Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 13

Àwọn Ayẹyẹ Tí Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí

Àwọn Ayẹyẹ Tí Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí

“Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—ÉFÉSÙ 5:10.

1. Irú àwọn èèyàn wo ni Jèhófà máa ń fà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kí sì nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí?

JÉSÙ sọ pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Bí Jèhófà bá ráwọn èèyàn bíi tìẹ tí wọ́n fẹ́ láti jọ́sìn rẹ̀ lẹ́mìí àti ní òtítọ́, ńṣe ló máa ń fà wọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àti Ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 6:44) Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà nìyẹn o! Àmọ́, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì gbọ́dọ̀ “máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú” nítorí olórí ẹlẹ̀tàn ni Sátánì.—Éfésù 5:10; Ìṣípayá 12:9.

2. Ṣàlàyé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn tó fẹ́ da ìsìn èké pọ̀ mọ́ ìsìn tòótọ́.

2 Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́bàá Òkè Sínáì yẹ̀ wò, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kí Áárónì ṣe ọlọ́run kan fáwọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ti ọkàn Áárónì wá, ó gbà láti ṣe ère oníwúrà kan fún wọn, ó sì wá sọ fún wọn pé Jèhófà ni ère náà dúró fún. Lẹ́yìn náà ló sọ fún wọn pé: “Àjọyọ̀ fún Jèhófà wà lọ́la.” Ṣé Jèhófà tiẹ̀ kọbi ara sí bí wọ́n ṣe da ìsìn èké pọ̀ mọ́ ìsìn tòótọ́ yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tà [3,000] ni Jèhófà pa lára àwọn tó bọ̀rìṣà yẹn. (Ẹ́kísódù 32:1-6, 10, 28) Kí la rí kọ́ nínú èyí? Ó kọ́ wa pé tá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, a ò gbọ́dọ̀ “fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan,” a sì gbọ́dọ̀ máa finú kan sin Jèhófà láìjẹ́ kí ohun àìmọ́ kankan ta bá òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Aísáyà 52:11; Ìsíkíẹ́lì 44:23; Gálátíà 5:9.

3, 4. Kí nìdí tó fi yẹ ká láwọn ìlànà Bíbélì lọ́kàn nígbà tá a bá ń gbé àwọn àṣà tó gbajúmọ̀ àtàwọn ayẹyẹ kan yẹ̀ wò?

3 Nígbà táwọn àpọ́sítélì wà láyé, wọ́n jà fitafita kí ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà má bàa wọnú ìsìn Kristẹni. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ tí ò nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà, ayẹyẹ wọn àtàwọn àjọ̀dún wọn wọnú ìsìn Kristẹni. Bó o ti ń ṣàgbéyẹ̀wò àlàyé tá a ṣe lórí díẹ̀ lára àwọn ayẹyẹ yìí, wàá kíyè sí bí wọ́n ṣe ń gbé ẹ̀mí ayé, èyí tó lòdì sí ẹ̀mí Ọlọ́run lárugẹ. Tá a bá dà á sílẹ̀, tá a tún un ṣà, ohun kan náà làwọn ayẹyẹ ayé yìí ń gbé lárugẹ, àwọn ni ohun tára ń yán hànhàn fún, ẹ̀kọ́ èké àti ìbẹ́mìílò. Àwọn nǹkan wọ̀nyí la sì mọ̀ mọ́ “Bábílónì Ńlá.” * (Ìṣípayá 18:2-4, 23) Má sì tún gbàgbé pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti rí àwọn ohun ìríra tó wà nínú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà níbi tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ayẹyẹ tí wọ́n mú wọnú ìsìn Kristẹni ti wá. Títí di báyìí, ohun ìríra làwọn ayẹyẹ wọ̀nyẹn ṣì jẹ́ fún un. Ẹ ò wá rí i nígbà náà pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ayẹyẹ wọ̀nyẹn ló yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa!—2 Jòhánù 6, 7.

