Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?

Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?

ORÍ 3

Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?

Kọ́kọ́ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:

Àwọn ànímọ́ wo ló ṣe pàtàkì lójú ẹ báyìí pé kẹ́ni tó o máa fẹ́ ní? Nínú àwọn àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí, fi àmì ✔ síwájú àwọn ànímọ́ mẹ́rin tó o gbà pé ó ṣe pàtàkì jù lọ.

□ Ó rẹwà □ Ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run

□ Ó kóni mọ́ra □ Ó ṣeé fọkàn tán

□ Ó gbajúmọ̀ □ Kì í hùwàkiwà

□ Ó máa ń ṣàwàdà □ Ó máa ń fètò sí ohun tó bá ń ṣe

Nígbà tó o ṣì kéré, ṣé ẹnì kan wà tọ́kàn ẹ máa ń fà sí ṣáá? Nínú àwọn àlàfo tó wà lókè yìí, fi àmì × síwájú ànímọ́ tó wù ẹ́ jù lọ lára onítọ̀hún nígbà yẹn.

KÒ SÓHUN tó burú nínú èyíkéyìí lára àwọn ànímọ́ tá a tò sókè yìí. Ó ní ibi tí gbogbo wọ́n dáa sí. Àmọ́, ǹjẹ́ o kíyè sí i pé nígbà tó o ṣì kéré, tọ́kàn ẹ ṣì máa ń fà sí ẹnì kan ṣáá, àwọn ànímọ́ tó jẹ mọ́ ẹwà ara lásán bí àwọn tá a tò sápá òsì yẹn ló sábà máa ń gbà ẹ́ lọ́kàn?

Àmọ́, bó o ṣe ń dàgbà, o bẹ̀rẹ̀ sí í lo agbára ìmòye rẹ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, bí àwọn tá a tò sápá ọ̀tún. Bí àpẹẹrẹ, o lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye pé ọmọbìnrin tó rẹwà jù lọ ládùúgbò yẹn lè má ṣeé gbára lé rárá tàbí kó jẹ́ pé oníwàkiwà lọmọkùnrin tó gbajúmọ̀ jù lọ ní kíláàsì yín. Bó o bá ti kọjá ìgbà ìbàlágà, ó ṣeé ṣe kó o wò ré kọjá àwọn ànímọ́ ti ara lásán kó o tó dáhùn ìbéèrè bíi, “Ṣé ẹni tó yẹ kí n fẹ́ nìyí?”

Kọ́kọ́ Mọra Ẹ Ná

Kó o tó lè mọ̀ bóyá ẹnì kan yẹ lẹ́ni tó o lè fẹ́, kọ́kọ́ mọra ẹ dáadáa. Kó o bàa lè mọ púpọ̀ sí i nípa ara ẹ, dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:

Ibo ni mo dáa sí? ․․․․․

Ibo ni mo kù sí? ․․․․․

Kí ni mò ń wá lára ẹni tí mo máa fẹ́, kí ló sì yẹ kí n ṣe nípa àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run? ․․․․․

Wàá rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ lèèyàn máa ṣe kó tó lè mọra ẹ̀ dáadáa, àmọ́ irú àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí náà ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀. Bó o bá ṣe mọra ẹ dunjú tó, bẹ́ẹ̀ lá á ṣe rọrùn fún ẹ tó láti wá ẹni tó máa mọyì ibi tó o dáa sí tá á sì lè fara da ibi tó o kù sí. * Àmọ́, bó o bá wá rò pé o ti rẹ́ni tó wù ẹ̀ ńkọ́?

Ṣé Ẹnikẹ́ni Ni Mo Lè Fẹ́?

“Á wù mí kí n mọ̀ ẹ́ ju báyìí lọ!” Ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn yẹn bá ẹ lójijì tàbí kó múnú ẹ dùn, ìyẹn sì sinmi lórí ẹni tó bá sọ bẹ́ẹ̀ sí ẹ. Ká wá sọ pé o gbà fónítọ̀hún ńkọ́? Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin tó yẹ kó o fẹ́ nìyẹn?

