń yọrí sí asọ̀.—Òwe 26:20.

12 Jèhófà kì í fojú tó dáa wo àwọn tó ń fi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ ba àwọn ẹlòmíì lórúkọ jẹ́ tàbí tí wọ́n fi ń fa ìpínyà. Ó sì kórìíra àwọn tó bá ń dá “asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.” (Òwe 6:16-19) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà di·aʹbo·los, la tú sí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, ọ̀kan lára àwọn orúkọ Sátánì sì ni. Òun ni “Èṣù,” ẹni ibi tó fọ̀rọ̀ èké ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́. (Ìṣípayá 12:9, 10) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ sọ ohunkóhun tó máa mú ká fìwà jọ èṣù. A ò fàyè gba ẹnikẹ́ni láti fọ̀rọ̀ èké bani lórúkọ jẹ́ nínú ìjọ torí ìyẹn ló máa ń fa àwọn iṣẹ́ ti ara bí “asọ̀” àti “ìpínyà.” (Gálátíà 5:19-21) Nítorí náà, kó o tó sọ ohunkóhun nípa ẹnikẹ́ni, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé: ‘Ṣé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni? Ṣó máa dáa kí n tan ọ̀rọ̀ náà kálẹ̀? Ṣó pọn dandan tàbí kẹ̀, ṣó tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu pé kí n sọ ọ̀rọ̀ náà fáwọn ẹlòmíì?’—Ka 1 Tẹsalóníkà 4:11.

13, 14. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ èébú ṣe máa ń nípa lórí àwọn tó ń gbọ́ ọ? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti kẹ́gàn àwọn ẹlòmíì, kí sì nìdí tí ẹni tó ń kẹ́gàn àwọn ẹlòmíì fi wà nínú ewu?

13 Èébú. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ẹyin lohùn, bó bá ti bọ́ kì í ṣe é kó jọ mọ́. Ká sòótọ́, àwọn ìgbà kan máa ń wà tí àìpé ẹ̀dá máa ń jẹ́ ká sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tá a máa wá kábàámọ̀ tó bá yá. Síbẹ̀, Bíbélì kì wá nílọ̀ lórí irú àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ ká máa gbọ́ nínú ilé Kristẹni tàbí nínú ìjọ. Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfésù 4:31) Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì pe “ọ̀rọ̀ èébú” ní “ọ̀rọ̀ burúkú,” “ọ̀rọ̀ tó ń bani jẹ́” àti “èpè.” Ọ̀rọ̀ èébú lè ba àwọn èèyàn lórúkọ jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn orúkọ ìnagijẹ tí kò buyì kúnni àti ṣíṣe lámèyítọ́ ẹnì kan ní gbogbo ìgbà ṣáá, ó sì lè jẹ́ kí wọ́n máa ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Èébú tètè máa ń dun àwọn ọmọdé kì í sì í pẹ́ táwọn náà á fi máa fi èébú dá a padà torí pé wọn ò dákan mọ̀.—Kólósè 3:21.

14 Ọ̀rọ̀ tó fakíki ni Bíbélì lò láti bẹnu àtẹ́ lu kíkẹ́gàn àwọn ẹlòmíì, ìyẹn fífi ọ̀rọ̀ èébú bu àwọn èèyàn kù. Ẹnikẹ́ni tó bá sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ dàṣà ń fi ara rẹ̀ sínú ewu, torí ó ṣeé ṣe kí wọ́n yọ ẹnikẹ́ni tó bá ń kẹ́gàn ẹlòmíì lẹ́gbẹ́, tó bá kọ̀ láti gba ìbáwí tí wọ́n fún un léraléra. Tí kò bá yí padà, ó tiẹ̀ lè pàdánù ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run ń mú bọ̀. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13; 6:9, 10) Ó dájú nígbà náà pé kò sí bá a ṣe fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run bọ́rọ̀ wa ò bá gbámúṣé, tí kò jóòótọ́, tí kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kì í gbéni ró.