4 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, a mọ̀ pé àwọn ayẹyẹ kan wà tí inú Jèhófà kò dùn sí. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì pé ká pinnu lọ́kàn wa pé a ò ní lọ́wọ́ sí wọn lọ́nàkọnà. Tá a bá ń ṣàyẹ̀wò ìdí tí inú Jèhófà ò fi dùn sírú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká lè dúró lórí ìpinnu wa láti má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ dídúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

OÒRÙN ÀKÚNLẸ̀BỌ NI WỌ́N SỌ DI KÉRÉSÌMESÌ

5. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé December 25 kọ́ ni wọ́n bí Jésù?

5 Bíbélì ò fìgbà kankan sọ rí pé àwọn kan ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù. Kò tiẹ̀ sẹ́ni tó mọ ọjọ́ tí wọ́n bí i. Àmọ́, ó dá wa lójú pé December 25 kọ́ ni wọ́n bí i, torí pé àkókò òtútù, tí yìnyín máa ń já bọ́ nìyẹn máa ń jẹ́ nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. * Lúùkù ṣáà sọ pé nígbà tí wọ́n bí Jésù, “àwọn olùṣọ́ àgùntàn [wà] . . . ní ìta” tí wọ́n ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn. (Lúùkù 2:8-11) Tó bá jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa ń wà “ní ìta” jálẹ̀ ọdún nìyẹn, ó ṣeé ṣe kí Lúùkù má pàfiyèsí sí i. Àmọ́, nítorí pé àkókò òtútù, tí yìnyín máa ń já bọ́ ni oṣù December ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, inú ilé làwọn darandaran ti máa ń bójú tó àwọn àgùntàn wọn, níwọ̀n bí kò ti lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa gbé “ní ìta.” Ìdí míì tá a tún fi mọ̀ pé kì í ṣe December 25 ni wọ́n bí Jésù ni ohun tó mú kí Jósẹ́fù àti Màríà dèrò Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìyẹn ni pé Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pàṣẹ pé káwọn èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀ ní ìlú ìbílẹ̀ wọn. (Lúùkù 2:1-7) Ó sì dájú pé Késárì ò ní fẹ́ pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fáwọn èèyàn tí ò fìgbà kan gba ti ìjọba Róòmù pé kí wọ́n lọ forúkọ sílẹ̀ ní ìlú ìbílẹ̀ wọn nírú àsìkò yẹn.

6, 7. (a) Ibo lọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àṣà Kérésìmesì ti ṣẹ̀ wá? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín báwọn èèyàn ṣe ń fúnra wọn lẹ́bùn nígbà Kérésì àti bó ṣe yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa fúnni lẹ́bùn?

6 Inú àwọn ayẹyẹ bí èyí tí wọ́n fi ń ṣe àyẹ́sí Saturn, ìyẹn òòṣà ohun ọ̀gbìn, nílùú Róòmù ni Kérésìmesì ti ṣẹ̀ wá kì í ṣe látinú Ìwé Mímọ́. Bákan náà, ìwádìí àwọn tó ṣe gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, fi hàn pé December 25 làwọn tó ń bọ òòṣà Mithra máa ń ṣe “ọjọ́ ìbí oòrùn àkúnlẹ̀bọ tí kò ṣeé borí.” Ó fi kún un pé, “ìgbà tí ẹgbẹ́ awo àwọn tó ń bọ oòrùn àkúnlẹ̀bọ túbọ̀ fìdí múlẹ̀ nílùú Róòmù ni wọ́n dá Kérésìmesì sílẹ̀,” ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ikú Kristi.