Ká sọ pé o fẹ́ ra bàtà tuntun kan. O lọ sí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta bàtà, o sì rí bàtà tó wù ẹ́ níbẹ̀. O wọ̀ ọ́ wò, àmọ́ ńṣe ló fún ẹ lẹ́sẹ̀ pinpin. Kí lo máa ṣe? Ṣé wàá ra bàtà náà bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀? Àbí wàá wá òmíràn tó bá ẹ lẹ́sẹ̀ mu. Ohun tó máa dáa jù lọ ni pé kó o dá bàtà náà pa dà, kó o sì wá òmíràn tó bá ẹ lẹ́sẹ̀ mu. Kò bọ́gbọ́n mu pé kó o máa wọ bàtà tó fún ẹ lẹ́sẹ̀ káàkiri!

Bọ́ràn ṣe máa ń rí nìyẹn béèyàn bá ń wá ẹni tó máa fẹ́. O lè rí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọkùnrin tàbí obìnrin tó ò ń bá pàdé ló wù ẹ́ láti fẹ́. Àmọ́, èyíkéyìí nínú wọn ò lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere fún ẹ. Ó ṣe tán, ẹni tó tẹ́ ẹ lọ́rùn tí ìwà ẹ̀ àtohun tó fẹ́ ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tìẹ, ló máa wù ẹ́ pé kó o fẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18; Mátíù 19:4-6) Ṣó o ti wá rí irú ẹni bẹ́ẹ̀? Bó o bá ti rí i, báwo ni wàá ṣe mọ̀ bóyá òun ló yẹ kó o fẹ́?

Má Wo Ojú Lásán

Kó o bàa lè dáhùn ìbéèrè tó gbẹ̀yìn yẹn, fara balẹ̀ ronú nípa ẹni tó o ní lọ́kàn láti fẹ́. Àmọ́ kó o ṣọ́ra o! Kó má lọ jẹ́ pé ohun tó o fẹ́ rí nìkan ni wàá máa rí. Torí náà, fara ẹ balẹ̀. Gbìyànjú láti mọ̀wà ẹni náà dáadáa. Ìyẹn sì máa béèrè pé kó o sapá gidigidi. Kò yẹ kíyẹn yà ẹ́ lẹnu ṣá o. Àpẹẹrẹ kan rèé: Jẹ́ ká sọ pé o fẹ́ ra ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ kan. Ǹjẹ́ o ò ní yẹ ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ náà wò dáadáa? Àbí bó bá ṣáà ti dáa lójú, ó parí náà nìyẹn? Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu pé kó o yẹ̀ ẹ́ wò tinú tẹ̀yìn, kó o sì tún wo bí ẹ́ńjìnnì ẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ sí pàápàá?

Wíwá ẹni téèyàn máa fẹ́ gbẹgẹ́ ju ríra ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ. Síbẹ̀, ojú lásán lọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ ń wò. Ó máa ń yá wọn lára láti sọ ohun tí wọ́n jọ fẹ́ràn. Wọ́n lè sọ pé: ‘Irú orin kan náà ló máa ń wù wá gbọ́.’ ‘Irú eré kan náà ló máa ń wù wá ṣe.’ ‘A kì í jiyàn lórí ohunkóhun!’ Àmọ́, bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, bó o bá ti kọjá ìgbà ìbàlágà, o ò ní máa wo ojú lásán mọ́. Wàá wá rí i pé o gbọ́dọ̀ fòye mọ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.”—1 Pétérù 3:4; Éfésù 3:16.

Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi máa pọkàn pọ̀ sórí bẹ́ ẹ ṣe jọ ń fara mọ́ ohun kan náà tó, fífiyè sí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ bí ẹ fara mọ́ ohun kan náà ló máa jẹ́ kó o mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, báwo ló ṣe máa ń ṣe bí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀? Ṣó máa ń rin kinkin pé òun lòun tọ̀nà, bóyá nípa ‘bíbínú fùfù’ tàbí kó máa ‘sọ̀rọ̀ èébú’? (Gálátíà 5:19, 20; Kólósè 3:8) Àbí olóye ẹ̀dá tí kì í rin kinkin mọ́ èrò rẹ̀ nítorí àtipa àlàáfíà mọ́ ni, bọ́ràn tó wà nílẹ̀ ò bá ṣáà ti ta ko ìlànà Bíbélì?—Jákọ́bù 3:17.