Ọ̀RỌ̀ TÓ “DÁRA FÚN GBÍGBÉNIRÓ”

15. Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ló “dára fún gbígbéniró”?

15 Báwo la ṣe lè lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ bí Ẹni tó fún wa ṣe fẹ́ ká lò ó? Ṣó o rántí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé “àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró” ni ká máa sọ lẹ́nu? (Éfésù 4:29) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró tó sì ń fáwọn ẹlòmíì lókun. Ó gba kéèyàn ronú jinlẹ̀ kó tó lè máa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Bíbélì ò ṣòfin pé àwọn ọ̀rọ̀ kan ni ká máa sọ, bẹ́ẹ̀ ni kò la àwọn “ọ̀rọ̀ tí ó sunwọ̀n” tí Ọlọ́run fọwọ́ sí pé ká máa sọ lẹ́sẹẹsẹ. (Títù 2:8) Tá a bá fẹ́ máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó “dára fún gbígbéniró,” a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́ta tá a fi ń dá irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ mọ̀ yàtọ̀, ìyẹn ni pé wọ́n gbámúṣé, òótọ́ ọ̀rọ̀ ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́. Pẹ̀lú àwọn ohun tá a fi ń dá irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ mọ̀ yàtọ̀ lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká wá jíròrò díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tó dáa fún gbígbéniró.—Wo àpótí náà  “Ṣé Ọ̀rọ̀ Ẹnu Mi Ń Gbéni Ró?” tó wà lójú ìwé 140.

16, 17. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ẹlòmíì? (b) Àwọn àǹfààní wo la ní láti gbóríyìn fáwọn ẹlòmíì nínú ìjọ? nínú ìdílé?

16 Gbígbóríyìn fúnni látọkàn wá. Jèhófà àti Jésù mọ̀ pé a ní láti máa gbóríyìn fáwọn èèyàn ká sì fi hàn pé a mọyì wọn. (Mátíù 3:17; 25:19-23; Jòhánù 1:47) Àwa Kristẹni náà ní láti máa gbóríyìn fáwọn ẹlòmíì látọkàn wá. Kí nìdí? Ìwé Òwe 15:23 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí ó . . . bọ́ sí àkókò mà dára o!” Wá bi ara ẹ pé: ‘Báwo ló ṣe máa ń rí lára mi táwọn èèyàn bá gbóríyìn fún mi? Ṣó máa ń wú mi lórí tó sì máa ń mú kínú mi dùn?’ Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn tí ẹnì kan bá sọ sí wa látọkàn wá máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan mọyì wa, pé ẹnì kan bìkítà nípa wa àti pé ohun tá a ṣe tí wọ́n fi gbóríyìn fún wa tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Irú ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn bẹ́ẹ̀ máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ ṣiṣẹ́ kára lọ́jọ́ iwájú. Níwọ̀n bí ìwọ alára ti máa ń mọrírì ẹ̀ táwọn èèyàn bá gbóríyìn fún ẹ, ṣé kò wá ní dáa kí ìwọ náà ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti máa gbóríyìn fàwọn ẹlòmíì báyìí?—Ka Mátíù 7:12.