Ìfẹ́ ló ń sún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti fúnni lẹ́bùn

7 Nígbà táwọn abọ̀rìṣà bá ń ṣàwọn ayẹyẹ wọ̀nyí, wọ́n máa ń fúnra wọn lẹ́bùn, wọ́n á filé pọntí, wọ́n á fọ̀nà rokà; ohun táwọn tó ń ṣe Kérésìmesì sì ń ṣe lónìí gan-an nìyẹn. Bíi tìgbà yẹn, àwọn èèyàn máa ń fúnra wọn lẹ́bùn lónìí, àmọ́ kì í ṣe lọ́nà tí Pọ́ọ̀lù ní ká máa gbà ṣe é nínú 2 Kọ́ríńtì 9:7, níbi tó ti sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” Ní tàwọn Kristẹni tòótọ́, ìfẹ́ ló máa ń sún wọn láti fúnni lẹ́bùn, wọn ò ya ọjọ́ kankan sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tó yẹ kí wọ́n fúnni lẹ́bùn, wọn kì í sì í retí pé káwọn táwọn fún lẹ́bùn san án padà. (Lúùkù 14:12-14; ka Ìṣe 20:35) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n mọrírì gbígbà tí wọ́n gbara wọn lọ́wọ́ pákáǹleke táwọn èèyàn máa ń kó sí nígbà Kérésìmesì àti àìbalẹ̀ ọkàn tó máa ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn nítorí pé wọ́n yáwó ṣọdún.—Mátíù 11:28-30; Jòhánù 8:32.

8. Ṣé ẹ̀bùn ọjọ́ ìbí làwọn awòràwọ̀ fún Jésù? Ṣàlàyé.

8 Àmọ́, àwọn kan lè máa jiyàn pé, ṣebí àwọn awòràwọ̀ fún Jésù lẹ́bùn ọjọ́ ìbí? Rárá o. Fífún tí wọ́n fún Jésù lẹ́bùn wulẹ̀ jẹ́ àṣà àwọn èèyàn lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n sábà máa ń gbé irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ dání bí wọ́n bá fẹ́ lọ rí èèyàn pàtàkì kan fúngbà àkọ́kọ́. (1 Àwọn Ọba 10:1, 2, 10, 13; Mátíù 2:2, 11) Kódà, kì í ṣe alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù ni wọ́n wá. Jésù ti kúrò lọ́mọ ọwọ́ tó wà ní ibùjẹ ẹran nígbà táwọn awòràwọ̀ wọ̀nyẹn wá wò ó, ó ti tó ọmọ oṣù mélòó kan nígbà yẹn, wọ́n sì ti gbé e délé.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ỌJỌ́ ÌBÍ

9. Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjèèjì tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ sínú Bíbélì?

9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdùnnú máa ń ṣubú layọ̀ nígbà téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, Bíbélì ò fìgbà kan sọ pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run kankan ṣe ọjọ́ ìbí. (Sáàmù 127:3) Àbí ńṣe lọkàn àwọn tó kọ Bíbélì fò ó? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀, torí pé wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀kan ni ti Fáráò ará Íjíbítì, èkejì sì ni ti Hẹ́rọ́dù Áńtípà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 40:20-22; Máàkù 6:21-29) Àmọ́, kò sóhun rere tó tìdí ayẹyẹ méjèèjì jáde, pàápàá ti Hẹ́rọ́dù torí níbi ayẹyẹ náà ni wọ́n ti gé orí Jòhánù Arinibọmi.

10, 11. Ojú wo làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi ń wo ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, kí sì nìdí?

10 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀, The World Book Encyclopedia sọ pé: “Àṣà ìbọ̀rìṣà làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ka ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹnikẹ́ni sí.” Bí àpẹẹrẹ, àwọn Gíríìkì ayé ọjọ́un gbà gbọ́ pé ẹ̀mí kan wà tó máa ń tọ olúkúlùkù èèyàn lẹ́yìn látọjọ́ tí wọ́n bá ti bí i, kó bàa lè máa dáàbò bò ó. Ìwé The Lore of Birthdays sọ pé: “Ẹ̀mí yìí máa ń ní àjọṣe abàmì pẹ̀lú òòṣà àkúnlẹ̀bọ tó ni ọjọ́ tí wọ́n bí ẹni tó ń ṣọjọ́ ìbí náà.” Ọjọ́ sì ti pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ̀ pé ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìwòràwọ̀ àti ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí.