Ohun míì tó tún yẹ kó o gbé yẹ̀ wò nìyí: Ṣé ẹni tó máa ń dọ́gbọ́n darí ẹlòmíì ṣe nǹkan tó fẹ́ ni, ṣó máa ń fẹ́ ṣe bí ọ̀gá, àbí òjòwú ni? Ṣó máa ń fẹ́ mọ gbogbo ibi tó o bá ń rìn sí? Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nicole sọ pé: “Mo máa ń gbọ́ táwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ń bára wọn jà nítorí pé ọ̀kan lára wọn ò máa pe èkejì lemọ́lemọ́ lórí fóònù láti máa sọ gbogbo bó ṣe ń rìn fún un. Àpẹẹrẹ burúkú nìyẹn lójú tèmi.”—1 Kọ́ríńtì 13:4.

Àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìwà ẹnì kan àti irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́ lèyí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì pé kó o mọ ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹni tó o fẹ́ fẹ́. Ojú wo làwọn ẹlòmíì fi ń wò ó? Ó máa dáa kó o bá àwọn tó ṣe díẹ̀ tí wọ́n ti mọ ẹni yìí sọ̀rọ̀, irú bí àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. Ìyẹn lo máa fi mọ̀ bóyá wọ́n ń “ròyìn rẹ̀ dáadáa.”—Ìṣe 16:1, 2.

Ohun tó tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o ṣe àkọsílẹ̀ bí ẹni tó o fẹ́ fẹ́ ṣe ń ṣe sí nínú àwọn ohun tá a ti jíròrò.

Irú ẹni tó jẹ́ ․․․․․

Ìwà rẹ̀ ․․․․․

Ohun tí wọ́n ń sọ nípa ẹ̀ ․․․․․

Wàá tún jàǹfààní púpọ̀ nípa wíwo  Ṣé Mo Lè Fẹ́ Ẹ? lójú ìwé 39 tàbí  Ṣé Mo Lè Gbé E Sílé? lójú ìwé 40. Àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ìwọ àti onítọ̀hún á lè fẹ́ra yín.

Lẹ́yìn tó o bá ti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, bó o bá wá pinnu pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kọ́ lo máa fẹ́ ńkọ́? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìbéèrè ńlá tó o máa ní láti dáhùn ni pé:

Ṣé Ká Fira Wa Sílẹ̀?

Oore ńlá ló máa ń jẹ́ nígbà míì báwọn méjì bá fira wọn sílẹ̀. Gbé àpẹẹrẹ Jill yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Inú mi kọ́kọ́ máa ń dùn pé ẹni tí mò ń fẹ́ máa ń fẹ́ mọ ibi tí mo wà, ohun tí mò ń ṣe àti ọ̀dọ̀ ẹni tí mo wà. Àmọ́, ó bá a débi pé kò fẹ́ kí n da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì, àfi òun nìkan ṣáá. Kódà, ó máa ń jowú bó bá rí èmi àtàwọn aráalé mi pa pọ̀, àgàgà dádì mi. Nígbà tá a fira wa sílẹ̀, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ẹrù ńlá kan kúrò léjìká mi!”

Irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Sarah náà nìyẹn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí i pé John, ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n jọ ń fẹ́ra máa ń fọ̀rọ̀ kanni lábùkù, ó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn, ó sì máa ń ráwọn èèyàn fín. Sarah rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ọjọ́ kan wà tó pẹ́ kó tó délé wa, ó ti tó wákàtí mẹ́ta tí mo ti ń dúró dè é! Nígbà tó kanlẹ̀kùn, mọ́mì mi ló lọ ṣílẹ̀kùn fún un. Àmọ́ kò kí wọn, ọ̀dọ̀ mi ló ń bọ̀ tààràtà bó ṣe gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, ó wá sọ fún mi pé: ‘Jẹ́ ká lọ, o ò mọ̀ pá a ti pẹ́ ni?’ Dípò kó sọ pé òun ti pẹ́,’ ó ní, ‘A ti pẹ́.’ Èmi tiẹ̀ retí pé kó ní kí wọ́n máà bínú, kó sì ṣàlàyé ohun tó mú kó pẹ́ dé. Àti pé èwo ni ti mọ́mì mi tó fojú pa rẹ́!” Ti pé ẹnì kan hùwà tá ò retí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ò fi dandan ní ká sọ pá ò ṣe mọ́. (Sáàmù 130:3) Àmọ́ nígbà tí Sarah wá rí i pé bí John ṣe máa ń ṣe nìyẹn, kì í wulẹ̀ ṣe pé ó ṣèèṣì, ó kúkú pinnu pé káwọn fira àwọn sílẹ̀.