17 Fi kọ́ra láti máa wá ibi táwọn ẹlòmíì dáa sí, kó o sì máa gbóríyìn fún wọn. Bí àpẹẹrẹ nínú ìjọ, ó ṣeé ṣe kó o gbọ́ àsọyé tẹ́nì kan ti múra sílẹ̀ dáadáa, tàbí kẹ̀, o lè ṣàkíyèsí ọ̀dọ́ Kristẹni kan tó ń sapá láti lé àwọn àfojúsùn kan nípa tẹ̀mí bá, ó sì lè jẹ́ pé àgbàlagbà kan lo kíyè si pé kì í pa ìpàdé jẹ́ láìka ara tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ sí. Ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn tá a bá sọ fún irú àwọn wọ̀nyí lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin, kó sì fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Àwọn tọkọtaya ní láti máa gbóríyìn fún ara wọn nínú ìdílé, kí wọ́n sì máa fi hàn pé àwọn mọyì ara àwọn. (Òwe 31:10, 28) Pàápàá jù lọ, àwọn ọmọdé máa ń fẹ́ láti tẹ̀ síwájú tí wọ́n bá rí i pé a mọyì àwọn, a sì mọrírì ohun tí wọ́n ń ṣe. Bí oòrùn àti omi ṣe máa ń tu ewéko lára tó sì ń mú kó dàgbà, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn àti ọ̀rọ̀ tá a sọ láti fi hàn pé a mọyì àwọn ọmọdé ṣe máa ń tù wọ́n lára. Ẹ̀yin òbí, ẹ máa wáyè láti gbóríyìn fáwọn ọmọ yín torí àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ni àti ìsapá wọn láti máa hùwà rere. Irú ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ káwọn ọmọ rẹ nígboyà, kí ọkàn wọn sì balẹ̀ póhun tó dáa làwọ́n ń ṣe, ìyẹn á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní sísapá láti ṣe ohun tó tọ́.

18, 19. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti tu àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nínú, báwo la sì ṣe lè ṣe é?

18 Ìtùnú. Jèhófà bìkítà nípa “àwọn ẹni rírẹlẹ̀” àti “àwọn tí a tẹ̀ rẹ́.” (Aísáyà 57:15) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà wá níyànjú pé ká “máa tu ara [wa] nínú lẹ́nì kìíní-kejì” ká sì “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:11, 14) Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ń rí ìsapá wa láti tu àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tó sorí kọ́ nínú, ó sì mọyì rẹ̀.

Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó ń gbé àwọn ẹlòmíì ró

19 Kí la wá lè sọ láti gbé àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n ti rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí wọ́n sorí kọ́ ró? Má ṣe rò pé o gbọ́dọ̀ yanjú ìṣòro náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ díẹ̀ ló sábà máa ń ṣèrànwọ́. Jẹ́ kó dá ẹni tó sorí kọ́ náà lójú pé o bìkítà nípa rẹ̀, o ò sì ní fi í sílẹ̀. Sọ fún ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì náà pé kó jẹ́ kẹ́ ẹ jọ gbàdúrà. Nínú àdúrà rẹ, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí onítọ̀hún rí i pé òun tóbi lọ́wọ́ àwọn èèyàn àti pé Ọlọ́run pàápàá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Jákọ́bù 5:14, 15) Tún fi dá a lójú pé àwọn ará nínú ìjọ nílò rẹ̀, ó sì tóbi lọ́wọ́ wọn. (1 Kọ́ríńtì 12:12-26) Ka ẹsẹ Bíbélì kan láti fi dá a lójú pé òótọ́ ni Jèhófà bìkítà nípa rẹ̀. (Sáàmù 34:18; Mátíù 10:29-31) Tó o bá lo àkókò tó pọ̀ tó láti sọ àwọn “ọ̀rọ̀ rere” pẹ̀lú ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ náà tó o sì sọ ọ́ látọkàn wá, èyí á jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ wọ́n sì mọyì rẹ̀ pẹ̀lú.—Ka Òwe 12:25.

20, 21. Kí làwọn nǹkan tó ń mú kí ìmọ̀ràn gbéṣẹ́?

20 Ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́. Gbogbo wa ló yẹ ká máa gba ìmọ̀ràn látìgbà dégbà torí pé aláìpé ni wá. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.” (Òwe 19:20) Àwọn alàgbà nìkan kọ́ ló máa ń fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Àwọn òbí pàápàá máa ń fún àwọn ọmọ wọn nímọ̀ràn. (Éfésù 6:4) Ó sì lè pọn dandan pé káwọn arábìnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí náà fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin nímọ̀ràn. (Títù 2:3-5) Ìfẹ́ tá a ní sáwọn ẹlòmíì ló máa jẹ́ ká fún wọn nímọ̀ràn tí wọ́n lè gbà láìjẹ́ kí wọ́n dà bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti fún àwọn èèyàn ní irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀? Ohun mẹ́ta tó lè ràn wá lọ́wọ́ rèé: ìwà agbaninímọ̀ràn náà àti ohun tó wà lẹ́yìn ìmọ̀ràn yẹn, ìdí tó fi gba ẹni yẹn nímọ̀ràn àti ọ̀nà tó gbà fún un nímọ̀ràn ọ̀hún.