11 Yàtọ̀ sí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kì í ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí torí pé ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà ni àti pé ó la ìbẹ́mìílò lọ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí míì táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run látijọ́ kì í fi í ṣe é ni pé kò bá ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé mu. Kí nìdí? Ìdí ni pé onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni tọkùnrin tobìnrin wọn, wọn ò sì ka ọjọ́ ìbí wọn sí nǹkan bàbàrà tó fi yẹ kí wọ́n máa filé pọntí, fọ̀nà rokà. * (Míkà 6:8; Lúùkù 9:48) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ni wọ́n ń fògo fún, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye tó fi jíǹkí wọn, ìyẹn dídá tó dá wọn sáyé. *Sáàmù 8:3, 4; 36:9; Ìṣípayá 4:11.

12. Báwo ni ọjọ́ ikú ṣe lè sàn ju ọjọ́ ìbí lọ?

12 Báwọn olóòótọ́ èèyàn bá kú, Ọlọ́run kì í gbàgbé wọn, ó sì dájú pé ó máa jí wọn dìde. (Jóòbù 14:14, 15) Abájọ tí Oníwàásù 7:1 fi sọ pé: “Orúkọ sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.” Àjọṣe tó dáa tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run ní ti pé à ń sìn ín tọkàntọkàn ni “orúkọ” wa dúró fún. Ó bá a mu nígbà náà pé dípò ọjọ́ ìbí, ikú lohun kan ṣoṣo tá a pa láṣẹ fáwọn Kristẹni láti máa rántí, ìyẹn ikú Jésù ẹni tá a lè tipasẹ̀ “orúkọ” rere rẹ̀ rí ìgbàlà.—Lúùkù 22:17-20; Hébérù 1:3, 4.

BÍBỌ ÒÒṢÀ ÌBÍMỌLÉMỌ LÓ DI ỌDÚN ÀJÍǸDE

13, 14. Ibo gan-an lọdún àjíǹde ti ṣẹ̀ wá?

13 Ayẹyẹ àjíǹde Kristi laráyé sọ pé àwọn ń ṣe lọ́jọ́ ọdún àjíǹde, àmọ́ ká sòótọ́, inú ìsìn èké ni ọdún àjíǹde ti ṣẹ̀ wá. Ìwádìí ti fi hàn pé látinú orúkọ abo òòṣà Eostre tàbí Ostara táwọn ọmọ ilẹ̀ Jámánì tó tẹ̀ dó sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń bọ ni Easter tí wọ́n ń pè ní ọdún àjíǹde lédè Yorùbá ti ṣẹ̀ wá. Kí wá ni ẹyin àti ehoro ní í ṣe pẹ̀lú ọdún àjíǹde? Gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé ẹyin “làwọn èèyàn mọ̀ jù gẹ́gẹ́ bí àmì àtúnwáyé àti àjíǹde,” ọjọ́ sì ti pẹ́ tí wọ́n ti ń lo ehoro gẹ́gẹ́ bí àmì ìbímọlémọ. Nítorí náà, òòṣà ìbímọlémọ làwọn èèyàn ń kúnlẹ̀ bọ bí wọ́n bá láwọn ń ṣayẹyẹ àjíǹde Kristi nígbà ọdún àjíǹde. *

14 Ǹjẹ́ o rò pé Jèhófà máa fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa fi ààtò bíbọ òòṣà ìbímọlémọ ṣèrántí àjíǹde Ọmọ rẹ̀? Ká má rí i! (2 Kọ́ríńtì 6:17, 18) Kódà, Ìwé Mímọ́ ò tiẹ̀ fìgbà kankan pàṣẹ pé ká máa ṣèrántí àjíǹde Jésù, kò sì fọwọ́ sí i. Tá a bá wá lọ ń ṣèrántí àjíǹde Jésù tá a sì ń pè é ní ọdún àjíǹde, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ aláìṣòótọ́.