Bíi ti Jill àti Sarah, bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ náà rí i pé ọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín ò wọ̀ mọ́ ńkọ́? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe gbójú fo bó ṣe ń ṣe ẹ́! Ó lè má rọrùn lóòótọ́, àmọ́ ohun tó máa dáa jù ni pé kẹ́ ẹ fira yín sílẹ̀. Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” Bí àpẹẹrẹ, bó o bá bá ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìwà tá a tò sábẹ́ ibi tí ìṣòro ti lè jẹ yọ lójú ìwé 39 àti 40 lọ́wọ́ ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín, ohun tó máa dáa jù ni pé kẹ́ ẹ fòpin sí àjọṣe yẹn, àyàfi tí ẹni tọ́ràn kàn bá ṣàtúnṣe. Lóòótọ́ o, ó lè má rọrùn láti fòpin sí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ àjọṣe tó wà títí lọ ni ìgbéyàwó. Torí náà, bọ́rọ̀ ò bá wọ̀ mọ́, ó sàn kéèyàn jẹ̀rora ẹ̀ fúngbà díẹ̀, ju kó fagídí tọrùn bọ̀ ọ́, kó wá máa jẹ̀ka àbámọ̀ títí lọ lẹ́yìn náà!

Bó O Ṣe Máa Sọ fún Un

Báwo lo ṣe lè fòpin sí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀? Kọ́kọ́ mọ bó ṣe yẹ kó o sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ibi tó yẹ kó o ti sọ ọ́, àti àkókò tó yẹ kó o sọ ọ́? Bíi báwo? Ó dára, ronú nípa bó o ṣe máa fẹ́ kéèyàn sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ẹ. (Mátíù 7:12) Ṣó o máa fẹ́ kó sọ ọ́ fún ẹ níṣojú àwọn ẹlòmíì? Kò dájú pé wàá fẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Kò dára kéèyàn fòpin sí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ lórí tẹlifóònù, lẹ́tà orí fóònù alágbèéká, tàbí lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà, àyàfi bí kò bá sí ọgbọ́n míì téèyàn lè dá sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, wá àkókò, kó o sì tún wá ibi tó dáa tẹ́yin méjèèjì á ti lè jíròrò ọ̀ràn pàtàkì náà.

Bó bá wá tó àkókò àtisọ̀rọ̀, kí ló yẹ kó o sọ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa “sọ òtítọ́” fúnra wọn. (Éfésù 4:25) Nítorí náà, ohun tó dáa jù lọ ni pé kó o fọgbọ́n sọ ọ́, àmọ́ jẹ́ kó ṣe kedere. Ṣàlàyé ìdí tó o fi rò pé kò ní ṣeé ṣe fún láti fẹ́ ẹ. Kò dìgbà tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń to gbogbo àléébù rẹ̀ níkọ̀ọ̀kan tàbí tó o bá ń dá a lẹ́bi ṣáá. Àní sẹ́, dípò tí wàá fi sọ pé, “O ò” ṣe tibí, “o ò” ṣe tọ̀hún, ó máa sàn kó o lo èdè tó fi bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ hàn, bíi “Mò ń fẹ́ ẹni tó lè . . . ” tàbí “Mo lérò pé a gbọ́dọ̀ fòpin sí àjọṣe yìí torí pé . . . ”