21 Ọwọ́ agbaninímọ̀ràn ló wà bóyá ìmọ̀ràn náà máa gbéṣẹ́ tàbí kò ní gbéṣẹ́. Bí ara rẹ pé, ‘Ìgbà wo ló máa ń rọrùn fún mi láti gba ìmọ̀ràn?’ Ó máa rọrùn fún ẹ láti gba ìmọ̀ràn tó o bá mọ̀ pé ẹni tó ń fún ẹ nímọ̀ràn bìkítà nípa ẹ, pé kì í ṣe pé inú ló bí i débẹ̀, tó o sì mọ̀ pé ire ẹ ló ń wá, tó fi fún ẹ nírú ìmọ̀ràn yẹn. Torí náà, ǹjẹ́ kò yẹ kí ìwọ náà máa fi àwọn kókó wọ̀nyí sọ́kàn tó o bá ń fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn? Ìmọ̀ràn tá a bá gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún máa ń yọrí sí rere. (2 Tímótì 3:16) Bóyá ńṣe là ń kà látinú Bíbélì ní tààràtà tàbí ńṣe la kàn fa ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ yọ, orí Ìwé Mímọ́ la gbọ́dọ̀ máa gbé ìmọ̀ràn tá à ń fún àwọn èèyàn kà. Nítorí náà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra kí wọ́n má bàa máa fipá mú àwọn ẹlòmíì láti tẹ̀ lé èrò wọn tàbí kí wọ́n máa yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ po kó lè dà bíi pé Bíbélì ti èrò wọn lẹ́yìn. Ìmọ̀ràn tún máa ń gbéṣẹ́ tó bá jẹ́ pé ọ̀nà tó tọ́ la gbà fún àwọn èèyàn. Ó máa ń rọrùn láti gba ìmọ̀ràn tá a bá fúnni pẹ̀lú inú rere, irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ kì í sì í bu ẹni tá a fún ní ìmọ̀ràn náà kù.— Kólósè 4:6.

22. Báwo lo ṣe pinnu láti máa lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ?

22 Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé ẹ̀bùn iyebíye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ sísọ. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló sì máa jẹ́ ká lo ẹ̀bùn náà lọ́nà tá ò fi ní ṣì í lò. Ẹ jẹ́ ká rántí pé ẹyin lohùn, bó bá ti bọ́ kì í ṣe é kó jọ mọ́. Ẹ jẹ́ ká sapá gidigidi nígbà náà láti máa lo ẹ̀bùn náà bí Ẹni tó fún wa ṣe fẹ́ ká lò ó, ìyẹn “fún gbígbéniró.” Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa fọ̀rọ̀ ẹnu wa gbé àwọn èèyàn ró, a ó sì máa fi tù wọ́n nínú, ó sì dájú pé ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 4 Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “ìfèrúyípo” nínú ìwé òwe 15:4 tún lè túmọ̀ sí “békebèke tàbí àyídáyidà.”

^ ìpínrọ̀ 7 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìmúlẹ̀mófo” tún lè túmọ̀ sí “aláìwúlò” àti “aláìléso.”—1 Kọ́ríńtì 15:17; 1 Pétérù 1:18.

^ ìpínrọ̀ 10 Bá a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìwà àìmọ́” nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ní ìtumọ̀ tó gbòòrò, ó sì lè ní ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀ nínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kì í ṣe gbogbo ìwà àìmọ́ ló máa yọrí sí ìgbẹ́jọ́, bí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ bá ń hùwà àìmọ́ tó burú jáì, tó sì kọ̀ láti ronú pìwà dà, ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́.—2 Kọ́ríńtì 12:21; Éfésù 4:19; wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2006.