ÀJỌ̀DÚN HALLOWEEN KÌ Í ṢE ÀJỌ̀DÚN TÓ MỌ́

15. Ibo gan-an ni àjọ̀dún Halloween ti bẹ̀rẹ̀, kí ló sì ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ọjọ́ tí wọ́n yàn láti máa ṣayẹyẹ ọ̀hún?

15 Nígbà àjọ̀dún Halloween, àwọn èèyàn máa ń múra bí eégún àti láwọn ọ̀nà míì tó ń dẹ́rù bani, wọ́n á sì tún fi oríṣiríṣi aṣọ ṣara wọn lóge. Bá a bá sì tọpasẹ̀ rẹ̀, ó rọrùn láti rí i pé nínú ẹ̀ya Celt nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti lórílẹ̀-èdè Ireland làṣà náà ti ṣẹ̀ wá. Ọjọ́ tí òṣùpá àrànmọ́jú bá wáyé kẹ́yìn ṣáájú November 1 ni wọ́n máa ń ṣayẹyẹ bíbọ òòṣà Samhain, tórúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Òpin Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn.” Wọ́n gbà gbọ́ pé lásìkò táwọn bá ń bọ Samhain làwọn máa ń mú ìbòjú tó wà láàárín àwọn èèyàn àtàwọn ẹ̀mí àìrí kúrò, tíyẹn á sì fún àwọn ẹ̀mí rere àti búburú láyè láti lè máa rìn kiri nínú ayé. Wọ́n sì tún gbà gbọ́ pé àsìkò yẹn lẹ̀mí àwọn òkú máa padà sí agboolé wọn, torí náà gbogbo ilé ni wọ́n ti máa ń to oúnjẹ àtohun mímu sórí tábìlì, kí wọ́n lè fi tu àwọn òkú tí wọ́n fẹ́ gbà lálejò lójú. Torí náà, táwọn ọmọdé bá múra bí eégún lónìí tí wọ́n ń lọ láti ojúlé dé ojúlé, tí wọ́n ń ṣẹ̀rù ba àwọn èèyàn tí ò bá ti fún wọn ní nǹkan, ààtò ìbọ̀rìṣà Samhain ni wọ́n ń gbé lárugẹ láìmọ̀.

MÁ ṢE SỌ AYẸYẸ ÌGBÉYÀWÓ RẸ DI ẸLẸ́GBIN

16, 17. (a) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó fàwọn ìlànà Bíbélì ṣàyẹ̀wò àwọn àṣà àdúgbò lórí ìgbéyàwó? (b) Kí ló yẹ káwọn Kristẹni máa fi sọ́kàn tó bá dọ̀rọ̀ fífọ́n ìrẹsì tàbí àwọn nǹkan míì lọ́jọ́ ìgbéyàwó?

16 Láìpẹ́, a ò ní gbọ́ “ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó . . . mọ́ láé” nínú Bábílónì Ńlá. (Ìṣípayá 18:23) Kí nìdí? Ìdí kan ni pé Bábílónì Ńlá ní àwọn àṣà ìbẹ́mìílò kan tó lè sọ ìgbéyàwó di ẹlẹ́gbin látọjọ́ ayẹyẹ ìgbéyàwó.—Máàkù 10:6-9.