Irú àkókò yìí kọ́ ni wàá máa ṣe mẹ-in mẹ-in tàbí tí wàá jẹ́ kó yí ẹ lérò pa dà. Rántí pé ohun pàtàkì kan ló mú kó o fẹ́ láti fòpin sí àjọṣe náà. Torí náà, jẹ́ ọlọgbọ́n bí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín bá ń gbìyànjú láti dọ́gbọ́n yí ẹ lérò pa dà. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lori sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti fòpin sí àjọṣe tó wà láàárín wa, ẹni tá a jọ ń fẹ́ra tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Mo lérò pé torí kí n lè máa káàánú ẹ̀ ló fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dùn mí gan-an. Àmọ́ mi ò tìtorí ìyẹn yí ìpinnu mi pa dà.” Bíi ti Lori, mọ ohun tó o fẹ́. Má sì ṣe yí ìpinnu rẹ pa dà. Jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́.Jákọ́bù 5:12.

Ohun Tó Lè Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tẹ́ Ẹ Bá Fira Yín Sílẹ̀

Má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bọ́rọ̀ náà bá ń dùn ẹ́ fún àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tẹ́ ẹ ti fira yín sílẹ̀. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Mo ti di aláìbalẹ̀-ọkàn, mo ti tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó; láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́.” (Sáàmù 38:6) Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kan tí wọ́n fẹ́ ẹ fún rere, tí wọ́n sì fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ lè gbà ẹ́ níyànjú pé kẹ́ ẹ máa bá eré ìfẹ́ yín lọ. Ṣọ́ra o! Ìwọ ni ìpinnu tó o bá ṣe máa já lé léjìká, kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí wọ́n ń fẹ́ ẹ fún rere. Nítorí náà má ṣe bẹ̀rù láti dúró lórí ìpinnu ẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà lè bà ẹ́ nínú jẹ́.

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, bó pẹ́ bó yá, ọ̀rọ̀ náà á kúrò lọ́kàn ẹ. Ní báyìí ná, ṣé wàá kúkú ṣe àwọn ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú ẹ̀dùn ọkàn rẹ, bí irú èyí tó wà nísàlẹ̀ yìí?

Sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún ẹnì kan tó o lè finú hàn. * (Òwe 15:22) Gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. (Sáàmù 55:22) Máa wá nǹkan ṣe. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Má máa dá wà! (Òwe 18:1) Máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì tí wọ́n lè gbé ẹ ró. Máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Fílípì 4:8.

Bó bá tún yá, o lè rí ẹlòmíì tẹ́ ẹ lè jọ fẹ́ra yín. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wàá lo ọgbọ́n tó o ti kọ́ láti fi wo bí onítọ̀hún ṣe rí gan-an. Ó ṣeé ṣe nígbà yẹn kí ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè náà, “Ṣé ẹni tó yẹ kí n fẹ́ nìyí?” jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni!

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 31, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Bó o bá ti lẹ́ni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín, báwo lẹ ò ṣe ní ki àṣejù bọ bẹ́ ẹ ṣe ń fìfẹ́ hàn síra yín?

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 17 O lè túbọ̀ mọra ẹ dunjú nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó wà ní Orí 1, lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Ṣó O Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó?”

^ ìpínrọ̀ 45 Àwọn òbí ẹ tàbí àwọn míì tó jẹ́ àgbàlagbà, bí àwọn alàgbà nínú ìjọ, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. O tiẹ̀ lè rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ ti ṣẹlẹ̀ sáwọn náà rí nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.Òwe 20:11.

ÌMỌ̀RÀN

Ẹ jọ máa ṣàwọn nǹkan tá á firú ẹni tẹ́ ẹ jẹ́ hàn:

● Ẹ jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

● Ẹ kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe jọ ń ṣe sí láwọn ìpàdé ìjọ àti lóde ẹ̀rí.

● Ẹ jọ máa kópa nínú títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe àti kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ìwádìí ti fi hàn léraléra pé ó ṣeé ṣe kí tọkọtaya tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra kọra wọn sílẹ̀.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí ọkàn mi bá ń fà sí aláìgbàgbọ́, màá ․․․․․

Kí n bàa lè mọ ohun táwọn ẹlòmíì ń sọ nípa ẹni tí mò ń fẹ́, mo lè ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Àwọn ànímọ́ dáadáa wo ló máa mú kó o jẹ́ ọkọ tàbí aya rere?

Àwọn ànímọ́ pàtàkì wo ló máa wù ẹ́ pé kẹ́ni tó o máa fẹ́ ní?

Àwọn ọ̀ràn tó díjú wo ló lè wáyé tó o bá fẹ́ ẹnì kan tí ẹ̀sìn rẹ̀ yàtọ̀ sí tìẹ?

Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà mọ púpọ̀ sí i nípa ìwà ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra àti ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹ̀?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 37]

“Bí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra bá ṣe ń ṣe sáwọn aráalé rẹ̀ ló ṣe máa ṣe síwọ náà.”—Tony

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 34]

“Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀”

“Má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà gbà pé ìlànà Bíbélì tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 6:14 yìí, bọ́gbọ́n mu. Síbẹ̀, ó lè máa wù ẹ́ kó o fẹ́ aláìgbàgbọ́. Kí nìdí? Nígbà míì, ó kàn lè jẹ́ ẹwà ẹ̀ ló ń dá ẹ lọ́rùn. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mark sọ pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń bá ọmọbìnrin náà pàdé níbi tá a ti ń dára yá. Láìlọ bá a, á wá sọ́dọ̀ mi, á sì máa bá mi sọ̀rọ̀. Kò ṣòro rárá láti bá a ṣọ̀rẹ́.”

Bó o bá rántí irú ẹni tó o jẹ́, tó ò fẹ́ ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì, tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú ẹ débi pé kì í ṣe tinú ẹ ṣáá lo máa ń ṣe, ó yẹ kó o mọ ohun tí wàá ṣe. Bó ti wù kí aláìgbàgbọ́ kan rẹwà tó, kó fani mọ́ra tó, tàbí kó jẹ́ olódodo tó, jẹ́ kó yé ẹ pé ní mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i.—Jákọ́bù 4:4.

Àmọ́ ṣá o, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Cindy ti wá rí i pé, bí ìfẹ́ ẹnì kan bá ti kó síni lórí, kì í rọrùn láti fòpin sí i. Ó sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń sunkún. Ọkàn mi kì í kúrò lára ọmọkùnrin náà, àní nígbà tí mo bá wà nípàdé pàápàá. Mo fẹ́ràn rẹ̀ gan-an débi pé ikú yá mi lára ju kí n pàdánù ọmọkùnrin náà lọ.” Kò pẹ́ púpọ̀ ṣá tí Cindy fi rí ọgbọ́n tó wà nínú ohun tí mọ́mì ẹ̀ ń sọ fún un nípa fífẹ́ aláìgbàgbọ́. Ó sọ pé: “Bémi àti ẹ̀ ṣe fira wa sílẹ̀ yẹn ló dáa. Ó dá mi lójú gbangba pé Jèhófà á pèsè ọkọ tèmi fún mi.”

Ṣé bíi ti Cindy lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì! O lè fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí rẹ. Ohun tí Jim ṣe nìyẹn nígbà tí ìfẹ́ ọmọbìnrin kan níléèwé wọn kó sí i lórí. Ó sọ pé: “Ìgbà tó yá ni mo ní káwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn náà. Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ gan-an nìyẹn tí mo fi yanjú ìṣòro náà.” Àwọn alàgbà ìjọ pẹ̀lú lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. O ò ṣe sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ọ̀kan nínú wọn?—Aísáyà 32:1, 2.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 39]

 Tí mo kọ èrò mi sí

Ṣé Mo Lè Fẹ́ Ẹ?

Kòṣeémánìí

□ Báwo ló ṣe máa ń lo àṣẹ tí wọ́n bá gbé lé e lọ́wọ́?—Mátíù 20:25, 26.

□ Kí làwọn àfojúsùn rẹ̀?—1 Tímótì 4:15.

□ Ṣó ti ń sapá báyìí kó bàa lè lé àwọn àfojúsùn yẹn bá?—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.