17 Àṣà orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Àwọn àṣà kan wà tó jọ pé kò sí nǹkan kan tó burú nínú wọn, àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn àṣà Bábílónì tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó máa mú ‘oríire’ bá tọkọtaya tàbí àwọn àlejò wọn ni. (Aísáyà 65:11) Ọ̀kan lára irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ni fífọ́n ìrẹsì, bébà wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ aláwọ̀ mèremère, nǹkan olómi, tàbí àwọn nǹkan míì dà sórí tọkọtaya lọ́jọ́ ìgbéyàwó. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìgbàgbọ́ pé oúnjẹ máa ń tu àwọn ẹ̀mí burúkú lójú tí kì í sì í jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ọkọ àti ìyàwó ní jàǹbá ni àṣà yìí ti wá. Láfikún, ó ti pẹ́ táwọn kan ti mọ ìrẹsì gẹ́gẹ́ bí àmì ìbímọlémọ, ìdùnnú àti ẹ̀mí gígùn. Ó dájú pé kò sẹ́ni tó fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tó máa lọ́wọ́ sírú àwọn àṣà tó ń buni kù wọ̀nyí.—Ka 2 Kọ́ríńtì 6:14-18.

18. Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló gbọ́dọ̀ máa wà lọ́kàn àwọn tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó àtàwọn tó bá wá yẹ́ wọn sí lọ́jọ́ ìgbéyàwó?

18 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tún gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn àṣà ayé tó lè bu iyì àti ẹ̀yẹ ọjọ́ ìgbéyàwó wọn kù tàbí tó lè nípa lórí ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í lo ẹ̀dà ọ̀rọ̀, wọn kì í sọ̀rọ̀ pálapàla, wọn kì í dápàárá rírùn tàbí kí wọ́n ṣàwọn àpọ́nlé tó lè mú kójú ti ọkọ àtìyàwó tàbí àwọn míì níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó. (Òwe 26:18, 19; Lúùkù 6:31; 10:27) Wọn kì í fẹ́ ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó lọ́nà táyé á gbọ́ tọ́run á mọ̀, torí pé ìyẹn ò fi hàn pé èèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími” ló jẹ́. (1 Jòhánù 2:16) Tó o bá ti ń múra láti ṣègbéyàwó, má gbàgbé pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kó o máa rántí ọjọ́ tó ṣe pàtàkì yìí sí rere. *

ṢÉ ÀÀTÒ ÌSÌN NI FÍFI IFE ỌTÍ GBÁRA?

19, 20. Kí ni ìwé kan sọ nípa fífi ife ọtí gbára, kí sì nìdí tí àwọn Kristẹni ò fi gbọ́dọ̀ bá wọn dá irú àṣà bẹ́ẹ̀?

19 Fífi ife ọtí gbára kì í ṣe nǹkan tuntun mọ́ níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó àtàwọn pọ̀pọ̀ṣìnṣìn míì. Ìwé International Handbook on Alcohol and Culture ti ọdún 1995 sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú àṣà títa ohun mímu sílẹ̀ láti fi júbà àwọn alálẹ̀ tàbí àwọn òòṣà kan . . . kí ẹbọ lè fín, tí wọ́n sì máa ń tọrọ ‘ẹ̀mí gígùn’ tàbí ‘àlàáfíà ara’ làṣà fífi ife ọtí gbára nígbà àṣeyẹ ti ṣẹ̀ wá.”

20 Ọ̀pọ̀ èèyàn lè má rò pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ni àṣà fífi ife ọtí gbára nígbà àṣeyẹ. Síbẹ̀, ńṣe làṣà nína ife ọtí sí “ọ̀run” dà bí ìgbà téèyàn ń tọrọ ìbùkún látọwọ́ ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó lágbára ju ẹ̀dá èèyàn lọ lọ́nà tí Ìwé Mímọ́ ò fọwọ́ sí.— Jòhánù 14:6; 16:23. *

“Ẹ̀YIN TÍ Ẹ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ, Ẹ KÓRÌÍRA OHUN BÚBURÚ”

21. Bí wọn ò tiẹ̀ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìjọsìn, àwọn ayẹyẹ wo làwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ bá wọn lọ́wọ́ sí, kí sì nìdí?