□ Báwo ló ṣe ń ṣe sáwọn ará ilé ẹ̀?—Ẹ́kísódù 20:12.

□ Àwọn wo ló ń bá rìn?—Òwe 13:20.

□ Kí lọ̀rọ̀ ẹ̀ máa ń dá lé?—Lúùkù 6:45.

□ Báwo lọ̀ràn owó ṣe máa ń rí lára ẹ̀?—Hébérù 13:5, 6.

□ Irú eré ìnàjú wo ló fẹ́ràn láti máa ṣe?—Sáàmù 97:10.

□ Báwo ló ṣe ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?—1 Jòhánù 5:3.

Irú Ẹni Tó Yẹ Kó Jẹ́

□ Ṣé òṣìṣẹ́ kára ni?—Òwe 6:9-11.

□ Ṣé kì í náwó nínàákúnàá?—Lúùkù 14:28.

□ Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní rere?—Ìṣe 16:1, 2.

□ Ṣó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò?—Fílípì 2:4.

Ibi Tí Ìṣòro Ti Lè Jẹ Yọ

□ Ṣé kì í pẹ́ bínú?—Òwe 22:24.

□ Ṣó máa ń fẹ́ bá ẹ ṣèṣekúṣe?—Gálátíà 5:19.

□ Ṣé oníjà ni àbí ó máa ń bú èèyàn?—Éfésù 4:31.

□ Ṣé bí ò bá tíì rí ọtí líle kò lè gbádùn ara ẹ̀?—Òwe 20:1.

□ Ṣé òjòwú àti onímọ̀-tara-ẹni nìkan ni?—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 40]

 Tí mo kọ èrò mi sí

Ṣé Mo Lè Gbé E Sílé?

Kòṣeémánìí

□ Báwo ló ṣe ń tẹrí ba sí nínú ilé àti nínú ìjọ? —Éfésù 5:21, 22.

□ Báwo ló ṣe ń ṣe sáwọn ará ilé ẹ̀?—Ẹ́kísódù 20:12.

□ Àwọn wo ló ń bá rìn?—Òwe 13:20.

□ Kí lọ̀rọ̀ ẹ̀ máa ń dá lé?—Lúùkù 6:45.

□ Báwo lọ̀ràn owó ṣe máa ń rí lára ẹ̀?—1 Jòhánù 2:15-17.

□ Kí làwọn àfojúsùn rẹ̀?—1 Tímótì 4:15.

□ Ṣó ti ń sapá báyìí láti lé àwọn àfojúsùn yẹn bá?—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.

□ Irú eré ìnàjú wo ló fẹ́ràn láti máa ṣe?—Sáàmù 97:10.

□ Báwo ló ṣe ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?—1 Jòhánù 5:3.

Irú Ẹni Tó Yẹ Kó Jẹ́

□ Ṣé òṣìṣẹ́ kára ni?—Òwe 31:17, 19, 21, 22, 27.

□ Ṣé kì í náwó nínàákúnàá?—Òwe 31:16, 18.

□ Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní rere?—Rúùtù 3:11.

□ Ṣó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò?—Òwe 31:20.

Ibi Tí Ìṣòro Ti Lè Jẹ Yọ

□ Ṣé alásọ̀ ni?—Òwe 21:19.

□ Ṣó máa ń fẹ́ kó o bá òun ṣèṣekúṣe?—Gálátíà 5:19.

□ Ṣó máa ń bú èèyàn àbí oníjà ni?—Éfésù 4:31.

□ Ṣé bí ò bá tíì rọ́tí líle kò lè gbádùn ara ẹ̀?—Òwe 20:1.

□ Ṣé òjòwú àti onímọ̀-tara-ẹni nìkan ni?—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Gbogbo bàtà kọ́ ló lè bá ẹ lẹ́sẹ̀ mu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni gbogbo àwọn tó ò ń bá pàdé ò lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere fún ẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ṣó o rò pé ó bọ́gbọ́n mu kó o wo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tinú tòde kó o tó rà á? Ṣé kò wá yẹ kó o ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ bó o bá fẹ́ yan ẹni tó o máa fẹ́!