21 Ohun táwọn èèyàn ń ṣe lóde òní fi hàn pé wọn ò níwà, èyí sì jẹ́ ká mọ̀ pé Bábílónì Ńlá ni wọ́n ń fara wé lọ́nà kan tàbí òmíràn. Abájọ táwọn orílẹ̀-èdè kan fi máa ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn àjọyọ̀ ọdọọdún tàbí Mardi Gras níbi táwọn èèyàn ti máa ń jó ijó tó ń gbé ìṣekúṣe àti àṣà àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn sùn lárugẹ. Ǹjẹ́ ó bójú mu fún ‘ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà’ láti wà níbi àjọyọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí kó wò ó lórí fídíò? Ṣé ìyẹn máa fi hàn pé o kórìíra ohun búburú látọkàn wá? (Sáàmù 1:1, 2; 97:10) Ẹ ò rí i póhun tó dáa jù nígbà náà ni pé ká fara wé onísáàmù tó gbàdúrà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí”!—Sáàmù 119:37.

22. Ìgbà wo ni Kristẹni kan lè pinnu ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ pé òun á lọ síbi ayẹyẹ kan tàbí òun kò ní lọ?

22 Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra, kí ìwà wọn láwọn ọjọ́ táwọn èèyàn ayé ń ṣàjọyọ̀ má lọ fi hàn pé àwọn náà ń lọ́wọ́ sí i. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:31; wo àpótí náà  “Bá A Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání,” lójú ìwé 158 àti 159.) Àmọ́, ó kù sọ́wọ́ Kristẹni kan láti pinnu bóyá òun máa dá àwọn àṣà kan tàbí òun máa lọ síbi ayẹyẹ kan tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìsìn èké, tí kò jẹ mọ́ ìṣèlú, tí kò gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ, tí kò sì lòdì sí ìlànà Ìwé Mímọ́ kankan. Síbẹ̀, ó ní láti wo bọ́ràn náà ṣe máa rí lára àwọn ẹlòmíì, kó má lọ dí ohun ìkọsẹ̀ fún wọn.

FÒGO FÚN ỌLỌ́RUN NÍNÚ Ọ̀RỌ̀ ÀTI ÌWÀ RẸ

23, 24. Báwo la ṣe lè ṣàlàyé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà fáwọn èèyàn lọ́nà tó múná dóko?

23 Ọ̀pọ̀ ló máa ń lo àwọn ọjọ́ àṣeyẹ ayé yìí láti pe mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ síbi àpèjẹ ráńpẹ́. Torí náà, bí ẹnì kan bá rò pé ńṣe là ń fìgbádùn du ara wa nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́, a lè fi pẹ̀lẹ́tù ṣàlàyé fún un pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbádùn ìfararora tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa. (Òwe 11:25; Oníwàásù 3:12, 13; 2 Kọ́ríńtì 9:7) Àwa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa máa ń gbádùn ara wa láwọn àkókò míì nínú ọdún, àmọ́, torí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àtàwọn ìlànà òdodo rẹ̀, a ò ní fẹ́ dá àwọn àṣà tó lè bí i nínú bá a bá ń ṣe àwọn àjọyọ̀ tó ń múnú wa dùn wọ̀nyẹn.—Wo àpótí náà,  “Ìjọsìn Tòótọ́ Máa Ń Fúnni Láyọ̀ Tí Kò Lẹ́gbẹ́,” lójú ìwé 156.

24 Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ti jèrè ọkàn àwọn èèyàn nípa lílo àwọn kókó tó wà nínú orí 16 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? * láti ṣàlàyé fáwọn tó dìídì fẹ́ mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nípa àwọn àṣà wọ̀nyí. Má gbàgbé pé àfojúsùn wa ni láti jèrè ọkàn wọn kì í ṣe láti máa bá wọn jiyàn. Nítorí náà, tó o bá ń ṣàlàyé àwọn kókó wọ̀nyí, máa fọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n, máa ṣe sùúrù, kó o sì “jẹ́ kí àsọjáde [rẹ] máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”—Kólósè 4:6.

25, 26. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun kí wọ́n sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

25 Gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn Jèhófà, a ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀. A mọ̀dí tá a fi gba àwọn nǹkan kan gbọ́, tá à ń ṣàwọn nǹkan kan, tá a sì kọ̀ láti lọ́wọ́ sáwọn míì. (Hébérù 5:14) Nítorí náà, ẹ̀yin òbí ní láti kọ́ àwọn ọmọ yín lọ́nà tí wọ́n á lè gbà máa ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń fún ìgbàgbọ́ wọn lókun, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè fi Ìwé Mímọ́ dáhùn táwọn èèyàn bá béèrè ìdí tí wọ́n fi gba àwọn nǹkan kan gbọ́, á sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́.—Aísáyà 48:17, 18; 1 Pétérù 3:15.

26 Kì í ṣe páwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” kì í lọ síbi àṣeyẹ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nìkan ni, àmọ́ wọn kì í tún ṣe màgòmágó. Lónìí, àwọn èèyàn máa ń rò pé ẹni tó bá ń fòótọ́ inú hùwà ò dákan mọ̀. Àmọ́, bá a ṣe máa ṣàlàyé nínú orí tó kàn, ọ̀nà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí pé ká máa gbà hùwà lọ̀nà tó dáa jù.

^ ìpínrọ̀ 3 Wo àpótí náà,  “Ṣó Yẹ Kí N Lọ́wọ́ sí Ayẹyẹ Yẹn?” tó wà lójú ìwé 148 àti 149. A to àwọn ọlidé àtàwọn ayẹyẹ kan sínú ìwé atọ́ka, ìyẹn Watch Tower Publications Index, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

^ ìpínrọ̀ 5 Lójú ohun tí Bíbélì sọ àti ohun tí ìtàn jẹ́ ká mọ̀, oṣù Étánímù ti àwọn Júù lọ́dún 2 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n bí Jésù, oṣù Étánímù yìí sì wà láàárín oṣù September àti October lórí Kàlẹ́ńdà tá à ń lò báyìí.—Wo Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ìwé 56 àti 57, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

^ ìpínrọ̀ 11 Nínú Májẹ̀mú òfin, obìnrin tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ gbọ́dọ̀ rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Léfítíkù 12:1-8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òfin yìí ló jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní èrò tó tọ́ nípa ọmọ bíbí, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ni ò jẹ́ kí wọ́n gba àṣà ìbọ̀rìṣà ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, torí ńṣe lòfin yẹn ń dọ́gbọ́n rán wọn létí pé téèyàn bá bímọ ogún tó ń fún ọmọ náà ni ẹ̀ṣẹ̀.—Sáàmù 51:5.

^ ìpínrọ̀ 13 Ìwádìí tún ti fi hàn pé ọdún àjíǹde ní nǹkan ṣe pẹ̀lú bíbọ abo òòṣà ìbímọlémọ àwọn ará Fòníṣíà tí wọ́n ń pè ní Ásítátè torí ẹyin àti ehoro làwọn àmì rẹ̀. Nínú oríṣiríṣi ère Ásítátè, wọ́n máa ń yà á bí ẹni tó ní ẹ̀yà ìbálòpọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tàbí kí wọ́n ya ehoro sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ kó sì tún mú ẹyin dání.

^ ìpínrọ̀ 18 Wo àpilẹ̀kọ mẹ́ta tó dá lórí ayẹyẹ ìgbéyàwó àtàwọn pọ̀pọ̀ṣìnṣìn míì nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2006, lójú ìwé 18 sí 31.

^ ìpínrọ̀ 20 Wo Ilé Ìṣọ́ February 15, 2007, ojú ìwé 30 sí 31.

^ ìpínrọ̀ 24 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.